Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 111


Ìpín 111

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Salem, Massachusetts, 6 Oṣù Kẹjọ 1836. Ní àkókò yìí àwọn olórí ìjọ wà nínú gbèsè nlá nítorí àwọn lãlã wọn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà. Ní gbígbọ́ pé owó nla kan yíò wà fún wọn ní Salem, Wòlíì, Sidney Rigdon, Hyrum Smith, àti Oliver Cowdery rin ìrìnàjò lọ sí ibẹ̀ láti Kirtland, Ohio, láti ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà, papọ̀ pẹ̀lú wíwàásù ìhìnrere. Àwọn arákùnrin náà ṣe onírúurú àwọn iṣẹ́ ìjọ wọ́n sì wàásù díẹ̀. Nigbàtí ó dàbí pé owó kankan kò ní tètè wá, wọ́n padà sí Kirtland. Onírúurú àwọn ohun tí ó hàn ketekete nínú ìtàn náà ni a sọ nípa wọn nínú ọ̀rọ̀ ìfihàn yìí.

1–5, Olúwa mójútó àìní àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ nípa ti ara; 6–11, Òun yíò fi àánú bá Síónì lò yíó sì ṣe ètò ohun gbogbo fún ire àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.

1 Èmi, Olúwa Ọlọ́run yín, èmi kò ṣe àìdunnú pẹ̀lú wíwá yín sí ìrinàjò yìí, láìka ti àwọn àìmòye yín sí.

2 Èmi ní ohun ìṣúra púpọ̀ nínú ìlú nlá yìí fún yín, fún ànfàní ti Síónì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú ìlú nlá yìí, ẹnití èmi yíò kójọpọ̀ jade ní àkókò tí ó tọ́ fún ànfàní Síónì, nípasẹ̀ jíjẹ́ ohun èlò yín.

3 Nítorínáà, ó tọ́ pé kí ẹ̀yin ó mọ̀ àwọn ènìyàn nínú ìlú nlá yìí, bí a ó ṣe darí yín, àti pé bí a ó ṣe fi fún yín.

4 Yíò sì ṣe ní àkókò tí ó tọ́ pé èmi yíò fi ìlú nlá yìí lé yín lọ́wọ́, pé ẹ̀yin yíò ní agbára ní orí rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kì yíò lè ṣe àwárí àṣírí àwọn ipa yín; àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀ tí ó jẹmọ́ wúrà àti fàdákà yíò jẹ́ tiyín.

5 Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu nípa ti àwọn gbèsè yín, nítorí èmi yíò fún yín ní agbára láti san wọ́n.

6 Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu nípa ti Síónì, nítorí èmi yíò fi àánú lò pẹ̀lú rẹ̀.

7 Ẹ dúró pẹ́ ní ìhín yìí, àti ní àwọn agbègbè yí kákiri;

8 Ibití ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ dúró sí, ní pàtàkì jùlọ, yíò jẹ́ títọ́ka sí fún yín nípasẹ̀ àlãfíà àti agbára Ẹ̀mí mi, tí yíò ṣàn sí ọ̀dọ̀ yín.

9 Ibí yìí ni ẹ̀yin lè gbà nípa yíyálò. Kí ẹ sì ṣe ìwádìí pẹ̀lú aápọn nípa àwọn olùgbé ibẹ̀ ní àtijọ́ àti àwọn tí wọ́n tẹ ìlú nlá yìí dó;

10 Nítorí àwọn ìṣúra pọ̀ ju ẹyọ kan lọ fún yín nínú ìlú nlá yìí.

11 Nítorínáà, kí ẹ̀yin ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n bí ejò àti síbẹ̀ láìní ẹ̀ṣẹ̀; èmi yíò sì ṣe ètò ohun gbogbo fún ire yín, bí ẹ̀yin bá ṣe yára tó láti gbà wọ́n. Àmín.