Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 7


Ìpín 7

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery, ni Harmony, Pennsylvania, oṣù kẹrin ọdún 1829, nígbàtí wọn bèerè nípasẹ̀ Urímù àti Tummimù bóyá Johannu, àyànfẹ́ ọmọ ẹhìn, sì wà nínú ẹran ara tàbí o ti kú. Ìfihàn náà jẹ́ ìyípadà èdè ti irú àkọsílẹ̀ èyí tí Johannu ṣe sí orí awọ-ẹranko tí ó sì fi pamọ́ fúnra rẹ̀.

1–3, Jòhánnù àyànfẹ́ yíò wà láàyè títí tí Olúwa yíò fi dé; 4–8, Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù di àwọn kọ́kọ́rọ́ ìhìnrere mú.

1 Olúwa sì wí fún mi pé: Jòhánù, àyànfẹ́ mi, kín ni ìwọ nfẹ́? Nítorí bí ìwọ bá béèrè ohun tí o fẹ́, èmi yíò fií fún ọ.

2 Èmi sì wí fún un pé: Olúwa, fi agbára fún mi ní orí ikú, kí èmi lè wà láàyè kí èmi sì mú awọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.

3 Olúwa sì wí fún mi pé: Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, nítorítí ìwọ béèrè èyí, ìwọ yíò dúró títí èmi yíò fi dé nínú ògo mi, ìwọ yíò sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn.

4 Àti nítorí ìdí èyí Olúwa sọ fún Pétérù: Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi yíò fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Nítorí ó fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi pé kí òun lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n ìwọ nfẹ́ kí o lè yára wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi.

5 Èmi sọ fún ọ, Pétérù, èyí jẹ́ ìfẹ́-inú rere; ṣùgbọ́n àyànfẹ́ mi nfẹ́ pé kí òun lè ṣe púpọ̀ síi, tàbí iṣẹ́ tí ó tóbi síbẹ̀ lààrin àwọn ènìyàn ju èyí tí ó ti ṣe ṣíwájú.

6 Bẹ́ẹ̀ni, òun ti dáwọ́lé iṣẹ́ títóbi kan; nítorínáà èmi yíò ṣe òun bíi ọ̀wọ́ inà àti ángẹ́lì tí ó njíṣẹ́ ìrànṣẹ́; òun yíò ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn tí wọn yíò di ajogún ìgbàlà tí wọn ngbé ní ilé ayé.

7 Àti pé èmi yíò jẹ́ kí ìwọ ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ fún òun àti fún arákùnrin rẹ Jákọ́bù; àti ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ta ni èmi yíò fi agbára yìí àti àwọn kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún títí èmi yíò fi dé.

8 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin méjèèjì yíò rí gbà gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú yín, nítorí ẹ ní ayọ̀ nínú ohun tí ẹ ti fẹ́.