Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 14


Ìpín 14

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wolíì Joseph Smith sí David Whitmer, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà 1829. Àwọn mọ̀lẹ́bí Whitmer ti ní ìfẹ́ púpọ̀ sí iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. Wòlíì náà ti fi ibùgbé rẹ̀ kalẹ̀ sí ilé Peter Whitmer Àgbà, níbẹ̀ ni ó ngbé títí tí iṣẹ́ ìtumọ̀ ìwé náà fi dé ìparí àti tí wọ́n fi gba àṣẹ láti tẹ ìwé tí ó nbọ̀ náà sí ìta. Mẹ́ta nínú àwọn ọmọ Whitmer, tí ọkọ̀ọ̀kan nínú wọn ti gba ẹ̀rí nípa bí ìwé náà ṣe jẹ́ òtítọ́ tó, wá wòye bí ó ṣe kàn wọ́n tó láti mọ́ ojúṣe tí wọ́n ní kárakára gẹ́gẹ́bí olúkúlùkù. Ìfihàn yìí àti méjì tí yíò tẹ̀lé e (Ìpín 15 àti 16) ni a gbà ní ìdáhùn sí ìbéèrè kan nípa lílo Urimù àti Thummimù. David Whitmer di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Mẹ́ta Ìwé Ti Mọ́mọ́nì.

1–6, Àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà ajarà yíò gba èrè ìgbàlà; 7–8, Iyè àìnípẹ̀kun ni ó ga jùlọ nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. 9–11 Krísti dá ọ̀run àti ayé.

1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan fẹ́ jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn.

2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyítí ó yè tí ó sí ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ láti pín sí ọ̀tọọ̀tọ̀ oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.

3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè, nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè, ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, kí ó sì kórè nígbàtí ọjọ́ sì wà, kí ó le kó ìgbàlà àìlópin pamọ́ fún ọkàn rẹ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run.

4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ tí ó sì kórè, òun kannáà ni Ọlọ́run pè.

5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn a ó ṣí i fún ọ.

6 Lépa láti mú jade wá àti láti ṣe àgbékalẹ̀ Síónì mi. Pa àwọn òfin mi mọ́ nínú ohun gbogbo.

7 Àti pé, bí ìwọ bá pa àwọn òfin mi mọ́ tí o sì fi orí tìí dé òpin ìwọ yíò ní ìyè ayérayé, ẹ̀bùn èyí tí ó ga jùlọ nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.

8 Yíò sí ṣe, pé bí ìwọ bá béèrè lọ́wọ̀ Bàbá ní orúkọ mi, pẹ̀lú ìgbágbọ́, ìwọ yíò gba Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó nfunni ní ọ̀rọ̀ sísọ, kí ìwọ kí ó lè dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí àwọn ohun tí ìwọ yíò rí àti tí ìwọ yíò gbọ́, àti bákannáà pé kí ìwọ kí ó lè kéde ironúpìwàdà sí ìran yìí.

9 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run alààyè, ẹnití ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, ìmọ́lẹ̀ tí kò lè fara sin nínú òkùnkùn;

10 Ati nísisìyí, èmi gbọ́dọ̀ mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi jade wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ilé Israeli.

11 Àti kíyèsíi, ìwọ ni Dáfídì, ìwọ̀ ni a sì pè láti ṣe ìrànlọ́wọ́; èyítí bí ìwọ bá ṣe ohun náà, bí o bá sì jẹ́ olõtọ́, a ó bùkún fún ọ ní ti ẹ̀mí àti ní ti ara, púpọ̀ ni èrè rẹ yíò sì jẹ́. Amín.