Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 5


Ìpín 5

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní ìlú Harmony, Pennsylvania, Oṣù Kejì 1829, tí Martin Harris béèrè fún.

1–10, Ìran yìí yíò gba ọ̀rọ̀ Olúwa nípasẹ̀ Joseph Smith; 11–18 Àwọn ẹlẹ́ri mẹ́ta yíò jẹ́ri sí Ìwé Ti Mọ́mọ́nì; 19–20, A ó fi ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa múlẹ̀ bí ti awọn ìgbà ìṣaájú; 21–35, Martin Harris lè ronúpìwàdà kí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlérìí náà.

1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé bí ìránṣẹ́ mi Martin Harris ṣe fẹ́ ẹ̀rí lati ọwọ́ mi, pé ìwọ, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, ti gba àwọn àwo àkọsílẹ̀ náà èyí tí ìwọ ti jẹ́rìí sí, tí o sì kọ àkọsílẹ̀ pé o ti gbã lati ọ̀dọ̀ mi;

2 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èyí ni ìwọ ó sọ fún un—ẹnití o bá ọ sọ̀rọ̀, sọ fún ọ pé: Èmi, Olúwa, èmi ni Ọlọ́run, mo sì ti fi àwọn nkan wọ̀nyí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, mo sì ti pàṣẹ fún ọ pé o níláti dúró bíi ẹlẹ́rìí àwọn nkan wọ̀nyí.

3 Àti pé èmi ti mú kí ìwọ, pé o nílati wọ inú majẹ̀mú pẹ̀lú mi, pé ìwọ kì yíò fi hàn wọ́n bíkòṣe sí àwọn ènìyàn wọnnì tí èmi ti pàṣẹ fún ọ; ìwọ kò sì ní agbára ní orí wọn bíkòṣe pé mo bá fi í fún ọ.

4 Àti pé ìwọ ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn àwo àkọsílẹ̀ náà; èyí sì jẹ́ ẹ̀bùn àkọ́kọ́ tí èmi fi fún ọ; àti pé mo ti paá láṣẹ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣebí ẹnipé o ní ẹ̀bùn míràn títí tí èrò mi yíó fi wá sí ìmúṣẹ nípa èyìí; nítorí èmi kì yíò fi ẹ̀bùn míràn fún ọ títí tí yíò fi parí.

5 Lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé ègbé yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olùgbé orí ilẹ̀ bí wọn kò bá fetísílẹ̀ sí àwọ̀n ọ̀rọ̀ mi;

6 Nítorí lẹ́hìn àkókò yìí a ó yàn ọ́, ìwọ yíò sì jade lọ láti fi àwọn ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn.

7 Kíyèsíi, bí wọn kò bá ní gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, wọn kì yíò gbà ọ́ gbọ́, ìránṣẹ mi Joseph, bí ó bá ṣeéṣe pé kí ìwọ fi gbogbo àwọn ohun wọnyí hàn wọ́n tí èmi ti fà lé ọ lọ́wọ́.

8 Áà, ìran aláìgbàgbọ́ àti ọlọ́rùn líle yìí—ìbínú mi ru sókè sí wọn.

9 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, mo ti fi àwọn ohun wọnnì pamọ́ èyítí mo ti fà fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, fún ìdí tí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi, a ó sì fi í hàn fún àwọn ìran ọjọ́ iwájú.

10 Ṣùgbọ́n ìran yìí yíò gba ọ̀rọ̀ mi nípasẹ̀ rẹ.

11 Àti pé ní àfikún sí ẹ̀rí rẹ, ẹ̀rí láti ẹnu mẹ́ta nínú àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn tí èmi yíò pè tí èmi ó sì yàn, sí àwọn ẹnití èmi yíò fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn, wọn yíò sì jade lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ mi èyí tí a ó fi fúnni nípasẹ̀ rẹ.

12 Bẹ́ẹ̀ni, wọn yíò mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́, nítorí láti ọ̀run ni èmi yíò ti kéde rẹ̀ fún wọn.

13 Èmi yíò fún wọn ní agbára pé kí wọn le kíyèsíi kí wọn sì wo àwọn nkan wọ̀nyí bí wọn ṣe rí;

14 Àti pé ẹlòmíràn ni èmi kì yíò fún ní agbára yìí, láti gba ẹ̀rí yìí kannáà láàrin ìran yìí, nínú ìbẹ̀rẹ̀ ti ìgbédìde yìí àti ìjádewá ìjọ mi láti inú aginjù—kedere bíi òṣùpá, tí ó sì mọ́lẹ̀ bíi oòrùn, tí ó sì ní ẹ̀rù bíi ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn àsìá.

15 Àti pé ẹ̀rí àwọn ẹlérìí mẹ́ta ni èmi yíò rán jade nípa ọ̀rọ̀ mi.

16 Àti pé kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, àwọn ni èmi yíò bẹ̀wò pẹ̀lú ìfarahàn Ẹ̀mí mi; wọn yíò sì di àtúnbí nípasẹ̀ mi, àní nípasẹ̀ omi àti Ẹ̀mí—

17 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ dúró fun ìgbà díẹ̀ kan síi, nítorí a kò tíì yàn yín—

18 Àti ẹ̀rí wọn náà yíò jade lọ bákannáà sí ìdálẹ́bi ìran yìí bí wọn bá sé ọkàn wọn le lòdì sí wọn;

19 Nítorí, pàsán ìsọdahoro yíò jade lọ sí ààrín àwọn olùgbé ilé ayé, yíò sì tẹ̀síwájú lati máa tú jade láti àkókò dé àkókò, bí wọn kò bá ronúpìwàdà, títí ilé ayé yíò fi di òfìfo, àti àwọn olùgbé rẹ̀ yíò fi jóná tán tí wọn yíò sì parun pátápátá nípa mímọ́lẹ̀ ti bíbọ̀ mi.

20 Kíyèsíi, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fun yín, àní bí mo ṣe sọ fún àwọn ènìyàn bákannáà nípa ìparun Jerusalẹmu; àti pé ọ̀rọ̀ mi ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní àkókò yìí bí a ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ìgbà ìṣaájú.

21 Àti pé nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ, ìwọ ìránṣẹ́ mi Joseph, láti ronúpìwàdà kí o sì rìn ní ìdúró ṣinṣin ní iwájú mi, kí o má sì ṣe fi ààyè gba ìyínilọ́kànpadà awọn ènìyàn mọ́.

22 Àti pé kí o dúró ṣinṣin nínú pípa àwọn òfin mọ́ pẹ̀lú èyítí èmi ti pàṣẹ fún ọ; bí o bá sì ṣe èyí, kíyèsíi, mo fún ọ ní ìyè ayérayé, àní bí wọn tilẹ̀ pa ọ́.

23 Àti pé nísisìyí, lẹ́ẹ̀kansíi, mo bá ọ sọ̀rọ̀, ìránṣẹ mi Joseph, nípa ọkùnrin náà tí ó fẹ́ ẹ̀rí—

24 Kíyèsíi, mo wí fún un, òun gbé ara rẹ̀ ga kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tó ní iwájú mi; ṣùgbọ́n bí òun bá lè tẹ orí ara rẹ̀ ba ní iwájú mi, tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nínú àdúrà nlá ati ìgbàgbọ́, nínú òtítọ́ ọkàn rẹ̀, nígbànáà ni èmi yíò fi fún un lati wo àwọn ohun tí ó ní ìfẹ́ láti rí.

25 Àti pé nígbànáà ni òun yíò sọ fún àwọn ènìyàn ìran yìí: Kíyèsíi, mo ti rí àwọn ohun tí Olúwa fi han Joseph Smith Kekere, mo sì mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé wọ́n jẹ́ òtítọ́, nítorí mo ti rí wọn, nítorí a ti fi wọ́n hàn sí mi nípa agbára Ọlọ́run àti tí kìí ṣe ti ènìyàn.

26 Àti pé èmi Olúwa pàṣẹ fún un, ìránṣẹ́ mi Martin Harris, pé òun kì yíò sọ ohun kankan fún wọn mọ́ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, bíkòṣe pé òun yíò sọ pé: mo ti rí wọn, a sì ti fi wọ́n hàn sí mí nípa agbára Ọlọ́run; ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí òun yíò sì sọ.

27 Ṣùgbọ́n bí òun bá sẹ́ èyìí òun yíò sẹ́ májẹ̀mú èyí tí ó ti dá pẹ̀lú mi ṣaájú, àti kíyèsíi, òun ti di ìdálẹbi.

28 Àti pé nísisìyí, bíkòṣe pé òun bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, tí òun sì jẹ́wọ́ fún mi àwọn ohun tí ó ti ṣe tí kò dára, àti kí ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú mi pé òun yíò pa àwọn òfin mi mọ́, àti pé òun yíò lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kíyèsíi, mo wí fún un, òun kì yíò ní irú ìran bẹ́ẹ̀, nítorí èmi kì yíò fi fún un lati wo awọn ohun náà nipa èyítí mo ti sọ̀rọ̀.

29 Àti pé bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, mo pàṣẹ fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, pé kí ìwọ ó sọ fún un, pé òun kì yíò ṣe ohunkóhun mọ́, tàbí kí ó yọ mí lẹ́nu mọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

30 Ati pé bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, kíyèsíi, mo wí fún ọ Joseph nígbàtí ìwọ bá ti túmọ̀ àwọn ojú ewé ìwé díẹ̀ síi, ìwọ yíò dúró fún ìgbà kan, àní títí tí èmi yíò fi tún pàṣẹ fún ọ; nígbàyìí ni ìwọ ó tún le túmọ̀.

31 Àti pé bíkòṣe pé ìwọ bá ṣe èyí, kíyèsíi, ìwọ kì yíò ní ẹ̀bùn kankan mọ́, èmi yíò sì gba àwọn ohun tí mo ti fi pamọ́ pẹ̀lú rẹ lọ.

32 Àti pé nísisìyí, nítorípé mo rí i tẹ́lẹ̀, ète ti ó dúró láti pa ọ run, bẹ́ẹ̀ni, mo rí i tẹ́lẹ̀ pé bí ìránṣẹ́ mi Martin Harris kò bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì gba ẹ̀rí láti ọwọ́ mi, pé òun yíò ṣubú sínú ìrékọjá;

33 Àti pé àwọn púpọ̀ ni wọn ndúró láti pa ọ́ run kúrò ní orí ilẹ̀ ayé; àti nítorí ìdí èyí, kí ọjọ́ rẹ ó lè gùn, mo ti fún ọ ní àwọn òfin wọ̀nyí.

34 Bẹ́ẹ̀ni, fún ìdí èyí mo ti sọ pé: Dúró, kí o sì dúró jẹ́ẹ́ títí tí èmi ó fi pàṣẹ fún ọ, èmi yíò sì pèsè ọ̀nà àbáyọ nípa èyítí ìwọ yíò le ṣe àṣeyọrí ohun èyití mo ti pàṣẹ fún ọ.

35 Àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa àwọn òfin mi mọ́, a ó gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Amin.