Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101


Ìpín 101

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 16 àti 17 Oṣù Kejìlá 1833. Ní àkókò yìí àwọn Ẹni Mímọ́ tí wọ́n ti péjọpọ̀ ní Missouri njìyà inúnibíni nlá. Àgbájọ àwọn adàlúrú ti lé wọn kúrò nínú àwọn ilé wọn ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson; díẹ̀ nínú àwọn Ẹni mímọ́ náà ti gbìyànjú láti ṣe àgbékalẹ̀ ara wọn ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Van Buren, Ìjọba Ìbílẹ̀ Lafayette, àti Ìjọba Ìbílẹ̀ Ray, ṣùgbọ́n inúnibíni tẹ̀lé wọn. Púpọ̀ ọ̀wọ́ àwọn Ẹni Mímọ́ ní àkókò náà wà ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Clay, Missouri. Àwọn ìdẹ́rùbà ikú ní ìdojúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ti inú ìjọ pọ̀ púpọ̀. Àwọn Ènìyàn Mímọ ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson ti pàdánù ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé, aṣọ wíwọ̀, àwọn ohun ọ̀sìn, àti àwọn ohun ìní ti ara ẹni míràn; àti pé púpọ̀ nínú àwọn èso oko wọn ni a ti bàjẹ́.

1–8, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a fìyà jẹ tí a sì pọ́n lójú nítori àwọn ìrékọjá wọn; 9–15, Ìbínú Olúwa yíò ṣubú sí orí àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Rẹ̀ ni a ó kójọpọ̀ ti a ó sì tù nínú; 16–21, Síónì àti àwọn èèkàn rẹ̀ ni a ó gbékalẹ̀; 22–31, Ìgbé ayé ní àkókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà ni a ṣe àpèjúwe; 32–42, Àwọn Ẹni Mímọ́ ni a ó bùkún ti a ó sì san ẹ̀san fún nígbànáà; 43–62, Òwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti àwọn igi ólífì ṣe àpẹrẹ àwọn ìyọnu àti ìràpadà Síónì lẹ́hìnwá; 63–75, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti tẹ̀síwájú ní kíkóra jọpọ̀; 76–80, Olúwa ṣe àgbékalẹ̀ Ìwé òfin ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà; 81–101, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti wí àwíìdákẹ́ fún ṣíṣe àtúnṣe ti àwọn ohunkóhun tí ó bá mú ìkùnsínú wá, gẹ́gẹ́bí òwe ti obìnrin nnì àti onídãjọ́ aláìṣõtọ́ náà.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, nípa àwọn arákùnrin yín àwọn tí a ti pọ́n lójú, àti tí a ti ṣe inúnibíni sí, àti tí a ti lé jáde kúrò ní ilẹ̀ ogún ìní wọn—

2 Èmi, Olúwa, ti gba ìpọ́njú náà láàyè látí wá sí orí wọn, nípa èyítí a ti pọ́n wọn lójú, ní ìyọrísí àwọn ìrékọjá wọn;

3 Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yíò ní wọn, wọ́n yíò sì jẹ́ tèmi ní ọjọ́ náà nígbàtí èmi yíò dé láti kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mi iyebíye jọ.

4 Nítorínáà, ó di dandan kí á bá wọn wí kí á sì dán wọn wò, àní bí Ábrahámù, ẹnití a pàṣẹ fún láti fi ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo rúbọ.

5 Nítorí gbogbo àwọn tí wọn kò bá lè faradà bíbáwí, ṣugbọ́n tí wọ́n kọ̀ mí, kò lè jẹ́ yíyàsímímọ́.

6 Kíyèsíi, mo wí fún yín, àwọn ariwo wà, àti àwọn èdè àìyédè, àti àwọn ìlara, àti àwọn ìjà, àti fífẹ́ràn ìfẹ́kũfẹ́ àti ojúkòkòrò lààrin wọn; nítorínáà nípa àwọn nkan wọ̀nyìí ni wọ́n sọ àwọn ogún ìní wọn di aláìmọ́.

7 Wọ́n lọ́ra láti fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn; nítorínáà, Olúwa Ọlọ́run wọn lọ́ra láti fetísílẹ̀ sí àwọn àdúrà wọn, láti dáwọn lóhùn ní ọjọ́ ìyọnu wọn.

8 Ní ọjọ́ àlãfíà wọn, wọ́n ka ìmọ̀ràn mi sí yẹpẹrẹ; ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ ìyọnu wọn, ní dandan ni wọn nwá mi.

9 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, láìṣírò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, inú mi kún pẹ̀lú ìyọ́nú sí wọn. Èmi kì yíò sì ta wọ́n nù pátápátá; àti pé ní ọjọ́ ìbínú èmi yíò rantí àánú.

10 Èmi ti búra, àṣẹ sì ti jade lọ nípa òfin ti ìṣaájú kan èyítí èmi ti fi fún yín, pé èmi yíò jẹ́ kí idà ìbínú mi ó sọ̀kalẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi; àti pé àní bí èmi ṣe wí, yíò wá sí ìmúṣẹ.

11 Ìbínú mi yíò di títú jade láìpẹ́ ní àìní òdiwọ̀n sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; èyí ni èmi yíò sì ṣe nígbati ago àìṣedéédé wọn bá kún.

12 Àti ní ọjọ́ náà gbogbo àwọn tí a bá rí ní orí ilé-ìsọ́ náà, tábí ní ọ̀nà míràn, gbogbo Ísráẹ́lì tèmi, ni a ó gbàlà.

13 Àti àwọn tí a ti fọ́nká ni a ó kójọpọ̀.

14 Àti gbogbo àwọn tí wọ́n ti ṣọ̀fọ̀ ni a ó tù nínú.

15 Àti gbogbo àwọn tí wọ́n ti fi ayé wọn sílẹ̀ fún orúkọ mi ni a ó dé ní adé.

16 Nitorínáà, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ní ìtùnú nípa Síónì; nítorí gbogbo ẹran ara wà ní ọwọ́ mi; ẹ dúró jẹ́ kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.

17 A kì yíò ṣí Síónì nípò kúrò ní àyè rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé àwọn ọmọ rẹ̀ ni a fọ́n ká.

18 Àwọn tí ó ṣẹ́kù, tí ọkàn wọ́n sì mọ́, yíò padà, wọn yío sì wá síbi àwọn ogún ìní wọn, àwọn àti àwọn ọmọ wọn, pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin, láti kọ́ àwọn ibi ahoro Síónì—

19 Àti gbogbo àwọn ohun wọ̀nyìí kí á lè mú àwọn wòlíì ṣẹ.

20 Àti, kíyèsíi, kò sí ibòmíràn tí a yàn yàtọ̀ sí èyíinì tí èmi ti yàn; bẹ́ẹ̀ni kì yíò sí ibòmíràn tí a ó yàn yàtọ̀ sí èyíinì tí èmi ti yàn, fún iṣẹ́ ti kíkó àwọn ènìyàn mímọ́ mi jọ—

21 Títí tí ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí a kì yíò rí ààyè fún wọn mọ́; àti nígbànáà ní èmi ní àwọn ibòmíràn èyítí èmi yíò yàn fún wọn, a ó sì pè wọ́n ní àwọn èèkàn, fún àwọn aṣọ títa tàbí okun Síónì.

22 Kíyèsíi, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi, pé gbogbo awọn tí wọ́n ké pe orúkọ mi, àti tí wọ́n sìn mí ní ìbámu sí ìhìnrere àìlópin mi, yíò kórajọ pọ̀, wọn yíò sì dúró ní àwọn ibi mímọ́;

23 Wọn yío sì múrasílẹ̀ fún ìfihàn náà èyítí yíò wá, nígbàtí àṣọ ìkéle tí bíbo tẹ́mpìlì mi, nínú àgọ́ àjọ mi, èyítí ó fi ayé pamọ́, yíò di mímú kúrò, àti tí gbogbo ẹran ara yíò rí mi papọ̀.

24 Àti pé olúkúlùkù ohun ìdibàjẹ́, ti ènìyàn, tàbí ti àwọn ẹranko ìgbẹ́, tàbí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tàbí ti ẹja inú òkun, tí wọ́n ngbé ní gbogbo orí ilẹ̀ ayé, ni a ó parun;

25 Àti bákannáà pé ìpilẹsẹ̀ ohun gbogbo yíò ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́; ohun gbogbo yíò sì di titun, kí ìmọ̀ mi àti ògo ó le gbé ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

26 Àti ní ọjọ́ náà ìṣọ̀tá ti ènìyàn, àti ìṣọ̀tá ti àwọn ẹranko, bẹ́ẹ̀ni, ìṣọ̀tá ti gbogbo ẹran ara, ni yíò dáwọ́dúró ní iwájú mi.

27 Àti ní ọjọ́ náà ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni bá beerè, a ó fi fún un.

28 Àti ní ọjọ́ náà Sátánì kì yíò ní agbára láti dán ẹnikẹ́ni wò.

29 Kì yíò sì sí ìkẹ́dùn nítorípé kò sí ikú.

30 Ní ọjọ́ náà ọmọdé kan kì yíò kú títí tí òun yíò fi di arúgbó; ìgbé ayé rẹ̀ yíò sì dàbí ọjọ́ orí ti igi;

31 Àti nígbàtí òun bá sì kú òun kì yíò sùn, èyítí í ṣe lati sọ pé nínú eruku, ṣùgbọ́n a ó pa á láradà ní ìṣẹ́jú àáyá, a ó sì gbà á sókè, ìsinmi rẹ̀ yíò sì logo.

32 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ní ọjọ́ náà nígbàtí Olúwa yíò dé, òun yíò fi ohun gbogbo hàn—

33 Àwọn ohun èyítí ó ti rékọjá, àti àwọn ohun tí ó farasin èyítí ẹnikẹ́ni kò mọ̀, àwọn ohun ti ayé, nípa èyítí a fi dá a, àti ìwúlò àti òpin rẹ̀—

34 Àwọn ohun tí ó níyelórí jùlọ, àwọn ohun tí ó wà lókè, àti àwọn ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀, àwọn ohun tí ó wà ní ilẹ̀ ayé, àti ní orí ilẹ̀ ayé, àti ní ọ̀run.

35 Àti gbogbo àwọn ẹnití wọ́n ti jìyà inúnibíni nítorí orúkọ mi, àti tí wọ́n fi ara dà nínú ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pè wọ́n láti fi ayé wọn sílẹ̀ nítorí mi síbẹ̀ wọn yíò kópa nínú gbogbo ògo yìí.

36 Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù àní sí ikú; nítorí nínú ayé yìí àyọ yín kò kún, sùgbọ́n nínú mi àyọ yín kún.

37 Nítorínáà, ẹ máṣe ṣe àníyàn ti ara, tàbí ti ìyè ti ara; ṣùgbọ́n ẹ ṣe àníyàn ti ọkàn, àti fún ìyè ti ọkàn.

38 Ẹ sì wá ojú Olúwa nígbàgbogbo, pé nínú ìpamọ́ra kí ẹ̀yin ó lè ní ọkan yín ní ìní, ẹ̀yin yíò sì ní ìyè ayérayé.

39 Nígbàtí a bá pe àwọn ènìyàn sínú ìhìnrere àìlopin mi, tí wọ́n sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú májẹ̀mú àìlópin, a kà wọ́n sí bíi iyọ̀ ayé àti adùn ti àwọn ènìyàn;

40 A pè wọ́n láti jẹ́ adùn ti àwọn ènìyàn; nítorínáà, bí iyọ̀ ayé náà bá sọ adùn rẹ̀ nù, kíyèsíi, òun kò wúlò fún ohun kan láti igbà náà bíkòṣe kí á dàá nù síta fún títẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn.

41 Kíyèsíi, èyí jẹ́ ọgbọ́n nípa àwọn ọmọ Síónì, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo wọn; a rí wọn bíi arúfin, nítorínáà ó di dandan kí á bá wọn wí—

42 Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a ó gbé ga.

43 Àti nísisìyí, èmi yíò fi òwe kan hàn sí yín, kí ẹ̀yin ó lè mọ ìfẹ́ inú mi nípa ìràpadà ti Síónì.

44 Ọkùnrin ọlọ́lá kan ní ìpín ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ àsàyàn gan an; òun sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀: Ẹ lọ sí inú ọgbà ajarà mi, àní sí orí àsàyàn ìpín ilẹ̀ yìí, kí ẹ sì gbin àwọn igi ólífì méjìlá;

45 Kí ẹ sì yan àwọn olùṣọ́ yíká wọn, àti kí ẹ mọ ilé ìṣọ́ gíga kan, kí ẹnìkan ó lè rí ilẹ̀ náà yíkáà kiri, láti jẹ́ olùṣọ́ kan ní orí ilé ìṣọ́ náà, kí á má baà lè ṣẹ́ àwọn igi ólífì mi lulẹ̀ nígbàtí àwọn ọ̀tá yíò dé láti jalè àti láti kó àwọn èsò ọgbà ajarà mi fún ara wọn.

46 Nísìsìyí, àwọn ìránṣẹ́ ọkùnrin ọlọ́lá náà lọ wọ́n sì ṣe bí olúwa wọn ṣe pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì gbìn àwọn igi ólífì náà, wọ́n sì ṣe ọgbà yíká kiri, wọ́n sì fi olùṣọ́ síbẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé ìṣọ́ kan.

47 Àti nígbàtí wọ́n ṣì nfi ìpìlẹ̀ èyí náà lélẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí ní ààrin ara wọn: Njẹ́ kínni olúwa mi nílò ilé ìṣọ́ gígá yìí fún?

48 Wọ́n sì nbéèrè fún ìgbà pípẹ́, ní wíwí láàrin ara wọn: Kínni olúwa mi nílò ilé ìṣọ́ gíga yìí fún, tí ó rí i pé àkókò àlãfíà ni èyí?

49 Ṣé a kò lè fi owó yìí fún àwọn tí npa owódà? Nítorí a kò nílò àwọn nkan wọ̀nyìí.

50 Àti níwọ̀nbí èrò wọn ti yapa ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn wọ́n di onímẹ̃lẹ́ gan an, wọn kò sì fetísílẹ̀ sí àwọn àṣẹ olúwa wọn.

51 Ọ̀tá sì wá ní òru, ó sì wó ọgbà náà lulẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ ọkùnrin ọlọ́lá náà sì dìde ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n sì sá; ọ̀tá náà sì ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́, ó sì sẹ́ àwọn igi ólífì náà lùlẹ̀.

52 Nísisìyí, kíyèsíi, ọkùnrin ọlọ́lá náà, olúwa ọgbà ajarà náà, ké pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn, Èéṣe! kíni ó fa ìdí búburú nlá yìí?

53 Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ti ṣe àní bí èmi ṣe pàṣẹ fún un yín bí, àti—lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti gbin ọgbà ajarà náà, kí ẹ sì ṣe ọgbà yí káàkiri, àti kí ẹ fi aṣọ́nà sí orí àwọn ògiri ibẹ̀—kí ẹ kọ́ ilé ìṣọ́ bákannáà, àti kí ẹ fi oluṣọ́ sí orí ilé ìṣọ́ náà, kí ẹ ṣọ́nà fún ọgbà ajarà mí, àti kí ẹ́ má sì ṣe sùnlọ, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ọ̀tá yíò wá bá yín?

54 Àti kíyèsíi, olùṣọ́ náà ní orí ilé ìṣọ ìbá ti rí ọ̀tá náà nígbàtí òun ṣì wà ní ibití ó jìnnà; àti nígbànáà ẹ̀yin ìbá le ti múra sílẹ̀ kí ẹ sì lé ọ̀tá kúrò ní wíwó ọgba ìbẹ̀ lúlẹ̀, àti pé ẹ̀yin ìbá lè gbà ọgbà ajarà mi là kúrò lọ́wọ́ apanirun náà.

55 Olúwa ọgbà ajarà náà sì sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀: Lọ, sì kó gbogbo àwọn tí ó kù nínú àwọn ìránṣẹ́ mi jọ, kí o sì mú gbogbo agbára tí ilé mi, èyítí í ṣe àwọn jagunjagun mi, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi, àti àwọn tí wọ́n kò dàgbà púpọ̀ bákannáà lààrin àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn tí wọ́n jẹ́ agbára ti ilé mi, yàtọ̀ sí àwọn wọnnì tí èmi ti yàn láti dúró pẹ́;

56 Kí ẹ sì lọ lójúkannáà sí ilẹ̀ ti ọgbà ajarà mi, kí ẹ sì ra ọgbà ajarà mi padà; nítorí tèmi ni í ṣe; èmi ti ràá pẹ̀lú owó.

57 Nítorínáà, ẹ lọ lójúkannáà sí ilẹ̀ mi; ẹ wó àwọn ògiri ti àwọn ọ̀tá mi; ẹ bi ilé ìṣọ wọn lulẹ̀, kí ẹ sì fọ́n àwọn olùṣọ́ wọn ká.

58 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá kórajọ dojúkọ yín, ẹ gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi, pé nígbà díẹ̀ èmi yíò lè wá pẹ̀lú ìyókù ilé mi èmi yíò sì gba ilẹ̀ mi.

59 Ìránṣẹ́ náà sì wí fún olúwa rẹ̀: Nígbàwo ni ìwọ̀nyìí yíò jẹ́?

60 Òun sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀: Nígbàtí èmi bá fẹ́; lọ lójúkannáà, kí o sì ṣe ohun gbogbo ohunkóhun ti èmi ti pàṣẹ fún ọ;

61 Èyí yíò sì jẹ́ èdídí àti ìbùkún mi ní orí rẹ—olõtọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú láàrin inú ilé mi, alákoso kan ninú ìjọba mi.

62 Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì lọ lójúkannáà, ó sì ṣe ohun gbogbo ohunkóhun tí olúwa rẹ̀ ti pàṣẹ fún un; àti lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ohun gbogbo wá sí ìmúṣẹ.

63 Lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi yíò fi ọgbọ́n inú mi hàn sí yín nípa gbogbo àwọn ìjọ, níwọ̀nbí wọ́n bá fẹ́ lati jẹ́kí á darí wọn ní ọnà tí ó tọ́ àti tí ó yẹ fún ìgbàlà wọn—

64 Pé kí iṣẹ́ kíkójọpọ̀ ti àwọn ènìyàn mímọ́ mi lè tẹ̀síwájú, kí èmi ó lè mú wọn dàgbà sókè sí orúkọ mi ní orí àwọn ibi mímọ́; nítorí àkókò ìkórè ti dé, ọ̀rọ̀ mi sì gbọdọ̀ wá sí ìmúṣẹ.

65 Nítorínáà, èmi gbọ́dọ̀ kó àwọn ènìyàn mi jọpọ̀, gẹ́gẹ́bí òwe ti àlìkámà àti èpò, kí á lè dáàbò bo àlìkámà nínú àwọn àká láti gba ìyè ayérayé, àti kí a lè dé wọn ládé pẹ̀lú ògo Sẹ̀lẹ́stíà, nígbàtí èmi yíò dé nínú ìjọba Bàbá mi láti san fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀ yíò ṣe rí;

66 Nígbàtí a ó di èpò ní àwọn ìtí, àti pé ìdì wọn ni a ó sì mú kí ó le, kí á lè jó wọn pẹ̀lú iná àjóòkú.

67 Nítorínáà, òfin kan ni mo fi fún gbogbo àwọn ìjọ, kí wọ́n ó lè tẹ̀síwájú láti kó ara jọ pọ̀ si àwọn ààyè èyítí èmi ti yàn.

68 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí mo ti wí fún yín nínú òfin ti ìṣaájú, ẹ máṣe jẹ́ kí kíkó arajọ yín ó jẹ́ ní ìkánjú, tàbí nípa ìyára; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo jẹ́ pípèsè níwájú yín.

69 Àti kí ohun gbogbo ó lè jẹ́ pípèsè níwájú yín, ẹ kíyèsí òfin náà èyítí mo ti fí fún yín nípa àwọn ohun wọ̀nyìí—

70 Èyítí ó wí pé, tàbí tí ó kọ́ni, láti ra gbogbo àwọn ilẹ̀ pẹ̀lú owó, èyítí a lè fi owó rà, ní agbègbè yíká kiri ilẹ̀ náà èyítí mo ti yàn láti jẹ́ ilẹ̀ Síónì, fún bíbẹ̀rẹ̀ ti kíkó àwọn ènìyàn mímọ́ mi jọ;

71 Gbogbo ilẹ̀ náà èyítí a lè rà ní ìpín Jackson, àti ní àwọn ìpín ní àyíká kiri, kí ẹ sì fi ìyókù sílẹ̀ ní ọwọ́ mi.

72 Nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ìjọ ó kó àwọn owó wọn jọ papọ̀; ẹ jẹ́ kí àwọn ohun wọ̀nyìí jẹ́ ṣíṣe ní àkókò wọn, ṣùgbọ́n kìí ṣe ní ìkánjú; ẹ sì kíyèsí láti jẹ́kí ohun gbogbo wà ní pípèsè níwájú yín.

73 Ẹ sì jẹ́kí a yan àwọn ènìyàn ọlọ́lá, àni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, kí ẹ sì rán wọn láti ra àwọn ilẹ̀ wọ̀nyìí.

74 Àti àwọn ìjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè ìlà oòrùn, nígbàtí a bá kọ́ wọn tán, bí wọn yíò bá fetísílẹ̀ sí ìmọràn yìí wọ́n lè ra àwọn ilẹ̀ kí wọ́n ó sì péjọpọ̀ ní orí wọn; àti ní ọ̀nà yìí wọ́n yíó le gbé Síónì kalẹ̀.

75 Ànító wà tẹ́lẹ̀, àní nísisìyí nínú ilé ìṣúra, bẹ́ẹ̀ni, àní ọ̀pọ̀, láti ra Síónì padà, àti láti ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ibi ahoro rẹ̀, láì tún ní jẹ́ bíbì lulẹ̀ mọ́, bí àwọn ìjọ̀, tí wọ́n npe ara wọn mọ́ orúkọ mi, bá ní ìfẹ́ láti fetísílẹ̀ sí ohùn mi.

76 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, àwọn wọnnì tí a ti fọ́nká lati ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí wọn ó tẹ̀síwájú nínú àwíìdákẹ́ fún àtúnṣe, àti ìràpadà, lati ọwọ́ àwọn tí a fi sípò bíi alákóso tí wọ́n sì wà ní ipò àṣẹ ní orí yín—

77 Gẹ́gẹ́bí àwọn òfin àti ìwé òfin ti àwọn ènìyàn, èyítí mo ti gbà láàyè láti jẹ́ gbígbé kalẹ̀, tí wọ́n sì níláti mójútó fún àwọn ẹ̀tọ́ àti ààbò ti gbogbo ẹran ara, gẹ́gẹ́bí àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ òdodo àti mímọ́;

78 Pé kí olúkúlùkù ènìyàn ó le hùwà nínú ẹ̀kọ́ àti ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó jẹ mọ́ ọjọ́ iwájú, ní ìbámu sí ìwà agbára láti yàn èyítí mo ti fi fún un, pé kí olúkúlùkù ènìyàn ó lè dáhùn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ ní ọjọ́ ti ìdájọ́.

79 Nítorínáà, kò tọ̀nà pé kí ẹnikẹ́ni ó nílati wà nínú ìgbèkùn ẹnikan sí òmíràn.

80 Àti fún ìdí yìí ni èmi ṣe àgbékalẹ̀ Ìwé òfin ti ilẹ̀ yìí, láti ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹnití èmi ti gbé dìde nítorí ìdí yìí gan an, àti tí mo sì ra ilẹ̀ náà padà nípa títa ẹ̀jẹ sílẹ̀.

81 Nísisìyí, kíni èmi yíò ha fi àwọn ọmọ Síónì wé? Èmi yíò fi wọ́n wé òwe ti obìnrin náà àti onídajọ́ aláìṣòótọ́ nnì, nítorí àwọn ènìyàn yẹ láti máa gbàdúrà nígbàgbogbo àti láì ṣe àárẹ̀, èyítí ó wípé—

82 Onídájọ́ kan wà ní ìlú nlá kan tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tàbí náání ènìyàn.

83 Obìnrin opó kan sì wà ní ìlú nlá náà, òun sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wípé: Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi.

84 Òun kò sì ṣe é fún àkókò díẹ̀ kan, ṣùgbọ́n lẹ́hìn ìgbànáà òun sọ nínú ara rẹ̀: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tàbí náání ènìyàn, síbẹ̀ nítorí tí opó yìí nyọ mí lẹ́nu èmi yíò gbẹ̀san rẹ̀, bíbẹ́ẹ̀kọ́ nípa wíwá rẹ̀ nígbàkũgbà òun yíò dámi lágara.

85 Báyìí ni èmi yíò fi àwọn ọmọ Síónì wé.

86 Ẹ jẹ́kí wọn ó wí àwíìdákẹ́ ni ẹsẹ̀ onídajọ́ náà;

87 Àti bí òun kò bá sì kíyèsí wọn, ẹ jẹ́ kí wọn ó wí àwíìdákẹ́ ní ẹsẹ̀ gómìnà ilú náà;

88 Bí gómìnà ilú náà kò bá kíyèsí wọn, ẹ jẹ́ kí wọ́n wí àwíìdákẹ́ ní ẹsẹ̀ ààrẹ;

89 Àti bí ààrẹ náà kò bá kíyèsí wọn, nígbànáà ni Olúwa yíò dìde yíò sì jade wá láti ibi ìsápamọ́ rẹ̀, àti nínú ìbínú rẹ̀ yío yọ orílẹ̀-èdè náà lẹ́nu;

90 Àti nínú gbígbóná àìdunnú rẹ̀, àti nínú ìbínù rẹ̀ tí ó rorò, ní àkókò rẹ̀, yíò ké àwọn ìríjú búburú, aláìṣòdodo, àti àwọn aláìṣòótọ́ kúrò, yíò sì yàn ìpín tiwọn fún wọn láàrin àwọn àgàbàgebè, àti àwọn aláìgbàgbọ́;

91 Àní nínú òkùnkùn lóde, níbití ẹkún, àti ìpohunréré ẹkún, àti ìpahínkeke wà.

92 Ẹ gbàdúrà, nítorínáà, pé kí á lè ṣí wọn létí sí àwọn igbe yín, kí èmi ó lè ṣàánú fún wọn, kí àwọn nkan wọ̀nyìí ó má baà lè wá sí orí wọn.

93 Ohun tí mo ti wí fún yín gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí gbogbo ènìyàn ó lè wà láìní àwáwí;

94 Kí àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn àti àwọn alákoso ó lè gbọ́ àti mọ̀ èyíinì tí wọn kò tíì gbà lérò rí láè;

95 Kí èmi ó lè tẹ̀síwájú láti mú kí ìṣe mi kí ó ṣẹ, ìṣe àrà mi, àti kí èmi le ṣe iṣẹ́ mi, iṣẹ́ àrà mi, kí àwọn ènìyàn ó lè mọ ìyàtọ̀ lààrin olódodo àti ènìyàn búburú, ni Ọlọ́run yín wí.

96 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, ó lòdì sí òfin mi àti ìfẹ́ inú mi pé kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert ó ta ilé ìṣúra mi, èyítí mo ti yàn fún àwọn ènìyàn mi, sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi.

97 Ẹ máṣe jẹ́kí èyíinì tí èmi ti yàn ó di aláìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ọ̀tá mi, nípa ìfọwọ́sí ti àwọn wọnnì tí wọ́n npe ara wọn mọ́ orúkọ mi;

98 Nítorí èyí jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dunni àti tí ó bani nínújẹ́ jọjọ sí mi, àti sí àwọn ènìyàn mi, ní ìyọrísí àwọn ohun wọnnì èyítí mo ti pàṣẹ àti èyítí yíò já lu àwọn orílẹ̀-èdè láìpẹ́.

99 Nítorínáà, ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí àwọn ènìyàn mi ó béèrè fún, kí wọ́n ó sì di ẹ̀tọ́ wọn mú ní orí èyíinì tí mo ti yàn fún wọn, bíó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì yíò gbà wọ́n láàyè láti gbé ní orí rẹ̀.

100 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi kò wípé wọn kì yíò gbé ní orí rẹ̀; nítorí níwọ̀nbí wọ́n bá mú èso jade àti àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìjọba mi wọn yíò gbé ní orí rẹ̀.

101 Wọn yíò kọ́, ẹlòmíràn kì yíò sì jogún rẹ̀; wọn yíò gbin àwọn ọgbà ajarà, wọn yíò sì jẹ èso inú rẹ̀. Àni bẹ́ẹ̀ni. Amín.