Ìpín 13
Àyọkúrò láti inú ìwé ìtàn ti Joseph Smith tí ó ṣe àpéjúwe ìlànà ìfinijoyè ti Wòlíì náà àti Oliver Cowdery sí oyè àlufáà ti Áárọ́nì ní itòsí Harmony, Pennsylvania, 15 Oṣù Karun 1829. Ìfinijoyè náà ni a ṣe lati ọwọ́ angẹ́lì kan tí ó kéde ara rẹ̀ bíi Jòhánnù, ẹ̀ni kannáà tí a pè ní Jòhánnù Onírìbọmi nínú Májẹ̀mu Titun. Angẹ́lì náà ṣe àlàyé pé òun nṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Péterù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù, àwọn Àpostélì ìgbàanì, tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà gíga, èyítí a pè ní Òyè àlùfáà Melkizedekì. Ìlérì náà ni a fi fún Joseph àti Oliver pé nígbàtí àkókò bá tó òyè àlufáà gíga yìí yíò di fífi lé wọn ní orí. (Wo ìpín 27:7–8, 12.)
Àwọn kọ́kọ́rọ́ àti agbára oyè àlùfáà ti Áárọ́nì ni a fi lélẹ̀.
1 Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Mèssíàh mo fi Oyè Àlùfáà ti Áárọ́nì fún yín, èyí tí ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti ti ìhìnrere ìrònúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírìbọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀; àti pé a kì yíò mú èyí kúrò ní ilé ayé mọ́ láé, títí tí àwọn ọmọ Léfì yíò fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan síi ẹbọ-ọrẹ kan sí Olúwa nínú ìṣòdodo.