Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 81


Ìpín 81

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 15 Oṣù Kejì 1832. Frederick G. Williams ni a pè lati jẹ́ olórí àlùfáà àti olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ ti àwọn olóyè àlùfáà gíga. Àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn fihàn pé nígbàtí a gbà ìfihàn yìí ní Oṣù Kejì 1832, ó pe Jesse Gause sí ipò iṣẹ́ olùdámọ̀ràn sí Joseph Smith nínú Àjọ Ààrẹ. Ṣùgbọ́n, nígbàtí ó kùnà láti tẹ̀síwájú nínu ìwà tí ó báramu pẹ̀lú ipò iṣẹ́ náà, a gba ìpè yìí lẹ́hìnnáà fún Frederick G. Williams. Ìfihàn náà (tí a fi àkókò rẹ̀ sí Oṣù Kejì 1832) nílati jẹ́ kíkíyèsí bíi ìgbésẹ̀ kan sí ójú ọ̀nà ṣíṣe àgbékalẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, ní pàtàkì ní pipeni sí ipò iṣẹ́ olùdámọ̀ràn nínú ìgbìmọ̀ náà àti ní ṣíṣe àlàyé ipò ọlá ti ààyè iṣẹ́ náà. Arákùnrin Gause ṣiṣẹ́ fún ìgbà kan ṣùgbọ́n wọ́n yọọ́ kúrò nínú ìjọ ní Oṣù Kejìlá 1832. Arákùnrin Williams ni a yàn sí ipò iṣẹ́ pàtàkì yìí ní 18 Oṣù Kejì 1833.

1–2, Àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba máa nfi gbogbo ìgbà wà ní ìkáwọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní; 3–7, Bí Frederick G. Williams bá jẹ́ olõtọ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, òun yíò ní ìyè ayérayé.

1 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams: Tẹ́tí sí ohùn ẹni tí ó nsọ̀rọ̀, sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì fetísí pípè pẹ̀lú èyítí a pè ọ́, àní lati jẹ́ àlùfáà gíga nínú ìjọ mi, àti olùdámọ̀ràn kan fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré;

2 Ẹni tí èmi ti fi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà fún, èyítí ó fi ìgbà gbogbo jẹ́ ti Àjọ Ààrẹ àwọn Olóyè àlùfáà Gíga:

3 Nítorínáà, lõtọ́ mo tẹ́wọ́gbàá emi yíò sì súre fún un, àti ìwọ pẹ̀lú, níwọ̀nbí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ nínú ìmọ̀ràn, ní ipò iṣẹ́ èyí tí mo ti yàn fún ọ, ní àdúrà gbígba nígbà gbogbo, ní gbígbé ohùn sókè àti nínú ọkàn rẹ, ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀, bákannáà nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ní kíkéde ìhìnrere ní ilẹ̀ alààyè, àti láàrin àwọn arákùnrin rẹ.

4 Àti ní ṣíṣé àwọn ohun wọ̀nyí ìwọ yíò ṣe rere títóbi jùlọ sí àwọn ẹ̀dá bíi tìrẹ, ìwọ yíò sì mú ìgbéga bá ògo rẹ̀ ẹni tí iṣe Olúwa rẹ.

5 Nísisìyí, jẹ́ olõtọ́; dúró ní ipò iṣẹ́ èyí tí mo ti yàn fún ọ; ran àwọn aláìlágbára lọ́wọ́, fa ọwọ́ tí ó rẹ̀ sókè, kí ẹ sì fi okun fún eékún aláìlera.

6 Àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ títí dé òpin ìwọ yíò gba adé ara àìkú, àti ìyè ayérayé nínú àwọn ibùgbé èyí tí èmi ti pèsè nínú ilé Bàbá mi.

7 Kíyèsíi, sì wòó, ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Álfà àti Ómégà, àní Jésù Krístì. Àmín.