Ìpín 116
Àyọkúrò kan láti inú ìtàn Joseph Smith, tó nṣe àtúnsọ ìfihàn kan ti a fifún Wòlíì Joseph Smith, nítòsí Ọkọ̀ Oju-omi Fẹrí ti Wight, ní ibìkan tí à pè ní Spring Hill, ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Daviess, Missouri, Oṣù Karun tàbí Oṣù Kẹfà 1838.
1 A sọ Spring Hill ní orúkọ Adam-ondi-Ahman, láti ọwọ́ Olúwa nítorípé, ni òun wí, ó jẹ́ ibi tí Ádámù yíò wá láti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò, tàbí tí Ẹni-àrúgbó Ọjọ́ náà yíò ti jókòó, bí a ṣe sọ nípasẹ̀ wòlíì Daniẹli.