Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42


Ìpín 42

Ìfihàn tí a fi fúnni ní àwọn abala méjì nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 9 àti 23 Oṣù Kínní 1831. Abala àkọ́kọ́ tí ó ní àwọn ẹsẹ 1 títí dé 72 nínú, ni a gbà ní ìṣejú àwọn alàgbà méjìlá àti ní ìmúṣẹ ìlérí tí Olúwa ṣe tẹ́lẹ̀ pé “òfin” náà yíó jẹ́ fífúnni ní Ohio (wo ìpín 38:32). Abala èkejì ní àwọn ẹsẹ 73 títí dé 93. Wòlíì fi ìfihàn yìí lélẹ̀ bíi èyí tí “ó kó òfin Ìjọ mọ́ra.”

1–10, Àwọn alàgbà ni a pè láti kede ìhìnrere, rì àwọn tí a yí lọ́kàn padà bọmi, àti láti kọ́ Ìjọ sókè; 11–12, A gbọ́dọ̀ pè wọ́n kí á sì yàn wọ́n àti kí wọ́n ó má a kọ́ni ní àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti a rí nínú àwọn ìwé mímọ́; 13–17, Wọ́n yíò kọ́ni, wọn yíò sì sọtẹ́lẹ̀ nípa agbára Ẹ̀mí; 18–29, Àwọn Ẹni-Mímọ́ ni a pàṣẹ fún láti máse pànìyàn, jalè, purọ́, ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ṣe panṣágà, tàbí sọ̀rọ̀ búburú lòdì sí àwọn ẹlòmíràn; 30–39, Àwọn òfin tí nṣe àkóso ọ̀rọ̀ yíya ohun ìnì sí mímọ́ ni a fi lélẹ̀; 40–42, Ìgbéraga àti ìmẹ́lẹ́ ni a kọ ẹ̀hìn sí 43–52, Àwọn aláìsàn ni a ó máa mú láradá nípasẹ̀ àmójútó àti nípa ìgbàgbọ́; 53–60, Àwọn ìwé mímọ́ ní wọ́n nṣe àkóso Ìjọ a sì níláti kéde wọn sí ayé; 61–69, Ibití Jérusálẹ́mù Titun yío wà àti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà ni a ó sọ di mímọ̀; 70–73, Àwọn ohun ìnì tí a ti yà sí mímọ́ ni a ó máa lò láti fi ṣe àtilẹ́hìn fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọ; 74–93, Àwọn òfin tí ó nṣe àkóso àgbèrè síṣe, panṣágà, ìpanìyàn, olè jíjà, àti jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni a fi lélẹ̀.

1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ẹ̀yin tí ẹ ti kó ara yín jọ papọ̀ ní orúkọ mi, àní Jésù Krístì ọmọ Ọlọ́run alààyè, Olùgbàlà aráyé; níwọ̀nbí ẹ̀yin ṣe gbàgbọ́ nínú orúkọ mi tí ẹ sì pa àwọn òfin mi mọ́.

2 Lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́ràn àti kí ẹ sì gba òfin èyítí èmi yíò fi fún yín gbọ́.

3 Nítorí lõtọ́ ni mo wí, pé bí ẹ̀yin ṣe pé jọ pọ̀ ní ìbámu sí àṣẹ pẹ̀lú èyítí mo ti pàṣẹ fún yín, àti pé tí ẹ̀yin sì fi ohùn ṣọ̀kan nípa ohun kan yìí, àti tí ẹ sì ti béèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, àní bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin yíò rí gbà.

4 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi fún yín ní òfin àkọ́kọ́ yìí, pé ẹ̀yin yíò jáde lọ ní orúkọ mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, bíkòṣe àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kekeré, àti Sidney Rigdon.

5 Mo sì fún wọn ní òfin kan pé wọ́n yío jade lọ fún àkókò díẹ̀, a ó sì fi fúnni nípa agbára Ẹ̀mí ìgbà tí wọn yíò padà.

6 Ẹ̀yin yíò sì jade lọ nínú agbára Ẹ̀mí mi, ní wíwàásù ìhìnrere mi, ní méjì méjì, ní orúkọ mi, ní gbígbé ohùn yín sókè bií pẹ̀lú ìró fèrè, ní kíkéde ọ̀rọ̀ mi bíi ti àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run.

7 Ẹ̀yin yíò sì jade lọ ní ṣíṣe ìrìbọmi pẹ̀lú omi, nípa wíwí pé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, nitorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.

8 Àti láti ìhín yìí ẹ̀yin yíò jade lọ sí àwọn agbègbè ìhà ìwọ̀ oòrùn; àti níwọ̀nbí ẹ̀yin bá ti rí àwọn wọnnì tí wọ́n yío gbà yín, ẹ̀yin yíò kọ́ ìjọ mi ní àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan—

9 Títí tí àkókò náà yíò dé nígbàtí a ó fi hàn fún yín láti òkè wá, nígbàtí ìlú Jérúsálẹ́mù Titun yío di pípèsè, kí ẹ̀yin ó lè kó ara jọ ní ọ̀kan, pé kí ẹ̀yin lè jẹ́ ènìyàn mi, èmi yíò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé ìránṣẹ́ mi Edward Partridge yíò dúró ní ipò iṣẹ́ èyi tí èmi ti yàn án sí. Yíò sì ṣe, pé bí òun bá rékọjá ẹlòmíràn ni a ó yàn dípò rẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.

11 Lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, pé a kì yíò fi fún ẹnikẹ́ni láti jade lọ láti wàásù ìhìnrere mi, tàbí láti kọ́ ìjọ mi, bíkòṣe pé a bá yàn án láti ọwọ́ ẹnití ó ní àṣẹ, tí ó sì jẹ́ mímọ̀ fún ìjọ pé ó ní àṣẹ àti pé òun náà ti jẹ́ yíyàn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nípasẹ̀ àwọn olórí ìjọ.

12 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn alàgbà, àlùfáà àti àwọn olùkọ́ ìjọ yìí yíò máa kọ́ àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere mi, èyítí wọ́n wà nínú Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, nínú èyí tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere wà.

13 Wọn yíò sì kíyèsí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà òfin ti ìjọ lati ṣe wọ́n, ìwọ̀nyìí ni yíò sì jẹ́ kíkọ́ni wọn, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe darí wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí.

14 Àti pé a ó fi Ẹ̀mí fún yín nípa àdúrà ìgbàgbọ́; bí ẹ̀yin kò bá sì gba Ẹ̀mí, ẹ kì yíò kọ́ni.

15 Àti pé gbogbo èyí ni ẹ̀yin yíò kíyèsí láti ṣe gẹ́gẹ́bí mo ti pàṣẹ nípa kíkọ́ni yín, títí tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìwé mímọ́ mi yío fi jẹ́ fífúnni.

16 Àti bí ẹ̀yin yíò ṣe gbé ohùn yín sókè nípa Olùtùnú, ẹ̀yin yíò sọ̀rọ̀ ẹ ó sì sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí ó ṣe dára lójú mi;

17 Nítorí, kíyèsíi, Olùtùnú náà mọ ohun gbogbo, òun sì jẹ́rìí ti Bàbá àti ti Ọmọ.

18 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èmi sọ̀rọ̀ sí ìjọ náà. Ìwọ kò gbọdọ̀ pàniyàn; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàniyàn kì yíò ní ìdáríjì ní ayé yìí, tàbí ní ayé tí ó nbọ̀.

19 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; ṣùgbọ́n ẹnití ó bá pànìyàn yíò kú.

20 Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ẹnití ó bá sì jalè tí kò sì ronúpìwàdà ni a ó lé jáde.

21 Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́; ẹnití ó bá pa irọ́ tí òun kò sì ronúpìwàdà ni a ó lé jáde.

22 Ìwọ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn aya rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, ìwọ yíò sì fi ara mọ́ òun níkan láì sí ẹ̀lòmíràn.

23 Àti ẹni tí ó bá sì wo òbìnrin kan láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ ti sẹ́ ìgbàgbọ́, òun kò sì lè ní Ẹ̀mí; àti bí òun kò bá sì ronúpìwàdà òun ni a ó lé jáde.

24 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; ẹni tí ó bá sì ṣe panṣágà, tí kò sì ronúpìwàdà, ni a ó lé jáde.

25 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe panṣágà tí ó sì ronupìwàdà pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, àti tí òun sì kọ ọ́ sílẹ̀, tí kò sì ṣe é mọ́, ni ẹ̀yin yíò dáríjì;

26 Ṣùgbọ́n bí òun bá tún ṣe é lẹ́ẹ̀kansíi, a kì yíò dárí jì í, ṣùgbọ́n a ó lé e jáde.

27 Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ búburú nípa ẹnìkejì rẹ, tàbí kí o ṣe é ní ibi kan.

28 Ìwọ mọ̀ pé àwọn òfin mi nípa àwọn ohun wọ̀nyí ni a fi fúnni nínú àwọn ìwé mímọ́ mi; ẹni tí ó bá ṣẹ̀ tí kò sì ronúpìwàdà ni a ó lé jáde.

29 Bí ìwọ bá fẹ́ràn mi ìwọ yíò sìn mi ìwọ yíò sì pa àwọn òfin mi mọ́.

30 Àti kíyèsíi, ìwọ yíò rantí àwọn aláìní, ìwọ yío sì yà lára àwọn ohun ìní rẹ sí mímọ́ fún àtilẹ́hìn wọn èyíinì tí ìwọ ní lati fi fúwọn, pẹ̀lú májẹ̀mú kan àti ìwé èdídí kan èyí tí a kò le sẹ́.

31 Àti níwọ̀nbí ẹ̀yin ṣe nfi lára ohun ìní yín fún àwọn aláìní, ẹ̀yin yíò ṣe é fún mi; a ó sì kó wọn wá síwájú bíṣọ́pù ìjọ mi àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, méjì nínú àwọn alàgbà, tàbí àwọn àlùfáà gíga, irú ẹnití òun yío yàn tàbí tí òun ti yàn tí ó sì ti yà sọ́tọ̀ fún ìdí náà.

32 Yíò sì ṣe, pé lẹ́hìn tí a bá kó wọn síwájú bíṣọpù ìjọ mi, àti lẹ́hìn tí òun bá ti gba àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí nípa ìyàsímímọ́ àwọn ohun ìní ìjọ mi, pé a kò lè gba wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ ìjọ, tí ó wà ní ìbámu sí àwọn àṣẹ mi, olukúlùkù ni a ó mú kí ó jíhìn fún mi, ìríjú kan ní orí ohun ìní rẹ̀, tàbí èyi tí òun ti gbà nípa ìyàsímímọ́, iye tí ó bá pọ̀ tó fún ara rẹ̀ àti mọ̀lẹ́bí.

33 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, bí àwọn ohun ìní bá wà ní ọwọ́ ìjọ, tàbí àwọn ẹnikẹ́ni nínú rẹ̀ tí ó pọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ fún àtilẹ́hìn wọn lẹ́hìn ìyàsímímọ́ àkọ́kọ́ yìí, èyí tí ó ṣẹ́kù lati yà sí mímọ́ fún bíṣọpù, a ó fi í pamọ́ lati tọ́jú àwọn tí wọn kò ní, láti àkókò dé àkókò, kí olúkúlùkù tí ó bá ṣe aláìní lè rí ìpèsè tí ó tó àti kí ó lè rí gbà ní ìbámu sí àìní rẹ̀.

34 Nítorínáà, ìyókù náà ni a ó fi pamọ́ sínú ilé ìṣúra mi, láti ṣe ìtọ́jú àwọn tálákà ati aláìní, gẹ́gẹ́bí a ó ti yàn án lati ọwọ́ ìgbìmọ̀ gíga ìjọ, àti bíṣọpù àti ìgbìmọ̀ rẹ̀.

35 Àti fún ìdí ríra àwọn ilẹ̀ fún ànfàní gbogbo ènìyàn ìjọ mi, àti fún kíkọ́ àwọn ilé ìjọ́sìn, àti fún kíkọ́ Jérúsálẹ́mù Titun náà èyí tí a ó fi hàn lẹ́hìnwá—

36 Pé kí á lè kó àwọn ènìyàn májẹ̀mú mi jọ sí ojú kan ní ọjọ́ náà nígbàtí èmi yíò dé sí tẹ́mpìlì mi. Àti pé èyí ni èmi ṣe fún ìgbàlà àwọn ènìyàn mi.

37 Yíò sì ṣe, pé ẹni tí ó bá ṣẹ̀ àti tí òun kò sì ronúpìwàdà ni a ó lé jáde kúrò nínú ìjọ, òun kì yíò sì gbà á padà ohun náà èyítí ó ti yà sí mímọ́ fún àwọn tálákà ati aláìní nínú ìjọ mi, tàbí ní ọ̀nà míràn, fún èmi—

38 Nítorí níwọ̀nbí ẹ̀yin ti ṣe èyí sí ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn wọ̀nyí, ẹ̀yin ti ṣe é sí mi.

39 Nítorí yíò sì ṣe, pé èyí tí èmi ti sọ láti ẹnu àwọn Wòlíì mi yíò wá sí ìmúṣẹ; nítorí èmi yíò yà sí mímọ́ lára ọrọ̀ àwọn tí wọ́n ti gba ìhìnrere mi lààrin àwọn Kèfèrí fún tálákà nínú àwọn ènìyàn mi tí wọ́n jẹ́ ilé Isráẹ́lì.

40 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbéraga nínú ọkàn yín; ẹ jẹ́kí àwọn aṣọ wíwọ̀ yín jẹ́ ọ̀bọ̀rọ́, kí ẹwà wọ́n sì jẹ́ ẹwà iṣẹ́ ọwọ́ tiyín;

41 Ẹ sì jẹ́ kí ohun gbogbo jẹ́ ṣíṣe ní mímọ́ níwájú mi.

42 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ́ aláìníṣẹ́; nítorí ẹni tí o bá wà láì ṣiṣẹ́ kì yíò jẹ àkàrà tàbí wọ àwọn aṣọ òṣìṣẹ́.

43 Àti pé ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó bá ṣe àìsàn, àti tí kò sì ní ìgbàgbọ́ lati rí ìmúláradá, ṣùgbọ́n tí ó gbagbọ́, ni a ó tọ́jú pẹ̀lú ìkẹ́, pẹ̀lú àwọn ewé àti ounjẹ tí kò le, àti èyíinì kìí ṣe nípasẹ̀ ọ̀tá kan.

44 Àti àwọn alàgbà ìjọ, méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni a ó pè, wọn yíò sì gbàdúrà wọn yíò sì gbé ọwọ́ lé wọn ní orúkọ mi; bí wọ́n bá sì kú wọ́n yío kú nínú mi, àti bí wọ́n bá sì yè wọ́n yíò yè nínú mi.

45 Ẹ̀yin yíò gbé papọ̀ nínú ìfẹ́, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yíò sunkún nítorí àdánù àwọn wọnnì tí wọ́n kú, àti pàápàá jùlọ nítorí àwọn wọnnì tí wọn kò ní ìrètí àjínde ológo.

46 Yíò sì ṣe pé àwọn wọnnì tí wọ́n bá kú nínú mi kì yíò tọ́ ikú wò, nítorí yíò jẹ́ dídùn sí wọn.

47 Àti àwọn wọnnì tí wọn kò bá kú nínú mi, ègbé ni fún wọn, nítorí ikú wọn jẹ́ ìkorò.

48 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, yíò sì ṣe pé ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi lati di wíwòsàn, àti tí a kò sì yàn fún ikú, yíò di wíwòsàn.

49 Ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ lati ríran yíò ríran.

50 Ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ lati gbọ́ràn yíò gbọ́ràn.

51 Arọ tí ó bá ní ìgbàgbọ́ lati fò yíò fò.

52 Àti àwọn tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ láti ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n tí wọ́n gbàgbọ́ nínú mi, wọ́n ní agbára láti di ọmọ mi; àti níwọ̀nbí wọn kò bá sì ré àwọn òfin mi kọjá ẹ̀yin yíò mójútó àwọn àìlera wọn.

53 Ìwọ yíò dúró sí ààyè iṣẹ́ ìríjú rẹ.

54 Ìwọ kò gbọdọ̀ mú aṣọ arákùnrin rẹ; ìwọ yío sanwó fún èyíinì tí ìwọ bá gbà lọ́wọ́ arákùnrin rẹ.

55 Àti pé bí ìwọ bá gbà ju èyíinì tí ó yẹ fún àtìlẹ́hìn rẹ, ìwọ yío fií sílẹ̀ sí ilé ìsúra mi, kí ohun gbogbo lè jẹ́ ṣíṣe ní ìbámu sí èyíinì tí èmi ti sọ.

56 Ìwọ yío béèrè, a ó sì fi àwọn ìwé mímọ́ mi fún ọ gẹ́gẹ́bí èmi ti yàn án, a ó sì pa wọ́n mọ́ ní àìléwu.

57 Àti pé ó jẹ́ ànfààní pé kí ìwọ ó pa ẹnu rẹ mọ́ nípa wọn, kí ẹ má sì ṣe kọ́ wọn títí tí ẹ̀yin yíò fi gbà wọ́n ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

58 Èmi sì fún yín ní òfin kan pé nígbànáà ni ẹ̀yin yíò fi wọ́n kọ́ gbogbo ènìyàn; nítorí a ó fi wọ́n kọ́ni sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn.

59 Ẹ̀yin yíò mú àwọn nkan tí ẹ̀yin ti gbà, èyí tí a fi fún yín nínú àwọn ìwé mímọ́ mi fún òfin kan, lati jẹ́ òfin mi fún àkóso ìjọ mi;

60 Àti pé ẹni tí ó bá ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn nkan wọ̀nyí ni a ó gbàlà, àti ẹni tí kò bá sì ṣe wọ́n ni a ó dá lẹ́bi bí òun bá tẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀.

61 Bí ẹ̀yin bá béèrè, ẹ̀yin yíò gba ìfihàn ní orí ìfihàn, ìmọ̀ ní orí ìmọ̀, kí ẹ̀yin lè mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ati ti àlãfíà—èyí tí ó nmú ayọ̀ wá, èyí tí ó nmú ìyè ayérayé wá.

62 Ẹ̀yin yíò béèrè, a ó sì fi hàn fún yín ní àkókò tí ó yẹ ní ojú mi ibi tí a ó kọ́ Jerúsalẹ́mù Titun sí.

63 Sì kíyèsíi, yíò sì ṣe tí a ó rán àwọn ìránṣẹ́ mi jade lọ sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá àti sí gúúsù.

64 Àti àní nísisìyí, ẹ jẹ́ kí ẹni tí ó bá nlọ sí ìlà-oòrùn kí ó kọ́ àwọn tí a ó yí lọ́kàn padà lati sá lọ sí ìwọ̀-oòrùn, àti èyí nítorí èyíinì tí ó nbọ̀ wá sí ilẹ̀ ayé, àti ti àwọn ẹgbẹ́ ìkọ̀kọ̀.

65 Kíyèsíi, ẹ̀yin yío fi ojú sí àwọn nkan wọ̀nyí, titóbi sì ni èrè yín yíò jẹ́; nítorí ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà, ṣùgbọ́n sí gbogbo ayé a kò fí fúnni láti mọ̀ wọ́n.

66 Ẹ̀yin yíò kíyèsí àwọn òfin èyítí ẹ̀yin ti gbà ẹ ó sì jẹ́ olõtọ́.

67 Àti pé lẹ́hìn-èyí ẹ̀yin yíò gba àwọn májẹ̀mú ti ìjọ, irú èyí tí yíò tó láti fi ìdí yín múlẹ̀, ní ìhín àti ní Jérúsálẹ́mù Titun.

68 Nítorínáà, ẹni tí kò bá ní ọgbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó béèrè lọ́wọ́ mi, àti pé èmi yíò fún un lọ́pọ̀lọpọ̀ láì sí ìbáwí.

69 Ẹ gbé ọkàn yín sókè kí ẹ sì yọ̀, nítorí fún yín ni ìjọba náà, tàbí ní ọ̀nà míràn, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọ náà ni a ti fi fún yín. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.

70 Àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ni yíò ní àwọn iṣẹ́ ìríjú wọn, àní bíi àwọn ọmọ ìjọ.

71 Àti àwọn alàgbà tàbí àwọn àlùfáà gíga tí a yàn láti ti bíṣọ́pù lẹ́hìn gẹ́gẹ́bí olùdámọ̀ràn nínú ohun gbogbo, níláti rí àtìlẹ́hìn gbà fún àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lára ohun ìní èyí tí a ti yà sí mímọ́ fún bíṣọ́pù, fún ire àwọn aláìní, àti fún àwọn nkan míràn, gẹ́gẹ́bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

72 Tàbí wọn yíò gba èrè tí ó tọ́ sí wọn fún gbogbo àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn, bọ́yá bíi ìríjú kan tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́, bí wọ́n bá ṣe rò pé ó dára jùlọ tàbí bí àwọn olùdámọ̀ràn àti bísọ́pù bá ṣe pinnu.

73 Àti bíṣọ́pù náà, bákannáà, yíò gba àtìlẹ́hìn rẹ̀, tàbí èrè tí ó bá tọ́ fún gbogbo àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nínú ìjọ.

74 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni nínú yín, tí ó bá ti kọ ẹnìkejì wọn sílẹ̀ nítorí àgbéèrè, tàbí ní ọ̀nà míràn, bí wọ́n bá jẹ́rìí níwájú yín pẹ̀lú gbogbo irẹ̀lẹ̀ ọkàn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ẹ̀yin kì yíò lé wọn jade lààrin yín.

75 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ríi pé àwọn kan ti kọ àwọn ẹnìkejì wọn sílẹ̀ nítorí àgbéèrè, àti pé àwọn fúnra wọn ni arúfin, tí àwọn ẹnìkejì wọn sì wà láàyè, ẹ̀yin yíò sì lé wọn jade kúrò lààrin yín.

76 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé kí ẹ kíyèsára kí ẹ sì sọ́ra, pẹ̀lú gbogbo ìwádìí, kí ẹ̀yin má baà gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ààrin yín bí wọ́n bá ti gbé ara wọn níyàwó;

77 Àti pé bí wọn kò bá tíì gbé ara wọn níyàwó, wọ́n yío ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn tàbí ẹ̀yín kì yíó gbà wọ́n.

78 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, olúkúlùkù èniyàn tí ó bá jẹ́ ti ìjọ Krístì yìí, níláti kíyèsí láti pa gbogbo àwọn òfin àti àwọn májẹ̀mú ti ìjọ mọ́.

79 Àti pé yíò sì ṣe, pé bí ẹnìkẹ́ni ní ààrin yín bá pànìyàn ẹ̀yin yíò sì fàá kalẹ̀ a ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ilẹ̀ náà; nítorí ẹ rántí pé òun kò ní ìdáríjì; àti pé wọn yíò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ilẹ̀ náà.

80 Àti bí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan bá ṣe àgbéèrè, ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin ni yíó jẹ́jọ́ níwájú àwọn alàgbà ìjọ méjì, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ó sì fi ìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní títako ọ̀kùnrin tàbí obìnrin náà nípasẹ̀ ẹlérìí méjì láti inú ìjọ, ati pé kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá; ṣùgbọ́n bí àwọn ẹlẹ́rìí náà bá pọ̀ ju méjì lọ ó dára jù.

81 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tàbí òbìnrin náà ni a ó dálẹ́bi láti ẹnu àwọn ẹlérìí méjì; àwọn alàgbà yíò sì gbé ẹjọ́ náà wá sí iwájú ìjọ, ìjọ̀ yíò sì gbé ọwọ́ wọn sókè láti tako ọ̀kùnrin tàbí òbìnrin náà, kí á lè ṣe sí wọn gẹ́gẹ́bí òfin Ọlọ́run.

82 Àti pé bí ó bá ṣèéṣe, ó ṣe dandan kí bíṣọ́pù náà wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

83 Àti pé báyìí ni ẹ̀yin yíò ṣe ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wá síwájú yín.

84 Àti pé bí ọkùnrin kan tàbí obìnrin bá jalè, a ó fàá kalẹ̀ fún òfin ilẹ̀ náà.

85 Ati pé bí ọkùnrin kan tàbí obìnrin bá jí ohun kan, a ó fàá kalẹ̀ fún òfin ilẹ̀ náà.

86 Àti pé bí ọkùnrin kan tàbí obìnrin bá parọ́, a ó fàá kalẹ̀ fún òfin ilẹ̀ náà.

87 Àti pé bí ọkùnrin kan tàbí obìnrin bá sì hùwà àìṣedéédé kan, a ó fàá kalẹ̀ fún òfin, àní èyí tí ṣe ti Ọlọ́run.

88 Àti pé bí arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, ìwọ yíò pè é sí ààrin ìwọ àti òun nìkan; àti bí òun bá sì jẹ́wọ́ ìwọ yíò báa làjà.

89 Àti pé bí òun kò bá sì jẹ́wọ́ ìwọ yíò fá a kalẹ̀ fún ìjọ, kìí ṣe sí àwọn ọmọ ìjọ, ṣùgbọ́n sí àwọn alàgbà. A ó sì ṣe é nínú ìpàdé kan, àti èyíinì kìí ṣe níwájú gbogbo ayé.

90 Àti bí arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ bá sì ṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, òun yíó jẹ́ bíbáwí níwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

91 Àti bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ ní gbangba, òun yíó jẹ́ bíbáwí ní gbangba, kí ojú kí ó lè tì í. Bí òun kò bá sì jẹ́wọ́, a ó fàá kalẹ̀ fún òfin Ọlọ́run.

92 Bí ẹnìkẹ́ni bá ṣẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun yíó jẹ́ bíbáwí ní ìkọ̀kọ̀, kí òun lè ní ànfààní láti jẹ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀ fún ẹni náà tí òun ṣẹ̀, àti fún Ọlọ́run, kí ìjọ Ọlọ́run má baà sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa rẹ̀.

93 Àti bayìí ni ẹ̀yin yío ṣe nínú ohun gbogbo.