Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 94


Ìpín 94

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtlánd, Ohio, 2 Oṣù Kẹjọ 1833. Hyrum Smith, Reynolds Cahoon, àti Jared Carter ni a yàn bíi ìgbìmọ̀ ìkọ́lé Ìjọ.

1–9, Olúwa fi òfin kan fúnni nípa ilé kíkọ́ fún iṣẹ́ Àjọ Ààrẹ; 10–12, Ilé ìtẹ̀wé kan ni a ó kọ́; 13–17, Àwọn ogún kan ni a yàn-sílẹ̀.

1 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, òfin kan ni mo fi fún yín, pé kí ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ti lílàkalẹ̀ àti pípalẹ̀mọ́ fún bíbẹ̀rẹ̀ àti ìpìlẹ̀ ìlú nlá ti èèkàn Síónì, níhĩn ní ilẹ̀ Kirtland, ní bíbẹ̀rẹ̀ ní ilé mi.

2 Àti kíyèsíi, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ síṣe gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ èyítí mo ti fi fún yín.

3 Ẹ sì jẹ́kí ìpín ilẹ̀ àkọ́kọ́ ní apá gúúsù jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí mi fún kíkọ́ ilé kan fún àjọ ààrẹ, fún iṣẹ́ àjọ ààrẹ, ní gbígba àwọn ìfihàn; àti fún iṣẹ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àjọ ààrẹ, nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ìjọ àti ìjọba.

4 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé a ó kọ́ ọ ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà márũn dín lọ́gọ́ta sí ẹsẹ̀ bàtà márũn lé lọ́gọ́ta ní ìbú nínú rẹ̀ àti ní gígùn níinú rẹ̀, ní àgbàlá ti inú lọ́hũn.

5 Àgbàlá ìsàlẹ̀ kan àti àgbàlá òkè kan yío sì wà, gẹ́gẹ́bí àpẹ̀rẹ̀ èyí tí a ó fi fún yín lẹ́hìnwá.

6 Yíó sì jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí Olúwa láti ìpìlẹ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ètò ti oyè àlùfáà, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ èyí tí a ó fi fún yín lẹ́hìnwá.

7 Yíó sì jẹ́ yíyà sí mímọ́ pátápátá sí Olúwa fún iṣẹ́ ti àjọ ààrẹ náà.

8 Ẹ̀yin kì yíò sì fi ààyè gba èyíkéyìí ohun àìmọ́ kankan láti wọlé wá sínú rẹ̀; ògo mi yíò sì wà níbẹ̀, àti pé èmi tìkárami yíò wà níbẹ̀.

9 Ṣùgbọ́n bí èyíkéyìí ohun àìmọ́ bá wọ inú rẹ̀, ògo mi kì yíò wà níbẹ̀; àti pé èmi tìkárami kì yíò wá sí inú rẹ̀.

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ìpín ilẹ̀ kejì ní apá àríwá yío jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí mi fún kíkọ́ ilé kan fún mi, fún iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ti ìtúmọ̀ àwọn ìwé mímọ́ mi, àti ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi yío pàṣẹ fún yín.

11 Yíò sì jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà márùn-dínlọ́gọ́ta sí márùn-lélọ́gọ́ta ní ìbú àti ní gígùn nínú rẹ̀, ní àgbàlá ti inú lọ́hũn; àgbàlá ìsàlẹ̀ kan àti àgbàlá òkè kan yío sì wà.

12 Ilé yìí yío sì jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí Olúwa pátápátá láti ìpìlẹ̀ rẹ̀, fún iṣẹ ti ìwé títẹ́ náà, nínú ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi yíò pàṣẹ fún yín, láti jẹ́ mímọ́, láìlábàwọ́n, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ nínú ohun gbogbo bí a ó ṣe fi fún yín.

13 Àti ní orí ìpín ilẹ̀ kẹta ni ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith yíò gba ogún ìní rẹ̀.

14 Àti ní orí ìpín ìkínní àti èkejì ní ìhà àríwá ni àwọn ìránṣẹ́ mi Reynolds Cahoon àti Jared Carter yíò gba àwọn ogún ìní wọn—

15 Pé kí wọ́n ó lè ṣe iṣẹ́ náà èyítí èmi ti yàn fún wọn, lati jẹ́ ìgbìmọ̀ kan láti kọ́ àwọn ilé tèmi, gẹ́gẹ́bí òfin náà, èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti fi fún yín.

16 Àwọn ilé méjèèjì wọ̀nyìí kì yíò jẹ́ kíkọ́ títí tí èmi yíò fi fún yín ní òfin kan nípa wọn.

17 Àti nísisìyí èmi kò fún yín mọ́ ní àkókò yìí. Amín.