Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58


Ìpín 58

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Woli Joseph Smith, ní Síónì, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, 1 August 1831. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ní ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ lẹ́hin dídée Woli ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sí Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, ìsìn ìfọkànsìn kan ti wáyé, wọn sì ti gba àwọ̀n ọmọ ìjọ méjì wọlé nípasẹ̀ ìrìbọmi. Láàrin ọ̀sẹ̀ náà, díẹ̀ lára àwọn ènìyàn mímọ́ ní Colesville lati ẹ̀ka ìjọ ti Thompson dé pẹ̀lú awọn miràn (wo ìpín 54). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìtara láti mọ ìfẹ́ Olúwa nípa wọn ní ibi ìpéjọpọ̀ titun náà.

1–5, Àwọn ti wọn bá fi ara da ìpọ́njú ni a ó dé ní ade pẹ̀lú ogo; 6–12 Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nílati múrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó ọ̀dọ́ àgùntàn ati ounjẹ alẹ́ Olúwa; 13–18, Àwọn Bíṣọ́pù ni onídajọ́ ní Israẹlì. 19–23, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíò pa awon ofin ilẹ̀ náà mọ́; 24–29, Awọn ènìyàn nílati lo òmìnira wọn láti ṣe rere.30–33, Olúwa npàṣẹ ó sì npa àṣẹ rẹ́; 34–43, Láti ronúpìwàdà, awọn, ènìyàn gbọdọ̀ jẹ́wọ́ kí wọ́n ó sì kọ àwọn ẹ̀ṣẹ wọn sílẹ̀; 44–58, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíò ra ogún ìní wọn àti pé wọ́n yío kórajọ pọ̀ ní Missouri; 59–65, A gbọ́dọ̀ wàásù ìhìnrere náà sí gbogbo ẹ̀dá.

1 Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, kí ẹ sì fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, àti pé kí ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lati ọ̀dọ̀ mi nípa ohun tí mo fẹ́ nípa yín, àti bákannáà nípa ilẹ̀ yìí èyi tí mo ti rãn yín sí.

2 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yin, ìbùkún ni fún ẹni náà tí ó pa àwọn òfin mi mọ́, boyá ní yíyè tàbí ní kíkú, àti ẹni náà tí ó jẹ́ olõtọ́ nínú ìpọ́njú, èrè ẹni yìí kannáà yíò pọ̀ púpọ̀ ní ìjọba ọ̀run.

3 Ẹ̀yin kò lè rí pẹ̀lú ojú ti ara, ní àkókò yìí, àwọn ètò Ọlọ́run yín nípa àwọn ohun wọnnì tí yíò wá lẹ́hinwá, àti ogo tí yíò tẹ̀lée lẹ́hìn ìpọnjú púpọ̀.

4 Nitori lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́nju ni àwọn ìbùkún yíò wá. Nítorínáà ọjọ́ kan nbọ̀ tí a ó dée yín ládé pẹ̀lu ògo nlá, wákatí náà kò tíì dé ṣùgbọ́n ó súnmọ́ itòsí.

5 Ẹ rantí èyí, tí mo ti sọ fún yín ṣaájú, kí ẹ̀yin baà lè fi sí ọkàn, kí ẹ sì gba èyí tí yíò tẹ̀lée.

6 Ẹ kiyesi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, nítorí ìdí èyí ni mo ṣe rán yín—pé kí ẹ lè jẹ olùgbọ́ràn, àti pé kí á lè pèsè ọkàn yín sílẹ̀ láti jẹ́rìí nípa àwọn ohun tí yíó wá;

7 Àti bákannáà pé kí a lè dá yín lọ́lá nínú fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, àti nínú ṣíṣe àkọsílẹ̀ nípa orí ilẹ̀ náà ní orí èyítí ìlú Síónì Ọlọ́run yíò dúró lé;

8 Àti bákannáà pé kí àsè àwọn ohun ọlọ́rã le jẹ́ pípèsè fún àwọn aláìní; bẹ́ẹ̀ni, àsè ti àwọn ohun ọlọ́rã, ti ọtí wáìnì lóri gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ títòrò dáradára, kí ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé èyi tí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì kò níí kùnà;

9 Bẹ́ẹ̀ni, oúnjẹ alẹ́ ti ilé Olúwa, tí a pèsè dáradára, sí èyítí a ó pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

10 Ní àkọ́kọ́, àwọn ọlọ́rọ̀ àti amòye, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti àwọn ọlọla;

11 Àti lẹ́hìn èyíinì ni ọjọ́ agbára mi yíò dé, nígbànáà ni àwon aláìní, àwon arọ, àti àwọn afọ́jú, àti odi, yío wọlé wá sí ibi ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùtàn, wọ́n ó sì kópa nínú oúnjẹ alẹ́ ti Olúwa, tí a pèsè fún ọjọ́ nlá náà tí yíò dé.

12 Kíyèsi, Emi, Oluwa, ti sọ ọ́.

13 Àti pé kí ẹ̀rí náà ó lè jáde lọ láti Síonì, bẹ́ẹ̀ni, láti ẹnu ìlú tí ó jẹ́ ìní ti Ọlọ́run—

14 Bẹ́ẹ̀ni, nítori ìdí èyí ni mo ṣe rán yín wá sí ìhín, àti tí mo ti yan ìránṣẹ mi Edward Partridge, tí mo sì ti fi ipò iṣẹ́ ìránṣe rẹ̀ fún un ní ilẹ̀ yìí.

15 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àìgbàgbọ́ àti ìfọ́jú ọkàn, ẹ jẹ́ kí ó kíyèsára bí bẹ́ẹ̀ kọ́ òun yíó ṣubú.

16 Ẹ kíyèsíi a ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ fún-un, a kì yíò sì fi fúnni mọ́ lẹ́ẹ̀kansíi.

17 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí ni a yàn láti jẹ́ onídàájọ́ ní Isráẹ́lì, bí ó ṣe wà ní àwọn ọjọ́ ìgbàanì, láti pín ilẹ̀ ìní Ọlọ́run fún àwọn ọmọ rẹ̀;

18 Àti láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa ẹri àwọn olódodo, àti nípa ìrànlọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin ìjọba náà tí a fi fúnni lati ọwọ́ àwọn Wòlíì Ọlọ́run.

19 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, òfin mi yíó jẹ́ pípamọ́ ní orí ilẹ̀ yìǐ.

20 Máṣe jẹ́kí ẹnikẹ́ni rò pé òun ni alákòóso; ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run jẹ́ alákòóso fún ẹni tí ndájọ́, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ràn èrò inú ti ara rẹ̀, tàbí, ní ọ̀nà míràn, oun tí ó ngbani ní ìmọ̀ràn tàbi tí ó jókòó ní orí aga ìdájọ́.

21 Máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó ré àwọn òfin ilẹ̀ náà kọjá, nitori ẹni tí ó bá npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ kì yíò nílò láti ré àwọn òfin ilẹ̀ náà kọjá.

22 Nítorínáà, e tẹríba fún àwọn agbára tí wọ́n wà, títí tí òun ó fi jọba ẹnití ó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lati jọba, tí yíò sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

23 Ẹ kíyèsíi, àwọn òfin tí ẹ̀yin ti gbà láti ọwọ́ mi jẹ́ àwọn òfin ti ìjọ, àti pé ní ọ̀nà yìí ni ẹ̀yin yíò dì wọ́n mú. Ẹ kíyèsíi, ọgbọ́n ni èyí.

24 Àti nísisìyí, bí mo ṣe ṣọ̀rọ̀ nípa ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀, àti àwọn tí òun ti yàn bíi olùdámọ̀ràn rẹ̀; àti bákannáà, ilẹ̀ ibùgbé fún ẹni náà tí èmi ti yàn láti mójútó ilé ìṣúra mi;

25 Nitorináà, ẹ jẹ́ kí won ó mú àwọn ẹbí wọn wá sí ilẹ̀ yìí, bí wọn yíò ṣe máa gba ìmọ̀ràn láàrin ara wọn àti èmi.

26 Nítorí ẹ kíyèsíi, kò tọ́ pé kí èmi ó pàsẹ nínú ohun gbogbo; nítorí ẹni tí a bá mú ní dandan nínú ohun gbogbo, òun kannáà jẹ́ ọ̀lẹ àti pé kìí ṣe ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀; nítorínáà òun kò gba èrè kankan.

27 Lõtọ́ ni mo wí, ènìyàn níláti lọ́wọ́ nínú isẹ́ rere pẹ̀lú ìtara, àti kí wọ́n ó ṣe ohun púpọ̀ láti inú ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọn ó sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdodo ṣẹ;

28 Nítorí agbára náà wà nínú wọn, nípa èyi tí wọ́n jẹ́ aṣojú fún ara wọn. Ati pé níwọ̀nbí àwọn ènìyàn bá ṣe rere wọn kì yíò pàdánù èrè wọn bí ó ti wù kí ó rí.

29 Ṣùgbọ́n ẹni náà tí kò ṣe ohunkóhun títí di ìgbà tí a pàṣẹ, tí òun sì gba àṣẹ kan pẹ̀lú iyè méjì ọkàn, àti tí òun pa á mọ́ pẹ̀lú ìlọ́ra, òun kannáà ni a dá lẹ́bi.

30 Tani èmi tí ó ṣe ẹ̀dá èniyàn, ni Olúwa wí, tí yío mú ẹni tí kò gbọ́ràn sí awọn òfin mi bíi aláìlẹ́ṣẹ̀?

31 Tani Emi, ni Oluwa wí, tí ó ti ṣe ilérí tí kò sì mú un ṣẹ?

32 Mo pàṣẹ àwọn ènìyàn kò sì gbọ́ràn; mo paá rẹ́ wọn kò sì gba ìbùkún náà.

33 Nígbànáà ni wọn wí nínú ọkàn wọn: Èyí kìí ṣe iṣẹ́ ti Olúwa, nítorí àwọn ìléri rẹ̀ kò ṣẹ. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀, nítorí èrè wọn ndúró ní ìsàlẹ̀, àti pé kìí ṣe láti òkè wá.

34 Ati nísisìyí mo fún yin ní àwọn ìtọ́sọ́nà síwájú síi nípa ilẹ̀ yìí.

35 Eyí jẹ́ ọgbọ́n inú mi pé kí ìránṣẹ́ mi Martin Harris ó jẹ́ àpẹrẹ fún ìjọ, nípa gbígbé àwọn owó rẹ̀ kalẹ̀ sí iwájú bíṣọ́pù ìjọ.

36 Àti bákannáà, èyí jẹ́ òfin fún gbogbo ẹni tí ó bá wá sí orí ilẹ̀ yìí lati gba ogún ìní; òun yíò sì ṣe pẹ̀lú àwọn owó rẹ̀ gẹ́gẹ́bí òfin ṣe darí.

37 Ó sì jẹ́ ọgbọ́n bákannáà pé kí àwọn ilẹ̀ jẹ́ rírà ní Independence, fún ibi ilé ìṣúra, ati pẹ̀lú fún ilé ìtẹ̀wé náà.

38 Àti pé àwọn ìtọ́ni míràn nípa ìránṣẹ́ mi Martin Harris ni a ó fi fún un nípasẹ̀ Ẹ̀mí, kí òun lè gba ogún ìní rẹ̀ bí ó ṣe dára ní ojú rẹ̀;

39 Ẹ sì jẹ́ kí òun ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó nlépa oríyìn ti aráyé.

40 Àti bákannáà ẹ jẹ́ kí ìranṣẹ́ mi William W. Phelps dúró ní ipò iṣẹ́ èyí tí mo yàn án sí, kí òun sì gba ogún ìní rẹ̀ nínú ilẹ̀ náà;

41 Àti bákannáà ó nílò lati ronúpìwàdà, nítorí èmi, Olúwa, inú mi kò dùn gidigidi síi, nítori òun nwá ọ̀nà láti tayọ, òun kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tó níwájú mi.

42 Ẹ kíyèsíi, ẹni tí ó bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, òun kannáà ni a dáríjì, ati pé Emi, Oluwa, kì yíò ránti wọn mọ́.

43 Nípa èyí ni ẹ ó le mọ̀ bí ẹnìkan bá ronúpiwàdà awọn ẹ̀sẹ̀ rẹ̀—kíyèsi, yíò jẹ́wọ́ wọn yíò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

44 Àti nísisìyí, lõtọ́, ni mo wí nípa ìyókù àwọn àlàgbà ìjọ mi, àkókò náà kò tíì tó, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, fún wọn lati gba ogun ìní wọn ní ilẹ̀ yìí, bíkòsepé wọn bá fẹ́ ẹ nípa àdúrà ìgbagbọ́, bíkòṣe pé a ó yàn án fún wọn lati ọwọ́ Oluwa nìkan.

45 Nitori, ẹ kíyèsíi, won yíò kó awọn èniyàn jọ papọ̀ lati àwọn òpin ilẹ̀ ayé.

46 Nísisìyí, ẹ kó ara yin jọ papọ̀; ati àwọn tí a kò yàn láti dúró ní ilẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ kí wọn ó wàásù ìhìnrere ní àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká, àti lẹhìn èyí kí wọ́n ó padà sí ilé wọn.

47 Ẹ jẹ́ kí wọ́n ó wàásù ní ojú ọ̀nà, kí wọn ó sì jẹrĩ nípa òtítọ́ náà ní ibi gbogbo, kí wọn ó sì pe àwọn ọlọ́rọ̀, àwọn ẹni gíga, àwọn mẹ̀kúnnù, àti àwọn aláìní láti ronúpìwàdà.

48 Ẹ sì jẹ́kí wọ́n ó kọ́ àwọn ìjọ, níwọ̀nbí àwọn olùgbé ayé yío bá ronúpìwàdà.

49 Àti pé ẹ jẹ́ kí á yan aṣojú kan nípa ohùn ìjọ, sí ìjọ ní Ohio, lati gba àwọn owó lati ra àwọn ilẹ̀ ní Síonì.

50 Mo sì fún ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ní òfin kan, pé òun yío kọ àpèjúwe kan ti ilẹ̀ Síonì, àti ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, bí a ó ṣe sọ ọ́ di mímọ̀ nípasẹ̀ Ẹmí fún òun;

51 Àti èpistelì kan ati ìwé owó dídá, ni yío jẹ́ gbígbékalẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjọ láti gba àwọn owó, tí a ó fi sí ọwọ́ biṣọ́pù, fúnra rẹ̀ tàbí aṣojú, bí ó ti rò pé ó tọ́ tabí bí òun bá ṣe darí, láti ra àwọn ilẹ̀ fún ogún ìní fún àwọn ọmọ Ọlọ́run.

52 Nítorí, ẹ kíyèsi, lõtọ́ ni mo wí fún yin, Olúwa fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀hìn àti àwọn ọmọ èniyàn ṣí ọkán wọn payá, àní lati ra gbogbo agbègbè yìí ní orílẹ̀-èdè, ní kánkán bí àkókò bá ṣe gbà wọ́n láàyè sí.

53 Ẹ kíyèsi, èyí jẹ́ ọgbọ́n. Ẹ jẹ́kí wọ́n ó ṣe èyí bí bẹ́ẹ̀kọ́ wọn kì yíò gba ogún ìní, bíkòṣe pé bí yíò bá jẹ́ nípa ìtajẹ̀silẹ̀.

54 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, níwọ̀nbí ilẹ ti wà tí a gbà, ẹ jẹ́kí a rán àwọn òsìsẹ́ jáde wá ní onírúurú sí orí ilẹ̀ yìí, láti ṣiṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run.

55 Ẹ jẹ́kí gbogbo nkan wọ̀nyí jẹ́ ṣíṣe létolétò; ẹ sì jẹ́kí àwọn ànfàní orí ilẹ náà ó máa di mímọ̀ láti àkókò dé àkókò, láti ọwọ́ biṣọ́pù tàbí aṣojú ìjọ.

56 Àti pé ẹ jẹ́kí isẹ àkójọpọ̀ náà máṣe jẹ́ ní ìyára, tàbí ní ìsáré; ṣùgbọ́n yíó jẹ́ ṣíṣe bí a ó ṣe fúnni ní ìmọ̀ràn lati ọwọ́ àwọn alàgbà ìjọ nínú àwọn ìpàdé àpéjọpọ̀, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ èyí tí wọ́n gbà láti àkókò dé àkókò.

57 Ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ mi Sidney Rigdon ó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ kí ó yà á sọ́tọ̀, àti ọ̀gangan ilẹ̀ ti tẹ́mpìlì, fún Olúwa.

58 Àti pé ẹ jẹ́ kí á pe ìpàdé àpéjọpọ̀ kan; àti lẹ́hìnnáà ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon àti Joseph Smith Kékeré, ó padà, àti bákannáà Oliver Cowdery pẹ̀lú wọn, lati ṣe àṣeparí ìyókù iṣẹ́ èyítí mo ti yàn fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn, àti ìyókù bí a ó ti ṣe àkóso rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àpéjọpọ̀.

59 Àti kí ẹnikẹ́ni máṣe padà kúrò ní orí ilẹ̀ yìí bíkòṣe pé òun jẹ́rìí lójú ọnà, nípa ohun náà tí òun mọ̀ àti tí ó gbàgbọ́ dájú jùlọ.

60 Ẹ jẹ́ kí á gba èyíinì tí a ti fi fún Ziba Peterson kúrò ní ọwọ́ rẹ̀; kí òun ó sì dúró bí ọmọ́ ìjọ, àti pé kí ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, títí tí òun yíò fi jẹ́ bíbáwí tó fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; nítorí òun kò jẹ́wọ́ wọ́n, òun sì gbèrò láti fi wọ́n pamọ́.

61 Ẹ jẹ́kí ìyókù àwọn alàgbà ìjọ, tí wọ́n nbọ̀ wá sí orí ilẹ̀ yìí, díẹ̀ nínú wọn tí a ti bùkún fún lọ́pọ̀lọpọ̀ àní tayọ òdiwọ̀n, kí wọn ó ṣe ìpàdé àpéjọpọ̀ bákannáà ní orí ilẹ̀ yìí.

62 Ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge ó darí ìpàdé àpéjọpọ̀ èyí tí wọn yíò ṣe.

63 Àti pé ẹ jẹ́ kí wọn ó padà bákannáà, ní wíwàásù ìhìnrere ní ojú ọ̀nà, kí wọ́n ó sì máa jẹ́rìí àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí a ti fi hàn sí wọn.

64 Nitorí, lõtọ́, ìró náà gbọ́dọ̀ jade lọ́ láti ìhín yìí sí gbogbo ayé, àti sí àwọn ìhà ìkangun ayé—ìhìnrere náà gbọ́dọ̀ jẹ́ kíkéde sí gbogbo ẹ̀dá, pẹ̀lú àwọn àmì tí yíò tẹ̀lé àwọn tí wọ́n gbàgbọ́.

65 Àti kíyèsíi Ọmọ Èniyàn nbọ̀. Amin.