Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 28


Ìpín 28

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, ní Fayette, New York, ní Oṣù Kẹsãn 1830. Hiram Page, ọmọ ìjọ kan, ní òkúta kan ó sì jẹ́wọ́ pé òun máa ngba àwọn ìfihàn nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìgbéga Síónì àti ètò Ìjọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìjọ ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ṣì ní ọ̀nà, àní Oliver Cowdery náà fi àṣìṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ní ipa ní orí òun. Ní àìpẹ́ sí àkókò ìpàdé àpéjọpọ̀ kan, Wòlíì béèrè tọkàntọkàn lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ yìí, ìfihàn yìí sì tẹ̀lé.

1–7, Joseph Smith ni ó mú kọ́kọ́rọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ lọ́wọ́, àti pé òun nìkan ni ó lè gba àwọn ìfihàn fún ìjọ; 8–10, Oliver Cowdery yío wàásù fún àwọn ara Lámánì; 11–16, Sátánì tan Hiram Page jẹ ó sì fún un ni àwọn ìfihàn tí kìí ṣe òtítọ́.

1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, Oliver, pé a ó fi fún ọ pé àwọn ọmọ ìjọ yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo èyíkéyìí tí ìwọ bá kọ́ wọn nípasẹ̀ Olùtùnú, nípa àwọn ìfihàn àti àwọn àṣẹ tí èmi ti fún ọ.

2 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, a kì yíò yan ẹnikẹ́ni láti gba àwọn àṣẹ àti àwọn ìfihàn nínú ìjọ yìí bí kòṣe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, nítorí òun gba wọn àní bíi Mose.

3 Àti pé ìwọ nilati jẹ́ olùgbọ́ràn sí àwọn ohun èyítí èmi yíò fi fún un, àní bíi ti Aárónì, láti kéde ní òtítọ́ àwọn àṣẹ àti àwọn ìfihàn, pẹ̀lú agbára àti àṣẹ sí ìjọ.

4 Àti pé bí Olùtùnú bá darí rẹ nígbàkúgbà láti sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni, tàbí nígbà gbogbo nípa ọ̀na àṣẹ sí ìjọ, ìwọ lè ṣe èyí.

5 Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọ ìwé nípa ti àṣẹ, ṣùgbọ́n nípa ọgbọ́n;

6 Àti pé ìwọ kò gbọdọ̀ pàṣẹ fún ẹni náà tí ó wà ní ipò olórí fún ọ, àti ẹnití ó jẹ́ olórí fún ìjọ;

7 Nítorí èmi ti fún un ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ohun ìjìnlẹ̀, àti àwọn ìfihàn tí a ti fi èdídí dì, títí èmi yíò fi yàn ẹlòmíràn fún wọn dípò rẹ̀.

8 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ pé ìwọ yíò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì ìwọ yíò sì wàásù ìhìnrere mi fún wọn; àti níwọ̀nbí wọ́n bá gba àwọn ìkọ́ni rẹ, ìwọ yíò mú ki a dá ìjọ mi sílẹ̀ ní ààrin wọn; àti pé ìwọ yíò sì gba àwọn ìfihàn, ṣùgbọ́n máṣe kọ wọ́n gẹ́gẹ́bí àṣẹ.

9 Àti pé nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ pé a kò fi hàn, àti pé ẹnikẹ́ni kò mọ ibi tí a ó kọ́ ìlú nlá Síónì sí, ṣùgbọ́n a ó fi fúnni lẹ́hìnwá. Kíyèsíi, mo wí fún ọ pé yíò wà ní ìkángun ààlà àwọn ará Lámánì.

10 Ìwọ kì yíó kúrò ní ìhín yìí títí ìpàdé àpéjọpọ̀ yíò fi parí; àti pé ìránṣẹ́ mi Joseph ni a ó yàn bí ààrẹ ní orí ìpàdé náà pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níbẹ̀, àti pé ohun tí ó bá sọ fún ọ ni kí ìwọ ó wí.

11 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ìwọ yíò mú arákùnrin rẹ, Hiram Page, ní ààrin òun ati ìwọ nìkan, kí o sì sọ fún un pé àwọn nkan tí òun ti kọ láti ara òkúta náà kìí ṣe láti ọwọ́ èmi àti pé Sátánì tàn án jẹ;

12 Nítorí, kíyèsíi, a kò tíì yan àwọn ohun wọ̀nyí fún un, bẹ́ẹ̀ni a kì yíò yan ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni nínú ìjọ yìí tí ó lòdì sí àwọn májẹ̀mú ìjọ.

13 Nítorí ohun gbogbo ni a gbọ́dọ̀ ṣe pẹ̀lú ètò, àti nípa ìfohùnṣọ̀kan nínú ìjọ, pẹ̀lú àdúrà ìgbàgbọ́.

14 Àti pé ìwọ yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ láti yanjú gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, gẹ́gẹ́bí àwọn májẹmú ti ìjọ, kí ìwọ ó tó rin ìrìnàjò rẹ lààrin àwọn ará Lámánì.

15 Àti pé a ó fi fún ọ láti ìgbà tí ìwọ yíó lọ, títí di ìgbà tí ìwọ yíò padà dé, ohun tí ìwọ yíò ṣe.

16 Àti pé ìwọ gbọ́dọ̀ la ẹnu rẹ nígbà gbogbo, ní kíkéde ìhìnrere mi pẹ̀lú ìró ìdùnnú. Àmín.