Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 125


Ìpín 125

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Nauvoo, Illinois, Oṣù kẹta 1841, nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní agbègbè Iowa.

1–4, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ niláti kọ́ àwọn ilú nlá àti láti kórajọ sí àwọn èèkàn ti Síónì.

1 Kíni ìfẹ́ inú Olúwa nípa àwọn ènìyàn mímọ́ ní Agbègbè Iowa?

2 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, mo wí fún yín, bí àwọn wọnnì tí wọ́n npe ara wọn mọ́ orúkọ mi tí wọ́n sì ngbìyànjú láti jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi, bí wọ́n yíò bá ṣe ìfẹ́ inú mi tí wọn yíó sì pa àwọn òfin mi mọ́ nípa wọn, ẹ jẹ́ kí wọn kó ara wọn jọ papọ̀ sí àwọn ibi tí èmi yíò yàn fún wọn nípasẹ̀ ìránṣẹ́ mi Joseph, kí wọn ó sì kọ́ àwọn ilú nlá sí orúkọ mi, kí wọn ó lè múra sílẹ̀ fún èyítí ó wà ní ìpamọ́ fún àkókò kan tí ó nbọ̀.

3 Ẹ jẹ́kí wọ́n ó kọ́ ilú nlá kan sí orúkọ mi ní orí ilẹ̀ tí òdìkejì ilú nlá Nauvoo, ẹ sì jẹ́kí orúkọ Sarahẹ́múlà ó jẹ́ orúkọ ní orí rẹ̀.

4 Àti pé ẹ jẹ́kí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wá láti ìlà oòrùn, àti ìwọ̀ rẹ̀, àti àríwá, àti gúúsù, tí wọ́n ní ìfẹ́ láti gbé inú rẹ̀, kí wọ́n ó gba ogún ìní wọn nínú ọ̀kannáà, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nílú nlá Nashville, tàbí nínú ìlú nlá Nauvoo, àti ní gbogbo àwọn èèkàn èyítí èmi ti yàn, ni Olúwa wí.