Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 98


Ìpín 98

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 6 Oṣù Kẹjọ 1833. Ìfihan yìí wá ní ìyọrísí inúnibíni sí àwọn Ẹni Mímọ́ ní Missouri. Pípọ̀síi àwọn olùgbé ọmọ Ìjọ ní Missouri yọ àwọn olùgbé mĩràn lẹ́nu, àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀lára ìdẹ́rùbà nípa iye àwọn Ènìyàn Mímọ́, ipá wọn ní ti òṣèlú àti ọrọ̀ ajé, àti àwọn yíyàtọ̀ wọn ní ti àṣà àti ẹ̀sìn. Ní Oṣù Keje 1833, àwọn jàndùkú kan ba àwọn ohun ìní Ìjọ jẹ́, wọ́n kun àwọn ọmọ Ìjọ méjì ní ọ̀dà àti ìyẹ́, wọ́n sì sọ pé kí àwọn Ènìyàn Mímọ́ fi Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ díẹ̀ nínú ìrohìn àwọn ìsòro ní Missouri ni ó ti dé ọ̀dọ̀ Wòlíì náà ní Kirtland láìsí àní-àní (ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ibùsọ̀ sí ibẹ̀), bí ipò ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ pàtàkì tó lè jẹ́ mímọ̀ fún un ní ọjọ́ yìí nípa ìfihàn nìkan.

1–3, Àwọn ìpọ́njú ti àwọn ẹni Mímọ́ yíò jẹ́ fún ire wọn; 4–8, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti bá òfin ilẹ̀ náà dá ọ̀rẹ́; 9–10 Àwọn ènìyàn olõtọ́, ọlọ́gbọ́n ati ẹni rere ni a níláti tì lẹ́hìn fún ìṣèjọba ti ayé; 11–15, Àwọn tí wọ́n fí ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nínú iṣẹ́ Olúwa yíò ni ìyè ayérayé; 16–18, Ẹ kọ ogun sílẹ̀ kí ẹ sì kéde àlãfíà; 19–22, àwọn Ẹni Mímọ́ ní Kirtland ni a báwí ti a sì pàṣẹ fún láti ronúpìwàdà; 23–32, Olúwa fi àwọn òfin Rẹ̀ hàn nípa àkóso àwọn inúnibíni àti àwọn ìpọ́njú tí a gbé lé orí àwọn ènìyàn Rẹ̀; 33–38, Ogun jẹ́ ohun tí a dá láre nígbàtí Olúwa bá pàṣẹ rẹ̀ nìkan; 39–48, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti dárí jì àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ẹnití, bí wọ́n bá ronúpìwàdà, wọn yíò bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìgbẹ̀san Olúwa bákannáà.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ jẹ́ kí á tu ọkàn yín nínú; bẹ́ẹ̀ni, ẹ yọ̀ títí láé, àti nínú ohun gbogbo ẹ máa dúpẹ́;

2 Ní dídúró de Olúwa pẹ̀lú sùúrù, nítorí àwọn àdúrà yín ti wọ etí Olúwa Sábáótì, a sì ti kọ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú èdídí àti májẹ̀mú yìí—Olúwa ti búra àti pàṣẹ pé wọn yíò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

3 Nítorínáà, òun fi ìlérí yìí fún yín, pẹ̀lú májẹ́mú kan tí a kò lè yípadà pé wọn yíò di mímúṣẹ; àti ohun gbogbo nípa èyí tí a ti pọ́n yín lójú yíò ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ire yín, àti sí ògo orúkọ mi, ni Olúwa wí.

4 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín nípa àwọn òfin ilẹ̀ náà, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí àwọn ènìyàn mi kíyèsíi láti ṣe ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi pàṣẹ fún wọn.

5 Àti pé òfin ilẹ̀ náà èyítí ó jẹ́ ìlànà-òfin, tí ó faramọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ ti òmìnira nnì ní síṣe ìtọ́jú àwọn ẹ̀tọ́ àti àwọn ànfàní, jẹ́ ti gbogbo aráyé, àti pé ó ṣeé dáláre níwájú mi.

6 Nítorínáà, èmi, Olúwa, dá yín láre, àti àwọn arákùnrin yín ti ìjọ mi, ní bíbá òfin náà ṣe ọ̀rẹ́ èyítí ó jẹ́ òfin ti ìlànà-òfin ti ilẹ̀ náà;

7 Àti bí ó ti jẹ mọ́ òfin ti ènìyàn, ohunkóhun tí ó pọ̀ tàbí kéré ju èyí, wá lati inú ibi.

8 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sọ yín di òmìnìra, nítorínáà ẹ̀yin di òmìnìra nítòótọ́; àti pé òfin náà bákannáà sọ yín di òmìnìra.

9 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbàtí àwọn ẹni búburú bá nṣe àkóso, àwọn ènìyàn á kẹ́dùn.

10 Nítorínáà, àwọn olõtọ́ ènìyàn àti àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni kí á wá pẹ̀lú aápọn, àti pé àwọn ènìyàn rere àti àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nílati ṣe àkíyèsí láti ṣe àtìlẹ́hìn; bíbẹ́ẹ̀kọ́ ohunkóhun tí ó bá kéré ju àwọn èyí lọ wá lati inú ibi.

11 Mo sì fún yín ní òfin kan, pé ẹ̀yin yíó kọ gbogbo ibi sílẹ̀ ẹ ó sì fi ara mọ́ rere gbogbo, kí ẹ̀yin ó lè gbé nípa gbogbo ọ̀rọ̀ èyítí ó jade wá láti ẹnu Ọlọ́run.

12 Nítorí òun yíò fi fún àwọn olõtọ́ ní ẹsẹ lórí ẹsẹ, ìkọ́ni lé ìkọ́ni; èmi yíò sì dán yín wò àti wádìí yín nípa èyí.

13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nínú iṣẹ́ mi, nítorí orúkọ mi, yíò rí i lẹ́ẹ̀kansíi, àní ìyè ayérayé.

14 Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá yín, nítorí èmi ti pàṣẹ nínú ọkàn mi, ni Olúwa wí, pé èmi yíò dán yín wò nínú ohun gbogbo, bóyá ẹ̀yin yíò dúró nínú májẹ̀mú mi, àní sí ikú, kí a lè ríi yín ní ìkàyẹ.

15 Nítorí bí ẹ̀yin kò bá lè dúró nínú májẹ̀mú mi ẹ̀yin kò lè di ẹni ìkàyẹ lati gbà mí.

16 Nítorínáà, ẹ kọ ogun sílẹ̀ kí ẹ sì kéde àlãfíà, kí ẹ sì wá ọ̀nà pẹ̀lú aápọn láti yí ọkàn àwọn ọmọ sí àwọn bàbá wọn, àti ọkàn àwọn bàbá sí àwọn ọmọ;

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ọkàn àwọn Júù sí àwọn Wòlíì, àti àwọn Wòlíì sí àwọn Júù; kí èmi ó má baà wá lati kọlu gbogbo ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ègún, àti kí gbogbo ẹran ara ó sì jóná níwájú mi.

18 Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkan yín ó dàrú, nítorí nínú ilé Bàbá mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ní ó wà, èmi sì ti pèsè ààyè kan sílẹ̀ fún yín; àti ní ibi tí Bàbá mi àti èmi wà, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yío wà bákannáà.

19 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, inú mi kò dùn gidigidi pẹ̀lú púpọ̀ àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ ní Kirtland;

20 Nítorí wọn kò kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, àti àwọn ọ̀nà búburú wọn, ìgbéraga ọkàn wọn, àti ojú kòkòrò wọn, àti gbogbo àwọn ohun ìríra wọn, kí wọ́n ó sì kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti ìyè ayérayé èyítí èmi ti fi fún wọn.

21 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé èmi, Olúwa, yíò bá wọn wí èmi ó sì ṣe ohunkóhun tí mo yàn, bí wọn kò bá ronúpìwàdà àti kíyèsí ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi ti sọ fún wọn.

22 Àti lẹ́ẹ̀kansíi èmi wí fún yín, bí ẹ̀yin bá kíyèsíi láti ṣe ohunkóhun tí èmi pàṣẹ fún yín, èmi, Olúwa, yíò yí gbogbo ìbínú àti ìrunú kúrò ní ọ̀dọ̀ yín, àti pé ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpáàdì kì yíò lè borí yín.

23 Nísisìyí, èmi bá yín sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹbí yín—bí àwọn ènìyàn bá kọlù yín, tàbí àwọn ẹbí yín, lẹ́ẹ̀kan, tí ẹ̀yin sì fi ara dàá pẹ̀lú sùúrù àti tí ẹ́ kò kẹ́gàn lòdì sí wọn, tàbí wá láti gbẹ̀san, ẹ̀yin yíò gba èrè;

24 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fi ara dàá pẹ̀lú sùúrù, a ó kàá fún yín bíi ohun tí a wọ̀n jáde bíi òdiwọ̀n tí ó yẹ fún yín.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, bí ọ̀tá yín bá kọlù yín ní ìgbà kejì, àti tí ẹ̀yin kò kẹ́gàn lòdì sí ọ̀tá yín, tí ẹ sì fi ara dàá pẹ̀lú sùúrù, èrè yín yíò jẹ́ ní ìlọ́po-ọgọ́rũn kan.

26 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, bí òun bá kọlù yín ní ìgbà kẹta, tí ẹ̀yin sì fi ara dàá pẹ̀lú sùúrù, èrè yín yíò di méjì sí yín ní ìlọ́po mẹ́rin;

27 Àti pé àwọn ẹ̀rí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí yíò dúró ní ìlòdìsí ọ̀tá yín bí òun kò bá ronúpìwàdà, a kì yíò sì pa wọ́n rẹ́ kúrò.

28 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ọ̀tá náà bá bọ́ lọ́wọ́ ìgbẹ̀san mi, kí a má baà mú òun wá sí ìdájọ́ níwájú mi, nígbànáà kí ẹ̀yin ó ríi pé ẹ kìlọ̀ fún un ní orúkọ mi, kí ó má tún wá mọ́ sí orí yín, tàbí sí orí ẹbí yín, àní àwọn ọmọ ọmọ yín sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹ́rin.

29 Àti nígbànáà, bí òun bá wá sí orí yín tàbí àwọn ọmọ yín, tàbí àwọn ọmọ ọmọ yín sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin, èmi ti fi ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́;

30 Àti nígbànáà bí ẹ̀yin bá dá a sí, ẹ̀yin yíò gba ère fún òdodo yín; àti bákannáà àwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ yín sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.

31 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀tá yín wà ní ọwọ́ yín; bí ẹ̀yin bá si san án fún un gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ẹ̀yin ní ìdáláre; bí òun bá ti wá ẹ̀mí yín, àti tí ẹ̀mí yín wà nínú ewu nípasẹ̀ rẹ̀, ọ̀tá yín wà ní ọwọ́ yín ẹ̀yin sì ní ìdáláre.

32 Kíyèsíi, èyí ni òfin náà tí èmi fún ìránṣẹ́ mi Néfì, àti àwọn bàbá yín, Jósefù, àti Jákobù, àti Isákì, àti Abrahámù, àti gbogbo àwọn Wòlíì àti àpóstélì tèmi ìgbàanì.

33 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èyí ni òfin náà tí èmí fún àwọn ènìyàn mi ìgbàanì, pé wọn kì yíò jade lọ sí ogun ní ìdojúkọ orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, tàbí ènìyàn kankan, bíkòṣe pé èmi, Olúwa pàṣẹ fún wọn.

34 Àti bí orílẹ̀-èdè, ahọ́n, tàbí ènìyàn kankan bá sì kéde ogun kọjú sí wọn, wọ́n yíò kọ́kọ́ gbé ọ̀págun àlãfíà sí àwọn ènìyàn, orílẹ̀-èdè, tàbí ahọ́n náà;

35 Àti pé bí àwọn ènìyàn náà kò bá gba ẹbọ-ọrẹ àlãfíà, bóyá ní ẹ̀ẹ̀kejì tàbí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kẹta, wọn yíò mú àwọn ẹ̀rí wọ̀nyìí wá síwájú Olúwa;

36 Nígbánáà èmi, Olúwa, yíò fún wọn ní òfin kan, èmi ó sì dá wọn láre ní jíjáde lọ ja ogun dojú kọ orílẹ̀-èdè, ahọ́n, tàbí ènìyàn náà.

37 Àti pé èmi, Olúwa, yíò ja àwọn ogun wọn, àti àwọn ogun àwọn ọmọ wọn, àti ti àwọn ọmọ ọmọ wọn, títí tí wọn yíò fi gba ẹ̀san wọn lára gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.

38 Kíyèsíi, èyí ni àpẹrẹ kan sí gbogbo ènìyàn, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, fún ìdáláre níwájú mi.

39 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí, lẹ́hìn tí ọ̀tá yín ti kọlù yín ní ìgbà àkọ́kọ́, òun ronúpìwàdà ó sì wá sí ọ̀dọ̀ yín ní bíbéèrè fún ìdáríjì yín, ẹ̀yin yíò dáríjì í, ẹ̀yin kì yíò sì ka á sí ẹ̀rí kan lòdì sí ọ̀tá yín mọ́—

40 Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí ìgbà keji àti ẹ̀kẹta; àti ní iye ìgbà tí ọ̀tá yín bá ronúpìwàdà ti ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ti ṣẹ̀ síi yín, ẹ̀yin yíò dárí jì í, títí di ìgba àádọ́rin ní ọ̀nà méje.

41 Àti bí òun bá dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí yín tí kò sì ronúpìwàdà ní ìgbà àkọ́kọ́, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ ẹ̀yin yíò dárí jì í.

42 Àti bí òun bá sì dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí yín ní ìgbà kejì, tí kò sì ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ èyin yíò dáríjì i.

43 Àti bí òun bá dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí yín ní ìgbà kẹta, tí kò sì ronúpìwàdà, ẹ̀yin yíò dárí jì í bákannáà.

44 Ṣùgbọ́n bí òun bá dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí yín ní ìgbà kẹrin ẹ̀yin kì yíò dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹ́ ó mú àwọn ẹ̀rí wọ̀nyìí wá síwájú Olúwa; a kì yíò sì pa wọ́n rẹ́ kúrò títí tí òun yíò fi ronúpìwàdà àti tí yío san ẹ̀san padà fún yín ní ìlọ́po mẹ́rin nínú ohun gbogbo èyí tí òun ti dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí yín.

45 Àti bí òun bá sì ṣe èyí, ẹ̀yin yíò dáríjì í pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín; bí òun kò bá sì ṣe èyí, èmi, Olúwa, yíò gbẹ̀san yín lára ọ̀tá yín ní ìlọ́po ọgọ́rũn;

46 Àti ní orí àwọn ọmọ rẹ̀, àti ní orí àwọn ọmọ ọmọ ti gbogbo àwọn tí wọ́n kórĩra mi, títí dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.

47 Ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọ bá rónúpìwàdà, tàbí àwọn ọmọ ọmọ, tí wọ́n sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run wọn, pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo agbára, iyè inú, àti okun wọn, tí wọ́n sì mú padàbọ̀ sípò ní ìlọ́po mẹ́rin fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn nípa èyí tí wọ́n ti ṣẹ̀, tàbí nípa èyí tí àwọn bàbá wọn ti ṣẹ̀, tàbí àwọn bàbá bàbá wọn, nígbànáà ní a ó darí ìbínú yín lọ kúrò;

48 Àti pé ẹ̀san kì yíò wá sí orí wọn mọ́, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, àti pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni a kì yíò mú wá mọ́ láé bíi ẹ̀rí níwájú Olúwa láti lòdì sí wọn. Amín.