Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 120


Ìpín 120

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 8 Oṣù Keje 1838, èyítí ó sọ ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ohun ìní tí a san bíi ìdámẹ́wàá di mímọ̀ bí a ṣe dárúkọ nínú ìfihàn tí ó ṣaájú, ìpín 119.

Lóotọ́, báyìí ni Olúwa wí, àkókò náà ti dé nísisìyí, tí a ó ṣe ètò lílò rẹ̀ láti ọwọ́ ìgbìmọ̀ kan, tí ó jẹ́ ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ mi, àti ti bíṣọ́ọ̀pù náà àti ìgbìmọ̀ rẹ̀, àti nípa ìgbìmọ̀ gíga mi; àti nípa ohùn tèmi sí wọn, ni Olúwa wí. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.