Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 115


Ìpín 115

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 26 Oṣù Kẹrin 1838, sísọ ìfẹ́ inú Ọlọ́run di mímọ̀ nípa kíkọ́ ibẹ̀ àti ilé Olúwa. Ìfihàn yìí ni a dárí rẹ̀ sí àwọn olórí òṣìṣẹ́ àti àwọn ọmọ Ìjọ.

1–4, Olúwa pe orúkọ ìjọ Rẹ̀ ní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; 5–6, Síónì àti àwọn èèkàn rẹ̀ jẹ́ àwọn ibi ààbò àti ibi ìsádi fún àwọn Ènìyàn Mímọ́; 7–16, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a pàṣẹ fún láti kọ́ ilé Olúwa kan ní Far West; 17–19, Joseph Smith ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé.

1 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí fún yín, ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon, àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith, àti àwọn olùdámọ̀ràn yín àwọn tí wọ́n wà àti tí a ó yàn lẹ́hìnwá;

2 Àti pẹ̀lú sí ọ, ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀;

3 Àti bákannáà sí ẹ̀yin olõtọ́ ìránṣẹ́ mi tí ẹ jẹ́ ti ìgbìmọ̀ gíga ti ìjọ mi ní Síónì, nítorí báyìí ni a ó pè é, àti sí gbogbo àwọn alàgbà àti àwọn ènìyàn Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn mi, tí wọ́n fọ́nká sí òkèèrè ní gbogbo ayé;

4 Nítorí báyìí ni a ó pe ìjọ mi ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, àní Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

5 Lõtọ́ ni mo wí fún gbogbo yín: Ẹ dìde kí ẹ sì tàn dáradára, kí ìmọ́lẹ̀ yín ó lè jẹ́ òdiwọ̀n fún àwọn orílẹ̀-èdè;

6 Àti pé kí pípéjọpọ̀ náà ní orí ilẹ̀ Síónì, àti ní orí àwọn èèkàn rẹ̀, ó lè jẹ́ fún ààbò, àti fún ìsádi kúrò nínú ìjì, àti kúrò nínú ìbínú nígbàtí a ó tú u jáde sí orí gbogbo ilẹ̀ ayé láìsí àdàlù.

7 Ẹ jẹ́ kí ìlú nlá náà, Far West, jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ àti tí a yà sọ́tọ̀ sí mi, a ó sì pè é ní ibi mímọ́ jùlọ, nítorí orí ilẹ̀ èyítí ìwọ dúró nnì jẹ́ mímọ́.

8 Nítorínáà, mo pàṣẹ fún yín láti kọ́ ilé kan sí mi, fún kíkójọ pọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ mi, pé kí wọ́n ó lè sìn mí.

9 Ẹ sì jẹ́kí ìbẹ̀rẹ̀ kan ó wà fún iṣẹ́ yìí, àti ìpìlẹ̀ kan, àti iṣẹ́ ìpalẹ̀mọ́ kan, ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tí ó tẹ̀lé yìí;

10 Ẹ sì jẹ́kí ìbẹ̀rẹ̀ náà ó jẹ́ ṣiṣe ní ọjọ́ kẹrin oṣù Keje tí ó nbọ̀; àti láti àkókò náà lọ kí àwọn ènìyàn mi ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú aápọn láti kọ́ ilé kan sí orúkọ mi;

11 Àti pé ní ọdún kan láti ọjọ́ yìí ẹ jẹ́kí wọ́n ó ṣe àtúnbẹ̀rẹ̀ fífí ìpìlẹ̀ ilé mi lélẹ̀.

12 Báyìí ẹ jẹ́kí wọn ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú aápọn láti àkókò náà títí tí yíò fi parí, láti òkúta igun ilé ibẹ̀ sí òrùlé ibẹ̀, títí tí kò fi ní sí ohun kan tí ó ṣẹ́kù tí a kò parí.

13 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ máṣe jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Joseph, tàbí ìránṣẹ́ mi Sidney, tàbí ìránṣẹ́ mi Hyrum, kí ó wà nínú gbèsè mọ́ fún kíkọ́ ilé kan sí orúkọ mi;

14 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́kí ilé kan ó jẹ́ kíkọ́ sí orúkọ mi ní ìbámu sí àpẹrẹ èyítí èmi yíò fi hàn sí wọn.

15 Àti bí àwọn ènìyàn mi kò bá kọ́ ọ ní ìbámu sí àpẹẹrẹ náà èyítí èmi yíò fi hàn sí àjọ ààrẹ wọn, èmi kì yíò tẹ́wọ́gbà á ní ọwọ́ wọn.

16 Ṣùgbọ́n bí àwọn ènìyàn mi bá kọ́ ọ ní ìbámu sí àpẹẹrẹ èyítí èmi yíò fi hàn sí àjọ ààrẹ wọn, àní ìránṣẹ́ mi Joseph àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, nígbànáà èmi yíò tẹ́wọ́gbà á ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi.

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìlú nlá ti Far West ó jẹ́ kíkọ́ kánkán nípa ìkójọ àwọn ènìyàn mímọ́ mi;

18 Àti bákannáà pé kí àwọn ibomíràn ó jẹ́ yíyàn fún àwọn èèkàn ní àwọn agbègbè yíkáàkiri, bí wọn yíò ṣe jẹ́ fífi hàn sí ìránṣẹ́ mi Joseph, láti àkókò dé àkókò.

19 Nítorí kíyèsíi, èmi yíò wà pẹ́lú rẹ̀, èmi yíò sì yà á sí mímọ́ níwájú àwọn ènìyàn; nítorí òun ni èmi ti fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí fún. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.