Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 96


Ìpín 96

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, èyítí ó nṣe àfihàn ètò ìlú nlá tàbí èekàn Síónì ní Kirtland, Ohio, 4 Oṣù Kẹfà 1833, bíi àpẹrẹ sí àwọn Ẹni Mímọ́ ní Kirtland. Àkókò náà jẹ́ ti ìpàdé àpapọ̀ àwọn àlùfáà gíga, ati pé olórí àkòrí ti wọ́n gbéyẹ̀wò ni ọ̀rọ̀ pípín àwọn ilẹ̀ kan, tí a mọ̀ sí oko French, tí ó jẹ́ ìní Ìjọ ní ẹ̀bá Kirtland. Níwọ̀n ìgbàtí ìpádé àpapọ̀ náà kò le fi ẹnu kò ní orí ẹnití yíò ṣe àmójútó oko náà, gbogbo ènìyàn fi ẹnu kò láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ náà.

1, Èèkàn Kirtland ti Síónì ni a ó sọ di alágbára; 2–5, Bíṣọ́ọ̀pù yíò pín àwọn ogún fún àwọn Ẹni Mímọ́; 6–9, John Johnson yíó di ọmọ ẹgbẹ́ èto ìsọ̀kan.

1 Kíyèsíi, mo wí fún yín, ọgbọ́n nìyí, nípa èyítí ẹ̀yin lè mọ bí ẹ ó ti ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó tọ́ ní ojú mi pé kí a mú èekàn yìí tí èmi ti gbé kalẹ̀ fún okun Síónì di alágbára.

2 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney ó máa ṣe ìtọ́jú ti ààyè náà èyítí a ti dárúkọ lààrin yín, ní orí èyítí èmi gbèrò láti kọ́ ilé mímọ́ mi.

3 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí wọ́n ó pín in sí àwọn ìpín, gẹ́gẹ́bí ọgbọ́n, fún ànfàní àwọn wọnnì tí wọn nwá àwọn ogún ìní, bí a ó ṣe pinnu rẹ̀ nínú ìgbìmọ̀ lààrin yín.

4 Nítorínáà, ẹ fi ìkíyèsára rí sí ọ̀rọ̀ yìí, àti ìpín èyíinì tí ó ṣe dandan fún ànfàní ètò ìṣọ̀kan mi, fún ìdí ti mímú ọ̀rọ̀ mi jade wá sí àwọn ọmọ ènìyàn.

5 Nítorí kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èyí jẹ́ títọ́ julọ ní ojú mi, pé kí ọ̀rọ̀ mi ó lè jade lọ sí ọ̀dọ àwọn ọmọ ènìyàn, fún èrò láti tẹrí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn ba fún rere yín. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ó jẹ́ ọgbọ́n ó sì tọ́ ní ojú mi, pé kí ìránṣẹ́ mi John Johnson, ẹbọ-ọrẹ ẹnití èmi ti tẹ́wọ́gbà, àti àwọn àdúrà ẹnití èmi ti gbọ́, sí ẹnití èmi fún ní ìlérí kan ti ìyè ayérayé níwọ̀nbí òun bá pa àwọn òfin mi mọ́ láti ìsisìnyí lọ—

7 Nítorí òun jẹ́ àtẹ̀lé ìran Jósẹ́fù àti alábàápín nínú àwọn ìbùkún ìlérí tí a ṣe fún àwọn bàbá rẹ̀—

8 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ó tọ́ ní ojú mi pé kí òun di ọmọ ètò ìṣọ̀kan náà, kí òun ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ ní mímú ọ̀rọ̀ mi jade wá sí àwọn ọmọ ènìyàn.

9 Nítorínáà ẹ̀yin yíò yàn òun sí ìbùkún yìí, òun yíò sì wá ọ̀nà pẹ̀lú aápọn láti mú àwọn ìdojúkọ tí wọ́n wà ní orí ilé náà tí a ti dárúkọ lààrin yín kúrò, kí òun ó lè gbé níbẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.