Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 26


Ìpín 26

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith, Oliver Cowdery, àti John Whitmer, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù keje 1830. (wo àkọlé sí ìpín 24).

1 A kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ àti lati wàásù; 2, Ofin nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan ni a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

1 Kíyèsíi, mo wí fún yín pé kí ẹ̀yin kí ó fi àkókò yín sílẹ̀ lati ṣe àṣàrò nínú àwọn ìwé mímọ́, àti lati ṣe ìwàásù, àti lati fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀ ní Colesville, àti lati ṣe àwọn iṣẹ́ yín lorí ilẹ̀ náà, irú èyí tí ó yẹ, títí tí ẹ̀yin yíò fi lọ sí apá ìwọ oòrùn lati ṣe ìpàdé àpéjọpọ̀ èyí tí ó nbọ̀; àti pé nígbànáà ni yío di mímọ̀ èyítí ẹ ó ṣe.

2 Àti pé ohun gbogbo yíó jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú ìfimọ̀ṣọ̀kan ninu ìjọ, nípa ọ̀pọ̀ àdúrà àti ìgbàgbọ́, nítorí ohun gbogbo ni ẹ ó gbà nípa ìgbàgbọ́. Amin.