Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 90


Ìpín 90

Ìfihàn sí Wòlíì Joseph Smith tí a fi fún un ní Kirtland, Ohio, 8 Oṣù Kejì 1833. Ìfihàn yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìgbésẹ̀ nínú ìdásílẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní (wo àkọlé sí ìpín 81); bíi àyọrísí rẹ̀, àwọn olùdámọ̀ràn tí a dárúkọ ni a yàn ní 18 Oṣù Kejì 1833.

1–5, Àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà ni a kó lé Joseph Smith lọ́wọ́ àti nípasẹ̀ rẹ̀ sí Ìjọ; 6–7, Sidney Rigdon àti Frederick G. Williams yíò ṣiṣẹ́ nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní; 8–11, Ìhìnrere náà ni yío jẹ́ kíkéde sí àwọn orílẹ̀-èdè Isráẹ́lì, sí àwọn Kèfèrí, àti sí àwọn Júù, olúkúlùkù ènìyàn ní gbígbọ́ ní èdè tirẹ̀; 12–18, Joseph Smith àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ yíò ṣe àgbékalẹ̀ ètò Ìjọ; 19–37, Onírúurú ẹnikọ̀ọ̀kan ni Olúwa gbà nímọ̀ràn lati rìn ní mímọ́ àti lati ṣiṣẹ́ nínú ìjọba Rẹ̀.

1 Báyìí ni Olúwa wí, lõtọ́, lõtọ́ mo wí fún ọ ọmọ mi, ati dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, gẹ́gẹ́bí ẹ̀bẹ̀ rẹ, nítorí àwọn àdúrà rẹ àti àwọn àdúrà àwọn arákùnrin rẹ ti gòkè wá sí etí mi.

2 Nítorínáà, alábùkúnfún ni ìwọ láti ìsisìyí lọ tí ó mú àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà lọ́wọ́ tí a fi fún ọ; ìjọba èyítí ó nbọ̀ wá fún ìgbà ìkẹhìn.

3 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba yìí ni a kì yíò gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà nínú ayé, tàbí ní ayé tí ó nbọ̀;

4 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ rẹ ni a ó fi àwọn ọ̀rọ̀ ìfihàn fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ni, àní sí ìjọ.

5 Àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbà àwọn ọ̀rọ̀ ìfihàn Ọlọ́run, jẹ́ kí wọn ó kíyèsára nípa bí wọ́n ṣe dìí mú bíbẹ́ẹ̀kọ́ wọn yíò sọ ọ́ di ohun kan yẹpẹrẹ, kí a sì mú wọn wá sí àbẹ́ ìdálẹ́bi nípa èyí, àti kí wọn ó kọsẹ̀ kí wọn ó sì ṣubú nígbàtí àwọn ìjì bá sọ̀kalẹ̀, àti tí afẹ́fẹ́ bá nfẹ́, àti tí òjò bá sọ̀kalẹ̀, tí ó sì npa orí ilé wọn.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún àwọn arákùnrin rẹ, Sidney Rigdon àti Frederick G. Williams, a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì bákannáà, a sì ka àwọn náà sí dọ́gba dọ́gba pẹ̀lú rẹ ní dídi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba tí ó kẹ́hìn yìí mú;

7 Bí ó ṣe jẹ́ pé bákannáà nípasẹ̀ iṣẹ́ àmójútó rẹ ní dídi àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ilé ìwé àwọn Wòlíì náà mú, èyí tí èmi ti pàṣẹ lati gbékalẹ̀;

8 Pé nípa èyí kí á lè sọ wọ́n di pípé nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn fún ìgbàlà Síónì, àti ti àwọn orílẹ̀-èdè Ísráẹ́lì, àti ti àwọn Kèfèrí, bíi iye àwọn tí wọn yíò gbàgbọ́;

9 Pé nípasẹ̀ iṣẹ́ àmojútó rẹ wọn yíò lè gba ọ̀rọ̀ náà, àti nípasẹ̀ iṣẹ́ àmojútó wọn ọ̀rọ̀ náà yíò lè jade lọ sí àwọn òpin ilẹ̀, sí àwọn Kèfèrí ní àkọ́kọ́, àti nígbànáà, kíyèsíi, sì wòó, wọn yíò kọjú sí àwọn Júù.

10 Àti nígbànáà ni ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí a ó fi ọwọ́ Olúwa hàn nínú agbára ní yíyí àwọn orílẹ̀-èdè lọ́kàn padà, àwọn abọ̀rìṣà orílẹ̀-èdè, ilé Jósefù, sí ìhìnrere ìgbàlà wọn.

11 Nítorí yíò sì ṣe ní ọjọ́ náà, tí olúkúlùkù ènìyàn yíò gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ní ahọ́n tirẹ̀, àti ní èdè tirẹ̀, nípasẹ̀ àwọn tí a ti yàn sí agbára yìí, nípa iṣẹ́ àkóso ti Olùtùnú náà, tí a tú sí orí wọn fún ìfihàn ti Jésù Krístì.

12 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fun yín, èmi fún yín ní òfin kan pé kí ẹ tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ti àjọ ààrẹ.

13 Nígbàtí ẹ̀yin bá sì ti parí títúmọ̀ ìwé àwọn Wòlíì, láti ìgbànáà lọ ẹ̀yin yío máa ṣe àkóso ní orí àwọn ọ̀rọ̀ ìjọ àti ti ilé ẹ̀kọ́ náà;

14 Àti láti àkókò dé àkókò, bí a ó ṣe fi hàn nípasẹ̀ Olùtùnú, ẹ̀yin yíò gba àwọn ìfihàn láti ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà;

15 Ẹ̀yin yíò sì ṣe àwọn ìjọ létòlétò, ẹ ó sì ṣe àṣàrò àti ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ ó sì ní òye nípa gbogbo àwọn ìwé rere, àti pẹ̀lú àwọn èdè, àwọn ahọ́n, àti ènìyàn.

16 Èyí ni yíò sì jẹ́ iṣẹ́ òwò àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín ní gbogbo ayé yín, láti ṣe àkóso nínú ìgbìmọ̀, àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọ àti ìjọba yìí létòlétò.

17 Ẹ máṣe jẹ́kí ojú tì yín, tàbí kí ẹ dààmú; ṣùgbọ́n ẹ gba ìbáwí nínú gbogbo ọkàn gíga àti ìgbéraga yín, nítorí yío mú ìkẹkùn wá sí orí ọkàn yín.

18 Ẹ ṣe àwọn ilé yín létòléto; ẹ mú ìmẹ́lẹ́ àti ìwà èérí jìnà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

19 Nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, jẹ́ kí á pèsè ibi kan, bí ó ṣe lè yá tó láti ṣe, fún ẹbí olùdamọ̀ràn àti akọ̀wé rẹ, àní Frederick G. Williams.

20 Sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi tí ó ti di ogbó, Joseph Smith Àgbà, dúró pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ ní orí ibití ó ngbé nísisìyí; ẹ má sì ṣe jẹ́kí ó di títà títí tí a ó fi dárúkọ rẹ̀ láti ẹnu Olúwa.

21 Ẹ sì jẹ́ kí olùdámọ̀ràn mi, àní Sidney Rigdon, dúró níbití ó ngbé nísisìyí títí tí ẹnu Olúwa yíò fi dárúkọ.

22 Ẹ sì jẹ́kí bíṣọ́ọ̀pù náà ó wádìí pẹ̀lú aápọn láti ní aṣojú kan, àti pé kí òun jẹ́ ẹnìkan tí ó ní ọrọ̀ ni ìpamọ́—ènìyàn Ọlọ́run, àti ti ó ní ìgbàgbọ́ tó ní agbára—

23 Pé nípa èyí kí a lè fún un ní agbára láti san gbogbo gbèsè; kí ilé ìsúra Olúwa ó má baà di ohun tí a mú àbùkù bá lójú àwọn ènìyàn.

24 Ẹ wádìí pẹ̀lú aápọn, ẹ gbàdúrà nígbà gbogbo, ẹ sì jẹ́ onígbàgbọ́, ohun gbogbo yíò sì ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ire yín, bí ẹ̀yin bá rìn déédé àti tí ẹ rántí májẹ̀mú nípa èyí tí ẹ̀yin ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara yín.

25 Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹbí yin jẹ́ kékeré, pàápàá ìránṣẹ mi tí ó ti di ogbó Joseph Smith Àgbà, bí ó ṣe kan àwọn wọnnì tí kìí ṣe ara àwọn ẹbí yín;

26 Kí àwọn ohun tí a ti pèsè fún yín, láti mú kí iṣẹ́ mi ó lè di mímúṣẹ, má baà di gbígbà kúrò lọ́wọ́ yín kí á sì fi fún àwọn tí kò yẹ—

27 Àti nípa bẹ́ẹ̀ kí ẹ̀yin lọ ní ìdíwọ́ nínú ṣíṣe àṣeyọrí àwọn nkan wọnnì èyítí èmi ti pàṣẹ fún yín.

28 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ìránṣẹ́-bìnrin mi Vienna Jaques ó gba owó láti lò fún àwọn ìnáwo rẹ̀, kí òun sì gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì;

29 Àti ìyókù owó náà lè jẹ́ yíyà sí mímọ́ sí mi, òun yíò sì gba èrè ní àkókò tí ó tọ́ ní ojú mi.

30 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ó tọ́ ní ojú mi pé kí òun ó gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì, kí òun sì gba ogún ìní kan láti ọwọ́ bíṣọpù;

31 Kí òun ó lè fìdí kalẹ̀ ní àlãfíà níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, àti tí kò wà ní àìnísẹ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ láti ìgbà yìí lọ.

32 Sì kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹ̀yin yíò kọ òfin yìí, ẹ ó sì wí fún àwọn arákùnrin yín ní Síónì, nínú ìkíni ti ìfẹ́, pé mo ti pè ẹ̀yín bákannáà láti ṣe àkóso ní orí Síónì ní àkókò tí ó tọ́ lójú mi.

33 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí wọn ó dáwọ́ dúró ní yíyọ́mí lẹ́nu ní orí ọ̀rọ̀ yìí.

34 Kíyèsíi, èmi wí fún yín pé àwọn arákùnrin yín ní Síónì ti bẹ̀rẹ̀ sí ronúpìwàdà, àwọn ángẹ́lì sì yọ̀ nítorí wọn.

35 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi kò ni inú dídùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan; èmi kò sì ní inú dídùn pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi William E. McLellin, tàbí pẹ̀lú ìránṣẹ mi Sidney Gilbert; àti bíṣọ́ọ̀pù bákannáà, àti pé àwọn míràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun láti ronúpìwàdà lé ní orí.

36 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé èmi, Olúwa, yíò jà pẹ̀lú Síónì, èmi ó sì pàrọwà pẹ̀lú àwọn alagbára rẹ̀, èmi ó bá a wí títí tí yíó fi di aṣẹ́gun àti tí yíó di mímọ́ níwájú mi.

37 Nítorí a kì yíò mú un kúrò ní ààyè rẹ̀. Èmi, Olúwa, ti sọ ọ́. Àmin.