Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110


Ìpín 110

Àwọn ìran tí a fihàn sí Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery nínú Tẹ́mpìlì ní Kirtland, Ohio, 3 Oṣù Kẹrin 1836. Àkókò náà jẹ́ ti ìpàdé Ọjọ́ Ìsìnmi kan. Ìtàn ti Joseph Smith sọ pé: “Ní ọ̀sán, mo ran àwọn Ààrẹ míràn lọ́wọ́ ní pípín Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa fún Ìjọ, ní gbígba á lọ́wọ́ Àwọn Méjìlá, àwọn tí wọ́n ní ànfààní láti ṣe iṣẹ́ oyè ní orí tábìlì mímọ́ náà ní ọjọ́ yìí. Lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn yìí sí àwọn arákùnrin mi, mo padà sí orí àga ìwàásù, ní dída àwọn aṣọ ìkéle sílẹ̀, àti títẹ orí ara mi ba, pẹ̀lú Oliver Cowdery, nínú àdúra ọ̀wọ̀ àti ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Lẹ́hìn dídìde kúrò nínú àdúrà, ìran yìí ni a ṣí sí àwa méjèèjì.”

1–10, Olúwa Olódùmarè fi ara hàn nínú ògo ó sì tẹ́wọ́gba Tẹ́mpìlì ti Kirtland bíi ilé Rẹ̀; 11–12, Mósè àti Elíásì bí ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ara hàn wọ́n sì fi àwọn kọ́kọ́rọ́ àti àwọn ìgbà ìríjú wọn lélẹ̀; 13–16, Elíjà padà ó sì fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìgbà rẹ̀ lélẹ̀ bí Málákì ti ṣe ìlérí.

1 A mú ìbòjú kúrò ní ọkàn wa, àwọn ojú àgbọ́yé wa sì ṣí.

2 Àwa rí Olúwa ní dídúró sí orí ibi ìgbáralé ti àga ìwàásù náà; níwájú wa; ní abẹ́ ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ ni iṣẹ́ ọnà tí ó jẹ́ ti wúrà gidi, ní àwọ tí ó dàbí amberì.

3 Àwọn ojú rẹ̀ bíi ọ̀wọ́ iná; irun orí rẹ̀ funfun bíi ìrì dídì tí kò ní èérí; ìwò ojú rẹ̀ tàn kọjá ìtànsán oòrùn; àti ohùn rẹ̀ dàbíi ìró omi púpọ̀, àní ohùn ti Jèhófàh, ní wíwí pé:

4 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ìkẹhìn; Èmi ni ẹni náà tí ó wà láàyè, èmi ni ẹni náà tí a pa; èmi ni alágbàwí yín pẹ̀lú Bàbá.

5 Kíyèsíi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; ẹ jẹ́ aláìlẽrí ní iwájú mi; nítorínáà, ẹ gbé orí yín sókè kí ẹ sì yọ̀.

6 Ẹ jẹ́kí ọkàn àwọn ìránṣẹ́ yín kí ó yọ̀, ẹ sì jẹ́kí ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn mi kí ó yọ̀, àwọn tí, pẹ̀lú agbára wọn, wọn ti kọ́ ilé yìí sí orúkọ mi.

7 Nítorí kíyèsíi, mo ti tẹ́wọ́ gba ilé yìí, orúkọ mi yíò sì wà níbẹ̀; èmi yíò sì fi ara mi hàn sí àwọn ènìyàn mi nínú àánú nínú ilé yìí.

8 Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò fi ara hàn sí àwọn ìránṣẹ́ mi, èmi ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn mi, bí àwọn ènìyàn mi yíò bá pa àwọn òfin mi mọ́, tí wọn kò sì sọ ilé mímọ́ yìí di àìmọ́.

9 Bẹ́ẹ̀ni ọkàn ti àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹgbẹ̀rún ní àwọn ọ̀nà mẹ́wàá-mẹ́wàá ni yíò yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ìyọrísí ti àwọn ìbùkún eyítí a ó tú jade, àti ẹ̀bùn náà èyítí a ti bùn àwọn ìránṣẹ́ mi nínú ilé yìí.

10 Òkìkì ilé yìí yíò sì kàn sí àwọn ilẹ̀ míràn; èyí sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ìbùkún èyítí a ó tú jade sí orí àwọn ènìyàn mi. Àni bẹ́ẹ̀ní. Àmín.

11 Lẹ́hìn tí ìran yìí parí, àwọn ọ̀run tún ṣi síwa lẹ́ẹ̀kansíi; Mósè sì fi ara hàn níwájú wa, ó sì fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti kíkójọ Ísráẹ́lì láti ìpín mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé fún wa, àti ṣíṣe aṣaájú àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá láti ilẹ̀ àríwá.

12 Lẹ́hìn èyí, Elíásì fi ara hàn, ó sì fi ìgbà ìríjú ìhìnrere ti Àbráhámù fúnni, ní wíwí pé nínú wa àti irú ọmọ wa ní gbogbo ìran lẹ́hìn wa ní yíó di ẹni ìbùkún.

13 Lẹ́hìn tí ìran yìí ti parí, ìran míràn tí ó tóbi àti tí ó logo tú jade sí orí wa; nítorí wòlíì Elíjà, ẹnití a mú lọ sí ọ̀run láì tọ́ ikú wò, dúró ní iwájú wa, ó sì wípé:

14 Kíyèsíi, àkókò náà ti dé ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí a ti sọ láti ẹnu Málákì—ní jíjẹ́rìí pé òun (Èlíja) ni á ó rán, kí ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù ti Olúwa tó dé—

15 Láti yí ọkàn ti àwọn bàbá sí àwọn ọmọ, àti ti àwọn ọmọ sí àwọn bàbá, bíbẹ́ẹ̀kọ́ kí gbogbo ilẹ̀ ayé má baà di kíkọlù pẹ̀lú ègún—

16 Nítorínáà, àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìgbà ìríjú yìí ni a ti fi sí ọwọ́ yín; àti nípa èyí ni ẹ̀yin yíò lè mọ̀ pé ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù ti Olúwa súnmọ́ itòsí, àní ni ẹnu ọ̀nà àwọn ìlẹ̀kùn.