Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 103


Ìpín 103

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 24 Oṣù Kejì 1834. Ìfihàn yìí ni a gbà lẹ́hìn tí Parley P. Pratt àti Lyman Wight dé sí Kirtland, Ohio, àwọn tí wọ́n dé láti Missouri láti dámọ̀ràn pẹ̀lú Wòlíì nípa ọ̀rọ̀ ìrànlọ́wọ́ àti ìmúpadàbọ̀ sípò àwọn Ènìyàn Mímọ́ sí àwọn ilẹ̀ wọn ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson.

1–4, Ìdí tí Olúwa fi fààyè silẹ̀ kí á ṣe inúnibíni sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson; 5–10, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíò borí bí wọ́n bá pa àwọn òfin mọ́; 11–20, Ìràpadà Síónì yíò wá nípa agbára, Olúwa yíò sì máa lọ níwájú àwọn ènìyàn Rẹ̀; 21–28, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níláti kó ara wọn jọ ní Síónì, àti pé àwọn tí wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn lélẹ̀ yíò rí wọn lẹ́ẹ̀kansíi; 29–40, Onírúurú àwọn arákùnrin ni a pè láti ṣetò Àgọ́ Síónì àti lati lọ sí Síónì; a ṣe ìlérí ìṣẹ́gun fún wọn bí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ kíyèsíi, èmi yíò fún yín ni ìfihàn kan àti ofin, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ bí ẹ ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ yín nípa ìgbàlà àti ìràpadà àwọn arákùnrin yín, àwọn tí wọ́n ti fọ́nká ní orí ilẹ̀ Síónì;

2 Nítorí lílé àti kíkọlù láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi, ní orí àwọn tí èmi yíò tú ìbínú mi lé láì ní òdiwọ̀n ní àkókò tèmi.

3 Nitorí mo ti gbà wọ́n láàyè di ìsisìyí, kí wọ́n ó lè fikún òdiwọ̀n àwọn àìṣedéédé wọn, kí ago wọ́n lè kún àkúnwọ́sílẹ̀;

4 Àti kí àwọn tí wọ́n npe ara wọn mọ́ orúkọ mi ó lè gba ìbáwí fún ìgbà díẹ̀ pẹ́lú ìbáwí tí ó dunni àti tí ó bani nínújẹ́, nítorípé wọn kò fetísílẹ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn òfin èyítí mo fi fún wọn pátápátá.

5 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi ti pa àṣẹ kan èyítí yío yé àwọn ènìyàn mi, níwọ̀nbí wọ́n bá fetísilẹ̀ láti wákàtí yìí sí ìmọ̀ràn èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run wọn, yíò fi fún wọn.

6 Kíyèsíi wọn yíò, nítorí mo ti pàṣẹ rẹ̀, bẹ̀rẹ̀sí borí àwọn ọ̀tá mi láti wákàtí yìí gan an.

7 Àti nípa fífetísílẹ̀ láti ṣe àkíyèsí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run wọn, yíò sọ́ fún wọn, wọn kì yíò dáwọ́dúró ní bíborí títí tí àwọn ìjọba ayé yìo fi wà ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ mi, àti tí a ó fi ilẹ̀ ayé fún àwọn enìyàn mímọ́, láti ní i láé ati láéláé.

8 Ṣùgbọ́n níwọ̀nbí wọn kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, àti tí wọ́n kò fetísílẹ̀ láti kíyèsí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ mi, àwọn ìjọba àyé yíò borí wọn.

9 Nítorí a gbé wọn kalẹ̀ kí wọ́n ó lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí ayé, àti láti jẹ́ àwọn olùgbàlà àwọn ènìyàn;

10 Àti níwọ̀nbí wọn kò bá jẹ́ olùgbàlà àwọn ènìyàn, wọn dàbí iyọ̀ tí ó ti sọ adùn rẹ̀ nù, àti pé láti ìgbà náà lọ kò dára fún ohunkóhun ṣùgbọ́n kí á dà á nù síta fún títẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn ènìyàn.

11 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi ti pàṣẹ pé àwọn arákùnrin yín tí a ti fọ́nká yíò padà sí àwọn ilẹ̀ àwọn ogún ìní wọn, wọn yíò sì kọ́ àwọn ibi ahoro Síónì.

12 Nítorí lẹ́hìn ìpọ́njú kíkan, bí mo ṣe wí fún yín nínú òfin ìṣaájú kan, ni ìbùkún náà yíò wá.

13 Kíyèsíi, èyí ni ìbùkún náà èyítí mo ti ṣe ìlérí lẹ́hìn àwọn ìpọ̀njú yín, àti àwọn ìpọ́njú ti àwọn arákùnrin yín—ìràpadà yín, àti ìràpadà ti àwọn arákùnrin yín, àní ìmúpadàbọ̀ sípò wọn sí ilẹ̀ ti Síónì, tí a ó gbé kalẹ̀, tí a ki yíò bì lulẹ̀ mọ́.

14 Bíó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá sọ àwọn ogún ìní wọn di àìmọ́ a ó bì wọ́n lulẹ̀; nítorí èmi kì yíò dá wọn sí bí wọ́n bá sọ àwọn ogún wọn di àìmọ́.

15 Kíyèsíi, mo wí fún yín, ìràpadà Síónì gbọdọ̀ wá nípa agbára;

16 Nítorínáà, èmi yíò gbe ẹnikan dìde fún àwọn ènìyàn mi, ẹnití yíò darí wọn gẹ́gẹ́bí Mósè ṣe darí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì.

17 Nítorí ẹ̀yin ni ọmọ Ísráẹ́lì, àti ti irú ọmọ Ábráhámù, a sì gbọdọ̀ darí yín jade kúrò ní oko ẹrú nípa agbára, àti pẹ̀lú ọwọ́ tí a nà jade.

18 Àti bí a ṣe darí àwọn bàbá yín ní àkọ́kọ́, àní bẹ́ẹ̀ni ìràpadà Síónì yíò jẹ́.

19 Nítorínáà, ẹ má ṣe jẹ́kí ọkàn yín kãrẹ̀, nítorí èmi kò wí fún yín bí mo ṣe wí fún àwọn bàbá yín: Àwọn ángẹ́lì mi yíò lọ ṣaájú yín, ṣùgbọ́n kìí ṣe wíwà níbẹ̀ mi.

20 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín: Àwọn ángẹ́lì mi yíò lọ ṣaájú yín, àti wíwà níbẹ̀ mi bákannáà, àti ní àkókò, ẹ̀yin yíò ní ìlẹ dáradára náà.

21 Lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, ni ẹni náà tí mo fi ìránṣẹ́ náà sí ẹnití Olúwa ọgbà ajarà sọ̀rọ̀, ṣe àkàwé rẹ̀ nínú òwe èyítí mo ti fi fún yín.

22 Nítorínáà ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ mi Joseph Smith Kékeré, ó wí fún agbára ilé mi, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi àti àwọn dídàgbà díẹ̀—Ẹ kó ara yín jọ pọ̀ sí ilẹ̀ Síónì, ní orí ilẹ̀ náà èyítí mo ti rà pẹ̀lú owó tí a ti yà sí mímọ́ fún mi.

23 Ẹ sì jẹ́kí gbogbo ìjọ ó rán àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn wá pẹ̀lú àwọn owó wọn, kí wọ́n ó sì ra àwọn ilẹ̀ àní bí mo ṣe pàṣẹ fún wọn.

24 Àti níwọ̀nbí àwọn ọ̀tá mi bá wá dojúkọ yín láti lé yín kúrò ní orí ilẹ̀ dáradára mi, èyítí mo ti yà sí mímọ́ láti jẹ́ ilẹ̀ Síónì, àní láti inú àwọn ilẹ̀ tiyín lẹ́hìn àwọn ẹ̀rí wọ̀nyìí, eyítí ẹ̀yin ti mú wá sí iwájú mi lòdì sí wọn, ẹ̀yin yíò fi wọ́n ré;

25 Ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá sì fi ré, èmi yíò fi ré, ẹ̀yin yíò sì gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi.

26 Ìwàníbìkan mi yíò sì wà pẹ̀lú yín àní ní gbígbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi, sí ìran kẹta àti ìkẹrin àwọn tí wọ́n kóríra mi.

27 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó bẹ̀rù láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi; nítorí ẹnití ó bá fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi yíò tún ríi padà.

28 Àti pé ẹnikẹ́ni tí kò bá fẹ́ láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi kìí ṣe ọmọ ẹ̀hìn mi.

29 Ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ó gbé ohùn rẹ̀ sókè nínú àwọn ìpéjọpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ìlà oòrùn, ní mímúra àwọn ìjọ̀ sílẹ̀ láti pa àwọn òfin mọ́ èyítí mo ti fi fún wọn nípa ìmúpadàbọ̀ sípò àti ìràpadà Síónì.

30 Ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt àti ìránṣẹ́ mi Lyman Wight ó máṣe padà sí ilẹ̀ àwọn arákùnrin wọn, títí tí wọn yíò fi gba àwọn ọ̀wọ́ láti gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì, ní mẹ́wã mẹ́wã tàbí ní ogoogún, tàbí ní àádọ́ta àádọ́ta, tàbí ní ọgọ́ọgọ́rũn, títí tí wọn yíò fi gba iye tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ti agbára ilé mi.

31 Kíyèsíi èyí jẹ́ ìfẹ́ inú mi; ẹ béèrè ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kìí fi ìgbà gbogbo ṣe ìfẹ́ mi.

32 Nítorínáà, bí ẹ̀yin kò bá lè gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wá kiri pé bóyá ó ṣeéṣe ẹ̀yin lè gba ọ̀ọ́dúnrún.

33 Àti bí ẹ̀yin kò bá lè gba ọ̀ọ́dúnrún, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wá kiri pé bóyá ó ṣeéṣe ẹ̀yin lè gba ọgọ́rũn kan.

34 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, òfin kan ni mo fi fún yín, pé ẹ̀yin kì yíò gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì títí tí ẹ̀yin yíò fi gba ọgọ́rũn kan ti agbára ilé mi, láti gòkè pẹ̀lú yín lọ sí ilẹ̀ Síónì.

35 Nítorínáà, bí mo ṣe wí fún yín, ẹ béèrè ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ẹ gbàdúrà kíkan-kíkan pé bóyá ó ṣeéṣe kí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, lè lọ pẹ̀lú yín, kí òun sì ṣe àkóso ní ààrin àwọn ènìyàn mi, àti kí ẹ ṣètò ìjọba mi ní orí ilẹ̀ tí a ti yà sí mímọ́, àti kí a sì fi ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Síónì kalẹ̀ ní orí àwọn òfin àti àwọn àṣẹ èyítí ó ti wà àti èyítí a ó fi fún yín.

36 Gbogbo ìṣẹ́gun àti ògo ni ó wá sí ìmúṣẹ sí yín nípasẹ̀ aápọn yín, ìṣòtítọ́, àti àwọn àdúrà ìgbàgbọ́.

37 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré.

38 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Lyman Wight ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon.

39 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams.

40 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Orson Hyde ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Orson Pratt, ibikíbi tí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, yíò dámọ̀ràn pẹ̀lú wọn, ní gbígba ìmúṣẹ àwọn òfin wọ̀nyìí èyítí mo ti fi fún yín, kí ẹ sì fi ìyókù sí ọwọ́ mi. Àni bẹ́ẹ̀ni. Àmín.