Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 97


Ìpín 97

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtlánd, Ohio, 2 Oṣù Kẹjọ 1833. Ìfihàn yìí ṣiṣẹ́ ní pàtàkì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlãfíà àwọn Ẹni Mímọ́ ní Síónì, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, ní ìdáhùn sí ìbéèrè Wòlíì lọ́wọ́ Olúwa fún ìfiyéni. Àwọn ọmọ Ìjọ ní Missouri ní àkókò yìí wà lábẹ́ inúnibíni tí ó nira púpọ̀ àti pé, ní 23 Oṣù Keje 1833, a fi tipátipá mú wọn lati fi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan láti kúrò ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson.

1–2, Púpọ̀ nínú àwọn Ẹni Mímọ́ ní Síónì (Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri) ní a bùkún fún nítorí ìṣòtítọ́ wọn; 3–5, Parley P. Pratt ni a yìn fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ ní Síónì; 6–9, Àwọn tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ ni Olúwa tẹ́wọ́gbà; 10–17, Ilé kan ni a ó kọ́ ní Síónì nínú èyítí àwọn ọlọ́kàn mímọ́ yíò rí Ọlọ́run; 18–21, Síónì ni ọlọ́kàn mímọ́ náà; 22–28, Síónì yíò ja àjàbọ́ lọ́wọ́ ìjìyà Olúwa bí òun bá jẹ́ olõtọ́.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, èmi bá yín sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn mi, àní ohùn ti Ẹ̀mi mi, kí èmi ó lè fi ìfẹ́ inú mi hàn sí yín nípa àwọn arákùnrin yín ní ilẹ̀ Síónì, púpọ̀ nínú ẹnití wọ́n jẹ́ onítẹríba nítòótọ́ àti tí wọ́n nwá ọ̀nà pẹ̀lú aápọn láti kọ́ ọgbọ́n àti láti wá òtítọ́ rí.

2 Lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ìbùkún ni fún irú wọn, nítorí tí wọn yíò rí gbà; nítorí èmi, Olúwa, fi àánù hàn sí gbogbo ọlọ́kàn tútù, àti sí orí gbogbo ẹnikẹ́ni tí èmi bá fẹ́, kí á lè dámi láre nígbàtí èmi bá mú wọn wá sí ìdájọ́.

3 Kíyèsíi, èmi wí fún yín, nípa ilé ẹ̀kọ́ ni Síónì, èmi, Olúwa, inú mi dùn gidigidi pé kí ilé ẹ̀kọ́ kan ó wà ní Síónì, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt, nítorí òun nbámi gbé.

4 Àti níwọ̀nbí òun bá tẹ̀síwájú láti máa bámi gbé òun yíò tẹ̀síwájú láti ṣe àkóso ilé ẹ̀kọ́ náà ní ilẹ̀ Síónì títí tí èmi yíò fi fún un ní àwọn òfin míràn.

5 Èmi yíò sì bùkún fún un pẹ̀lú awọn ìbùkún ní ìlọ́po púpọ̀, ní sísọ àsọyé gbogbo ìwé mímọ́ àti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ sí ìdàgbàsókè ilé ẹ̀kọ́ náà, àti ti ìjọ ní Síónì.

6 Àti sí àwọn ìyókù ní ilé ẹ̀kọ̀ náà, èmi, Olúwa, ní ìfẹ́ láti fi àánú hàn; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan wà tí wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ bíbáwí, a ó sì fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn.

7 A ti fi àáké lé gbòngbò àwọn igi náà; gbogbo igi tí kò bá sì mú èso rere wá ni a ó gé lulẹ̀ tí a ó sì gbé jù sínú iná. Èmi, Olúwa, ti sọ ọ́.

8 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹni gbogbo láàrin wọn tí wọ́n mọ pé ọkàn àwọn jẹ́ òtítọ́, àti tí wọ́n jẹ́ oníròbìnújẹ́, àti tí ẹ̀mí wọn ní ìrora, tí wọ́n sì ní ìfẹ́ láti kíyèsí àwọn májẹ̀mú wọn nípa ẹbọ̀—bẹ́ẹ̀ni, olukúlùkù ẹbọ èyítí èmi, Olúwa, yíò pàṣẹ—wọ́n jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sími.

9 Nítorí èmi, Olúwa, yíò mú kí wọ́n mú èso rere jade wá bí igi kan tí ó kún fún èso púpọ̀ eyítí a gbìn sí orí ilẹ̀ rere, ní ẹ̀bá odò aláìlẽrí kan, èyí tí ó so èso tí ó níye ní orí púpọ̀ jade.

10 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ kọ́ ilé kan sí mi ní ilẹ̀ Síónì, ní ìrí àpẹrẹ náà èyítí mo ti fún yín.

11 Bẹ́ẹ̀ni, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ọ ní kánkán, nípa ìdámẹ́wã àwọn ènìyàn mi.

12 Kíyèsíi, èyí ni ìdámẹ́wã àti ẹbọ náà èyítí èmi, Olúwa, béèrè lọ́wọ́ yín, kí á lè kọ́ ilé kan sí mi fún ìgbàlà Síónì—

13 Fún ibi ìdúpẹ́ kan fún gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, àti fún ibi ìkọ́ni kan fún gbogbo àwọn tí a pè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní gbogbo onírúurú àwọn ìpè àti àwọn ipò iṣẹ́ wọn;

14 Kí wọ́n ó lè jẹ́ pípé ní ṣíṣe àgbọ́yé iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, nínú ìkọ́ni pẹ̀lú ọ̀rọ̀, nínú ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àti nínú ẹ̀kọ́, nínú ohun gbogbo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé, àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba èyítí a ti gbé lée yín lọ́wọ́.

15 Àti pé níwọ̀nbí àwọn ènìyàn mi bá kọ́ ilé kan sí mi ní orúkọ Olúwa, àti tí wọn kò fi ààyè gba ohun àìmọ́ kankan láti wá sí inú rẹ̀, kí ó má baà di àìmọ́, ògo mi yíò sì sinmi lé orí rẹ̀;

16 Bẹ́ẹ̀ni, èmi tìkárami yíò sì wà níbẹ̀, nítorí èmi yíò wá sí inú rẹ̀, àti pé gbogbo àwọn ọlọ́kàn mímọ́ tí wọ́n bá wá sí inú rẹ̀ yíò rí Ọlọ́run.

17 Ṣùgbọ́n bí ó bá di aláìmọ́ èmi kì yíò wá sí inú rẹ̀, ògo mi kì yíò sì wà níbẹ̀; nítorí èmi kì yíò wá sí inú àwọn tẹ́mpìlì àìmọ́.

18 Àti, nísisìyí, kíyèsíi, bí Síónì bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyìí òun yíò ṣe rere, yíò sì tàn ara rẹ̀ ká àti pé yíò di ológo púpọ̀, yíò tóbi púpọ̀, yíò sì ní ẹ̀rù púpọ̀.

19 Àwọn orílẹ̀-èdè ayé yíò sì bu ọlá fún un, wọ́n yíò sì wípé: Nítòótọ́ ilú nla ti Ọlọ́run ni Síónì í ṣe, àti nítòótọ́ Síónì kò lè ṣubú, tàbí kí á ṣi i nípò kúrò ní ààyè rẹ̀, nítorí Ọlọ́run wà níbẹ̀, àti pé ọwọ́ Olúwa wà níbẹ̀;

20 Òun sì ti búra nípa agbára ti ipá rẹ̀ láti jẹ́ ìgbàlà rẹ̀ àti ilé ìsọ́ gíga rẹ̀.

21 Nítorínáà, lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, ẹ jẹ́ kí Síónì ó yọ̀, nítorí èyí ni Síónì—ọlọ́kàn mímọ́ náà; nítorínáà, ẹ jẹ́ kí Síónì ó yọ̀, nígbàtí gbogbo olùṣe búburú yíò ṣọ̀fọ̀.

22 Nítorí kíyèsíi, sì wòó, ẹ̀san nbọ̀ kánkán sí orí àwọn aláìwà bí Ọlọ́run bíi ìjì; tani yíò sì ja àjàbọ́ nínú rẹ̀?

23 Pàṣán Olúwa yíò ré kọjá ní òru àti ní ọ̀sán, àti pé ìròhìn rẹ̀ yíò sì jẹ́ ìjayà fún gbogbo ènìyàn; bẹ́ẹ̀ni, a kì yíò lè dá a dúró títí tí Olúwa yíò fi dé;

24 Nítorí ìbínú Olúwa ti ru sókè ní ìdojúkọ àwọn ohun ìríra wọn àti gbogbo àwọn iṣẹ́ búburú wọn.

25 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Síónì yíò ja àjàbọ́ bí òun bá kíyèsí láti ṣe ohun gbogbo èyíkéyìí tí èmi ti pàṣẹ fún un.

26 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá kíyèsí lati ṣe ohunkóhun tí èmi ti pàṣẹ fún un, èmi yíò bẹ̀ẹ́ wò gẹ́gẹ́bí gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ̀, pẹ̀lú ìpọ́njú líle, pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn, pẹ̀lú ìyọnu, pẹ̀lú idà, pẹ̀lú ẹ̀san, pẹ̀lú iná ajónirun.

27 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí á kàá sí i léti lẹ́ẹ̀kan yìí, pé èmi, Olúwa, ti tẹ́wọ́gba ẹbọ-ọrẹ rẹ̀; àti pé bí òun kò bá dẹ́ṣẹ̀ mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun wọ̀nyìí kì yíò wá si orí rẹ̀;

28 Èmi yíò sì bùkún fún un pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìbùkún, àti ìlọ́po àwọn ìbùkún ní ìlọ́po púpọ̀ sí orí rẹ̀, àti sí orí ìrandíran rẹ̀ láé ati títí láéláé, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí. Amín.