Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 24


Ìpín 24

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennsylvania, ní Oṣù Keje 1830. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pé oṣù mẹ́rin tí a kó ìjọ náà jọ, inúnibíni ti ó ndojúkọ ìjọ náà ti le, àti pé àwọn olórí níláti wá ààbò nípa fífi ara pamọ́ fún ìgbà díẹ̀. Àwọn ìfihàn mẹ́ta wọ̀nyí ni a fi fúnni ní àkókò yìí láti mú wọn lọ́kàn le, fún wọn ní ìwúrí, àti láti kọ́ wọn.

1–9, Joseph Smith ni a pè láti túmọ̀, wàásù, àti láti sọ àsọyé àwọn ìwé mímọ́; 10–12 Oliver Cowdery ni a pè láti wàásù ìhìnrere; 13–19, Òfin náà ni a fi hàn nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu, àwọn ègún, gbígbọn erùpẹ̀ ẹsẹ̀ bàtà ẹni sílẹ̀, àti lílọ láì mú owó tàbí aṣọ ìpààrọ̀.

1 Kíyèsíi, ìwọ ni a pè tí a sì yàn láti kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi; èmi sì ti gbé ọ sókè kúrò nínú àwọn ìpọ́njú rẹ, mo sì ti fún ọ ní ìmọ̀ràn, pé a ti gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, àti pé a ti gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn agbára Sátánì àti òkùnkùn!

2 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò le yọ̀ọ̀da rẹ nínú àwọn ìrékọjá rẹ; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, máa lọ ní ọ̀nà rẹ kí o má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.

3 Gbé ipò iṣẹ́ rẹ ga; àti pé lẹ́hìn tí o bá ti fúrúgbìn sínú àwọn oko rẹ tí ìwọ sì ti dáàbò bo wọ́n, lọ́ kánkán sí ìjọ èyítí ó wà ní Colesville, Fayette, àti ní Manchester, wọn yíò sì ràn ọ́ lọ́wọ́; àti pé èmi yíò bùkún wọn nínú ẹ̀mí àti ní ti ara;

4 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà ọ́, èmi yíò rán ègún sí orí wọ̀n dípò ìbùkún.

5 Àti pé ìwọ yíò tẹ̀ síwájú ní kíké pe Ọlọ́run ní orúkọ mi, àti ní kíkọ àwọn ohun èyítí a ó fi fún ọ lati ọwọ́ Olùtùnú, àti ní sísọ àsọyé gbogbo àwọn ìwé mímọ́ fún ìjọ.

6 Àti pé a ó fi fún ọ ní àkókò náà gan ohun tí ìwọ yíò sọ àti èyítí ìwọ yíò kọ, àti pé wọn yíò gbọ́ ọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yíò rán ègún sí wọn dípò ìbùkún.

7 Nítorí ìwọ yíò ya gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ sọ́tọ̀ ní Síónì; àti pé nínú èyí ni ìwọ yíò ní okun.

8 Ní sùúrù nínú àwọn ìpọ́njú, nítorí púpọ̀ ni ìwọ yíò ní; ṣùgbọ́n fi ara dà wọ́n, nítorí, wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ, àní títí dé òpin ọjọ́ ayé rẹ.

9 Àti pé nínú àwọn iṣẹ́ ti ara ìwọ kì yíò ní okun, nítorí èyí kìí ṣe ìpe rẹ. Ṣe àmójútó ìpè rẹ ìwọ yíò sì ní ohun tí o nílò láti gbé ìpò iṣẹ́ rẹ ga, àti láti sọ àsọyé gbogbo àwọn ìwé mímọ́, àti pé ìwọ yíó tẹ̀ síwájú ní gbígbé ọ́wọ́ lé àwọn ènìyàn ní orí àti ní fífi ẹsẹ̀ àwọn ìjọ múlẹ̀.

10 Àti pé arákùnrin rẹ Oliver yíò tẹ̀síwájú láti máa kéde orúkọ mi ní iwájú àwọn ènìyàn ayé, àti pẹ̀lú sí ìjọ. Àti pé kí òun má ṣe rò pé òun le sọ tó nípa ọ̀nà mi; sì wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ̀ títí dé òpin.

11 Nínú mi òun yíò ní ògo, àti pé kìí ṣe ti ara rẹ̀, bóyá nínú àìní agbára tàbí nínú okun, bóyá nínú ìgbèkùn tàbí ní òmìnira;

12 Àti ní gbogbo ìgbà, àti ní ibi gbogbo, òun yíò la ẹnu rẹ̀ yíò sì kéde ìhìnrere mi pẹ̀lú bíi ohùn fèrè, ní ọ̀sán àti ní òru. Emi yíò sì fún un ní okun irú èyítí a kò mọ̀ lààrin àwọn ènìyàn.

13 Má ṣe béèrè àwọn iṣẹ́ ìyanu, bíkòṣe pé mo bá paá láṣẹ fún ọ, bíkòṣe ti lílé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, mímú àwọn àláìsàn lára dá, àti láti dojú ìjà kọ àwọn ejò olóró, àti àwọn oró tí wọn lè pani;

14 Àti pé àwọn ohun wọ̀nyí ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe, bí kò ṣepé àwọn tí wọ́n nfẹ́ ẹ bá béèrè lọwọ́ rẹ, kí àwọn ìwé mímọ́ baà lè wá sí ìmúṣẹ; nítorí ìwọ gbọdọ̀ ṣe ní ìbámu sí èyíinì tí a kọ.

15 Àti pé ní ibikíbi tí ìwọ bá wọ̀, tí wọn kò sì gbà ọ́ ní orúkọ mi, ìwọ yíò fi ègún sílẹ̀ dípò ìbùkún, nípa gbígbọn erùpẹ̀ ẹsẹ̀ bàtà rẹ sílẹ̀ lòdì sí wọn gẹ́gẹ́bí ẹrí, àti ní wíwẹ ẹsẹ̀ rẹ mọ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà.

16 Yíò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ọwọ́ lé ọ pẹ̀lú ìwà ipá, òun ni ìwọ yíò pàṣẹ pé kí a kọlù ní orúkọ mi; àti, kíyèsíi, èmi yíò kọlù wọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, ní àkókò tí ó yẹ ní ojú mi.

17 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ òfin lọ pẹ̀lú rẹ yíò gba ìdálẹ́bi nípa òfin náà.

18 Àti pé ìwọ kì yíò mú owó tàbí àpò, tàbí ọ̀pá, tàbí ẹ̀wù méjì, nítorí ìjọ yíò fi fún yín ní wákàtí náà gan an ohun tí ẹ̀yin bá nílò fún oúnjẹ àti fún aṣọ, ati fún bàtà àti owó, àti fún àpò.

19 Nítorí a pè yín láti wá tún ọ̀gbà-àjàrà mi ṣe pẹ̀lú àtúnṣe nlá, bẹ́ẹ̀ni, àní fún ìgbà tí ó kẹhìn; bẹ́ẹ̀ni, àti bákannáà gbogbo àwọn wọnnì tí ẹ̀yin ti yàn, àwọn náà yíò sì ṣe àní ní ìbámu sí àpẹrẹ yìí. Amin.