Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 17


Ìpín 17

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, David Whitmer, àti Martin Harris ní Fayette, New York, Oṣù Kẹfà 1829, síwájú kí wọ́n ó tó wo àwọn àwo tí a fín nínú èyí tí àkọsílẹ̀ Ìwé Ti Mọ́mọ́nì wà. Joseph àti akọ̀wé rẹ̀, Oliver Cowdery ti kọ́ ẹ̀kọ́ lati inú ìtumọ̀ àwọn àwo Ìwé Ti Mọ́mọ́nì pé àwọn Ẹlérìí pàtàkì mẹ́ta ni a ó yàn (wo Ìwé Étérì 5:2–4; Ìwé Néfì 11:3; 27:12). Oliver Cowdery, David Whitmer, àti Martin Harris ti ní ìwúrí nípa fífẹ́ nínú ìmísí láti jẹ́ Ẹlérìí pàtàkì mẹ́ta náà. Wòlíì náà beerè lọ́wọ́ Olúwa, ìfihàn yìí ni a sì fi fúnni ní ìdáhùn nípasẹ̀ Urímù àti Túmmímù.

1–4, Nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlérìí Mẹ́ta yíò rí àwọn àwo náà ati àwọn ohun mímọ́ mìíràn; 5–9 Krísti jẹ́rìí sí jíjẹ́ àtọ̀runwá Ìwé Ti Mọ́mọ́nì.

1 Kíyèsíi, mo wí fún yín, pé ẹ gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ pé bí o bá ṣe é pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrèdí ti ọkàn, ẹ̀yin yíò rí àwọn àwo náà, àti àwo ìgbàyà bákannáà, idà ti Lábánì, Urímù àti Túmmímù, èyítí a kó fún arákùnrin Járedì ní orí òkè, nígbàtí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀ ní ojú korojú, àti àwọn ìdarí ìyanu èyí tí a fún Léhì nígbàtí ó wà nínú aginjù, ní ààlà Òkun Pupa.

2 Àti pé nípa ìgbàgbọ́ yín ni ẹ̀yin yíò lè rí wọn, àní nípa ìgbàgbọ́ náà èyí tí àwọn Wòlíì ìgbàanì ní.

3 Àti pé lẹ́hìn tí ẹ bá ti ní ìgbàgbọ́, tí ẹ sì ti rí wọn pẹ̀lú ojú yín, ẹ̀yin yíò jẹ́rìí sí wọn, nípa agbára Ọlọ́run;

4 Àti pé èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe kí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, má baà di píparun, kí èmi baà lè mú àwọn èrò òdodo mi ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn nínú iṣẹ́ yìí.

5 Àti pé ẹ̀yin yíò jẹ́rìí pé ẹ̀yin ti rí àwọn ohun wọ̀nyí, àní bí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kekere, náà ṣe rí wọn; nítorí nípa agbára mi ni òun fi rí wọn, àti nítorípé ó ní ìgbàgbọ́.

6 Àti pé òun ti túmọ̀ ìwé náà, àní abala èyí tí mo pàṣẹ fún un, àti pé bí Olúwa àti Ọlọ́run yín ṣe wà láàyè ó jẹ́ òtítọ́.

7 Nítorínáà, ẹ̀yin ti gba agbára kan náà, àti ìgbàgbọ́ kan náà, àti ẹ̀bùn kan náà gẹ́gẹ́bí ti òun.

8 Àti pé bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn òfin mi ìkẹ́hìn yìí, èyí ti mo ti fi fún yín, àwọn ẹnu ọ̀nà ọ̀run apáàdi kì yíò lè borí yín; nítorípé oore ọ̀fẹ́ mi tó fún yín, a ó sì gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.

9 Àti pé èmi, Jésu Krísti, Olúwa yín àti Ọlọ́run yín ti sọ ọ́ fún yín, kí èmi baà lè mú àwọn èrò òdodo mi ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn. Amin.