Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 80


Ìpín 80

Ìfihan tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Stephen Burnett, ní Hiram, Ohio, 7 Oṣù Kejì 1832.

1–5, Stephen Burnett àti Eden Smith ni a pè láti wàásù ní èyíkéyìí ibi tí wọ́n bá yàn.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún ọ ìránṣẹ́ mi Stephen Burnett: Lọ, lọ sí inú ayé kí o sì wàásù ìhìnrere sí olukúlùkù ẹ̀dá tí ó bá wá ní abẹ́ ìró ohùn rẹ.

2 Àti níwọ̀nbí ìwọ bá fẹ́ alábarìn kan, èmi yíò fi ìránṣẹ́ mi Eden Smith fún ọ.

3 Nítorínáà, ẹ lọ kí ẹ sì wàásù ìhìnrere mi, bóyá sí ìhà àríwá tàbí sí gúúsù, sí ìlà oòrùn tàbí sí ìwọ oòrùn kò já mọ́ ohun kan, nítorí ẹ̀yin kò lè ṣìnà.

4 Nítorínáà, ẹ kéde àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ lõtọ́, àti tí ẹ mọ̀ pé ó jẹ òtítọ́.

5 Kíyèsíi, èyí ni ìfẹ́ inú ẹni náà tí ó pè yín, Olùràpàdà yín, àní Jésù Krístì. Àmín.