Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 53


Ìpín 53

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Algernon Sidney Gilbert, ní Kirtland, Ohio, 8 Oṣù Kẹfà 1831. Ní ìdáhùn sí ìbéèrè Sidney Gilbert, Wòlíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa iṣẹ́ àti ìyànsípò arákùnrin Gilbert nínú ìjọ.

1–3, Ìpè àti ìyànsípò Sidney Gilbert nínú ìjọ ni láti yàn án bíi alàgbà; 4–7, Òun ó sì tún ṣiṣẹ́ sìn bíi aṣojú fún bíṣọ́pù.

1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert, pé mo ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ; àti pé ìwọ ti ké pè mí pé kí a lè fi nkan náà hàn fún ọ, lati ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ, nípa ìpè àti yíyàn rẹ nínú ìjọ, èyí tí èmi, Olúwa, ti gbé dìde ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí.

2 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, tí a kàn mọ́ àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, fún ọ ní òfin kan pé kí ìwọ ó kọ ayé sílẹ̀.

3 Gba ìfinijoyè tèmi sí orí rẹ, àní ti ipò alàgbà, láti wàásù ìgbàgbọ́ àti ironúpìwàdà àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi, àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ nípa ìgbọ́wọ́ léni.

4 Àti bákannáà lati jẹ́ aṣojú fún ìjọ yìí ní ibi náà tí a ó yàn lati ọwọ́ bíṣọpù, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí a ó fi fúnni níkẹhìn.

5 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ yíò rin ìrìnàjò rẹ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon.

6 Kíyèsíi, ìwọ̀nyí ni àkọ́kọ́ àwọn ìlànáà tí ìwọ yíò gbà; ìyókù ni a ó sì sọ di mímọ̀ ní ọjọ́ iwájú, gẹ́gẹ́bí làálàá rẹ nínú ọgbà ajarà mi.

7 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi fẹ kí ìwọ ó kọ́ ẹ̀kọ́ pé ẹni náà nìkan ni a ó gbàla tí ó fi orí tìí dé òpin. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.