Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 126


Ìpín 126

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní ilé Brigham Young, ní Nauvoo, Illinois, 9 Oṣù Keje 1841. Ní àkókò yìí Brígham Young ni Ààrẹ ti Iyéjú àwọn Àpóstélì Méjìlá.

1–3, Brigham Young ni a yìn fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí a sì rọ̀ lóókún níti ìrìnàjò ọjọ́ iwájú sí ilẹ̀ òkèèrè.

1 Arákùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n ati àyànfẹ́-gidi, Brigham young, lõtọ́ báyìí ni Oluwa wí fún ọ: Ìránṣẹ́ mi Brígham, a kò béèrè lọ́wọ́ rẹ mọ́ láti fi ẹbí rẹ sílẹ̀ bíi ti àwọn ìgbà àtẹ̀hìnwá, nítorí ẹbọ- ọrẹ rẹ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí mi.

2 Èmi ti rí iṣẹ́ ati lãlã rẹ ní rírin àwọn ìrìnàjò fún orúkọ mi.

3 Nítorínáà mo pàṣẹ fún ọ láti rán ọ̀rọ̀ mi sí òkẽrè, kí o sì ṣe àmòjùtó pàtàkì ti ẹbí rẹ láti àkókò yìí, láti ìgbà yìí lọ àti títí láé. Àmín.