Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 118


Ìpín 118

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 8 Oṣù Keje 1838, ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀, “Fi ìfẹ́ inú rẹ hàn wá, Olúwa, nípa ti àwọn Méjìlá náà.”

1–3, Olúwa yíò pèsè fún àwọn ẹbí àwọn Méjìlá náà; 4–6, Àwọn àlàfo láàrin àwọn Méjìlá ni a dí.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí: Ẹ jẹ́kí á ṣe ìpàdé gbogbogbòò kan lọ́gán; ẹ jẹ́ kí á ṣe ètò àwọn Méjìlá; kí á sì yan àwọn ènìyàn láti dí ààyè àwọn wọnnì tí wọn ti ṣubú.

2 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Thomas ó dúró fún ìgbà kan ní ilẹ̀ Síónì, láti kéde ọ̀rọ̀ mi.

3 Ẹ jẹ́kí àwọn ìyókù ó tẹ̀síwájú láti wàásù láti wákàtí náà, àti pé bí wọ́n bá ṣe èyí ní gbogbo ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, nínú ọkàn tutu àti ìtẹríba, àti ìpamọ́ra, èmi, Olúwa, fi ìlérí kan fún wọn pé èmi yíò pèsè fún àwọn ẹbí wọn; àti pé ìlẹ̀kùn àìtàsé yíò ṣí fún wọn, láti ìsisìyí lọ.

4 Àti ní ìgbà ìrúwé tí ó nbọ̀ ẹ jẹ́kí wọ́n ó lọ kúrò láti lọ ní orí àwọn omi nlá, àti níbẹ̀ kí wọ́n tan ìhìnrere mi káàkiri, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, kí wọn ó sì jẹ́rìí àkọsílẹ̀ orúkọ mi.

5 Ẹ jẹ́kí wọ́n ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ mi ní ìlú nlá ti Far West, ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin tí ó nbọ̀, ní ọ̀gangan orí ilẹ̀ ibití a ó kọ́ ilé mi sí, ni Olúwa wí.

6 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi John Taylor, àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi John E. Page, àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Wilford Woodruff, àti pẹ̀lú ìránṣẹ́ mi Willard Richards, jẹ́ yíyàn láti dí àwọn ààyè àwọn wọnnì tí wọn ti ṣubú, kí á sì sọ ìyànsípò wọn di mímọ̀ fún wọn lábẹ́ òfin.