Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 4


Ìpín 4

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí bàbá rẹ̀, Joseph Smith Àgbà, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Kejì 1829.

1–4, Síṣe iṣẹ́-ìsìn akíkanjú kó àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yọ; 5–6, Àwọn ìwà bĩ ti Ọlọ́run mú wọn yẹ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́; 7, Àwọn ohun ti Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ lílépa.

1 Nísisìyí kíyèsíi, isẹ́ ìyanu kan ti fẹ́ jáde wá láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.

2 Nítorínáà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run, ẹ ríi wípé ẹ sìn-ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ipá, iyè àti okun, kí ẹ̀yin baà lè dúró láì ní ìdálẹ́bi níwájú Ọlọ́run ní ọjọ́ ìkẹhìn.

3 Nítorínáà, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run, a pè yìn sí iṣẹ́ náà;

4 Nítorí, kíyèsíi, oko ti funfun nísisìyí fún ìkórè; sì wòó, ẹnití ó bá fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú ipá rẹ̀, òun náà ni ó kórè sínú àká kí òun má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó mú ìgbàlà wá fún ẹ̀mí rẹ̀;

5 Àti pé ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti ìfẹ́, pẹ̀lú fífi ojú sí ògo Ọlọ́run nìkan, mú un yẹ fún iṣẹ́ náà.

6 Ẹ rántí ìgbàgbọ́, ìwà rere, ìmọ̀, àìrékọjá, sùúrù, inú rere sí ọmọnìkejì, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, aápọn.

7 Ẹ béèrè, ẹ̀yin yíò sì rí gbà; ẹ kan ilẹ̀kùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Àmín.