Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 75


Ìpín 75

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Amherst, Ohio, 25 Oṣù Kínní 1832. Abala yìí ní àwọn ìfihàn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú (àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹsẹ 1 títí dé 22 àti èkejì nínú àwọn ẹsẹ 23 títí dé 36) tí a fi fúnni ní ọjọ́ kannáà. Àkókò náà jẹ́ ti ìpàdé àpéjọpọ̀ kan níbití a ti gbà Joseph Smith wọlé tí a sì yàn án bíi Ààrẹ ti Oyè Àlùfáà Gíga. Àwọn alàgbà kan, ní ìfẹ́ ọkàn láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa àwọn ojúṣe wọn lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn ìfihàn yìí ni ó tẹ̀lée.

1–5, Àwọn alàgbà olõtọ́ tí wọ́n nwàásù ìhìnrere yíò jogún ìyè ayérayé; 6–12, Ẹ gbàdúrà láti gba Olùtùnú, ẹnití ó nkọ́ni ní ohun gbogbo; 13–22, Àwọn alàgbà ni wọn yíò jókòó ní ìdájọ́ ní orí àwọn tí wọ́n bá kọ ọ̀rọ̀ wọn; 23–36, Àwọn ẹbí ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yíò gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ìjọ.

1 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, èmi tí mo nsọ̀rọ̀ àní nípa ohùn Ẹ̀mí mi, àní Álfà àti Omégà, Olúwa yín àti Ọlọ́run yín—

2 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin tí ẹ ti fi orúkọ yín sílẹ̀ láti jade lọ́ kéde ìhìnrere mi, àti láti pa ẹ̀ka ọgbà ajarà mi.

3 Ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín pé ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ̀yin ó jade lọ kí ẹ má sì ṣe dúró, tàbí kí ẹ̀yin jẹ́ aláìníṣẹ́ ṣùgbọ́n kí ẹ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára yín—

4 Ní gbígbé ohùn yín sókè bíi pẹ̀lú ìró fèrè, ní kíkéde òtítọ́ náà gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn àti àwọn òfin èyí tí èmi ti fi fún yín.

5 Àti ní báyìí, bí ẹ̀yin bá jẹ́ olõtọ́ ẹ̀yin yíò kó ìtí lọ́pọ̀lọpọ̀, à ó sì dée yín ládé pẹ̀lú ọlá, àti ògo, àti àìkú àti ìyè ayérayé.

6 Nitorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi William E. McLellin, èmi pa àṣẹ náà rẹ́ tí mo fi fún un láti lọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìlà oòrùn;

7 Èmi sì fi àṣẹ titun kan fún un àti òfin titun kan, nínú èyí tí èmi, Olúwa, bá a wí nítorí àwọn íkùnsínú ọkàn rẹ̀;

8 Òun sì dẹ́ṣẹ̀; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi dárí jì í mo sì wí fún un lẹ́ẹ̀kansíi, Lọ sínú àwọn orílẹ̀-èdè ìhà gúúsù.

9 Ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Luke Johnson ó lọ pẹ̀lú rẹ̀, kí wọn ó sì kéde àwọn ohun tí èmi ti pàṣẹ fún wọn—

10 Ní kíké pe orúkọ Olúwa fún Olùtùnú náà, èyí tí yíò kọ́ wọn ní ohun gbogbo tí ó tọ̀nà fún wọn—

11 Ní gbígba àdúrà nígbà gbogbo pé kí wọn ó máṣe kãrẹ̀; níwọ̀n bí wọ́n bá sì ṣe èyí, èmi yíò wà pẹ̀lú wọn àní títí dé òpin.

12 Kíyèsíi, èyí ni ìfẹ́ inú Olúwa Ọlọ́run yín nípa yín. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

13 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Orson Hyde àti ìránṣẹ́ mi Samuel H. Smith rin ìrìnàjò lọ sí inú àwọn orílẹ̀-èdè apá ìlà oòrùn, kí wọ́n ó sì kéde àwọn ohun tí èmi ti pàṣẹ fún wọn; àti níwọ̀n bí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́, wòó, èmi yíò wà pẹ̀lú wọn àní títí dé òpin.

14 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ìránṣẹ́ mi Lyman Johnson, àti ìránṣẹ́ mi Orson Pratt, pé àwọn pẹ̀lú yíò rin ìrìnàjò wọn lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè apá ìlà oòrùn; àti kíyèsíi, sì wòó, èmi wà pẹ̀lú wọn bákannáà, àní títí dé òpin.

15 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún ìránṣẹ́ mi Asa Dodds, àti ìránṣẹ́ mi Calves Wilson, pé àwọn pẹ̀lú yíò rin ìrìnàjò wọn lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè apá iwọ̀ oòrùn, wọn yíó sì kéde ìhìnrere mi, àní bí èmi ṣe pàṣẹ fún wọn.

16 Ẹni tí ó bá sì jẹ́ olõtọ́ yíò borí ohun gbogbo, a ó sì gbé e sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.

17 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún ìránṣẹ́ mi Major N. Ashley, àti ìránṣẹ́ mi Burr Riggs, ẹ jẹ́ kí wọn ó rin ìrìnàjò wọn bákannáà lọ sí orílẹ̀-èdè apá gúúsù.

18 Bẹ́ẹ̀ni, ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn wọnnì rin ìrìnàjò wọn, bí mo ti pàṣẹ fún wọn, ní lílọ láti ilé dé ilé, àti láti ìletò dé ìletò, àti láti ìlú nlá dé ìlú nlá.

19 Àti ní èyíkéyìí ilé tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọn sì gbà yín, ẹ̀yin yíò fi ìbùkún yín sí orí ilé náà.

20 Àti inú èyíkéyìí ilé tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọn kò sì gbà yín, ẹ̀yin yíò kúrò ní ilé náà kánkán, ẹ ó sì gbọn erùpẹ̀ ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ bíi ẹ̀rí kan takò wọ́n.

21 Ẹ̀yin yíò sì kún fún ayọ̀ àti inú dídùn; kí ẹ̀yin sì mọ èyí, pé ní ọjọ́ ìdàjọ́ ẹ̀yin yíò jẹ́ onídãjọ́ ní orí ilé náà, ẹ ó sì dá wọn lẹ́bi;

22 Yíò sì sàn fún àwọn kèfèrí ní ọjọ́ ìdájọ́, jù fún ilé náà; nítorínáà, ẹ di àmùrè yín kí ẹ sì jẹ́ olõtọ́, ẹyin yíò sì borí ohun gbogbo, a ó sì gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.

23 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, báyìí ni Olúwa wí fún yín, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, tí ẹ ti fi orúkọ sílẹ̀ kí ẹ lè mọ ìfẹ́ inú rẹ̀ nípa yín—

24 Kíyèsíi, mo wí fún yín, pé ó jẹ́ ojúṣe ìjọ láti ṣe ìrànwọ́ ní ṣíṣe àtìlẹ́hìn fún àwọn ẹbí àwọn wọnnì, àti bákannáà láti ṣe àtìlẹ́hìn fún àwọn ẹbí àwọn wọnnì tí a pè àti tí ó jẹ́ dandan lati rán wọn lọ sí inú ayé láti kéde ìhìnrere sí aráyé.

25 Nítorínáà, èmi, Olúwa, fi òfin yìí fún yín, pé kí ẹ gba ibùgbé fún àwọn ìdílé yín, níwọ̀nbí àwọn arákùnrin yín bá nfẹ́ láti ṣí ọkàn wọn payá.

26 Ẹ sì jẹ́ kí gbogbo irú àwọn tí wọ́n bá lè gbà ibùgbé fún àwọn ìdílé wọn, àti àtìlẹ́hìn ìjọ fún wọn, ó máṣe kùnà láti lọ sí inú ayé, yálà sí ìlà oòrùn tàbí sí ìwọ̀ oòrùn, tàbí sí àríwá, tàbí sí gúúsù.

27 Ẹ jẹ́ kí wọn ó béèrè wọn yíò sì rí gbà, kàn ìlẹ̀kùn a ó sì ṣí i fún wọn, a ó sì fi hàn fún wọn láti òkè wá, àní nípasẹ̀ Olùtùnú, ibi tí wọn yíò lọ.

28 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé olúkúlùkù ènìyàn tí fi ipá mú láti pèsè fún ìdílé tirẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó pèsè, òun kì yíò sì pàdánù adé rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí; ẹ sì jẹ́ kí òun ṣiṣẹ́ nínú ìjọ.

29 Ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn ó jẹ́ aláápọn nínú ohun gbogbo. Àti pé aláìníṣẹ́ kì yíò ní àyè nínú ìjọ, bíkòṣe pé òun ronúpìwàdà tí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe.

30 Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Simeon Carter àti ìránṣẹ́ mi Emer Harris ó fi ìmọ̀ ṣe ọ̀kan nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà;

31 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Ezra Thayre àti ìránṣẹ́ mi Thomas B. Marsh;

32 Bákannáà ìránṣẹ́ mi Hyrum Smith àti ìránṣẹ́ mi Reynolds Cahoon;

33 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Daniel Stanton àti ìránṣẹ́ mi Seymour Brunson;

34 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Sylvester Smith àti ìránṣẹ́ mi Gideon Carter;

35 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Ruggles Eames àti ìránṣẹ́ mi Stephen Burnett;

36 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Micah B. Welton àti bákannáà ìránṣẹ́ mi Eden Smith. Àní bẹ́ẹ̀ ni. Àmín.