Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 19


Ìpín 19

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Manchester, New York, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ ìgbà ooru 1829. Nínú ìtàn rẹ̀, Wòlíì náà ṣe àfihàn rẹ̀ bíi “òfin ti Ọlọ́run tí kìí sìí ṣe ti ènìyàn, sí Martin Harris, tí a fi fúnni láti ọ̀dọ̀ ẹni náà tí ó jẹ́ Ayérayé.”

1–3 Krístì ní gbogbo agbára; 4–5, Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbí kí wọ́n ó jìyà; 6–12, Ìbáwí àìlópin jẹ́ ìbáwí ti Ọlọ́run; 13–20, Krístì jìyà fún gbogbo ènìyàn, pé kí wọn ó má baà jìyà bí wọn bá lè ronúpìwàdà; 21–28, Wàásù ìhìnrere ironúpìwàdà; 29–41, Kéde àwọn ìhìn ayọ̀.

1 Èmi ni Álfà àti Òmégà, Krístì Olúwa; bẹ́ẹ̀ni, àní èmi ni, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, Olùràpadà aráyé.

2 Èmi, lẹ́hìn tí mo ti ṣetán tí mo sì parí ìfẹ́ inú ẹni náà tí èmi í ṣe tirẹ̀, àní Bàbá náà, nípa èmi—tí mo ti ṣe èyí kí èmi ó baà lè mú ohun gbogbo wá sábẹ́ àkóso èmi tìkara mi—

3 Níní gbogbo agbára ní ìkáwọ́, àní láti pa Sátánì àti awọn iṣẹ́ rẹ̀ run ní òpin ayé, àti ní ọjọ́ ìdájọ́ nlá tí ó kẹ́hìn, èyí tí èmi yíò ṣe ní orí àwọn olùgbé ibẹ̀, ní dídájọ́ olukúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀ àti awọn ohun èyí tí ó ti ṣe.

4 Àti pé dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà tàbí kí wọn ó jìyà, nítorí èmi, Ọlọ́run, mo jẹ́ àìnípẹ̀kun.

5 Nítorínáà, èmi kò pa àwọn ìdájọ́ èyítí èmi yíó ṣe rẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ègbé yíò wá síwájú, ẹkún, ìpohùnréré ẹkún, àti ìpahínkeke, bẹ́ẹ̀ni, sí àwọn tí wọ́n bá wà ní ọwọ́ òsì mi.

6 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò kọọ́ pé kò ní sí òpin sí oró yìí, ṣùgbọ́n a kọọ́ pé oró àìnípẹ̀kun.

7 Lẹ́ẹ̀kansíi, a kọọ́ pé ìdálẹ́bi ayérayé; nítorínáà ó hàn gbangba ju àwọn ìwé mímọ́ míràn lọ, pé kí èyí lè ṣiṣẹ́ ní orí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, ní àpapọ̀ fún ògo orúkọ mi.

8 Nítorínáà, èmi yíò ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀ yìí fún ọ, nítorí ó yẹ kí ìwọ mọ̀ àní gẹ́gẹ́bí àwọn àpostélì mi.

9 Èmi nsọ̀rọ̀ sí ẹ̀yin tí a yàn nípa ohun yìí, àní bíi ẹnìkan, kí ẹ̀yin baà lè wọ inú ìsinmi mi.

10 Nítorí, kíyèsíi, ohun ìjìnlẹ̀ ti ìwà-bí-Ọlọ́run, báwo ni ó ṣe tóbi tó! Nítorí, kíyèsíi, èmi jẹ́ àìnípẹ̀kun, àti pé ìbáwí èyí tí a fi fúnni láti ọwọ́ mi jẹ́ àìlópin, nítorí Àìnípẹ̀kun ni orúkọ mi. Nítorínáà—

11 Ìjìyà ayérayé jẹ́ ìjìyà ti Ọlọ́run.

12 Ìjìyà àìlópin jẹ́ ìjìyà ti Ọlọ́run.

13 Nitorí-èyí, mo pàṣẹ fún ọ lati ronúpìwàdà, kí o sì pa àwọn òfin mọ́ èyítí ìwọ ti gbà láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kekere, ní orúkọ mi.

14 Àti pé nípa agbára mi títóbi jùlọ ni ìwọ fi gbà wọ́n.

15 Nísisìyí mo pàṣẹ fún ọ lati ronúpìwàdà—ronúpàwàdà, bí bẹ́ẹ̀kọ́ èmi yíò nà ọ́ pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu mi, àti pẹ̀lù ìrunú mi, àti pẹ̀lú ìbínu mi, àti pé àwọn ìrora rẹ yíò dunni jọjọ—bí yíò ṣe dunni tó ìwọ kò mọ̀, bí yíò ṣe ní oró tó ìwọ kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ni, bí yíò ṣe nira láti faradà tó ìwọ kò mọ̀.

16 Nítorí kíyèsíi, èmi, Ọlọ́run, ti jìya àwọn ohun wọ̀nyí fún gbogbo èniyàn, pé kí àwọn má baà jìyà bí wọ́n bá ronúpìwàdà;

17 Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá ní ronúpìwàdà wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà àní bí ti èmi;

18 Ìjìyà tí èyítí ó mú èmi tìkara mi, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi jù ohun gbogbo lọ, láti gbọ̀n-rìrì nítorí ìrora, àti lati ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, àti láti jìyà ní ara àti ẹ̀mí—àti lati fẹ́ pé kí èmi máṣe mu nínú aago kíkorò náà, kí èmi sì fàsẹ́hìn—

19 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ògo ni fún Bàbá, àti pé èmi kópa mo sì ṣe àṣeparí àwọn ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn.

20 Nítorínáà, mo pàṣẹ fún ọ lẹ́ẹ̀kansíi lati ronúpìwàdà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yíò rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú agbára mi títóbi jùlọ; àti pé kí ìwọ jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ yíó jìyà àwọn ìbáwí èyítí èmi ti sọ, nínú èyíti ó jẹ́ kékeré jùlọ, bẹ́ẹ̀ni, àní nínú ìwọ̀n tí ó kéré jù ni ìwọ ti tọ́wò ní àkókò tí mo gba ẹ̀mí mi kúrò.

21 Àti pé mo pàṣẹ fún ọ pé kí o má ṣe wàásù ohun míràn bíkòṣe ìrònúpìwàdà, àti kí o máṣe fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn fún ayé títí yíò fi jẹ́ ọgbọ́n nínú mi.

22 Nitorí wọn kò tíi lè gba ẹran báyìí, ṣùgbọ́n wàrà ni wọ́n gbọdọ̀ gbà; nítorínáà, wọn kò gbọdọ̀ mọ àwọn ohun wọnyìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọ́n yío ṣègbé.

23 Kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ mi; rìn nínú ìwà pẹ̀lẹ́ ti Ẹ̀mí mi, ìwọ yíò sì ní àlãfíà nínú mi.

24 Èmi ni Jésù Krístì; Èmi wá nípa ìfẹ́ ti Bàbá, Èmi sì nṣe ìfẹ́ rẹ̀.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ; tàbí kí o lépa ẹ̀mí ẹnìkéjì rẹ.

26 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ohun ìní rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi òmìnira jọ̀wọ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ títẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí tí ó ní òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú—

27 Èyítí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ mi sí àwọn Kèfèrí, pé láìpẹ́ kí ó le lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù, tí àwọn ará Lámánì jẹ́ ìyókù wọn, pé kí wọn ó le gba ìhìnrere náà gbọ́, ati kí wọ́n ó sì má baà tún fi ojú sọ́na fún Messia kan lati wá ẹni tí ó ti wá tẹ́lẹ̀.

28 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi pàṣẹ fún ọ pé kí ìwọ ó máa gbàdúrà ní gbígbé ohùn sókè àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nínú ọkàn rẹ; bẹ́ẹ̀ni, níwájú àwọn ènìyàn àti ní ìkọkọ̀, ní gbangba àti nínú ìyẹ́wù.

29 Àti pé ìwọ yíò kéde àwọn ìrohìn ayọ̀, bẹ́ẹ̀ni, kéde rẹ̀ ní orí àwọn òkè, àti ní gbogbo ibi gíga, àti lààrin àwọn ènìyàn gbogbo tí a ó gbà ọ́ láàyè láti rí.

30 Àti pé ìwọ yíò ṣe é pẹ̀lú gbogbo ìwà ìrẹ̀lẹ̀, níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, láì pẹ̀gàn àwọn apẹ̀gàn.

31 Àti pé nípa àwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ ni ìwọ kí yíò sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yío kéde ironúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà, àti ìdárìjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa ìrìbọmi, àti nípa iná, bẹ́ẹ̀ni, àní Ẹ̀mí Mímọ́.

32 Kíyèsíi, èyí jẹ́ títóbi ati tí ìkẹhìn nínú òfin tí èmi yíò fi fún ọ nípa ohun yìí; nítorí èyí yíò tó fún irìn òòjọ́ rẹ, àní títí dé òpin ọjọ́ ayé rẹ.

33 Àti pé òṣì ni ìwọ yíò gbà bí ìwọ kò bá ka àwọn ìmọràn wọ̀nyìí sí, bẹ́ẹ̀ni, àní ìparun tìrẹ àti ohun ìní rẹ.

34 Fi apákan ohun ìní rẹ fún ni, bẹ́ẹ̀ni, àní apákan àwọn ilẹ̀ rẹ, àti gbogbo rẹ̀ bí kò ṣe ìtọ́jú àwọn ẹbí rẹ.

35 San gbèsè tí ìwọ ti jẹ atẹ̀wé. Yọ ara rẹ kúrò nínú ìgbèkùn.

36 Kúrò ní ilé àti ibùgbé rẹ, bíkòṣe nígbàtí ìwọ bá fẹ́ láti rí àwọn ẹbí rẹ.

37 Àti pé sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira sí gbogbo ènìyàn; bẹ́ẹ̀ni, wàásù, gbani níyànjú, kéde òtítọ́, àní pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú ìró ìdùnnú, ní kíkígbe—Hòsánnà, Hòsánnà, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run!

38 Gbàdúrà nígbà gbogbo, èmi yíò sì tú Ẹ̀mí mi sí orí rẹ, àti pé púpọ̀ ni ìbùkún rẹ yíò jẹ́—bẹ́ẹ̀ni, àní ju bí ìgbà tí ìwọ rí àwọn ohun ìṣúra ti ayé ati àwọn ohun àìtọ́ gbogbo ní ìwọ̀n bí ó ṣe tó.

39 Kíyèsíi, ìwọ ha lè ka èyí láì yọ̀ àti láì gbé ọkàn rẹ sókè fún ìdùnnú?

40 Tàbí ìwọ ha le sáré káàkiri síi gẹ́gẹ́bí afọ́jú adarí?

41 Tàbí ìwọ ha le ní ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́, àti pé kí ìwọ hùwà bí ọlọ́gbọ́n níwájú mi? Bẹ́ẹ̀ni, wá sí ọ̀dọ̀ èmi Olùgbàlà rẹ. Amin.