Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 63


Ìpín 63

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, ní 30 Oṣù Kẹjọ 1831. Wòlíì náà, Sidney Rigdon, àti Oliver Cowdery ti dé sí Kirtland ní 27 Oṣù Kẹjọ láti àbẹ̀wò wọn sí Missouri. Ìtàn ti Joseph Smith ṣe àpèjúwe ìfihàn yìí: “Ní àwọn ìgbà wọ̀nyí ti Ìjọ wà ní èwe, àìbalẹ̀ ara púpọ̀ wà lati gba ọ̀rọ̀ Olúwa ní orí olukúlùkù àkòrí tí ó jẹ mọ́ ìgbàlà wa ní ọ̀nàkọnà; àti bí Síónì ṣe jẹ́ ohun ti ara pàtàkì jùlọ tí ó wà níwájú nísisìyí, mo béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún ọ̀rọ̀ síwájú síi ní orí ṣíṣe àkójọ àwọn Ẹni Mímọ́, àti ríra ilẹ̀ náà, àti àwọn ọ̀rọ̀ míràn.”

1–6, Ọjọ́ ìbínú kan yíò wá sí orí àwọn ènìyàn búburú; 7–12, Àwọn àmì máa nwá nípa ìgbàgbọ́; 13–19, Àwọn ọlọ́kàn àgbéèrè yíò sẹ́ ìgbàgbọ́ a ó sì gbé wọn jù sínú adágún iná; 20, Àwọn olõtọ́ yíò gba ogún ìní kan ní oríi ilẹ̀ ayé tí ó ti paradà; 21, Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìṣirò ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní orí Òkè Ìyípadà ní ti ara ni a kò tíì fi hàn; 22–23, Àwọn olùgbọ́ràn gba àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà; 24–31, Àwọn ogún ìní ní Síónì níláti jẹ́ rírà; 32–35, Olúwa pàṣẹ àwọn ogun, àwọn ènìyàn búburú sì pa àwọn ènìyàn búburú; 36–48, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti kó ara wọn jọ sí Síónì kí wọ́n ó sì pèsè àwọn owó láti kọ́ ọ; 49–54, A ṣe ìdánilójú àwọn ìbùkún fún àwọn olõtọ́ ní Bíbọ̀ Ẹ̀kejì, ní Àjínde náà, àti nínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà; 55–58, Èyí ni ọjọ́ ìkìlọ̀ kan; 59–66, Orúkọ Olúwa ni a npè ní asán nípasẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n npè é láì ní àṣẹ.

1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì ṣí ọkàn yín payá àti pé kí ẹ sì fi eti síi láti ọ̀nà jíjìn; kí ẹ sì tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ npe ara yín ní ènìyàn Olúwa, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àti ìfẹ́ rẹ̀ nípa yín.

2 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, ni mo wí, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹni náà tí ìbínú rẹ̀ ru sókè sí àwọn ènìyàn búburú àti aṣọ̀tẹ̀;

3 Ẹnití ó ní ìfẹ́ láti mú àní àwọn tí òun yío mú, àti kí ó pa wọ́n mọ́ ní ayé àwọn tí òun yío pamọ́;

4 Ẹni tí ó ngbé dúró nípa ìfẹ̀ àti ìdùnnú òun tikara rẹ̀; àti tí ó nparun nígbàtí ó bá wùú, tí ó sì ní agbára láti ju ẹ̀mí sí ọ̀run àpáàdì.

5 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, fọ ohùn mi, ẹ sì níláti gbọ́ràn sí i.

6 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí, ẹ jẹ́ kí àwọn ènìyàn búburú ó kíyèsára, ẹ sì jẹ́ kí àwọn aṣọ̀tẹ̀ ó bẹ̀rù kí wọ́n ó sì wárìrì; àti pé ẹ jẹ́ kí àwọn aláìgbàgbọ́ ó dákẹ́ ẹnu wọn, nítorí ọjọ́ ìbínú náà yíò wá sí orí wọn bíi ìjì, gbogbo ẹran ara ni yíò sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.

7 Ẹni tí ó bá sì nwá àwọn àmì yíò rí àwọn àmì, ṣùgbọ́n kìí ṣe sí ìgbàlà.

8 Lõtọ́, ni mo wí fún yín, àwọn kan wà lààrin yín tí wọ́n nwá àwọn àmì, àti pé irú ìwọ̀nyí ti wà àní láti àtètèkọ́ṣe.

9 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, ìgbàgbọ́ kì yíò wá nípa àwọn àmì, ṣùgbọ́n àwọn àmì yíò tẹ̀lé àwọn tí wọ́n gbàgbọ́.

10 Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àmì máa nwá nípa ìgbàgbọ́, kìí ṣe nípa ìfẹ́ ènìyàn, tàbí bí ó bá ṣe jẹ́ dídùn inú wọn, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ti Ọlọ́run.

11 Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àmì máa nwá nípa ìgbàgbọ́, sí àwọn iṣẹ́ nlá, nítorí láì sí ìgbàgbọ́ kò sí ẹni tí ó mú inú Ọlọ́run dùn; àti pé ẹni tí Ọlọ́run bá nbínú sí òun kì yíò sì ní inú dídùn síi; nítorínáà, sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ òun kì yíò fi àwọn àmì hàn, kìkì nínú ìbínú sí ìdálẹ́bi wọn.

12 Nítorínáà, èmi, Olúwa, kò ní inú dídùn sí àwọn wọnnì lààrin yín tí wọn nwá àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyànu fún ìgbàgbọ́, àti tí kìí ṣe fún ire àwọn ènìyàn sí ògo mi.

13 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi fi àwọn òfin fún yín, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ti yapa kúrò nínú àwọn òfin mi tí wọn kò sì pa wọ́n mọ́.

14 Àwọn kan wà ní ààrin yín tí wọ́n jẹ́ panṣágà lọ́kùnrin àti panṣágà lóbìnrin; díẹ̀ nínú àwọn tí wọ́n ti yapa kúrò ní ara yín, àwọn mìíràn ṣì wà pẹ̀lú yín tí a ó fi wọ́n hàn lẹ́hìnwá.

15 Ẹ jẹ́ kí irú wọn ó kíyèsára kí wọ́n ó sì rónúpìwàdà ní kíákíá, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ìdájọ́ yíò wá sí orí wọn bíi ìkẹ́kùn, àti pé a ó fi ìwà àìmoye wọn hàn, iṣẹ́ wọn yíò sì tọ̀ wọ́n lẹ́hìn ní ojú àwọn ènìyàn.

16 Àti pé lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí mo ṣe wí ní ìṣaájú, ẹni tí ó bá wo obìnrin láti ṣe ìfẹ́kũfẹ́ pẹ̀lũ rẹ̀, tàbí bí ẹnikẹ́ni bá ronú àgbèrè ní ọkàn wọn, wọn kì yíò ní Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n wọn yíò sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn yíò sì bẹ̀rù.

17 Nísisìyí, èmi, Olúwa, ti wí pé àwọn tí wọ́n nbẹ̀rù, àti aláìgbàgbọ́, àti gbogbo àwọn òpùrọ́, àti ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn àti tí ó npa irọ́, àti alágbéèrè, àti oṣó, ni wọn yíò ní ipa ti wọn nínú adágún èyí tí ó njó pẹ̀lú iná àti imí ọjọ́, èyi tí ṣe ikú ẹ̀ẹ̀kejì.

18 Lõtọ́ ni mo wí, pé wọn kì yíò ní ipa nínú àjínde àkọ́kọ́.

19 Àti nísisìyí kíyèsíi, èmi, Olúwa, wí fún yín pé a kò dá yín láre, nítorí àwọn nkan wọ̀nyí wà láàrin yín.

20 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá faradà nínú ìgbàgbọ́ tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi, òun kan náà ni yíò borí, yíò sì gba ogún ìní kan ní orí ilẹ̀ ayé nígbàtí ọjọ́ ìpaláradà yíò dé;

21 Nígbàtí a ó pa ayé láradà, àní gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ èyítí a fi hàn fún àwọn àpóstélì mi ní orí òkè; ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ èyí tí ẹ̀yin kò tíì gbà síbẹ̀.

22 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pe bí èmi ṣe wí pé èmi yíò sọọ́ di mímọ̀, ìfẹ́ ọkàn mi fún yín, kíyèsíi èmi yíò sọ ọ́ di mímọ̀ fún yín, kìí ṣe nípa ọ̀nà òfin, nítorí púpọ̀ ni àwọn tí wọn kò ṣe àkíyèsí láti pa àwọn òfin mi mọ́.

23 Ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó pa àwọn òfin mi mọ́ ni èmi yíò fún ní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba mi, òun kannáà yíò sì jẹ́ kànga omi iyè nínú rẹ̀, ní ríru sókè sí ìyè ayérayé.

24 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èyí ni ìfẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run yín nípa àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, pé kí wọ́n ó kó ara wọn jọ papọ̀ sí orí ilẹ̀ Síónì, kìí ṣe pẹ̀lú ìkánjú, bí bẹ́ẹ̀kọ́ ìdàrúdàpọ̀ yíò wà, èyí tí ó lè fa àjàkálẹ̀ àrùn.

25 Kíyèsíi, ilẹ ti Síónì náà—èmi, Olúwa, dì í mú ní ọwọ́ tèmi;

26 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi, Olúwa, fi fún Késárì àwọn ohun tí íṣe ti Késárì.

27 Nítorínáà, èmi Olúwa fẹ́ kí ẹ̀yin ó ra àwọn ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin ó lè ní ànfàní ní orí ayé, kí ẹ̀yin ó lè ní ẹ̀tọ́ lójú ayé, kí á má baà lè rú wọn sókè sí ìbínú.

28 Nítorí Sátánì ti fi sí wọn lọ́kàn láti bínú sí yín, àti títí dé títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

29 Nísisìyí, a kì yíò rí ilẹ̀ Síónì gbà bíkòṣe nípa rírà tàbí nípa ẹ̀jẹ̀, bíbẹ́ẹ̀kọ́ kì yíò sí ogún ìní kankan fún yín.

30 Bí ó bá sì jẹ́ nípa rírà, kíyèsíi ẹ̀yin jẹ́ alábùkúnfún;

31 Bí ó bá sì jẹ́ nípa ẹ̀jẹ̀, bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún yín láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ wòó, àwọn ọ̀tá yín ti kọlù yín, ẹ̀yin yíò sì di jíjẹ́ níyà láti ilú nlá dé ìlu nlá, àti láti sínágọ́gù dé sínágọ́gù, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni yíò sì lè dúró láti gba ogún ìní kan.

32 Èmi, Olúwa, èmi nbínú sí àwọn ènìyàn búburú; èmi ndi Ẹ̀mí mi mú kúrò lọ́dọ̀ àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.

33 Èmi ti búra nínú ìbínú mi, mo sì pàṣẹ àwọn ogun sí orí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn búburú yíò sì máa pa ènìyàn búburú, ẹ̀rù yíò sì wá sí orí olúkúlùkù ènìyàn;

34 Àti pé àwọn ẹni mímọ́ bákannáà yío fi agbára káká yọ kúrò; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi, Olúwa, èmi wà pẹ̀lú wọn, èmi yíò sì sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀run kúrò níwájú Bàbá mi a ó sì run àwọn ènìyàn búburú pẹ̀lú iná àjóòkú.

35 Àti kíyèsíi, eléyí kò tíì yá, ṣùgbọ́n láìpẹ́.

36 Nísisìyí, ní rírí pé èmi, Olúwa, ti pàṣẹ gbogbo nkan wọ̀nyí sí orí ilẹ̀ ayé, èmi fẹ́ kí àwọn ẹni mímọ́ mi jẹ́ kíkójọ ní orí ilẹ̀ Síónì;

37 Àti pé olúkúlùkù ènìyàn níláti mú ìwà òdodo ní ọwọ́ rẹ̀ àti ìṣòtítọ́ bíi àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ wọn, kí wọn ó sì gbé ohùn ìkìlọ̀ sókè sí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé; àti kí wọn ó kéde nípa ọ̀rọ̀ àti nípa sísá kúrò pé ìsọdahoro yíò wá sí orí àwọn ènìyàn búburú.

38 Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi ní Kirtland to àwọn àníyàn wọn nípa ti ara lẹ́sẹẹsẹ, àwọn tí wọ́n ngbé ní orí ilẹ̀ oko yìí.

39 Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Titus Billings, ẹnití ó ni ìtọ́jú ibẹ̀, ó ta ilẹ̀ náà, kí òun ó lè gbáradì ní àkókò ìrúwé tí ó nbọ̀ láti rin ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Síónì, pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọn ngbé ní orí ilẹ̀ náà níbẹ̀, bíkòṣe àwọn tí èmi yío fi pamọ́ fun ara mi, ti wọn kì yíò lọ títí tí èmi yíò fi pàṣẹ fún wọn.

40 Ẹ sì jẹ́kí á fi àwọn owó tí a bá lè fí sílẹ̀, kò sì jẹ́ ohun kan sími bóyá ó jẹ́ kékeré tàbí púpọ̀, ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Síónì, sí àwọn ẹni tí èmi ti yàn láti gbà á.

41 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, yíò fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, ní agbára kí ó lè ṣeéṣe fún un lati mọ̀ ìyàtọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí àwọn wọnnì tí wọn yíò lọ sí ilẹ̀ Síónì, àti nínú àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi wọnnì tí wọn yíò dúró.

42 Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney dúró sí ilé ìtajà rẹ̀, tàbí ní ọ̀nà míràn, ilé ìtajà náà, fún ìgbà díẹ̀ síi.

43 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí òun ó fi gbogbo owó èyí tí ó bá lè fi fúnni, lati jẹ́ fífi ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Síónì.

44 Kíyèsíi, àwọn nkan wọ̀nyí wà ní ọwọ́ òun tìkararẹ̀, ẹ jẹ́ kí òun ṣe gẹ́gẹ́bí ọgbọ́n.

45 Lõtọ́ ni mo wí, ẹ jẹ́ kí á ṣe ìlànà fún òun bíi aṣojú fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn tí wọn yíò dúró, kí á sì ṣe ìlànà fún un sí agbára yìí;

46 Àti nísisìyí ẹ yára ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ilé ìjọ, ní sísọ àsọyé àwọn nkan wọ̀nyí fún wọn, pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery. Kíyèsíi, èyí ni ìfẹ́ mi, ní gbígba àwọn owó àní bí èmi ṣe darí.

47 Ẹni tí ó bá jẹ́ olõtọ́ tí ó sì faradà yíò borí ayé.

48 Ẹnití ó bá fi àwọn ìṣúra ránṣẹ́ sí Síónì yíò gba ogún ìní kan ní ayé yìí, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yíò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́hìn, àti bákannáà yíò gba èrè ní ayé tí nbọ̀.

49 Bẹ́ẹ̀ni, ìbùkún sì ni fún àwọn òkú tí wọn kú nínú Olúwa, láti ìsisìyí lọ, nígbàtí Olúwa yíò dé, tí àwọn ohun àtijọ́ yíò sì kọjá lọ, tí ohun gbogbo yíò sì di ọ̀tun, wọn yíò jí dìde kúrò nínú òkú tí wọn kì yíò sì kú mọ́ lẹ́hìn náà, wọn yíò sì gba ogún kan ní iwájú Olúwa, ní ìlú mímọ́ náà.

50 Àti ẹni náà tí ó bá wà láàyè nígbátí Olúwa yíò dé, tí òun sì wà nínú ìgbàgbọ́, ìbùkún ni fún un; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti yàn án fún un láti kú ní ọjọ́ orí ènìyàn.

51 Nísisìyí, àwọn ọmọdé yíò dàgbà títí tí wọn yíò fi di arúgbó; àwọn arúgbó yíò kú; ṣùgbọ́n wọn kì yíò sùn nínú eruku, ṣùgbọ́n a ó pa wọ́n lára dà ní ìṣẹ́jú àáyá.

52 Nísisìyí, fún ìdí èyí ni àwọn àpóstélì ṣe wàásù sí gbogbo ayé nípa àjínde àwọn òkú.

53 Àwọn nkan wọ̀nyí ni àwọn ohun tí ẹ̀yin gbọ́dọ̀ máa wá kiri; àti, ní sísọ ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà ti Olúwa, wọ́n ti súnmọ́ itòsí nísisìyí, àti ní àkókò tí ó nbọ̀, àní ní ọjọ́ bíbọ̀ Ọmọ Enìyàn.

54 Àti pé títí di wákàtí náà àwọn aláìlọ́gbọ́n wúndía yío wà láàrin àwọn olóye; àti ní wákàtí náà ni ìyàsọ́tọ̀ pátápátá yío dé sí àwọn olódodo àti àwọn ènìyàn búburú; àti ní ọjọ́ náà ni èmi yíò rán àwọn ángẹ́lì mi láti fa àwọn ènìyàn búburú tu àti lati jù wọ́n sínú iná tí a kò le pa.

55 Àti nísisìyí kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi, Olúwa, èmi kò ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon; òun gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, kò sì gba ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n òun nmú Ẹ̀mí banújẹ́;

56 Nítorínáà ìwé kíkọ rẹ̀ kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, òun yíò sì kọ òmíràn; bí Olúwa kò bá sì gbà á, kíyèsíi òun kì yíò dúró mọ́ sí ipò iṣẹ́ èyítí èmi ti yàn án sí.

57 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìfẹ́ nínú ọkàn wọn, pẹ̀lú ọkàn tútù, láti kìlọ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lati ronúpìwàdà, ẹ jẹ́ kí á ṣe ìlànà fún wọn sínú agbára yìí.

58 Nítorí èyí ni ọjọ́ ìkìlọ̀, àti pé kìí ṣe ọjọ́ ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí èmi, Olúwa, èmi kì yíò di gígàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.

59 Kíyèsíi, èmi wá láti òkè, agbára mi sì wà ní ìsàlẹ̀. Èmi wà ní orí ohun gbogbo, àti nínú ohun gbogbo, èmi sì la ohun gbogbo já, mo ṣe àyẹ̀wò ohun gbogbo, àti pé ọjọ́ náà dé tán tí ohun gbogbo yíò wà ní abẹ́ àkóso mi.

60 Kíyèsíi, èmi ni Álfà àti Òmégà, àní Jésù Krístì.

61 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí gbogbo ènìyàn ó ṣọ́ra nípa bí wọn ṣe npe orúkọ mi ní ètè wọn—

62 Nítorí kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà tí wọ́n wà lábẹ́ ìdálẹ́bi yìí, tí wọ́n nlo orúkọ Olúwa, tí wọn sì nlò ó lásán, láìní àṣẹ.

63 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ìjọ ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti pé èmi, Olúwa, yíò sì ní wọ́n; bíbẹ́ẹ̀kọ́ a ó ké wọ́n kúrò.

64 Ẹ rantí pé èyíinì tí ó wá láti òkè jẹ́ mímọ́, a sì gbọ́dọ̀ sọ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ìṣọ́ra, àti nípa ìjánu ti Ẹ̀mí; àti nínú èyí kò sí ìdálẹ́bi, ẹ̀yin sì gba Ẹ̀mí nípasẹ̀ àdúrà; nítorínáà, bí kò bá sí èyí ìdálẹ́bi yíò wà síbẹ̀.

65 Ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon, ó wá ibùgbé kan fun wọn, bí a ṣe kọ́ wọn nípasẹ̀ àdúrà láti ọwọ́ Ẹ̀mí.

66 Àwọn nkan wọ̀nyí wà lati lè borí nípasẹ̀ sùúrù, pé kí irú wọn lè gbà ìwúwo ògo ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìdálẹ́bi tí ó tóbi jù. Àmín.