Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 86


Ìpín 86

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 6 Oṣù Kejìlá 1832. Ìfihàn yìí ni a gbà nigbàtí Wòlíì nṣe iṣẹ́ àtúnyẹ̀wò àti àtúnkọ àfọwọ́kọ ìwé ti ìtúmọ̀ Bíbélì.

1–7, Olúwa fúnni ní ìtumọ̀ òwe àlìkámà àti èpò; 8–11, Ò ṣe àlàyé àwọn ìbùkún oyè àlùfáà fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ajogún lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́bíi ti ẹran ara.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, nípa òwe ti àlìkámà àti ti èpò náà:

2 Ẹ kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí, oko náà ni ayé, àwọn àpóstélì sì ni àwọn afúrúgbìn ti irúgbìn náà;

3 Àti lẹ́hìn tí wọ́n ti sùn onínúnibíni nlá náà ti ìjọ, tí ó ti yapa, alágbèrè, àní Bábílónì, tí o mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ó mu nínú ago rẹ̀, nínú àwọn ọkàn tí ọ̀tá náà, àní Sátánì, jókòó láti jọba—kíyèsíi òun fúrúgbìn àwọn èpò; nítorínáà, àwọn èpò fún àlìkámà lọ́rùn ó sì darí ìjọ sínú ijù.

4 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsíi, ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹhìn, àní nísisìyí nígbàtí Olúwa bẹ̀rẹ̀ láti mú ọ̀rọ̀ náà jade wá, àti tí àkọ́kọ́yọ ewé ọkà nhú sókè bọ̀ àti tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ síbẹ̀—

5 Ẹ kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn ángẹ́lì nkígbe sí Olúwa ní ọ̀sán àti ní óru, àwọn tí wọ́n ṣetán tí wọ́n sì ndúró kí á rán wọn jade láti kórè àwọn oko náà kanlẹ̀;

6 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún wọn, ẹ má ṣe fa àwọn èpò tu nígbàtí àkọ́kọ́yọ ewé rẹ̀ ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ síbẹ̀ (nítorí lõtọ́ ìgbàgbọ́ yín kéré), bí bẹ́ẹ̀kọ́ ẹ ó pa àlìkámà run pẹ̀lú.

7 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí àlìkámà àti èpò ó dàgbà papọ̀ títí tí ìkórè yíò fi gbó tán dáradára; nígbà náà ni ẹ̀yin yíò kọ́kọ́ kó àlìkámà jọ kúrò ní ààrin àwọn èpò, àti lẹ́hìn kíkó àlìkámá jọ, ẹ kíyèsíi kí ẹ sì wòó, àwọn èpò ní a ó dì jọ ní ìtí, oko náà yíò sì dúró fún jíjó níná.

8 Nítorínáà, báyìí ni Olúwa wí fún yín, pẹ̀lú ẹnití oyè àlùfáà náà ti tẹsíwájú nípasẹ̀ ìdílé àwọn baba yín—

9 Nítorí ẹ̀yin ni ajogún lábẹ́ òfin, gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, àti ní ìfipamọ́ kúrò fún ayé pẹ̀lú Krístì nínú Ọlọ́run—

10 Nítorínáà ìwàláàyè àti oyè àlùfáà yín dúró, ó sì gbọdọ̀ dúró nípasẹ̀ yín àti àwọn ìdílé yín títí di ìmúpadàbọ̀ sípò ohun gbogbo tí a sọ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì mímọ́ láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀.

11 Nítorínáà, ìbùkún ni fún yín bí ẹ̀yin bá tẹ̀síwájú nínú ìwà rere mi, ìmọ́lẹ̀ kan sí àwọn Kèfèrí, àti nípasẹ oyè àlùfáà yìí, olùgbàlà kan sí àwọn ènìyàn mi Ísráẹ́lì. Olúwa ti sọ ọ́. Àmín.