Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 39


Ìpín 39

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí James Covel, ní Fayette, New York, 5 Oṣù kíní 1831. James Covel ẹnití ó ti jẹ́ ìránṣẹ́ nínú ìjọ Elétò fún bíi ogójì ọdún, dá májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa pé òun yíò gbọ́ràn sí àṣẹ yówù tí Olúwa bá fún òun nípasẹ̀ Wòlíì Joseph.

1–4, Àwọn Ẹni Mímọ́ ní agbára láti di ọmọ Ọlọ́run; 5–6, Láti gba ìhìnrere jẹ́ lati gba Krístì; 7–14, A pàṣẹ fún James Covel lati ṣe ìrìbọmi kí ó sì ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà Olúwa; 15–21, Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa níláti wàásù ìhìnrere saájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì; 22–24, Àwọn tí wọ́n gba ìhìnrere ni a ó kójọ ní ìsisìyí àti ní ayérayé.

1 Fetísílẹ̀ kí o sì tẹ́tísí ohùn ẹni náà tí ó wà láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé, Èmi Ni Nlá náà, àní Jésù Krístì—

2 Ìmọ́lẹ̀ náà àti ìyè ayé; ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ntàn nínú òkùnkùn tí òkùnkùn náà kò sì leè borí rẹ̀;

3 Ẹni kannáà tí ó wá ní ààrin gbùngbùn àkókò sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, tí àwọn tèmi kò sì gbà mí;

4 Ṣùgbọ́n sí iye àwọn tí wọ́n gbà mí, ni èmi fi agbára fún láti di ọmọ mi; àní bẹ́ẹ̀ ni èmi yíò fún iye àwọn tí wọ́n bá gbà mí, ní agbára láti di ọmọ mi.

5 Àti pé lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, ẹnití ó bá gba ìhìnrere mi gbà mí; ẹnití kò bá sì gba ìhìnrere mi kò gbà èmi.

6 Èyí sì ni ìhìnrere mi—ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi nípa omi, àti nigbànáà ni ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá, àní Olùtùnú náà, èyítí ó nfi ohun gbogbo hàn, àti tí ó nkọ́ni ní àwọn ohun àlãfíà ti ìjọba náà.

7 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, ìwọ ìránṣẹ́ mi James, èmi ti wo àwọn iṣẹ́ rẹ èmi sì mọ̀ ọ́.

8 Àti lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ọkàn rẹ ti yẹ nísisìyí níwájú mi ní àkókò yìí, àti pé, kíyèsíi, èmi ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún sí orí rẹ;

9 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbànújẹ́, nítorí ìwọ ti kọ̀ mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nítori ìgbéraga àti àwọn àniyàn ayé.

10 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, àwọn ọjọ́ ìtúsílẹ̀ rẹ ti dé, bí ìwọ yíò bá fetisílẹ̀ sí ohùn mi, èyi tí ó nwí fún ọ pé: Dìde kí a sì rì ọ́ bọmi, kí o sì wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, ní pípe orúkọ mi, ìwọ yíò sì gba Ẹ̀mí mi, àti ìbùkún kan tí ó pọ̀ tó bí ìwọ kò ti mọ̀ rí.

11 Àti bí ìwọ bá ṣe èyí, èmi ti pèsè rẹ sílẹ̀ fún iṣẹ́ kan tí ó tóbi ju èyí lọ. Ìwọ yíò wàásù ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi, èyí ti mo ti rán jade ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí, májẹ̀mú náà èyí tí èmi ti rán jade láti gba àwọn ènìyàn mi padà, tí wọ́n jẹ́ ti ilé Isráẹlì.

12 Yíò sì ṣe tí agbára yíò bà lé ọ; ìwọ yíò ní ìgbàgbọ́ nlá, èmi yíò sì wà pẹ̀lú rẹ èmi yíò sì lọ́ ṣíwájú rẹ.

13 A ti pè ọ́ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi, àti láti kọ́ ìjọ mi, àti láti mú Síónì jáde wá, kí òun kó lè yọ̀ ní orí àwọn òkè, kí ó sì gbilẹ̀.

14 Kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, a kò pè ọ́ láti lọ sí inú àwọn orílẹ̀-èdè ìlà oòrùn, ṣùgbọ́n a pè ọ́ láti lọ sí Ohio.

15 Àti níwọ̀nbí àwọn èniyàn mi yíò ti kó ara wọn jọ pọ̀ ní Ohio, èmi ti fi ìbùkún kan pamọ́ sí ibi ìpamọ́ irú èyí tí a kò tíì mọ̀ lààrin àwọn ọmọ ènìyàn, a ó sì túu jáde lé orí wọn. Àti láti ibẹ̀ àwọn ènìyàn yíò jade lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.

16 Kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé àwọn ènìyàn ní Ohio pèmí nínú ìgbàgbọ́, pẹ̀lú èrò pé èmi yíò dá ọwọ́ mi dúró nínú ìdájọ́ ní orí àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n èmi kò lè sẹ́ ọ̀rọ̀ mi.

17 Nítorínáà bẹ̀rẹ̀síí ṣe pẹ̀lú agbára rẹ kí o sì pe àwọn òṣìṣẹ́ olódodo wá sínú ọgbà ajarà mi, kí á lè pẹ̀ka rẹ̀ fún ìgbà ìkẹhìn.

18 Àti pé níwọ̀nbí wọn bá ti ronúpìwàdà tí wọ́n sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi, tí a sì yà wọ́n sí mímọ́, èmi yíò dá ọwọ́ mi dúró ní ìdájọ́.

19 Nítorínáà, jáde lọ, ní kíkígbe pẹ̀lú ohùn rara, wipe: Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀; ní kíkígbe: Hosannà! Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run Gíga Jùlọ.

20 Jáde lọ ní ṣíṣe ìrìbọmi pẹ̀lú omi, ní títún ọ̀na ṣe ní iwájú mi nítorí àkókò bíbọ̀ mi;

21 Nítorí àkókò náà kù sí dẹ̀dẹ̀; ọjọ́ náà tàbí wákàtí náà ẹnìkan kò mọ̀; ṣùgbọ́n dájúdájú yíò dé.

22 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àwọn nkan wọ̀nyí gbà èmi; àti pé a ó kó wọn jọ sí ọ̀dọ̀ mi ní ayé yìí àti ní ayérayé.

23 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, yíò sì ṣe pé ní orí iye àwọn tí ìwọ bá ṣe ìrìbọmi fún pẹ̀lú omi, ìwọ yíò gbé ọwọ́ lé wọn, wọn yíò sì gba ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́, wọn yíò sì máa wo ọ̀nà fún àwọn àmì bíbọ̀ mi, wọn yíò sì mọ̀ mí.

24 Kíyèsíi, èmi nbọ̀ kánkán. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.