Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 51


Ìpín 51

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Thompson, Ohio, 20 Oṣù Karũn 1831. Ní àkókò yìí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti wọn nrin ìrìn àjò láti àwọn ìpínlẹ̀ apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ síí dé sí Ohio, ó sì di dandan pé kí á ṣe àwọn ètò tí ó dájú fún títẹ̀dó wọn. Bí ètò yìí ṣe jẹ́ ojúṣe kan gbógì fún ipò oyè bíṣọ́pù, Bíṣọpù Edward Partridge béèrè fún ìtọ́sọ́nà ní orí ọ̀rọ̀ náà, Wòlíì sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa.

1–8, Edward Partridge ni a yàn láti ṣe ètò àwọn iṣẹ́ ìríjú àti àwọn ohun ìní lẹ́sẹẹsẹ; 9–12, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níláti ṣe pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́ láì ṣègbè sí ara wọn; 13–15, Wọ́n nílati ní ilé ìṣúra ti bíṣọ́pù àti kí wọ́n ó sì ṣe ètò àwọn ohun ìní gẹ́gẹ́bí òfin Olúwa; 16–20, Ohio ni yíó jẹ́ ibi ìpéjọpọ̀ sí fún ìgbà díẹ̀.

1 Fetísílẹ̀ sí mi, ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí, èmi yíò sì sọ̀rọ̀ fún ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, èmi yíò sì tọ́ọ sọ́nà; nítorí ó jẹ́ dandan pé kí òun gba ìtọ́sọ́nà ní orí bí òun yíò ṣe ṣètò àmójútó àwọn ènìyàn yìí.

2 Nítórí ó jẹ́ dandan pé kí á ṣe èto wọn gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi; bí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀, a ó ké wọn kúrò.

3 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, àti àwọn wọnnì tí òun ti yàn, àwọn ẹnití inú mi dùn sí gidigidi, kí wọ́n ó fún àwọn ènìyàn yí ní àwọn ìpín wọn, ní ọgbọọgba fún ẹnikọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú ẹbí rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ipò rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó fẹ́ àti àwọn àìní rẹ̀.

4 Àti pé ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, nìgbà tí òun bá ti fún ẹnìkan ní ìpín rẹ̀, kí ó fún un ní ìwé kíkọ tí yíò fún un ní ààbò ní orí ìpín rẹ̀, pé òun yíò mú un lọ́wọ́, àní ẹ̀tọ́ yìí àti ogún ìní yìí nínú ìjọ, títí tí òun yíò fi rú òfin tí òun kò sì ní jẹ́ kíkà yẹ mọ́ nípasẹ̀ ohùn ìjọ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti májẹ̀mú ìjọ, láti jẹ́ ti ìjọ.

5 Àti bí òun bá sì rú òfin tí a kò sì kà á yẹ mọ́ láti jẹ́ ti ìjọ, òun kì yíò ní agbára láti pe ìpín náà ní tirẹ̀ èyí tí ó ti yà sí mímọ́ fún bíṣọpù fún àwọn aláìní àti tálákà nínú ìjọ mi; nítorínáà, òun kì yíò fi ẹ̀bùn náà sí ọwọ́ ara rẹ̀, ṣugbọ́n òun yío ní ẹ̀tọ́ ní orí ìpín náà èyí tí òun ní ìwé òfin lé ní orí nìkan.

6 Báyìí ni a ó sì fi ohun gbogbo dánilójú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin ilẹ̀ náà.

7 Àti pé ẹ jẹ́ kí á yan èyí tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn yìí fún àwọn ènìyàn yìí.

8 Àti owó èyí tí ó bá kù fún àwọn ènìyàn yìí—ẹ jẹ́ kí á yan aṣojú kan fún àwọn ènìyàn yìí, lati mú owó náà láti fi pèsè oúnjẹ àti aṣọ, gẹ́gẹ́bí ohun tí àwọn ènìyàn yìí fẹ́.

9 Ẹ sì jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ olõtọ́ ní ìṣe, àti kí wọ́n rí bákannáà láàrin àwọn ènìyàn yìí, kí wọn ó gbà bákannáà, kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọ̀kan, àní bí èmi ṣe pàṣẹ fún yín.

10 Ẹ má sì ṣe jẹ́ kí á gba ohun tí íṣe ti àwọn ènìyàn yìí kí a sì fúnni fún èyíinì tí íṣe ti ìjọ míràn.

11 Nítorínáà, bí ìjọ míràn bá gba owó ti ìjọ yìí, ẹ jẹ́ kí wọn ó tún san owó sínú ìjọ yìí gẹ́gẹ́bí wọ́n bá ṣe fi ẹnu kò;

12 Àti pé èyí yío sì jẹ́ ṣíṣe nípasẹ̀ bíṣọpù tábi aṣojú náà, èyí tí a ó yàn nípa ohùn ìjọ.

13 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́kí bíṣọ́pù ó yan ilé ìṣúra kan fún ìjọ yìí; ẹ sì jẹ́kí á fi ohun gbogbo ní owó àti ní oúnjẹ, tí ó bá pọ̀ ju èyí tí a nílò fún ohun tí àwọn ènìyàn yí fẹ́, pamọ́ sí ọwọ́ bíṣọpù.

14 Ẹ sì jẹ́ kí òun náà pẹ̀lú ó fi pamọ́ fún ara rẹ̀ bí òun bá ṣe fẹ́, àti fún àìní àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí a ti gbà á ní ṣíṣe iṣẹ́ yìí.

15 Àti báyìí ni èmi fún àwọn ènìyàn yìí ní ànfààní láti ṣe ètò ara wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin mi.

16 Èmi sì ya ilẹ̀ yìí sí mímọ́ fún wọn fún àkókò díẹ̀, títí tí èmi, Olúwa, yíò fi pèsè fún wọn ní ọ̀nà míràn, tí á o sì pàṣẹ pé kí wọ́n ó kúrò ní ìhín.

17 Àti pé wákàtí àti ọjọ́ náà ni a kò fifún wọn, nítorínáà ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iṣẹ́ ní orí ilẹ̀ yìí fún àwọn ọdún díẹ̀, èyí yíò sì yípadà sí wọn fún rere wọn.

18 Kíyèsíi, èyí yíò jẹ́ àpẹrẹ kan fún ìránṣẹ́ mi Edward Partridge, ní àwọn ibòmíràn, ní gbogbo àwọn ìjọ.

19 Ẹnikẹ́ni tí a bá sì rí tí ó jẹ́ olõtọ́, ẹni tí ó tọ́, àti ọlọ́gbọ́n ìríjú ni yíò wọlé sí inú ayọ̀ Olúwa rẹ̀, yíò sì jogún ìyè ayérayé.

20 Lõtọ́, ni mo wí fún yín, èmi ni Jésù Krístì, tí ó nbọ̀ kánkán, ní wákàtí tí ẹ̀yin kò lerò. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.