Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 134


Ìpín 134

Ìkéde kan ti ìgbàgbọ́ nípa àwọn ìjọba àti àwọn òfin ní gbogbogbò, tí a gbà wọlé nípasẹ̀ ìbò ìfohùnṣọ̀kan ní àpéjọ gbogbogbò kan ti Ìjọ tí a ṣe ní Kirtland, Ohio, 17 Oṣù Kẹjọ 1835. Ọ̀pọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ kójọ papọ̀ láti jíròrò ní orí àbá àwọn ohun tí ó wà nínú àtẹ̀jáde ìkínní ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú. Ní àkókò náà, ìkéde yìí ni a fún ní àwọn ọ̀rọ̀ ìsaájú wọ̀nyìí: “Pé ìgbàgbọ́ wa nípa àwọn ìjọba ayé àti àwọn òfin ni gbogbogbò má le jẹ́ títúmọ̀ sí òdì tàbí gbígbọ́ sí òdì, a ti ròó pé ó tọ́ láti gbée kalẹ̀, ní ìparí ìwé yìí, èrò ọkàn tiwa nípa èyí kannáà.”

1–4, Àwọn ìjọba níláti dáàbò bo òmìnira ti ẹ̀rí ọkàn àti ìjọ́sìn; 5–8, Gbogbo ènìyàn níláti di àwọn ìjọba wọn mú kí wọn ó sì tẹríba àti bọ̀wọ̀ fún òfin; 9–10, Àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn kò níláti lo àwọn agbára òfin ìlú; 11–12, Àwọn ènìyàn ní ìdáláre ní dídáàbò ara wọn àti àwọn ohun ìní wọn.

1 A gbàgbọ́ pé àwọn ìjọba jẹ́ àgbékalẹ̀ Ọlọ́run fún ànfàní ènìyàn; àti pé òun nmú kí àwọn ènìyàn o dáhùn fún àwọn ìṣe wọn tí ó jẹmọ́ wọn, méjèèjì ní ṣiṣe àwọn òfin àti ṣíṣe àmójútó wọn, fún ire àti ààbò gbogbo ìlú.

2 A gbàgbọ́ pé kò sí ìjọba tí ó lè wà ní àlãfíà, bíkòṣe pé irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ jẹ́ ṣíṣe tí a sì dì wọ́n mú ní àìrékọjá bí yío ṣe jẹ́ áàbò sí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ní òmìnira ẹ̀rí ọkàn, ẹ̀tọ́ àti ṣiṣe àkóso ohun ìní, àti dídáàbò bo ẹ̀mí.

3 A gbàgbọ́ pé gbogbo àwọn ìjọba ní ó ṣe dandan fún láti nílò àwọn òṣiṣẹ́ ọba àti àwọn onídajọ́ lati ṣe ìfimúlẹ̀ àwọn òfin ti ìjọba kannáà; àti pé irú àwọn wọ̀nyìí tí yío ṣe àmójútó òfin ní ìṣòtítọ́ àti òdodo ni yíò jẹ́ wíwárí àti dídìmú nípasẹ̀ ohùn àwọn ènìyàn bí ó bá jẹ́ ìlú olómìnira, tàbí ìfẹ́ inú ti ọba.

4 A gbàgbọ́ pé ẹ̀sìn jẹ́ àgbékalẹ̀ Ọlọ́run; àti pé àwọn ènìyàn nílati jíyìn fún un, àti sí òun nìkanṣoṣo, fún ṣiṣe èyí, bíkòṣe pé àwọn èrò inú wọn nípa ẹ̀sin wọn bá ta wọ́n jí láti tẹ àwọn ẹ̀tọ́ àti àwọn òmìnira ti àwọn ẹlòmíràn mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n a kò gbàgbọ́ pé òfin ẹ̀dá ènìyàn ní ẹ̀tọ́ láti dásí dídámọ̀ràn àwọn àkóso ìjọ́sìn láti dè ẹ̀rí-ọkàn àwọn ènìyàn, tàbí sọ àwọn ọ̀nà fún àwọn ìjọ́sìn ìta gbangba tàbí ti ìdákọ́nkọ́; pé onídájọ́ ìjọba nílati dẹ́kun ìwà ọ̀daràn, ṣùgbọ́n kì yío darí ẹ̀rí ọkàn láé; ó níláti fì ìyà jẹ ẹ̀bi, ṣùgbọ́n kì yío tẹ òmìnira ọkàn mọ́lẹ̀ láé.

5 A gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó ní ojúṣe láti fi ara mọ́ ati lati ṣe ti onírúurú àwọn ìjọba nínú èyítí wọ́n ngbé, níwọ̀n bí wọ́n bá ní ìdáàbò bò nínú àwọn ẹ̀tọ́ abínibí àti àìlèyípadà wọn nípasẹ̀ òfin ti irú àwọn ìjọba bẹ́ẹ̀; àti pé ìṣọ̀tẹ̀ àti tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun kò yẹ fún olúkúlùkù olùgbé inú ìlú tí a dáàbò bò bẹ́ẹ̀, yío sì jẹ́ jíjẹ níyà bí ó ti yẹ; àti pé gbogbo àwọn ìjọba ni ó ní ẹ̀tọ́ láti fì ìdí irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ bí ó ṣe bá èrò ọkàn tiwọn mu pé ó dára jùlọ láti dáàbò bo ànfàní gbogbo ará ilú; bákanáà, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ṣíṣe òmìnira ti ẹ̀rí ọkàn ní mímọ́.

6 A gbàgbọ́ pé a níláti bọ̀wọ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn ní àyè rẹ̀, àwọn alákoso àti onídajọ́ bẹ́ẹ̀, tí a fí sí ipò fún ìdáàbò bò àwọn aláìṣẹ̀ àti ìjìyà àwọn tí wọ́n jẹ̀bi; àti pé sí àwọn òfin gbogbo ènìyàn jẹ gbèsè ìtẹríba àti títẹ̀lé, nítorípé láìsí wọn, àlãfíà àti ìrẹ́pọ̀ yío jẹ́ rírọ́pò pẹ̀lú ìrúfin àti ẹ̀rù; àwọn òfin ti ènìyàn ni ó jẹ́ gbígbékalẹ̀ fún ìdí pàtó ti ṣíṣe àkóso àwọn ànfàní wa bí ẹni kọ̀ọ̀kan àti àwọn orílẹ̀-èdè, láàrin ènìyàn sí ènìyàn; àti àwọn òfin ti Ọlọ́run ni a fifúnni láti ọ̀run, tí ó ndámọ̀ràn àwọn àkóso ní orí àwọn àníyàn ti ẹ̀mí, fún ìgbàgbọ́ àti ìjọ́sìn, méjèjì tí ó níláti jẹ́ dídáhùn fún láti ọ̀dọ̀ ènìyàn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

7 A gbàgbọ́ pé àwọn alákoso, àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìjọba ní ẹ̀tọ́, wọ́n sì ní ojúṣe láti fi àwọn òfin lélẹ̀ fún ìdáàbò bo gbogbo àwọn ará ìlú ní fífi òmìnira lo ìgbàgbọ́ ti ẹ̀sìn wọn; ṣùgbọ́n a kò gbàgbọ́ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ nínú òdodo láti gba ànfàní yìí kúrò lọ́wọ́ àwọn ará ilú, tàbí dí wọn lọ́wọ́ nínú àwọn èrò ọkan wọn, níwọ̀n ìgbà tí a bá fi ìbuyìfún àti ọ̀wọ̀ fún àwọn òfin náà àti tí irúfẹ́ àwọn èrò ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ kò fi ara mọ́ ìṣọ̀tẹ̀ tàbí ìdìmọ̀ ibi.

8 A gbàgbọ́ pé rírú òfin gbọ́dọ̀ jẹ́ jíjẹ níyà ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀ràn náà; pé ìpànìyàn, ọ̀tẹ̀, olè jíjà, jíjí nkan onínkan, àti dída àlãfíà gbogbo ìlú rú, ní gbogbo ọ̀nà, gbọ́dọ̀ jẹ́ jíjẹ níyà ní ìbámu sí bíburú ìrúfin wọn àti bí ipá wọn sí ìwà ibi láàrin àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àwọn òfin ti ìjọba náà nínú èyítí a ti dá ọ̀ràn yìí; àti pé fún àlãfíà àti ìrọra ìlú náà, gbogbo ènìyàn níláti bọ́ síwájú kí wọn ó sì lo agbára wọn ní mímú àwọn ọ̀daràn sí àwọn òfin dáradára wá sí ìjìyà.

9 A kò gbàgbọ́ pé ó tọ́ láti da ipá ti ẹ̀sìn mọ́ ti ìjọba aláṣẹ, níbití a ó ti ṣe ìtọ́jú ẹgbẹ́ ẹ̀sin kan tí a ó sì dá òmíràn lẹ́kun nínú àwọn ànfàní rẹ̀ ní ti ẹ̀mí, àti tí àwọn ẹ̀tọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀, bíi àwọn olùgbé ìlú, yí jẹ́ fífi dùn wọ́n.

10 A gbàgbọ́ pé gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn ní ẹ̀tọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn fún ìwà àìbófinmu tí wọ́n bá hù, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ètò àkóso àti àwọn ìlànà ti irú àwọn ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀; bí ó bá jẹ́ pé irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ wà fún ìdàpọ̀ àti dídúró déédé; ṣùgbọ́n a kò gbàgbọ́ pé èyíkéyìí ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn ní àṣẹ láti mú ènìyàn wá sí ìjẹ́jọ́ ní orí ẹ̀tọ́ ti ohun ìní tàbí ìwàláàyè, láti gba àwọn ohun ayé yìí lọ́wọ́ wọn, tàbí láti fi wọ́n sí inú ìdẹ́rùbà ti bóyá ìwàláàyè tàbí ti ẹ̀yà ara, tàbí láti ṣe ìpalára jíjẹ níyà àfojúrí sí wọn. Wọ́n kàn le yọ wọ́n kúrò ní ìjọ wọn, kí wọn ó sì gba ìbákẹ́gbẹ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn.

11 A gbàgbọ́ pé ènìyàn nílati pè sí òfin ilú fún àtúnṣe gbogbo àwọn àìṣododo àti àwọn ẹ̀hónú, níbití ìpalára jíjẹ níyà ilòkulò ẹnikan bá wà tàbí tí ẹ̀tọ́ ohun ìní tàbí orúkọ ẹni bá jẹ́ títẹ̀ mọ́lẹ̀, níbití irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ bá wà láti dáàbò bo èyí kannáà; ṣugbọ́n a gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn ní ìdáláre ní dídáàbò bo ara wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àti ohun ìní, àti ìjọbá náà, kúrò nínú àwọn ìkọlù àìbófin mu àti àwọn ìkọjá ààyè ti gbogbo ènìyàn ní àkókò pàjáwìrì, níbití a kò ní le tètè pè fún àwọn òfin, àti kí ìrànlọ́wọ́ ṣeéṣe.

12 A gbàgbọ́ pé ó tọ́ láti wàásù ìhìnrere sí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé, kí a sì kìlọ̀ fún àwọn olódodo láti gba àra wọn kúrò nínú ìdíbàjẹ́ ayé náà; ṣùgbọ́n a kò gbàgbọ́ pé ó tọ́ láti dá sí ọ̀rọ̀ àwọn òndè-ìránṣẹ, bóyá kí a wàásù ìhìnrere sí, tàbí rì wọ́n bọmi lòdì sí ìfẹ́ inú àti ìfẹ́ ti àwọn olúwa wọn, tàbí lati yọjúràn sí tàbí lo ipá le wọn ní orí ní kékeré jùlọ láti mú wọn di aláìnítẹlọ́rùn pẹ̀lú àwọn ipò tí wọ́n wà ní ayé yìí, nípa bẹ́ẹ̀ fi ayé àwọn ènìyàn náà sínú ewu; irú dídásí ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a gbàgbọ́ pé ó jẹ́ àìbófinmu àti àìṣòótọ́, tí ó sì léwu sí àlàáfìà olúkúlùkù ìjọba tí ó fi àyè sílẹ̀ gba àwọn ọ̀mọ ènìyàn l’ati jẹ́ mímú lẹ́rú.