Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 52


Ìpín 52

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí àwọn alàgbà Ìjọ, ní Kirtland, Ohio, 6 Oṣù Kẹfà 1831. Ìpàdé àpapọ̀ kan ti wáyé ní Kirtland, bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta tí ó sì parí ní ọjọ́ kẹfà oṣù Kẹfà. Nínú ìpàdé yìí a ṣe àwọn ìfinijoyè àkọ́kọ́ tí ó ní àpẹrẹ sí ipò iṣẹ́ àlùfáà gíga, àti pé àridájú ìfarahàn àwọn ẹ̀mí èké àti ìtànjẹ ní a ṣe àkíyèsí tí a sì fi wọ́n bú.

1–2, Ìpàdé àpapọ̀ tí ó kàn ni a yàn lati wáyé ní Missouri; 3–8, Yíyan àwọn alàgbà kan tí wọn yíò rin ìrìnajò papọ̀ ni a ṣe; 9–11, Àwọn alàgbà náà yíò kọ́ni ní ohun tí àwọn àpóstélì àti àwọn Wòlíì ti kọ sílẹ̀; 12–21, Àwọn tí a ti fi òyè hàn nípa ọwọ́ Ẹ̀mí mú àwọn èso ìyìn àti ọgbọ́n jáde wá; 22–44, Onírúurú àwọn alàgbà ni a yàn láti jade lọ wàásù bí wọn ṣe nrìn ìrìnàjo lọ si Missouri fún ìpadé àpapọ̀.

1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún àwọn alàgbà ìjọ tí òun ti pè tí ó sì yàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹ́hìn wọ̀nyí, nípa ohùn Ẹ̀mí rẹ̀—

2 Wípé: èmi, Olúwa, yíò sọọ́ di mímọ̀ fún yín ohun tí èmi yío fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe láti àkókò yìí títí di ìgbà ìpadé àpapọ̀ míràn, èyí tí a ó ṣe ní Missouri, ní orí ilẹ̀ èyí tí èmi yíò yà sí mímọ́ fún àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n jẹ́ ìyókù ti Jakọbù, àti àwọn tí wọ́n jẹ́ ajogún gẹ́gẹ́bíi májẹ̀mú náà.

3 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon rin ìrìnàjò wọn ní àìpẹ́ bí wọ́n bá ti lè ṣe ìgbáradì láti fi ilé wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì lè rìn ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ Missouri.

4 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́ sí mi, a ó jẹ́kí ó di mímọ̀ fún wọ́n ohun tí wọn yíò ṣe;

5 Àti bákannáà, níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́, a ó sọọ́ di mímọ̀ fún wọn ilẹ̀ ogún ìní yín.

6 Àti níwọ̀nbí wọn kò bá jẹ́ olõtọ́, a ó ké wọn kúrò, àní bí èmi ṣe fẹ́, bí ó ṣe dára ní ojú mi.

7 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Lyman Wight àti ìránṣẹ́ mi John Corrill ó rin ìrìnàjò wọ́n kánkán;

8 Àti bákannáà kí ìránṣẹ́ mi John Murdock, àti ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith, rin ìrìnàjò wọn lọ sí ibi kan náà gba ọ̀nà Detroit.

9 Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó rin ìrìnàjò láti ibẹ̀ kí wọ́n ó máa wàásù ọ̀rọ̀ náà bí wọ́n ṣe nlọ, láì sọ ohun míràn ju èyí tí àwọn Wòlíì àti àwọn àpóstélì ti kọ, àti èyí tí a ti kọ́ wọn lati ọ̀dọ̀ Olùtùnú nípasẹ̀ àdúrà ìgbàgbọ́.

10 Ẹ jẹ́kí wọ́n lọ ní méjì méjì, àti báyìí ni kí wọ́n ó sì máa wàásù bí wọ́n ṣe nlọ ní ìkọ̀ọ̀kan ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn, ní ṣíṣe ìrìbọmi nípa omi, àti gbígbé ọwọ́ lé wọn ní orí ní ẹ̀bá omi náà.

11 Nítorí bayìí ni Olúwa wí, èmi yíò ké iṣẹ́ mi kúrú nínú òdodo, nítorí ọjọ́ náà nbọ̀ tí èmi yíò rán ìdájọ́ jade sí ìṣẹgun.

12 Ẹ sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Lyman Wight ó ṣọ́ra nítorí Sátánì nfẹ́ láti fẹ́ ẹ dànù bíi ìyàngbò.

13 Sì kíyèsíi, ẹni tí ó bá jẹ́ olõtọ́ ni a ó fi ṣe alákoso ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan.

14 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi yíò fún yín ní àpẹrẹ nínú ohun gbogbo, kí á má baà tàn yín jẹ; nítorí Sátánì wà ní òkèèrè ni ilẹ̀ náà, òun sì nlọ káàkiri ní títan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ—

15 Nísisìyí ẹni tí ó bá ngbàdúrà, tí ọkàn rẹ̀ ní ìrora, òun kan náà jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sími tí ó bá gbọ́ràn sí àwọn ìlànà mi.

16 Ẹni tí ó bá nsọ̀rọ̀, tí ọkàn rẹ̀ ní ìrora, ẹni tí èdè rẹ̀ ṣe pẹ̀lẹ́ tí ó sì gbéniga, òun kannáà jẹ́ ti Ọlọ́run tí òun bá gbọ́ràn sí àwọn ìlànà mi.

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹni tí ó bá wárìrì lábẹ́ agbára mi ni a ó sọ di alágbára, òun yíò sì mú èso ìyìn àti ọgbọ́n jáde wá, gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn àti àwọn òtítọ́ tí èmi ti fi fún yín.

18 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹni tí ó bá borí tí kò sì mú àwọn èso jade wá, àní gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ yìí, kìí ṣe tèmi.

19 Nítorínáà, nípa àpẹrẹ yìí ni ẹ̀yin yíò mọ àwọn ẹ̀mí nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ lábẹ́ gbogbo àwọn ọrun.

20 Àti pé àwọn ọjọ́ náà ti dé; gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni a ó ṣe sí wọn.

21 Kíyèsíi, òfin yìí ni a fi fún gbogbo àwọn alàgbà tí èmi ti yàn.

22 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Thomas B. Marsh àti ìránṣẹ́ mi Ezra Thayre rin ìrìnàjò wọn bákannáà, ní wíwàásù ọ̀rọ̀ náà lójú ọ̀nà sí ilẹ̀ yí kannáà.

23 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Isaac Morley àti ìránṣẹ́ mi Ezra Booth rin ìrìnàjò wọn, bákannáà ní wíwàásù ọ̀rọ̀ náà lójú ọ̀nà sí ilẹ̀ yìí kannáà.

24 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Edward Partridge àti Martin Harris rin ìrìnàjò wọn pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon àti Joseph Smith Kékeré.

25 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi David Whitmer àti Harvey Whitlock pẹ̀lú ó rin ìrìnàjò wọn, kí wọn ó sì wàásù lójú ọ́nà sí ilẹ̀ yìí kannáà.

26 Ẹ sì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt àti Orson Pratt rin ìrìnàjò wọn, kí wọ́n ó sì wàásù lójú ọ̀nà, àní lọ sí ilẹ̀ yìí kannáà.

27 Àti ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Solomon Hancock àti Simeon Carter pẹ̀lú rin ìrìnàjò wọn lọ sí ilẹ̀ yìí kannáà, kí wọ́n ó sì wàásù ní ojú ọ̀nà.

28 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Edson Fuller àti Jacob Scott pẹ̀lú ó rin ìrìnàjò wọn.

29 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Levi W. Hancock àti Zebedee Coltrin pẹ̀lú rin ìrìnàjò wọn.

30 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Reynolds Cahoon àti Samuel H. Smith pẹ̀lú rin ìrìnàjò wọn.

31 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Wheeler Baldwin àti William Carter pẹ̀lú rin ìrìnàjò wọn.

32 Ẹ sì jẹ́ kí á yàn àwọn ìránṣẹ́ mi Newel Knight àti Selah J. Griffin, kí àwọn náà sì rin ìrìnàjò wọn bákannáà.

33 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí, ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn wọ̀nyí rin ìrìnàjò wọn lọ sí ibi kan, ní onírúurú ọ̀nà wọn, ẹnìkan kì yío sì mọ lé orí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn, tàbí rin ìrìnàjò ní ojú ọ̀nà tí ẹlòmíràn.

34 Ẹni tí ó bá jẹ́ olõtọ́, òun náà ni a ó pamọ́ tí a ó sì bùkún fún pẹ̀lú èso lọ́pọ̀lọpọ̀.

35 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Wakefield àti Solomon Humphrey rin ìrìnàjò wọn lọ sí àwọn ilẹ̀ apá ìla oòrùn;

36 Ẹ jẹ́ kí wọ́n ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn, kí wọ́n ó máṣe kéde ohun míràn ju àwọn ìkọ́ni àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì, ohun náà tí wọ́n ti rí àti tí wọ́n ti gbọ́ tí wọ́n sì gbàgbọ́ dájú jùlọ, kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ó lè wá sí ìmúṣẹ.

37 Gẹ́gẹ́bí àyọrísí ìwà ìrékọjá, ẹ jẹ́ kí a gba èyí tí a fi fún Heman Basset kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, kí á sì gbé lé orí Simonds Ryder.

38 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí á yan Jared Carter gẹ́gẹ́bí àlùfáà kan, àti bákannáà George James ni kí a yàn bíi àlùfáà.

39 Ẹ jẹ́ kí ìyókù àwọn alàgbà ó máa ṣe àmójútó àwọn ìjọ, kí wọ́n ó sì máa kéde ọ̀rọ̀ náà ní awọn agbègbè ní àyíká wọn; ẹ sì jẹ́ kí wọ́n ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ wọn kí ó má baà sí ìwà ìbọ̀rìṣà tàbí ìṣe búburú.

40 Àti nínú ohun gbogbo kí ẹ̀yin ó rantí àwọn aláìní àti àwọn tálákà, àwọn aláìsàn àti àwọn olùpọ́njú, nítorí ẹni tí kò bá ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, òun kannáà kìí ṣe ọmọ ẹ̀hìn mi.

41 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon àti Edward Partridge ó mú ìwé ìkaniyẹ kan pẹ̀lú wọn lati inú ìjọ. Kí á sì gba ọ̀kan fún ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery bákannáà.

42 Àti pé báyìí, àní bí èmi ti wí, bí ẹ̀yin bá jẹ́ olõtọ́ ẹ̀yin yíò kó ara yín jọ pọ̀ láti yọ̀ ní orí ilẹ̀ Missouri, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ ìní yín, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín nísisìyí.

43 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, èmi, Olúwa, yíò ṣe ìlú náà kánkán ní àkókò rẹ̀, èmi yíò sì fi adé dé orí àwọn olõtọ́ pẹ̀lú ayọ̀ àti pẹ̀lú ìdùnnú.

44 Kíyèsíi, èmi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, èmi yíò sì gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹ́hìn. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.