Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 23


Ìpín 23

Onírúurú àwọn ìfihàn márũn kan tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Manchester, New York, Oṣù Kẹrin 1830, sí Oliver Cowdery, Hyrum Smith, Samuel H. Smith, Joseph Smith Àgbà, àti Joseph Knight Àgbà. Bíi àbájáde ìbéèrè àtọkànwá tí àwọn ènìyàn marũn tí a dárúkọ láti mọ àwọn ojúṣe wọn gẹ́gẹ́bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, Wòlíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa òun sì gba ìfihàn kan fún olukúlùkù ènìyàn.

1–7, Àwọn ọmọ ẹ̀hìn ti ìgbà àkọ́kọ́ wọ̀nyí ni a pè láti wàásù, gbàni níyànjú, àti lati mú Ìjọ lọ́kàn le.

1 Kíyèsíi, èmi nbá ọ sọ̀rọ̀, Oliver, àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀. Kíyèsíi, alábùkúnfún ni ìwọ, ìwọ kò sì sí ní abẹ́ ìdálẹ́bi kankan. Ṣùgbọ́n sọ́ra fún ìgbéraga, kí ìwọ má baà bọ́ sí inú ìdánwò.

2 Sọ ìpè rẹ di mímọ̀ fún ìjọ, àti bákannáà níwájú gbogbo ayé, a ó sì ṣí ọkàn rẹ láti wàásù òtítọ́ láti ìsisìyí lọ àti títí láéláé. Amin.

3 Kíyèsíi, èmi nbá ọ sọ̀rọ̀, Hyrum, àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀; nítorí ìwọ náà kò sí ní abẹ́ ìdálẹ́bi kankan, à sì ti ṣí ọkàn rẹ, àti pé okùn ahọ́n rẹ ti tú; àti ìpè rẹ ni sísọ ọ̀rọ̀ ìyànjú, àti láti máa mú ìjọ ní ọ̀kàn le ní gbogbo ìgbà. Nítorínáà ojúṣe rẹ jẹ́ sí ìjọ títí láéláé, àti èyí nítorí ẹbí rẹ. Amin.

4 Kíyèsíi, èmi nbá ọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀, Samuel; nítorí ìwọ náà kò sí ní abẹ́ ìdálẹ́bi kankan, àti ìpè rẹ ni sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú, àti lati máa mú ìjọ̀ ní ọkàn le; àti pé a kò tíì pe ìwọ láti wàásù ní iwájú àwọn aráyé. Amin.

5 Kíyèsíi, èmi nbá ọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀, Joseph; nítorí ìwọ náà kò sí ní abẹ́ ìdálẹ́bi kankan, àti ìpe rẹ ni sísọ ọ̀rọ̀ ìyànjú bákannáà, àti lati máa mú ìjọ ní ọkàn le; èyí sì ni ojúṣe rẹ láti ìsisìyìí lọ àti títí láéláé. Amin.

6 Kíyèsíi, èmi fi hàn fún ọ, Joseph Knight, nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé ìwọ̀ gbọdọ̀ gbé àgbèlébú rẹ, nínú èyítí ìwọ gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sókè kíkán ní ìwáju gbogbo ayé àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kọ̀rọ̀, àti nínú ẹbí rẹ, àti lààrin àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti níbi gbogbo.

7 Àti, kíyèsíi, ojúṣe rẹ ni láti parapọ̀ pẹ̀lú ìjọ òtítọ́, kí o sì fi èdè rẹ fún ọ̀rọ̀ ìyànjú láì dúró, kí ìwọ lè gba èrè òṣìṣẹ́. Amin.