Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107


Ìpín 107

Ìfihàn ní orí oyè àlùfáà, tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, ní nkan bíi Oṣù Kẹrin 1835. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé a ṣe àkọsílẹ̀ ìpín yìí ní 1835, àwọn àkọsílẹ̀ onítàn fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn ẹsẹ 60 títí dé 100 ṣe àgbéwọ̀ ìfihàn kan tí a fi fúnni nípasẹ̀ Joseph Smith ní 11 Oṣù Kọkànlá 1831. Ìpín yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìdásílẹ̀ ti Ìyejú Méjìlá ní Oṣù Kejì ati Oṣù Kẹta 1835. Ó ṣeéṣe kí Wòlíì ti fi í sílẹ̀ ní ìṣejú àwọn wọnnì tí wọn ngbaradì láti lọ kúrò ní 3 Oṣù Karũn 1835, nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àkọ́kọ́ ti iyejú wọn.

1–6, Àwọn oyè àlùfáà méjì ni ó wà: Melkísédekì àti Áarónì; 7–12, Àwọn tí wọ́n bá di ipò Òyè Àlùfáà ti Melkisédékì mú ní agbára láti ṣiṣẹ́ ipò ní gbogbo àwọn ipò iṣẹ́ nínú Ìjọ; 13–17, Àjọ bísọ́ọ̀pù ní ó nṣe àkóso Oyè Àlùfáà ti Áarónì, èyítí nbójútó àwọn ìlànà àfojúrí; 18–20, Oyè Àlùfáà ti Melkisédékì ni ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí mú; Oyè Àlùfáà Áarónì ní ó di kọ́kọ́rọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì mú; 21–38, Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Àwọn Méjìlá, àti àwọn Àádọ́rin ni ó jẹ́ àwọn iyejú adarí, àwọ́n tí ìpinnu wọn níláti jẹ́ ṣíṣe ní ìṣọ̀kan àti òdodo; 39–52, Ètò pátríákì ni a gbékalẹ̀ láti Ádámù sí Nóà; 53–57, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti àtijọ́ kórajọ ní Adam-ondi-Ahman, Oluwa sì fi ara hàn sí wọn; 58–67, Àwọn méjìlá náà ni wọn yíò ṣe ètò àwọn olóyè Ìjọ; 68–76, Àwọn Bísọ́ọ̀pù nṣiṣẹ́ bí onídãjọ́ gbogbogbòò ní Ísráẹ́lì; 77–84, Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Àwọn Méjìlá ni wọ́n jẹ́ olùgbẹ́jọ́ tí ó ga jùlọ nínú Ìjọ; 85–100, Àwọn ààrẹ olóyè àlùfáà ni wọ́n nṣe àkóso ìyejú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

1 Àwọn oyè àlùfáà méjì ni ó wà nínú ìjọ, orúkọ wọn ni, Melkisédékì àti Áarónì, nínú èyí tí Oyè Àlùfáà ti Léfì wà.

2 Ìdí tí a fi npe èkínní ní oyè àlùfáà Melkisédékì ni pé Melkisédékì jẹ́ irú àlùfáà gíga nlá.

3 Síwájú ọjọ́ rẹ̀ a npèé ní Oyè Àlùfáà Mímọ́, ní àtẹ̀lé Ètò ti Ọmọ Ọlọ́run.

4 Ṣùgbọ́n nítorí ìtẹríba tàbí ọ̀wọ̀ sí orúkọ Ẹnití Ó Tóbi Jùlọ, láti yẹ̀ra fún àpọ̀jù àtúnpè orúkọ rẹ̀ léraléra, àwọn, ìjọ náà, ní ọjọ́ ìgbàanì, pe oyè àlùfáà náà tẹ̀lé Melkisédékì, tàbí Oyè àlùfáà Melkisédékì.

5 Gbogbo àwọn àṣẹ̀ miràn tàbí àwọn ipò nínú ìjọ̀ jẹ́ àwọn àsomọ́ sí oyè àlùfáà yìí.

6 Ṣùgbọ́n àwọn ìpín tàbí àwọn àkorí nlá méjì ló wà—ọ̀kan jẹ́ Oyè Àlùfáà Melkisédékì, èkejì sì ni ti Áarónì tàbí Oyè Àlùfáà ti Lefì.

7 Ipò iṣẹ́ ti alàgbà wà lábẹ́ oyè àlùfáà ti Melkisédékì.

8 Oyè Àlùfáà Melkisédékì di ẹ̀tọ́ ti àjọ ààrẹ mú, ó sì ní agbára àti àṣẹ ní orí gbogbo àwọn ipò iṣẹ́ nínú ijọ̀ ní gbogbo ìgbà ní ayé, láti ṣe ìpínfúnni nínú àwọn ohun ti ẹ̀mí.

9 Àjọ Ààrẹ ti Oyè Àlùfáà Gíga, nípa ètò ti Melkisédékì, ní ẹ̀tọ́ lati ṣe iṣẹ́ ipò nínú gbogbo ipò iṣẹ́ nínú ìjọ.

10 Àwọn àlùfáà gíga nípa ètò ti oyè Àlùfáà ti Melkisédékì ní ẹ̀tọ́ lati ṣe iṣẹ́ ipò nínú ipò tiwọn, lábẹ́ ìdárí àjọ ààrẹ, ní ṣíṣe àmójútó àwọn ohun ti ẹ̀mí, àti bákannáà ní ipò iṣẹ́ ti alágbà, àlùfáà (ti ipa ti Léfì), olùkọ́, díakonì, àti ọmọ ìjọ.

11 Alàgbà kan ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ ipò dípò rẹ̀ nigbà tí àlùfáà gíga náà kò bá sí níbẹ̀.

12 Àlùfáà gíga àti alàgbà ni wọn yíó ṣe àmójútó nínú àwọn ohun ti ẹ̀mí, ní ìbámu sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin ìjọ; wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ lati ṣe iṣẹ́ ipò ní gbogbo àwọn ipò iṣẹ́ ti ìjọ wọ̀nyí nígbàtí kò bá sí àwọn aláṣẹ tí ó ga jù níbẹ̀.

13 Oyè àlùfáà kejì ni a pè ní Oyè àlùfáà ti Áarónì, nítorípé a fi fún Áarónì àti irú ọmọ rẹ̀, jákèjádò gbogbo àwọn ìran wọn.

14 Ìdí tí a fi pèé ní oyè àlùfáà tí ó kéré ní pé ó jẹ́ àsomọ́ sí èyí tí ó tóbi jù, tàbí Oyè Àlùfáà Melkisédékì, ó sì ní agbára ní ṣíṣe àmójútó àwọn ìlànà àfojúrí.

15 Àjọ bíṣọ́pù ni àjọ ààrẹ ti òyè àlùfáà yìí, ó sì ní àwọn kọ́kọ́rọ́ tàbí àṣẹ èyí kan náà.

16 Kò sí ẹnìkan tí ó ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin sí ipò iṣẹ́ yìí, láti ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti oyè àlùfáà yìí, bíkòṣe pé óun jẹ́ irú ọmọ Áarónì gan-an.

17 Ṣùgbọ́n nítorípé àlùfáà gíga ti Òyè Àlùfáà Melkisédékì ní àṣẹ láti ṣe iṣẹ́ ipò ní gbogbo àwọn ipò iṣẹ́ tí ó kéré, òun lè ṣe iṣẹ́ ní ipò bíṣọpù nigbàtí a kò bá rí àtẹ̀lé ti Áarónì gan an, níwọ̀nbí a bá pe òun àti tí a yà á sọ́tọ̀ tí á sì ṣe ìlànà fún un sí agbára yìí lati ọwọ́ Àjọ Ààrẹ ti Òyè Àlùfáà Melkisédékì.

18 Agbára àti àṣẹ ti èyítí ó ga jù, tàbí Oyè Àlùfáà Melkisédékì, ni lati di àwọn kọ́kọ́rọ́ gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí mú nínú ìjọ—

19 Láti ní ànfàní gbígba àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba ọ̀run, láti jẹ́ kí ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún wọn, láti dàpọ̀ pẹ̀lú àpéjọ gbogbogbòò àti ìjọ ti Àkọ́bí, àti láti jẹ ìgbádùn ìdàpọ̀ àti ìwàníbẹ̀ ti Ọlọ́run Bàbá, àti Jésù onílàjà ti májẹ̀mú titun.

20 Agbára àti àṣẹ ti èyítí ó kéré jù, tàbí Oyè Àlùfáà Áarónì, ni láti di àwọn kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́lì mú, àti láti ṣe àmójútó àwọn ìlànà àfojúrí, ìwé ti ìhìnrere, ìrìbọmi ti ironúpìwàdà fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀, ní ìbámu sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin.

21 Ní dandan àwọn ààrẹ wà, tàbí àwọn olórí òṣìṣẹ́ tí wọ́n jade wá láti, tàbí tí a yàn láti ọwọ́ tàbí láti ààrin àwọn tí a yàn sí onírúurú ipò nínú oyè àlùfáà méjèèjì wọ̀nyí.

22 Láti Oyè Àlùfáà Melkisédékì, àwọn Olórí Àlùfáà Gíga mẹ́ta, tí ẹgbẹ́ náà ṣàyàn, tí a fi ọwọ́ sí tí a sì ṣe ìlànà fún sí ipò náà, àti tí a tìlẹ́hìn nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, ìgbàgbọ́, àti àdúrà ìjọ, yíó jẹ́ iyejú Àjọ Ààrẹ ti Ìjọ.

23 Àwọn arìnrìnàjò olùdámọ̀ràn méjìlá ni a pè láti jẹ́ Àwọn Àpóstélì Méjìlá, tàbí àwọn ẹlérìí pàtàkì ti orúkọ Krísti ní gbogbo ayé—báyìí ni yíyàtọ̀ wọn sí àwọn òṣìṣẹ́ míràn nínú ìjọ nínú àwọn ojúṣe ìpe wọn.

24 Wọ́n sì jẹ́ iyejú kan, tí ó dọ́gba ní àṣẹ àti agbára sí àwọn ààrẹ mẹ́ta tí a sọ ṣaájú.

25 Àwọn Àádọ́rin ni a pè bákannáà láti wàásù ìhìnrere, àti láti jẹ́ àwọn ẹlérìí pàtàkì sí àwọn Kèfèrí àti ní gbogbo ayé—báyìí ni yíyàtọ̀ wọn sí àwọn òṣìṣẹ́ míràn nínú ìjọ nínu àwọn ojúṣe ìpe wọn.

26 Wọ́n sì jẹ́ iyejú kan, tí ó dọ́gba ní àṣẹ sí ti àwọn ẹlérìí pàtàkì Méjìlá náà tàbí àwọn Àpóstélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dárúkọ.

27 Àti pé olúkúlùkù ìpinnu tí èyíkéyìí àwọn ìyejú wọ̀nyí bá ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ nípa ìfòhùnṣọkan ti àwọn kan náà; èyí ni pé, olúkúlùkù ọmọ ẹgbẹ́ nínú iyejú kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ sí àwọn ìpinnu wọ̀nyìí, ní ọ̀nà láti mú kí àwọn ìpinnu wọn ó ní irú agbára tàbí àṣẹ àmúyẹ kannáà pẹ̀lú ara wọn—

28 Àwọn tí wọ́n pọ̀jù lè ṣe iyejú nígbàtí àwọn ipò kan bá mú kí ó má ṣeéṣe lati jẹ́kí ó yàtọ̀—

29 Bíkòṣe pé ọ̀rọ̀ rí báyìí, àwọn ìpinnu wọn kì yíò yẹ sí àwọn ìbùkún kannáà èyítí ìpinnu tí iyejú ti àwọn ààrẹ mẹ́ta ní ẹ̀tọ́ sí ní ìgbàanì; ẹnití a yàn ní ipa ètò ti Melkisédékì, àti tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ àti àwọn ènìyàn mímọ́.

30 Àwọn ìpinnu ti àwọn iyejú wọ̀nyìí, tàbí ọ̀kan nínú wọn, níláti jẹ́ ṣíṣe nínú òtítọ́ gbogbo, ní mímọ́, àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, inú tútù àti ìpamọ́ra, àti ní ìgbàgbọ́, àti ìwà rere, àti ìmọ̀, àìrékọjá, sùúrù, ìwàbí Ọlọ́run, inú rere sí ọmọnìkejì àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́;

31 Nítorípé ìlérí náà ni pé, bí àwọn nkan wọ̀nyìí bá kún inú wọn wọn kì yíò ṣe aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa.

32 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé èyíkéyìí ìpinnu àwọn iyejú wọ̀nyìí jẹ́ nínú àìṣòdodo, a lè gbé e wá síwájú àpéjọ gbogbogbòò ti onírúurú àwọn iyejú, èyítí ó jẹ́ àwọn aláṣẹ ìjọ nípa ti ẹ̀mí; bíbẹ́ẹ̀kọ́ kò le sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nínú ìpinnu wọn.

33 Àwọn Méjìlá náà jẹ́ Olórí Ìgbìmọ̀ Gíga tí ó nrìnrìnàjò, láti ṣe iṣẹ́ oyè ní orúkọ Olúwa, lábẹ́ ìdarí Àjọ Ààrẹ ti Ìjọ, ní ìbamu sí ìgbékalẹ̀ ti ọ̀run; láti kọ́ ìjọ, àti láti ṣe àkóso gbogbo ọ̀rọ̀ ti èyí kannáà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní àkọ́kọ́ sí àwọn Kèfèrí àti ní ẹẹ̀kejì sí àwọn Júù.

34 Àwọn Àádọ́rin ni wọn yío ṣiṣẹ́ ní orúkọ Olúwa, lábẹ́ ìdarí ti àwọn Méjìlá náà tàbí olórí ìgbìmọ̀ tí ó nrìnrìnàjò, nínú ìmúdúró ìjọ àti títò lẹ́sẹẹsẹ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti èyí kannáà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní àkọ́kọ́ sí àwọn Kèfèrí àti lẹ́hìnnáà sí àwọn Júù—

35 Àwọn Méjìlá tí a rán jade, tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́, láti ṣi ìlẹ̀kùn nípa kíkéde ìhìnrere ti Jésù Krístì, àti ní àkọ́kọ́ sí àwọn Kèfèrí àti lẹ́hìnnáà sí àwọn Júù.

36 Àwọn ìgbìmọ̀ gíga ti agbègbè kan, ní àwọn èèkàn ti Síónì, jẹ́ àkójọ iyejú kan tí ó dọ́gbà ní àṣẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìjọ, nínú gbogbo àwọn ìpinnu wọn, sí iyejú ti àjọ ààrẹ, tàbí sí ìgbìmọ̀ gíga tí ó nrìnrìnàjò.

37 Ìgbìmọ̀ gíga ní Síónì jẹ́ àkójọ iyejú kan tí ó dọ́gba ní àṣẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìjọ, nínú gbogbo àwọn ìpinnu wọn, sí àwọn ìgbìmọ̀ ti àwọn Méjìlá ní àwọn èèkàn Síónì.

38 Ó jẹ́ ojúṣe ìgbìmọ̀ gíga tí ó nrìnrìnàjò láti pè àwọn Àádọ́rin, nígbàtí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́, láti dí àlàfo àwọn onírúurú àwọn ìpè fún wíwàásù àti ṣíṣe àmójútó ìhìnrere, dípò èyíkéyìí àwọn míran.

39 Ojúṣe ti àwọn Méjìlá ni, ní gbogbo àwọn ẹ̀ka nlá ti ìjọ, láti yàn àwọn ìránṣẹ ajíhìnrere, bí a ó ṣe yàn wọ́n fún wọn nípa ìfihàn—

40 Ètò oyè àlùfáà yìí ni a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ́ fífi fúnni láti ọwọ́ bàbá sí ọmọ, àti pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ó jẹ́ ti àwọn àtẹ̀lé ọmọ ti àyànfẹ́ irú ọmọ, ẹnití a ṣe àwọn ìlérí fún.

41 Ètò yìí ni a gbé kalẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ti Ádámù, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá nípasẹ̀ ìdílé ní ọ̀nà tí a tò tẹ̀létẹ̀lé yìí:

42 Láti Ádámù sí Sẹ́tì, ẹnití a yàn nípasẹ̀ Ádámù ní ẹni ọdún mọ́kàndínlãdọ́rin, tí a sì ṣúre fún un nípasẹ̀ rẹ̀ ní ọdún mẹ́ta ṣaájú ikú rẹ̀ (Ádámù), àti tí ó gba ìlérí Ọlọ́run lati ọwọ́ bàbá rẹ̀, pé irú ọmọ rẹ̀ ni yíò jẹ́ yíyàn lati ọwọ́ Olúwa, àti pé wọn yíò jẹ́ pípamọ́ títí dé òpin ilẹ̀ ayé;

43 Nítorípé òun (Sẹ́tì) jẹ́ ẹni pípé, ìrí rẹ̀ sì jọ gẹ́gẹ́ bíi ìrí ti bàbá rẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí òun dàbí pé ó rí bíi bàbá rẹ̀ nínú ohun gbogbo, àti pé a lè dáa mọ̀ yàtọ̀ nípa ojọ́ orí rẹ̀ nìkan.

44 Énósì ni a yàn ní ẹni ọdún mẹ́rìnlé lãdóje àti oṣù mẹ́rin, nípa ọwọ́ Ádámù.

45 Ọlọ́run pe Kénánì nínú aginjù ní ogójì ọdún ọjọ́ orí rẹ̀; ó bá Ádámù pàdé ní rírin ìrìnàjò sí ibi Ṣẹdolámákì. Ẹni ọdún mẹ́tàdín láàdọ́rũn ni í ṣe nígbàtí òun gba ìfinijoyè rẹ̀.

46 Máhálálélì jẹ́ ẹni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó dín mẹ́rin àti ọjọ́ méje nígbàtí a ṣe ìlànà ìfinijoyè fún un nípa ọwọ́ Ádámù, ẹnití ó ṣure fún un pẹ̀lú.

47 Járédì jẹ́ ẹni igba ọdún nígbàtí a ṣe ìlànà ìfinijoyè fún un lábẹ ọwọ́ Ádámù, ẹnití ó ṣúre fún un pẹ̀lú.

48 Énọ́kù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbàtí a ṣe ìlànà ìfinijoyè fún un lábẹ ọwọ́ Ádámù; òun sì jẹ́ ẹni ọdún márùn dín láàdọ́rin Ádámù sì ṣúre fún un.

49 Òun sì rí Olúwa, ó sì bá a rìn, ó sì wà níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà; ó sì bá Ọlọ́run rìn fún òjìdínnírinwó àti márũn ọdún, èyítí ó fi dàgbà di ẹni òjì lé nírinwó ó dín mẹ́rin ọdún, kí a tó ṣíi nípò padà.

50 Metúsẹ́là sì jẹ́ ẹni ọgọ́rũn ọdún nígbàtí a ṣe ìlànà fún un lábẹ́ ọwọ́ Ádámù.

51 Lámẹ́kì sì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbàtí a ṣe ìlànà fún un lábẹ́ ọwọ́ Sẹ́tì.

52 Nóà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́wàá nígbàtí a ṣe ìlànà fún un lábẹ́ ọwọ́ Métúsẹlà.

53 Ọdún mẹ́ta ṣaájú ikú Ádámù, ó pe Sẹ́tì, Énọsì, Kénánì, Máhálálélì, Járédì, Énọ́kù, àti Mẹ̀túsẹlà, tí gbogbo wọ́n jẹ́ àlùfáà gíga, pẹ̀lú ìyókù irú ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olõtọ́, sí àfonífojì Adam-ondi-Ahman, àti níbẹ̀ ó fi ìbùkún rẹ̀ ìkẹhìn sí orí wọn.

54 Olúwa sì fi ara hàn sí wọn, wọ́n sì dìde sókè wọ́n sì ṣúre fún Ádámù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Míkáẹlì, ọmọ aládé, olórí ángẹ́lì.

55 Olúwa sì fi ìtura fún Ádámù, ó sì wí fún un pé: Èmi ti gbé ọ kalẹ̀ láti jẹ́ olórí; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yìò wá láti ipasẹ̀ rẹ, ìwọ sì jẹ́ ọmọ aláde kan ní orí wọn títí láé.

56 Ádámù sì dìde sókè ní ààrin ìjọ náà; àti, láìṣírò pé ó ti tẹ̀ wá sílẹ̀ pẹ̀lú ọjọ́ orí, nítorítí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sọtẹ́lẹ̀ ohunkóhun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí ìrú ọmọ rẹ̀ títí dé ìràn tí ó kẹ́hìn.

57 Gbogbo àwọn nkan wọ̀nyìí ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ti Énọ́kù, a ó sì jẹ́rìí wọn ní àkókò tí ó yẹ.

58 Ó jẹ́ ojúṣe ti àwọn Méjìlá, bákannáà, láti yàn àti láti ṣe àgbékalẹ̀ ètò gbogbo àwọn olóyè míràn ti ìjọ, ní ìbámu sí ìfihàn èyítí ó sọ wipe:

59 Sí ìjọ Krístì ní ilẹ̀ Síónì, ní àfikún sí àwọn òfin ìjọ nípa iṣẹ́ ìjọ—

60 Lõtọ́, ni mo wí fún yín, ni Olúwa Àwọn Ọmọ Ogun wí, àwọn alàgbà alákòóso gbọdọ̀ wà láti ṣe àkóso àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ipò iṣẹ́ alàgbà;

61 Àti bákannáà àwọn àlùfáà láti ṣe àkóso ní orí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ipò iṣẹ́ àlùfáà;

62 Àti bákannáà àwọn olùkọ́ láti ṣe àkóso ní orí àwọn wọnnì tí wọn jẹ́ ti ipò iṣẹ́ olùkọ́, ní ọ̀nà kan náà, àti bákannáà àwọn díákónì—

63 Nítorínáà, láti díákónì sí olùkọ́, àti láti olùkọ́ sí àlùfáà, àti láti àlùfáà sí alàgbà, ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí a ṣe yàn wọ́n, gẹ́gẹ́bí àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin ìjọ.

64 Nigbànáà ni ó kan Oyè Àlùfáà Gíga, èyítí ó tóbi jù gbogbo rẹ̀ lọ.

65 Nítorínáà, ẹnìkan gbọdọ̀ jẹ́ yíyàn lati inú Oyè Àlùfáà Gíga láti ṣe àkóso ní orí oyè àlùfáà, a ó sì pè é ní Ààrẹ ti Oyè Àlùfáà Gíga ti ìjọ;

66 Tàbí, ní ọ̀nà míràn, Àlùfáà Gíga Alákòóso ní orí Oyè Àlùfáà Gíga ti Ìjọ.

67 Láti ọ̀dọ̀ èyí kannáà ni ṣíṣe àmójútó àwọn ìlànà àti àwọn ìbùkún ní orí ìjọ ti nwá, nípasẹ̀ ìgbọ́wọ́lé ní orí.

68 Nítorínáà, ipò iṣẹ́ ti bíṣọ́ọ̀pù kò dọ́gba pẹ̀lú rẹ̀; nítorí ipò iṣẹ́ ti bíṣọ́ọ̀pù wà fún ṣíṣe àmójútó ohun gbogbo nípa ti ara;

69 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ bíṣọ́ọ̀pù gbọ́dọ̀ jẹ́ yíyàn láti Oyè Àlùfáà Gíga, bíkòṣe pé òun bá jẹ́ àtẹ́lé ti Áarónì ní tòótọ́ gan an;

70 Nítorí bíkòṣe pé òun jẹ́ àtẹ̀lé ti Áarónì ní tòótọ́ gan an òun kì yíò lè di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà náà mú.

71 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àlùfáà gíga kan, èyí ni pé, ní ipa ètò ti Melkisédékì, lè jẹ́ yíyà sọ́tọ̀ sí ṣíṣe àkóso àwọn nkan ti ara, nípa níní ìmọ̀ wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí òtítọ́;

72 Àti bákannáà láti jẹ́ onídajọ́ ní Ísráẹlì, láti ṣe iṣẹ ìjọ, láti jókòó nínú ìdájọ́ ní orí àwọn olùrékọjá gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí bí a ó ṣe gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ní ìbámu sí àwọn òfin, nípa ìrànlọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ẹnití òun ti yàn tàbí tí yíò yàn lààrin àwọn alàgbà ìjọ.

73 Èyí ni ojúṣe bíṣọ́ọ̀pù ẹnití kìí ṣe àtẹ̀lé Áarónì nítòótọ́ gan an, ṣùgbọ́n tí a ti yàn sí Oyè Àlùfáà Gíga ní ipa ètò ti Melkisédékì.

74 Báyìí ni yíò jẹ́ onídajọ́, àni onídajọ́ gbogbogbòò lààrin àwọn olùgbé Síónì, tàbí ní èèkàn ti Síónì kan, tàbí ní èyíkéyìí ẹ̀ka ìjọ níbití a ó ti yàá sọ́tọ̀ sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, títí tí a ó fi mú àwọn ààlà Síónì gbòòrò síi àti tí yíò di dandan láti ní àwọn bíṣọ́ọ̀pù tàbí àwọn onídájọ́ mĩràn ní Síónì tàbí ní ibòmíràn.

75 Àti níwọ̀nbí a bá yàn àwọn bíṣọ́ọ̀pù míràn wọn yíò ṣiṣẹ́ ní ipò iṣẹ́ kannáà.

76 Ṣùgbọ́n àtẹ̀lé Áarónì kan nítòótọ́ gan an ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin sí ipò àjọ ààrẹ ti oyè àlùfáà yìí, sí àwọn kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, láti ṣiṣẹ́ ní ipò iṣẹ́ bíṣọ́pù ní òmìnira, láìsí àwọn olùdámọ̀ràn, bíkòṣe ní irú ibití Ààrẹ kan ti Oyè Àlùfáà Gíga, ní ipa ètò ti Melkisédékì, bá njẹ́ ẹjọ́, láti jókòó bíi onídajọ́ kan ní Ísráẹ́lì.

77 Àti pé ìpinnu ti èyíkéyìí nínú àwọn ìgbìmọ̀ wọ̀nyìí, ní ìbámu pẹ̀lú òfin èyítí ó wípé:

78 Lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, iṣẹ́ tí ó jẹ́ pàtàkì jùlọ ti ìjọ, àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sòro jùlọ ti ìjọ, níwọ̀nbí kò bá sí ìtẹ́lọ́rùn ní orí ìpinnu ti bíṣọ́pù náà tàbí àwọn onídajọ́, a ó fà á kalẹ̀ a ó sì gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ igbìmọ̀ ìjọ, níwájú Àjọ Ààrẹ ti Oyè Àlùfáà Gíga.

79 Àjọ Ààrẹ ti ìgbìmọ̀ àwọn Olóyè Àlùfáà Gíga yíò sì ní agbára láti pe àwọn àlùfáà gíga míràn, àní méjìlá, láti ṣe ìrànlọ́wọ́ bíi àwọn olùdámọ̀ràn; àti pé báyìí ni Àjọ Ààrẹ ti àwọn Olóyè Àlùfáà Gíga àti àwọn olùdámọ̀ràn yíò ní agbára láti pinnu ní orí ẹ̀rí ní ìbámu sí àwọn òfin ìjọ.

80 Àti lẹ́hìn ìpinnu yìí a kì yíò mú un wá sí ìrántí mọ́ níwájú Olúwa; nítorí èyí ni ìgbìmọ̀ tí ó ga jùlọ tí ìjọ Ọlọ́run, àti ìpinnu tí ó kẹ́hìn ní orí àwọn àríyànjiyàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀mí.

81 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti ìjọ tí a yọ sẹ́hìn kúrò nínú ìgbìmọ ìjọ yìí.

82 Àti níwọ̀nbí Ààrẹ ti Oyè-àlùfáà Gíga kan bá rú òfin, a ó mú un wá sí ìrántí níwájú ìgbìmọ̀ gbogbogbòò ti ìjọ, àwọn ẹnití olùdámọ̀ràn méjìlá ti Oyè-àlùfáà Gíga yíò ràn lọ́wọ́;

83 Ìpinnu wọn ní orí rẹ̀ yíò sì jẹ́ òpin àríyànjiyàn nípa rẹ̀.

84 Báyìí, kò sí ẹnití a ó yọ kúrò nínú òtítọ́ àti àwọn òfin Ọlọ́run, pé kí ohun gbogbo lè jẹ́ síṣe pẹ̀lú ètò àti pẹ̀lú ọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo.

85 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ojúṣe ààrẹ kan ní orí ipò iṣẹ́ ti díákónì ni láti ṣe àkóso ní orí àwọn díákónì méjìlá, láti jókòó ni ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, àti láti kọ́ wọn ní ojúṣe wọn, gbígbé ara wọn sókè nínú ẹ̀mí, bí a ṣe fi fúnni ní ìbámu sí àwọn májẹ̀mú.

86 Àti bákannáà ojúṣe ààrẹ ní orí ipò iṣẹ́ ti àwọn olùkọ́ ni láti ṣe àkóso ní orí àwọn olùkọ́ mẹ́rìnlélógún, àti láti jókòó ní ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, ní kíkọ́ wọn ní àwọn ojúṣe ti ipò iṣẹ́ wọn, bí a ṣe fi fúnni nínú àwọn májẹ̀mú.

87 Bákannáà ojúṣe ààrẹ ní orí Oyè Àlùfáà ti Áárónì ni láti ṣe àkóso ní orí àwọn àlùfáà méjìdínlàádọ́ta, àti láti jókòó ní ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, láti kọ́ wọn ní àwọn ojúṣe ti ipò iṣẹ́ wọn, bí a ṣe fi fúnni nínú àwọn májẹ̀mú—

88 Àarẹ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ bíṣọ́ọ̀pù kan; nítorí èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe ti oyè àlùfáà yìí.

89 Lẹ́ẹ̀kansíi, ojúṣe ti ààrẹ ní orí ipò iṣẹ́ ti àwọn alàgbà ni láti ṣe àkóso ní orí àwọn alàgbà mẹ́rìndínlọ́gọ́rũn, àti láti jókòó ní ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, àti láti kọ́ wọn ní ìbámu sí àwọn májẹ̀mú.

90 Àjọ ààrẹ yìí jẹ́ ọ̀kan tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn àádọ́rin, a sì gbé e kalẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọn kò rìn ìrìnàjò sí inú gbogbo ayé.

91 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ojúṣe Ààrẹ ti ipò iṣẹ́ Oyè-àlùfáà Gíga ni láti ṣe àkóso ní orí gbogbo ìjọ, àti láti wà bíi Mósè—

92 Kíyèsíi, ọgbọ́n ni èyí; bẹ́ẹ̀ni, láti jẹ́ aríran, olùfihàn, olùtúmọ̀, àti wòlíì, pẹ̀lú níní gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run èyítí ó fi sí orí olóri ìjọ náà.

93 Ó sì jẹ́ ní ìbámu sí ìran tí ó nṣe àfihàn ètò ti àwọn Ãdọ́rin, pé kí wọ́n ó ní ààrẹ méje láti ṣe àkóso ní orí wọn, tí a yàn lára iye ti àwọn ãdọ́rin;

94 Àti pé ààrẹ èkeje ti àwọn ààrẹ wọ̀nyìí ni yíó ṣe àkóso ní orí àwọn mẹ́fà;

95 Àti pé àwọn ààrẹ méje wọ̀nyìí ni wọn yío yan àwọn ãdọ́rin míràn ní àfikún sí àwọn ãdọ́rin ti àkọ́kọ́ nínú èyí tí àwọn náà wà, wọn yíó sì níláti ṣe àkóso ní orí wọn;

96 Àti bákannáà àwọn ãdọ́rin míràn, títí di ãdọrin nígbà méje, bí iṣẹ́ inú ọgbà àjàrà bá béèrè fún un ní dandan.

97 Àti pé àwọn ãdọ́rin wọ̀nyìí níláti jẹ́ àwọn ìránṣẹ tí nrìn ìrìnàjo, sí àwọn Kèfèrí ní àkọ́kọ́ àti bákannáà sí àwọn Júù.

98 Ní ìdàkejì àwọn olóyè ìjọ míràn, tí wọn kìí ṣe ara àwọn Méjìlá, tàbí ti Àádọrin, kò sí lábẹ́ ojúṣe láti rin ìrìnàjò lààrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n wọ́n lè rìn ìrìnàjò bí ipò tí wọ́n wà bá ṣe gbà wọn láàyè tó, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ wọ́n lè di àwọn ipò iṣẹ́ tí ó ga àti èyí tí ó ní ojúṣe mú nínú ìjọ.

99 Nítorínáà, nísìsìyìí kí olúkúlùkù ènìyàn kọ́ nípa ojúṣe rẹ̀, àti láti ṣíṣẹ́ ní ipò iṣẹ́ èyítí a yàn án sí ní àìṣèmẹ́lẹ́ gbogbo.

100 Ẹnití ó bá ṣe ọ̀lẹ kì yíò jẹ́ ẹni ìkàyẹ̀ láti dúró, ati ẹnití kò bá kọ́ ẹ̀kọ́ ní ti ojúṣe rẹ̀ àti tí ó fi ara rẹ̀ hàn bí ẹnití a kò tẹ́wọ́gbà kì yíò jẹ́ ẹni ìkàyẹ láti dúró. Àni bẹ́ẹ̀ni. Àmín.