Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 68


Ìpín 68

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 1 Oṣù Kọkànlá 1831, ní ìdáhùn sí àdúrà pé kí ọkàn Olúwa ó di sísọ di mímọ̀ nípa Orson Hyde, Luke S. Johnson, Lyman E. Johnson, àti William E. McLellin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé abala ìfihàn yìí ni a darí sí ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin mẹ́rin wọ̀nyí, púpọ̀ nínú ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó jẹ mọ́ gbogbo Ìjọ. Ìfihàn yí ní a mú gbòòrò lábẹ́ ìdarí Joseph Smith nígbàtí a tẹ̀ ẹ́ nínú àtúntẹ̀ Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti 1835.

1–5, Àwọn ọ̀rọ̀ àwọn alàgbà nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí wọn jẹ́ ìwé–mímọ́; 6–12, Àwọn alàgbà ni yío wàásù wọ́n yío sì rì bọmi, àwọn àmì yíò sì tẹ̀lé àwọn onígbàgbọ́ tọ̃tọ́; 13–24, Àwọn àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Áarónì lè ṣiṣẹ́ bíi Bíṣọ́pù Olùdarí (èyí ni, lati di àwọn kọ́kọ́rọ́ àjọ ààrẹ mú bíi bíṣọ́pù) ní abẹ́ ìdarí Àjọ Àarẹ Kĩnní; 25–28, Àwọn òbí ni a pàṣẹ fún láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìhìnrere; 29–35, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yío ma ṣe àkíyèsí ọjọ́ ìsinmi, wọn yío ṣiṣẹ́ pẹ̀lú aápọn, wọn yío sì gbàdúrà.

1 Ìránṣẹ́ mi, Orson Hyde, ni a pè nípa jíjẹ oyè àlùfáà láti kéde ìhìnrere àìlópin, nípa Ẹ̀mí ti Ọlọ́run alààyè, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, àti láti ilẹ̀ dé ilẹ̀, nínú àwọn ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú, nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ní sísọ àsọyé pẹ̀lú wọn àti ní títúmọ̀ gbogbo àwọn ìwé mímọ́ fún wọn.

2 Àti, kíyèsíi, sì wòó, èyí jẹ́ àpẹrẹ fún gbogbo àwọn tí a ti yàn sí ipò oyè àlùfáà yìí, tí a ti yàn iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn láti tẹ̀síwájú—

3 Èyí sì jẹ́ àpẹrẹ fún wọn, pé wọn yío maa sọ̀rọ̀ bí Ẹ̀mí Mímọ́ bá ṣe darí wọn.

4 Àti pé ohunkóhun tí wọn yíò sọ nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí wọn yíò jẹ́ ìwé mímọ́, yíò jẹ́ ìfẹ́ inú Olúwa, yíò jẹ́ èrò inú Olúwa, yíò jẹ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, yíò jẹ́ ohùn Olúwa, àti agbára Ọlọrun sí ìgbàlà.

5 Kíyèsíi, èyí jẹ́ ìlérí Olúwa sí yín, Áà ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi.

6 Nísisìyí, ẹ tújúká, ẹ má sì ṣe bẹ̀rù, nítorí èmi Olúwa mo wà pẹ̀lú yín, èmi yíò sì dúró tì yín; ẹ̀yin yíò sì jẹ́rìí mi, àní Jésù Krístì, pé èmi ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè, pé èmi ti wà, pé èmi wà síbẹ̀, àti pé èmi ni yíò wá.

7 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí ọ, ìránṣẹ́ mi Orson Hyde, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Luke Johnson, àti sí ìránṣẹ́ mi Lyman Johnson, àti sí ìránṣẹ mi William E. McLellin, àti sí gbogbo àwọn olõtọ́ alàgbà ti ìjọ mi—

8 Ẹ lọ sí gbogbo ayé, ẹ wàásù ìhìnrere náà sí gbogbo ẹ̀dá, ní ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ èyí tí èmi ti fi fún yín, ní rírì bọmi ní orúkọ ti Bàbá, àti ti Ọmọ, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.

9 Àti pé ẹni tí ó bá gbàgbọ́ tí a sì rìbọmi ni a ó gbàlà, àti ẹni tí kò bá sì gbàgbọ́ ni a ó dálẹbi.

10 Ẹni tí ó bá sì gbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún pẹ̀lú àwọn àmì tí yíò tẹ̀lée, àní bí a ṣe kọ̀wé rẹ̀.

11 Àti sí yín ni a ó fi fún láti mọ àwọn àmì ti àwọn àkókò, àti àwọn àmì Bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn;

12 Àti pé iye àwọn wọnnì tí Bàbá yíò jẹ́rìí, sí ẹ̀yin ni a ó fi agbára fún láti fi èdídí dĩ wọ́n fún ìyè ayérayé. Àmín.

13 Àti nísisìyí, nípa àwọn nkan ní àfikún sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin, àwọn ni ìwọ̀nyí—

14 Àwọn wọ̀nyí dúró lẹ́hìn-èyí, ni àkókò tí ó yẹ lójú Olúwa, àwọn bíṣọ́pù míràn tí a ó yà sọ́tọ̀ sí ìjọ, lati ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àní ní ìbámu pẹ̀lú ti ìkínní;

15 Nísisìyí wọ́n yío jẹ́ àwọn àlùfáà gíga tí wọ́n yẹ, àti pé wọn yío jẹ́ yíyàn lati ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Èkínní ti Oyè Àlùfáà Melkisédékì, bíkòṣe pé bí wọ́n bá jẹ́ irú ọmọ Áárónì gan-an.

16 Àti pé bí wọ́n bá jẹ́ irú ọmọ Áárónì gan-an wọ́n ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti wà ní ipò àjọ bíṣọ́ọ́pù, bí wọ́n bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọkùnrin Áarónì;

17 Nítorí àkọ́bí ní ẹ̀tọ́ sí Àjọ Ààrẹ ní orí oyè àlùfáà yìí, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ tàbí àṣẹ ti òun kannáà.

18 Kò sí ènìyàn kan tí ó ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin sí ipò yìí, láti di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà yìí mú, bíkò ṣepé òun jẹ́ irú ọmọ gan-an àti àkọ́bí ọmọ Áárónì.

19 Ṣùgbọ́n, bí àlùfáà gíga nínú Oyè Àlùfáà Melkisédékì ti ní àṣẹ láti ṣe iṣẹ́ ipò ní gbogbo àwọn ipò tí ó kéré, òun lè ṣe iṣẹ́ ipò ní ipò iṣẹ́ bíṣọ́ọ̀pù nígbatí a kò bá rí irú ọmọ Áárónì gan-an, bí a bá pè é tí a sì yà á sọ́tọ̀ tí a sì yàn án sí ipò agbára náà, lábẹ́ ìfọwọ́sí ti Àjọ Ààrẹ Èkínní ti Oyè Àlùfáà Mélkisédékì.

20 Àti pé irú ọmọ Áárónì gan-an, bákannáà, gbọ́dọ̀ jẹ́ yíyàn láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ yìí, tí a sì ríi pé ó yẹ, ati tí a fi àmì òróró yàn, tí a sì yàn án lábẹ́ ìfọwọ́sí Àjọ Ààrẹ yìí, bíbẹ́ẹ̀kọ́ wọn kò ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti ṣe iṣẹ́ ipò nínú oyè àlùfáà wọn.

21 Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ ànfààní ti àṣẹ náà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ wọn sí oyè àlùfáà sísọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ bàbá sí ọmọ, wọ́n lè béèrè ìfi àmì òróró yàn wọn nígbàkũgbà bí wọ́n bá lè fi ìdí ìrandíran wọn múlẹ̀, tàbí tí wọ́n bá lè pinnu rẹ̀ nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa lábẹ́ ìfọwọ́sí Àjọ Ààrẹ tí a dárúkọ lókè yìí.

22 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, kì yíò sí bíṣọ́ọ̀pù tàbí àlùfáà gíga kan tí a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí tí a ó pè lẹ́jọ́ tàbí dá lẹ́bi fún rírú èyíkéyìí òfin, bíkòṣe pé ó jẹ́ níwájú Àjọ Ààrẹ Èkínní ti ìjọ;

23 Àti níwọ̀nbí òun bá jẹ̀bi níwájú Àjọ ààrẹ yìí, nípa ìjẹ́rìí èyí tí a kò lè fi ẹ̀sùn kàn, a ó dá a lẹ́bi;

24 Bí òun bá sì ronúpìwàdà a ó dárí jì í, ní ìbámú pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin ti ìjọ.

25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, níwọ̀nbí àwọn òbí bá ní àwọn ọmọ ní Síónì, tàbí ni èyíkéyìí àwọn èèkàn rẹ̀ tí a ti ṣètò, tí kò kọ́ wọn láti ní òye ẹ̀kọ́ ironúpìwàdà, ìgbàgbọ́ nínú Krístì Ọmọ́ Ọlọ́run alààyè, àti ìrìbọmi àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ nípa ìgbọ́wọ́lé, nígbà tí wọ́n bá di ọmọ ọdún mẹ́jọ, ẹ̀ṣẹ̀ náà wà ní orí àwọn òbí.

26 Nítorí èyí ni yíò jẹ́ òfin fún àwọn olùgbé Síónì, tàbí sí èyíkéyìí èèkàn rẹ̀ tí a ti ṣètò.

27 A ó sì ri àwọn ọmọ wọn bọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbàtí wọ́n bá pé ọmọ ọ̀dún mẹ́jọ, wọn ó sì gba ìgbọ́wọ́lé.

28 Wọn yíò sì kọ́ àwọn ọmọ wọn bákannáà láti gbàdúrà, àti láti rìn ní títọ́ níwájú Olúwa.

29 Àti pé àwọn olùgbé Síónì yíò kíyèsí ọjọ́ ìsìnmi bákannáà láti yà á sì mímọ́.

30 Àwọn olùgbé Síónì yíò sì rantí àwọn lãlã wọn bakannáà, níwọ̀nbí a bá yàn wọ́n lati ṣiṣẹ́, nínú gbogbo ìṣòtítọ́; nítorí àwọn aláìníṣẹ́ yíò wà ní ìrántí níwájú Olúwa.

31 Nísisìyí, èmi, Olúwa, èmi kò ní inú dídùn sí àwọn olùgbé Síónì, nítorí àwọn aláìníṣẹ́ wà lààrin wọn; àti pé àwọn ọmọ wọn bákannáà ndàgbà sókè nínú ìwà búburú; bákannáà wọ́n kò fi tọkàntọkàn wá àwọn ọrọ̀ ti ayérayé, ṣùgbọ́n ojú wọ́n kún fún ojúkòkòrò.

32 Àwọn nkan wọ̀nyí kò yẹ kí wọ́n rí bẹ́ẹ̀, ó sì gbọ́dọ̀ di mímú kúrò láàrin wọn; nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lọ sí ìlẹ Síónì.

33 Àti pé òfin kan ni èmi fi fún wọn—pé ẹni tí kò bá kíyèsí àwọn àdúrà rẹ̀ níwájú Olúwa ní àkókò wọn, ẹ jẹ́kí òun wà ní ìrántí níwájú onídajọ́ àwọn ènìyàn mi.

34 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́ àti òdodo, nítorínáà, ẹ máṣe ré wọn kọjá, tàbí yọ kúrò nínú wọn.

35 Kíyèsíi, èmi ni Álfà àti Ómégà, èmi sì nbọ̀ kánkán. Amin.