Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 74


Ìpín 74

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Wayne, New York, ni 1830. Àní ṣaajú ìgbékalẹ̀ Ìjọ, àwọn ìbéèrè ti wáyé nípa ọ̀nà dídára fún ìrìbọmi, èyítí ó darí Wòlíì láti lépa àwọn ìdáhùn ní orí àkòrí náà. Ìtàn ti Joseph Smíth sọ pé ìfihàn yí ni àlàyé Ⅰ Kóríntì 7:14, ẹsẹ ìwé mímọ́ tí o ti máa nfi ìgba gbogbo jẹ́ lílò láti ṣe ìdáláre ìrìbọmi àwọn ọmọdé.

1–5, Paulù gba Ìjọ ìgbà tirẹ̀ nímọ̀ràn láti má ṣe pa àwọn òfin Mósè mọ́; 6–7, àwọn ọmọdé jẹ́ mímọ́ a sì yà wọ́n sí mímọ́ nípasẹ̀ Ètùtù.

1 Nítorí aláìgbàgbọ́ ọkọ ni a sọ di mímọ́ nípasẹ̀ aya, àti aláìgbàgbọ́ aya ni a sọ di mímọ́ nípa ọkọ; bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ yín ìbá jẹ́ aláìmọ́, ṣùgbọ́n nísisìyí wọ́n jẹ́ mímọ́.

2 Nísisìyí, ní àwọn ọjọ́ ti àwọn àpóstélì òfin ìkọlà wà láàrin gbogbo àwọn Júù tí wọ́n kò gbàgbọ́ nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì.

3 Ó sì ṣe pé èdè-àìyédè nlá ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn náà nípa òfin ìkọlà, nítorí aláìgbàgbọ́ ọkọ ní ìfẹ́ síi pé kí á kọ àwọn ọmọ rẹ̀ nílà kí wọ́n ó sì wà ní abẹ́ òfin Mósè, òfin èyí tí a ti mú ṣẹ.

4 Ó sì ṣe pé àwọn ọmọ, tí a ti wò dàgbà ní abẹ́ òfin Mósè, ní ìkíyèsí àwọn àṣà àwọn bàbá wọn tí wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìnrere ti Krístì, nínú èyí tí wọ́n di aláìmọ́.

5 Nítorínáà, nítorí ìdí èyí ni àpóstélì ṣe kọ̀wé sí ìjọ, ní fífún wọn ní òfin kan, tí kìí ṣe ti Olúwa, ṣùgbọ́n ti ara rẹ̀, pé onígbàgbọ́ kan kì yíò ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́, bíkòṣe pé a mú òfin ti Mósè kúrò ní ààrin wọn,

6 Kí àwọn ọmọ wọn lè wà ní àìkọlà; àti pé kí àṣà náà ó lè kúrò, èyí tí ó sọ pé àwọn ọmọdé wà ní àìmọ́; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà láàrin àwọn Júù;

7 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ jẹ́ mímọ́, a ti yà wọ́n sí mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù ti Jésù Krístì; èyí sì ni ohun tí àwọn ìwé mímọ́ túmọ̀ sí.