Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 89


Ìpín 89

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 27 Oṣù Kejì 1833. Nítorítí àwọn arákùnrin ìbẹ̀rẹ̀ nlo tábà nínú àwọn ìpàdé wọn, Wòlíì náà ni ìdarí láti ṣe àṣàrò ní orí ọ̀rọ̀ náà; ní àyọrísí, ó béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa rẹ̀. Ìfihàn yìí, tí a mọ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n, ni ó jẹ́ àbájáde.

1–9, Lílo wáínì, awọn ohun mímu lílé, tábà, àti àwọn ohun mímu gbígbóná ni a kà sí èèwọ̀; 10–17, Àwọn ewé, àwọn èso, ẹran, àti ọkà oníhóró ni a yàn fún lílò ènìyàn àti ti àwọn ẹranko; 18–21, Ìgbọ́ràn sí òfin ìhìnrere, tí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n wà nínú rẹ̀, nmú àwọn ìbùkún ti ara àti ti ẹ̀mí wá.

1 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kan, fún ànfàní ìgbìmọ̀ àwọn olórí àlùfáà, tí wọ́n kóra jọ ní Kirtland, àti ìjọ, àti bákannáà àwọn ẹni mímọ́ ní Síónì—

2 Láti fi ìkíni ránṣẹ́ sí; kìí ṣe nípa òfin tàbí ipá, ṣùgbọ́n nípa ìfihàn àti ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ní fífí ètò àti ìfẹ́ inú Ọlọ́run hàn jade nínú ìgbàlà ti ara fún gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn—

3 Tí a fi fúnni fún ìlànà ẹ̀kọ́ kan pẹ̀lú ìlérí, tí a mú bádọ́gba sí ipá ti àwọn aláìlágbára àti àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlágbára jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹni mímọ́, àwọn tí wọ́n jẹ́ tàbí tí a lè pè ní àwọn ẹni mímọ́.

4 Kíyèsíi, lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín: Ní ìyọrísí àwọn ohun buburú àti ète èyítí ó wà àti tí yíò wà nínú ọkàn àwọn èniyàn tí wọn ndìtẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, èmi ti kìlọ̀ fún yín, mo sì kìlọ̀ fún yín ṣaájú, nípa fífún yín ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí nípa ìfihàn—

5 Pé níwọ̀nbí ẹnikẹ́ni bá mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle ní àrin yín, kíyèsíi kò dára, bẹ́ẹ̀ni kò tọ́ níwájú Bàbá yín, bíkòṣe ní kíkó ara yín jọ pọ̀ nìkan láti rú ẹbọ àmi májẹ̀mú yín níwájú rẹ̀.

6 Àti, kíyèsíi, èyí níláti jẹ́ ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ni, wáìnì tí kò ní àbàwọ́n tí ó jẹ́ ti èso ajarà, tí ẹ ṣe fúnra yín.

7 Àti, lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn ọtí líle kò wà fún ikùn, ṣùgbọ́n fún wíwẹ ara yín.

8 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, tábà ki ise fún ara, tàbí fún ikùn, kò sì dára fún ènìyàn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ewé fún ọgbẹ́ àti gbogbo ẹran ọ̀sìn tí ó bá nṣe àìsàn, láti lò pẹ̀lú ọgbọ́n àti mímọ̀ọ́ṣe.

9 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn ohun mímu gbígbóná kìí ṣe fún ara tàbí ikùn.

10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo àwọn ewé tí ó péye ni Ọlọ́run ti yàn fún àgbékalẹ̀, ìwàláàyè ẹ̀dá, àti ìlò ti ènìyàn—

11 Olúkúlùkù ewé ní àkókò tiwọn, àti olúkúlùkù èso ní àkókò tiwọn; gbogbo ìwọ̀nyí láti lò pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìdúpẹ́.

12 Bẹ́ẹ̀ni, ẹran bákannáà ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, Èmi, Olúwa, ti yàn án fún lílò ènìyàn pẹ̀lú ìdúpẹ́; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ wọ́n níláti jẹ́ lílò díẹ̀díẹ̀ ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì;

13 Ó sì jẹ́ dídùn inú mi pé kí wọ́n ó máṣe jẹ́ lílò, bíkòṣe ní àwọn ìgbà ọ̀rinrin, tàbí ti òtútù, tàbí ìyàn.

14 Gbogbo èso oníhóró ni a yàn fún lílò ènìyàn àti ti àwọn ẹranko, láti jẹ́ ọ̀pá ìwàláàyè, kìí ṣe fún ènìyàn nìkan ṣugbọ́n fún àwọn ẹranko ìgbẹ́, àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo onírúurú àwọn ẹranko tí wọn nsáré tàbí rákò ní orí ilẹ̀;

15 Àti pé ìwọ̀nyìí ni Ọlọ́run dá fún lílò ènìyàn ní àwọn ìgbà ìyàn nikàn àti ebi tí ó pọ̀ lápọ̀jù.

16 Gbogbo èso onihóró ni ó dára fún oúnjẹ ènìyàn; bíi ti èso ajarà bákannáà; èyíinì tí ó mú èso wá, bóyá nínú ilẹ̀ tàbí ní orí ilẹ̀—

17 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àlìkámà fún ènìyàn, àti ọkà fún màlúù, àti oríṣí èso oníhóró óòtì fún ẹṣin, àti ọkà bàbà fún àwọn ẹyẹ àti fún ẹlẹ́dẹ̀, àti fún gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́, àti bálì fún gbogbo àwọn ẹranko tí ó wúlò, àti fún àwọn ohun mímu aláìlágbára, bíi àwọn èso oníhóró míràn bákannáà.

18 Àti gbogbo àwọn èniyàn mímọ́ tí wọ́n bá rantí láti pa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mọ́ àti lati ṣe wọ́n, ní rírìn pẹ̀lú ìgbọràn sí àwọn òfin náà, yíò gba ìlera ní ìdodo wọn àti mùdùnmúdùn sí àwọn egungun wọn;

19 Wọn yíò sì rí ọgbọ́n àti àwọn ìṣura ìmọ̀ nlá, àní àwọn ìṣura tí ó pamọ́;

20 Àti pé wọn yíò sáré kì yíò sì rẹ̀ wọ́n, wọn yíò sì rìn àárẹ̀ kì yíò sì mú wọn.

21 Àti Èmi, Olúwa, fún wọn ní ìlérí kan, pé ángẹ́lì apanirun yíò ré wọn kọjá, bíi ti àwọn ọmọ Isráẹlì, kì yíò sì pa wọn. Àmín.