Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 60


Ìpín 60

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Independence, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, 8 Oṣù Kẹjọ 1831. Ní àkókò yìí àwọn alàgbà tí wọn ti rin ìrìnàjò sí Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson tí wọ́n sì kópa nínú ìyàsímímọ́ ilẹ̀ náà ati ibi tẹ́mpìlì fẹ́ lati mọ̀ ohun tí wọ́n nílati ṣe.

1–9, Àwọn alàgbà ni yíò wàásù nínú àwọn ìpéjọpọ̀ àwọn olùṣe búburú; 10–14, Wọn kì yíò fi àkókò wọn ṣòfò, tàbí kí wọ́n bo tálẹ́ntì wọn mọ́lẹ̀; 15–17, Wọ́n lè wẹ ẹsẹ̀ wọn bíi ìjẹ́rìí lòdì sí àwọn tí wọ́n kọ ìhìnrere.

1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún àwọn alàgbà ìjọ̀ rẹ̀, tí wọ́n níláti padà kánkán sí ilẹ̀ ibití wọ́n ti wá: Kíyèsíi, ó jẹ́ inú dídùn fún mi, pé ẹ̀yin ti wá sí ìhín.

2 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn kan ni inú mi kò dùn gidigidi, nítorí wọn kò la ẹnu wọn, ṣùgbọ́n wọ́n fi tálẹ́ntì tí èmi fi fún wọn pamọ́, nítorí ìbẹ̀rù ènìyàn. Ègbé ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀, nítorí ìbínú mi rú sókè sí wọn.

3 Yíò sì ṣe, bí àwọn kò bá jẹ́ olõtọ sími sí i, a ó gbàá kúrò, àní èyíinì tí wọ́n ní.

4 Nítorí èmi, Olúwa, nṣe àkóso ní àwọn ọ̀run lókè, àti láàrin àwọn ọmọ ogun ti ilẹ̀ ayé; àti pé ní ọjọ́ náà nígbàtí èmi yíò kó àwọn ìní mi iyebíye jọ, gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ èyíinì tí ó fi agbára Ọlọ́run hàn.

5 Ṣùgbọ́n, lõtọ́, èmi yíò wí fún yín nípa ìrìnàjò yín sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti wá. Ẹ jẹ́kí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kan jẹ́ síṣe, tàbí kí ẹ rà á, bí ó bá ṣe dára ní ojú yín, kò ṣe pàtàkì sí èmi, kí ẹ sì rin ìrìnàjò yín kánkán lọ sí ibi tí a npè ní St. Louis.

6 Ati láti ibẹ̀ ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi, Sidney Rigdon, Joseph Smith Kékeré, àti Oliver Cowdery, rin ìrìnàjò wọn sí Cincinnati;

7 Àti pé ní ìhínyìí ẹ jẹ́kí wọ́n ó gbé ohùn wọn sókè kí wọn ó sì kéde ọ̀rọ̀ mi ní ohùn rara, láì bínú tàbí láìṣiyèméjì, ní gbígbé ọwọ́ mímọ́ sí òkè orí wọn. Nítorí èmi ní agbára láti sọ yín di mímọ́, a sì ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

8 Ẹ sì jẹ́kí àwọn ìyókù rin ìrìnàjò wọn láti St. Louis, ní méjì méjì, kí wọ́n ó sì máa wàásù ọ̀rọ̀ náà, kìí ṣe pẹ̀lú ìkánjú, láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn èniyàn búburú, títí tí wọn yíò fi padà sí àwọn ìjọ lati ibití wọ́n ti wá.

9 Àti gbogbo èyí fún ire àwọn ìjọ; nítorí èrò yìí ni èmi ṣe rán wọn.

10 Àti kí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge fi fúnni lára owó tí mo fi fún un, apákan fún àwọn alàgbà mi tí a ti pa láṣẹ lati padà;

11 Àti pé ẹni tí ó bá ní agbára, ẹ jẹ́ kí òun dá a padà nípasẹ̀ aṣojú; àti ẹni tí kò bá sì ní agbára, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a kì yíò béèrè.

12 Àti nísisìyí èmi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyókù tí wọn yío wá sí ilẹ̀ yìí.

13 Kíyèsíi, a ti rán wọn láti wàásù ìhìnrere mi láàrin ipéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú; nísisìyí, èmi fún wọn ní òfin kan, báyìí: Ìwọ kò gbọdọ̀ fi àkókò rẹ ṣòfò, tàbí kí ìwọ ó bo tálẹ́ntì rẹ mọ́lẹ̀ kí ó má baà di mímọ̀.

14 Àti lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti wá sí ilẹ̀ Síónì, tí ẹ sì ti kéde ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin yíò padà kánkán, ní kíkéde ọ̀rọ̀ mi lààrin ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú, kìí ṣe pẹ̀lú ìkánjú, tàbí nínú ìbínú tàbí pẹ̀lú ijà.

15 Àti pé kí ẹ̀yin gbọn erùpẹ̀ ẹsẹ̀ bàtà yín lòdì sí àwọn wọnnì tí wọ́n kò gbà yín, kìí ṣe ní ìṣejú wọn, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ẹ ó mú wọn bínú, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀; kí ẹ̀yin sì wẹ ẹsẹ̀ yín, bíi ẹ̀rí lòdì sí wọn ni ọjọ́ ìdájọ́.

16 Kíyèsíi, èyí tó fũn yín, àti ìfẹ́ ẹni náà tí ó rãn yín.

17 Àti pé láti ẹnu ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, ni a ó ti sọ ọrọ̀ nípa Sidney Rigdon àti Oliver Cowdery di mímọ̀. Ìyíókù di ẹ̀hìnwá. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.