Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 105


Ìpín 105

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní orí Odò Fishing, Missouri, 22 Oṣù Kẹfà 1834. Ní abẹ́ jíjẹ́ aṣiwájú ti Wòlíì, àwọn Ènìyàn Mímọ́ lati Ohio ati àwọn agbègbè mĩràn rìn lọ sí Missouri ninú ọ̀wọ́ kan tí a mọ̀ ní ìgbẹ̀hìn bíi Àgọ́ Síonì. Èrò wọn ni láti sin àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n ti lé jáde pàdà sí àwọn ilẹ̀ wọn ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson. Àwọn ara Missouri tí wọ́n ti yọ àwọn Ènìyàn Mímọ́ lẹ́nu bẹ̀rù ìránró lati Àgọ́ Síonì wọ́n sì fi ìwànwára kọlu àwọn Ènìyàn Mímọ́ kan tí wọ́n ngbé ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Clay, Missouri. Lẹ́hìn ti gómìnà Missouri ré ìlérí rẹ̀ padà láti ṣe àtilẹ́hìn fún àwọn Ènìyàn Mímọ́, Joseph Smith gba ìfihàn yìí.

1–5, Síónì yíó di kíkọ́ nípa síṣe deédé sí òfin Sẹ̀lẹ́stíà; 6–13, A dá ìràpadà Síónì dúró fún ìgbà díẹ̀; 14–19, Olúwa yíò ja àwọn ogun Síónì; 20–26, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níláti jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí wọ́n má sì ṣe yangàn ti àwọn iṣẹ́ tó ní agbára bí wọ́n ṣe npéjọ; 27–30, Àwọn ilẹ̀ ní Jackson àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yíká rẹ̀ níláti jẹ́ rírà; 31–34, Àwọn alàgbà yíó gba ẹ̀bùn ti ẹ̀mí nínú ilé Olúwa ní Kirtland; 35–37, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí a pè tí a sì yàn ni a ó yà sí mímọ́; 38–41, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíó gbé ọ̀págun àlãfíà kan sókè sí ayé.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín ẹ̀yín tí ẹ ti péjọ papọ̀ pẹ̀lú ara yín kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ ti ìfẹ́ inú mi nípa ìràpadà àwọn ènìyàn tèmi tí a ti pọ́n lójú—

2 Kíyèsíi, mo wí fún yín, bí kìí bá ṣe ti ìrékọjá àwọn ènìyàn mi, ní sísọ̀rọ̀ nípa ìjọ àti tí kìí ṣe àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, bóyá wọn ìbá ti di ẹni ìràpadà àní nìsisìyí.

3 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, wọn kò tíì kọ́ ẹ̀kọ́ láti jẹ́ olùgbọ́ràn sí àwọn ohun èyítí mo béèrè lọ́wọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n kún fún gbogbo ìwà ibi, wọn kò sì fi lára ohun ìní wọn, bí ó ṣe yẹ fún awọn ènìyàn mímọ́, fún àwọn tálákà àti àwọn tí a pọ́nlójú ní ààrin wọn;

4 Wọn kò sì wà ní ìṣọ̀kan ní ìbámu sí ìdàpọ̀ náà tí a béèrè nípasẹ̀ òfin tí ìjọ̀ba sẹ̀lẹ́stíà;

5 A kò sì lè kọ́ Síónì bíkòṣe pé ó jẹ́ nípa àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ òfin ti ìjọba sẹ̀lẹ́stíà; bíbẹ́ẹ̀kọ́ èmi kì yíò le gbà á sí ọ̀dọ̀ èmi tìkárami.

6 Àwọn ènìyàn mi sì gbọ́dọ̀ jẹ́ bíbáwí títí tí wọn yíò fi kọ́ ẹ̀kọ́ ìgbọ̀ràn, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, nípa àwọn ohun tí wọ́n jìyà.

7 Èmi kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí a yàn láti síwájú àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n jẹ́ àwọn alàgbà àkọ́kọ́ ti ìjọ mi, nítorí kìí ṣe gbogbo wọn ni wọ́n wà lábẹ́ ìdálẹ́bi yìí;

8 Ṣùgbọ́n mò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọ mi ní òkèrè—ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà tí yíò wípé: Níbo ni Ọlọ́run wọ́n wà? Kíyèsíi, òun yíò gbà wọ́n sílẹ̀ ní igbà wàhálà, bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwa kì yíò gòkè lọ sí Siónì, a ó sì fi àwọn owó wa pamọ́.

9 Nítorínáà, ní àyọrísí àwọn ìrékọjá ti àwọn ènìyàn mi, ó tọ̀nà nínú mi pé kí àwọn alàgbà mi ó dúró fún ìgbà díẹ̀ fún ìràpadà Síónì—

10 Kí àwọn fúnra wọn ó lè múrasílẹ̀, àti kí àwọn ènìyàn mi lè jẹ́ kíkọ́ ní pípé síi, àti kí wọn o ní ìrírí, àti kí wọn ó mọ̀ ní pípé síi nípa ojúṣẹ wọn, àti àwọn ohun èyítí mo béèrè lọ́wọ́ wọn.

11 A kò sì lè mú èyí wá sí ìmúṣẹ títí tí àwọn alàgbà mi yío di bíbùn ní ẹ̀bùn agbára láti òkè wá.

12 Nítorí kíyèsíi, èmi ti pèsè ẹ̀bùn nlá kan àti ìbùkún láti jẹ́ títú jade sí orí wọn, níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́ àti tí wọ́n tẹ̀síwájú síi nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níwájú mi.

13 Nítorínáà ó tọ̀nà nínú mi pé kí àwọn alàgbà mi ó dúró fún ìgbà díẹ̀, fún ìràpadà Síónì.

14 Nítorí kíyèsíi, èmi kò beerè lọ́wọ́ wọn láti ja àwọn ogun Síónì; nítorí, bí mo ṣe wí nínú àṣẹ ti ìṣaájú, àni bẹ́ẹ̀ náà ni èmi yíò múṣẹ—èmi yíò ja àwọn ogun yín.

15 Kíyèsíi, apanirun náà tí mo ti rán jade lọ láti parun àti láti sọ àwọn ọ̀tá mi di àìwúlò; àti pé ní àwọn ọdún tí kò pọ̀ sí ìsisìyí a kì yíò fí wọ́n sílẹ̀ láti sọ ogún mi di àìmọ́, àti láti sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ mi ní orí ilẹ̀ náà èyítí èmi ti yà sí mímọ́ fún àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ mi.

16 Kíyèsíi, mo ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, láti wí fún agbára ilé mi, àní àwọn jagunjagun mi, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi, àti àwọn dídàgbà díẹ̀, láti kórajọ papọ̀ fún ìràpadà àwọn ènìyàn mi, kí wọn ó sì wó àwọn ilé ìsọ́ ti àwọn ọ̀tá mi lulẹ̀, kí a sì tú àwọn asọ́nà wọn ká;

17 Ṣùgbọ́n agbára ilé mi kò tíì fetisílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

18 Ṣùgbọ́n níwọ̀nbí àwọn wọnnì bá wà tí wọ́n fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, èmi ti pèsè ìbùkún kan àti ẹ̀bùn kan fún wọn, bí wọn bá tẹ̀síwájú ní jíjẹ́ olõtọ́.

19 Èmi ti gbọ́ àwọn àdúrà wọn, èmi ó sì gba ẹbọ-ọrẹ wọn; ó sì tọ̀nà ni ojú mi pé a nílati mú wọn wá dé tó báyìí fún ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn.

20 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, òfin kan ni mo fi fún yín, pé iyé àwọn tí wọ́n ti wá sí ìhín yìí, tí wọ́n lè dúró ní agbègbè yíkáàkiri, ẹ jẹ́ kí wọ́n ó dúró;

21 Àwọn wọnnì tí wọn kò bá sì le dúró, tí wọ́n ní àwọn ẹbí ní ìlà oòrùn, ẹ jẹ́ ki wọ́n ó dúro fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀nbí ìránṣẹ́ mi Joseph yíò ti yàn fún wọn;

22 Nítorí èmi yíò báa dámọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ yìí, ohun gbogbo èyíkéyìí tí òun bá sì yàn fún wọn ni yíò di mímúṣẹ.

23 Ẹ sì jẹ́kí gbogbo ènìyàn mi tí wọn ngbé ní àwọn agbègbè yíkáàkiri ó jẹ́ olõtọ́ gan an, àti kí wọn ó kún fún àdúrà, kí wọn ó sì ní ìrẹ̀lẹ̀ níwájú mi, wọn kì yíò sì ṣe àfihàn àwọn ohun èyítí èmi ti fi hàn sí wọn, títí tí yíó fi jẹ́ ọgbọ́n nínú mi pé kí a fi wọ́n hàn.

24 Ẹ máṣe sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ni kí ẹ máṣe yangàn ìgbàgbọ́ tàbí ti àwọn iṣẹ́ tí ó ní agbára, ṣùgbọ́n ẹ kó ara yín jọ pọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, bí ẹ bá ṣe lè pọ̀ tó ní agbègbè kan, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára ti àwọn ènìyàn náà;

25 Sì kíyèsíi, èmi yíò fún yín ní ojúrere àti ore ọ̀fẹ́ ní ojú wọn, pé kí ẹ̀yin ó lè sinmi ní àlãfíà àti ní àìléwu, nígbatí ẹ̀yin nwí fún àwọn ènìyàn pé: Ẹ ṣe ìdájọ́ àti òdodo fún wa gẹ́gẹ́bí òfin, kí ẹ sì ṣe àtúnṣe fún wa ní ti àwọn àṣìṣe wa.

26 Nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ní ọ̀nà yìí ẹ̀yin lè rí ojúrere ní ojú àwọn ènìyàn náà, títí tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísráelì yíò di nlá.

27 Èmi yíò sì rọ ọkàn àwọn ènìyàn náà, bí mo ṣe ṣe sí ọkàn Fáráo, láti ìgbà dé ìgbà, títí tí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti àwọn alàgbà mi, àwọn ẹnití èmi ti yàn, yíò fi ní àyè láti kó agbára ilé mi jọ,

28 Àti láti rán àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti ṣe ìmúṣẹ èyí tí mo ti pàṣẹ nípa ríra gbogbo àwọn ilẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Jackson tí a bá lè rà, àti ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ itòsí yíkáàkiri.

29 Nítorí ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyìí jẹ́ rírà; àti lẹ́hìn tí wọ́n bá jẹ́ rírà kí àwọn ènìyàn mímọ́ mi le ni wọ́n ní ìní gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ìyàsímímọ́ èyítí mo ti fi fúnni.

30 Àti lẹ́hìn tí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyìí bá ti di rírà, èmi yíò ka ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti Ísráẹlì sí aláìlẹ́bi ní gbígba àwọn ilẹ̀ tiwọn, èyítí wọ́n ti rà tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn owó wọn, àti ti wíwó lulẹ̀ àwọn ilé ìṣọ́ ti àwọn ọ̀tá mi èyítí ó lè wà ní orí wọn, àti títú àwọn asọ́nà wọn ká, àti gbígbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi sí ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin ti àwọn tí wọn kórira mi.

31 Ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́ ẹ jẹ́ kí ẹgbẹ ọmọ ogun mi ó di nlá púpọ̀ gan, ẹ sì jẹ́kí á yàá sí mímọ́ níwájú mi, kí ó lè lẹ́wà bíi oòrùn, àti mọ́lẹ̀ bíi òṣùpá, àti pé kí àwọn àsìá rẹ̀ lè ní ẹ̀rù sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;

32 Kí á lè mú àwọn ìjọba ayé nípá láti jẹ́wọ́ pé ìjọba Síónì jẹ́ ìjọba ti Ọlọ́run wa àti Krístì rẹ̀ ní tòótọ́; nítorínáà, ẹ jẹ́ kí á tẹríba sí àwọn òfin rẹ̀.

33 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ó tọ̀nà ní ojú mi pé àwọn alàgbà àkọ́kọ́ ti ìjọ mi níláti gba ẹ̀bùn wọn láti òkè wá nínú ilé mi, èyítí mo ti pàṣẹ láti kọ́ sí orúkọ mi ní ilẹ̀ Kirtland.

34 Ẹ sì jẹ́kí àwọn àṣẹ wọnnì èyítí mo ti fi fúnni nípa Síónì àti òfin rẹ̀ ó jẹ́ ṣíṣe àti mímúṣẹ, lẹ́hìn ìràpadà rẹ̀.

35 Ọjọ́ ìpè kan ti wà, ṣùgbọ́n àkókò náà ti dé fún ọjọ́ yíyàn; ẹ sì jẹ́kí àwọn tí a yàn ó jẹ́ ẹni ìkàyẹ.

36 A ó sì sọ ọ́ di mímọ̀ sí ìránṣẹ́ mi, nípa ohùn ti Ẹ̀mí, àwọn tí a yàn; a ó sì yà wọ́n sí mímọ́;

37 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá tẹ̀lé ìmọ̀ràn èyítí wọ́n gbà, wọn yíò ní agbára lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láti ṣe àṣeyọrí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Síónì.

38 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, ẹ béèrè fún àlãfíà, kìí ṣe sí àwọn tí wọ́n ti kọlù yín nìkan, ṣùgbọ́n sí gbogbo ènìyàn bákannáà;

39 Ẹ sì gbé ọ̀págun àlãfíà kan sókè, kí ẹ sì kéde àlãfíà sí àwọn ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;

40 Kí ẹ sì dá àwọn àbá fún àlãfíà sí àwọn tí wọ́n ti kọlù yín, ní ìbámu sí ohùn ti Ẹ̀mí èyítí ó wà nínú yín, ohun gbogbo yíò sì ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere yín.

41 Nítorínáà, ẹ jẹ́ olõtọ́; ẹ sì kíyèsíi, ẹ sì wòó, èmi wà pẹ̀lú yín àní títí dé òpin. Àní bẹ́ẹ̀ní. Àmín.