Àwọn Ìwé Mímọ́
Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú


Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú

Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ni àkójọpọ̀ àwọn ìfihàn àtọ̀runwá àti àwọn ìkéde tí ó ní ìmísí ti a fúnni fún ìdásílẹ̀ àti ìlànà ti ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn ìpín náà jẹ́ àwọn tí a darí wọn sí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, àwọn ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́, àwọn ìkìlọ̀, àti àwọn ìyànjú tí ó wà fún ire gbogbo aráyé ó sì jẹ́ ìpè sí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti gbọ́ ohùn Olúwa Jésù Krístì, tí ó nsọ̀rọ̀ sí wọn fún wíwà ní àlãfíà ti ara àti ìgbàlà ayérayé wọn.

Púpọ̀jùlọ nínú àwọn ìfihàn náà nínú ìkójọpọ̀ yìí ni a gbà nípasẹ̀ Joseph Smith Kékeré, tí ó jẹ́ Wòlíì àkọ́kọ́ àti ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwọn míràn jẹ́ èyí tí ó jade nípasẹ̀ díẹ̀ nínú àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ (wo àwọn àkọlé sí Ẹ&M 135, 136, àti 138, àti àwọn Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 1 àti 2).

Ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn idíwọ̀n iṣẹ́ Ìjọ ní àpapọ̀ pẹ̀lú Bíbélì Mímọ́, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti Píálì Olówó Iyebíye. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nítorítí kìí ṣe ìtumọ̀ àwọn ìwé àtijọ́, ṣùgbọ́n orírun rẹ̀ jẹ́ ti òde òní a sì fifúnni láti ọwọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn àsàyàn Wòlíì Rẹ̀ fún ìmúpadàbọ̀-sípò iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀ àti ìgbékalẹ̀ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí. Nínú àwọn ìfihàn náà, a ngbọ́ ohùn jẹ́jẹ́ ṣùgbọ́n dídúró ṣinṣin ti Olúwa Jésù Krístì, tí ó nsọ̀rọ̀ lákọ̀tun ní ìgbà ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò; àti iṣẹ́ tí a ti bẹ̀rẹ̀ níhĩnyí jẹ́ ìmúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀kejì, ní ìmúṣẹ àti ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ti gbogbo àwọn Wòlíì mímọ́ láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀.

Joseph Smith Kékeré ni a bí ní 23 Oṣù Kejìlá, 1805, ní Sharon, Ìjọba Ìbílẹ̀ Windsor, Vermont. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀, ó ṣípòpadà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ lọ sí Manchester ọjọ́ òní, ní ìwọ̀ oòrùn New York. Ó jẹ́ pé ìgbàtí ó ngbé níbẹ̀ ní ìgbà ìrúwé 1820, nígbàtí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlá ní ọjọ́ orí, ni ó ní ìrírí ìran rẹ̀ àkọ́kọ́, nínú èyítí Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì bẹ̀ẹ́ wò fúnra wọn. A sọ fún un nínú ìran yìí pé Ìjọ òtítọ́ ti Jésù Krístì tí a ti gbékalẹ̀ ní àwọn ìgbà Májẹ̀mú Titun, àti tí ó ti ṣe àmójútó ẹ̀kúnrẹrẹ́ ìhìnrere náà, kò sí ní orí ilẹ̀ ayé mọ́. Àwọn ìṣípayá àtọ̀runwá míràn tẹ̀lé e nínú èyítí a ti kọ́ ọ láti ọwọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ángẹ́lì; a fi hàn sí i pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ pàtàkì fún un láti ṣe ní orí ilẹ̀ ayé àti pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ó mú Ìjọ Jésù Krístì padàbọ̀ sípò sí orí ilẹ̀ ayé.

Bí àkókò ṣe nlọ, Joseph Smith ni a mú kí ó ṣeéṣe fún nípasẹ̀ ìranlọ́wọ́ àtọ̀runwá láti túmọ̀ àti láti ṣe àtẹ̀jáde Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní àkókò yìí kannáà òun àti Olíver Cowdery ni a yàn sí Oyè-àlùfáà ti Áarónì láti ọwọ́ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi nínú Oṣù Karũn 1829 (wo Ẹ&M 13), àti ní kété lẹ́hìnnáà a yàn wọ́n sí Oyè-àlùfáà ti Melkisédekì láti ọwọ́ àwọn Àpóstélì ìgbàanì Petérù, Jamesì, àti Jòhánnù (wo Ẹ&M 27:12). Àwọn jíjẹ-oyè-àlùfáà mĩràn tẹ̀lé e nínú èyítí àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà ti di fífúnni láti ọwọ́ Mósè, Èlíjà, Élíásì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Wòlíì ìgbàanì (wo Ẹ&M 110; 128:18, 21). Àwọn jíjẹ-oyè-àlùfáà wọ̀nyìí jẹ́, ni tòótọ́, ìmúpadàbọ̀-sípò àṣẹ àtọ̀runwá fún ènìyàn ní orí ilẹ̀ ayé. Ní 6 Oṣù Kẹrin 1830, lábẹ ìdarí láti ọ̀run wá, Wòlíì Joseph Smith ṣe ètò Ìjọ náà, báyìí sì ni Ìjọ òtítọ́ Jésù Krístì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan síi bíi àgbékalẹ̀ kan láàrin àwọn ènìyàn, pẹ̀lú àṣẹ láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìhìnrere àti láti ṣe àmójútó àwọn ìlànà ìgbàlà. (Wo Ẹ&M 20 àti Píálì Olówó Iyebíye, Joseph Smith—History 1.)

Àwọn ìfihàn mímọ́ wọ̀nyí ni a gbà ní ìdáhùn sí àdúrà, ní àwọn àkókò àìní, wọ́n sì jade wá láti inú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tòótọ́ ní ìgbé ayé àwọn ènìyàn gidi. Wòlíì náà àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ wá ìtọ́ni àtọ̀runwá, àwọn ìfihàn wọ̀nyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n rí i gbà. Nínú àwọn ìfihàn náà a nrí ìmúpadàbọ̀-sípò àti ìfarahàn ìhìnrere Jésù Krístì àti gbígbà wọlé ìgbà ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò. Ṣíṣípòpadà Ìjọ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti New York àti Pennsylvania sí Ohio, sí Missouri, sí Illinois, àti ní ìkẹ̀hìn sí Great Basin ti ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà àti àwọn ìgbìyànjú tí ó ní agbára ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní gbígbìdánwò láti kọ́ Síónì sí orí ilẹ̀ ayé ní àwọn àkókò òde òní ni a fi hàn bákannáà nínú àwọn ìfihàn wọ̀nyí.

Púpọ̀ nínú àwọn ìpín ìbẹ́rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìyírọ̀padà àti ṣíṣe àtẹ̀jade Ìwé ti Mọ́mọ́nì (wo àwọn ìpín 3, 5, 10, 17, àti 19). Àwọn ìpín díẹ̀ lẹ́hìnnáà ṣe àfihàn iṣẹ́ Wòlíì Joseph Smith ní síṣe ìyírọ̀padà Bíbélì pẹ̀lú ìmísí, láàrin ìgbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpín pàtàkì ti ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ jẹ́ gbígbà (wò, fún àpẹrẹ, àwọn ìpín 37, 45, 73, 76, 77, 86, 91, àti 132, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyítí ó ní ìbáṣepọ̀ tààrà pẹ̀lú ìyírọ̀padà Bíbélì).

Nínú àwọn ìfihàn náà, àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni a gbé kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn àlàyé nípa irú àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ bí ìwà ọ̀run ti Ọlọ́run Olórí, orírun ènìyàn, jíjẹ́ òdodo Sátánì, èrèdí ara kíkú, ṣíṣe dandan ìgbọ́ràn, ìdí fún ironúpìwàdà, àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ti Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà àti ìṣesí tí wọ́n jẹ mọ́ ìgbàlà, àyànmọ́ ilẹ̀ ayé, àwọn ipò ènìyàn ní ọjọ́ iwájú lẹ́hìn Àjínde àti Ìdájọ́, jíjẹ́ ayérayé ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó, àti àdánidá jíjẹ́ ayérayé ti ẹbí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìfarahàn díẹ̀díẹ̀ ti ètò iṣẹ́ àmójútó Ìjọ ni a fihàn pẹ̀lú pípè àwọn bíṣọ́pù, Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Ìgbìmọ̀ ti àwọn Méjìlá, àti ti Àádọ́rin àti ìgbékalẹ̀ àwọn ipò iṣẹ́ ìdarí àti àwọn ìyejú mĩràn. Lákotan, ẹ̀rí tí a fifúnni nípa Jésù Krístì—ìwà ọ̀run Rẹ̀, ọlá nlá Rẹ̀, pípé Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àti agbára ìrànipadà Rẹ̀—mú kí ìwé yìí níye ní orí púpọ̀ sí ìran ènìyàn ó sì “níye ní orí sí Ìjọ bíi àwọn ọrọ̀ ti gbogbo Ilẹ̀ Ayé” (wo àkọlé sí Ẹ&M 70).

Àwọn ìfihàn náà jẹ kíkọsílẹ̀ ní ojúlówó láti ọwọ́ àwọn akọ̀wé Joseph Smith, àwọn ọmọ Ìjọ sì fi tọkàntọkàn pín àwọn ẹ̀dà àfọwọ́kọ pẹ̀lú ara wọn. Láti ṣe ẹ̀dá àkọsílẹ̀ tí yío pẹ́ títí síi, láìpẹ́ àwọn àkọ̀wé ṣe ẹ̀dà àwọn ìfihàn wọ̀nyí sí inú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ àfọwọ́kọ, èyítí àwọn olùdarí Ìjọ lò ní ṣíṣe ìpalẹ̀mọ́ àwọn ìfihàn náà lati jẹ́ títẹ̀. Joseph Smith àti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìbẹ́rẹ̀ wo àwọn ìfihàn náà bí wọ́n ṣe wo Ìjọ: ní jíjẹ́ alààyè, níní ipá, tí ó sì le jẹ́ títúnṣe pẹ̀lú àfikún ìfihàn. Bákannáà wọ́n dáamọ̀ pé ó ṣeéṣe kí àwọn àṣìṣe àìtinúwá ti ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ ti ṣíṣe ẹ̀dà àwọn ìfihàn náà ati ṣíṣe ìpalẹ̀mọ́ wọn fún títẹ̀jáde. Nípa báyìí, ìpàdé àpapọ̀ kan ti Ijọ́ pe Joseph Smith ní 1831 láti “ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe tàbí àìdára èyítí òun le ti ṣe àwárí nípa Ẹ̀mí Mímọ́.”

Lẹ́hìn tí àwọn ìfihàn náà ti di gbígbéyẹ̀wò ati títúnṣe, àwọn ọmọ Ìjọ ní Missouri bẹ̀rẹ̀ sí títẹ ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní A Book of Commandments for the Government of the Church of Christ, (Ìwé Àwọn Òfin fún Ìṣèjọba ti Ìjọ Krístì), èyítí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn ìbẹ̀rẹ̀ ti Wòlíì nínú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbìdánwò àkọ́kọ́ yìí láti tẹ̀ àwọn ìfihàn náà parí, nígbàtí àwọn jàndùkú èrò kan ba ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ jẹ́ ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson ní 20 Oṣù Keje, 1833.

Ní gbígbọ́ nípa ìparun ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti Missouri, Joseph Smith àti àwọn olùdarí Ìjọ mìíràn bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpalẹ̀mọ́ láti tẹ àwọn ìfihàn náà ní Kirtland, Ohio. Lẹ́ẹ̀kansíi láti ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe, ṣe àfọ̀mọ́ àwọn ọ̀rọ̀, àti ṣe ìdámọ̀ àwọn ìdàgbàsókè nínú ẹ̀kọ́ àti ìgbékalẹ̀ Ìjọ, Joseph Smith mójútó yíyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú àwọn ìfihàn kan láti palẹ̀ wọn mọ́ fún títẹ̀jáde ní 1835 bíi Doctrine and Covenants of the Church of the Latter Day Saints (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti Ìjọ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn). Joseph Smith fi àṣẹ sí àtúntẹ̀ míràn ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, èyítí ó jẹ́ títẹ̀jáde ní oṣù díẹ̀ péré lẹhìn ikú ajẹ́rìíkú ti Wòlíì ní 1844.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti ìbẹ̀rẹ̀ mọ rírì àwọn ìfihàn náà wọ́n sì rí wọn bíi àwọn ọ̀rọ̀ àfiránṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní àkókò kan nígbàtí 1831 nparí lọ, onírúurú àwọn alàgbà Ìjọ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́rìí pé Olúwa ti jẹ́ ẹ̀rí sí ọkàn wọn nípa òtítọ́ àwọn ìfihàn náà. Ẹ̀rí yìí ni a tẹ̀ jáde nínú àtúntẹ̀ ti 1835 ti Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú bíi ẹ̀rí kíkọ ti àwọn Àpóstélì Méjìlá:

Ẹ̀rí náà ti
Àwọn Àpóstélì Méjìlá sí Òtítọ́ ti
Ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú

Ẹ̀rí náà ti àwọn Ẹlérìí sí Ìwé àwọn Òfin Olúwa, èyítí Ó fifún Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ Joseph Smith Kékeré, ẹnití a yàn nípasẹ̀ ohùn Ìjọ fún èrò yìí:

Àwa, nítorínáà, ní ìfẹ́ láti jẹ́rìí sí gbogbo aráyé, sí olúkúlùkù èdá ní orí ilẹ̀ ayé, pé Olúwa ti jẹ́rìí sí ọkàn wa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a tú sí orí wa, pé àwọn òfin wọ̀nyí jẹ́ fífi fúnni nípa ìmísí Ọlọ́run, àti tí ó ní èrè fún gbogbo ènìyàn wọ́n sì jẹ́ òtítọ́ gan an.

Awa fi ẹ̀rí yìí fún ayé, pẹ̀lú Olúwa bíi olùrànlọ́wọ́ wa; ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Bàbá, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni a fún wa ní ààyè láti ní ànfàní ti jíjẹ́rìí yìí sí ayé, nínú èyítí awa yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ní gbigbàdúrà sí Olúwa nígbà gbogbo pé kí àwọn ọmọ ènìyàn ó lè jẹ ànfàní nípa rẹ̀.

Orúkọ àwọn Méjìlá náà ni:

  • Thomas B. Marsh

  • David W. Patten

  • Brigham Young

  • Heber C. Kimball

  • Orson Hyde

  • William. E. McLellin

  • Parley P. Pratt

  • Luke S. Johnson

  • William Smith

  • Orson Pratt

  • John F. Boynton

  • Lyman E. Johnson

Nínú àwọn àtúntẹ̀ tẹ̀lé-n-tẹ̀lé lẹ́hìnwá ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, àwọn àfikún ìfihàn tàbí àwọn ohun àkọsílẹ̀ míràn ni a ti fi kún un, bí a ṣe gbà wọ́n àti bí a ṣe tẹ́wọ́gbà wọ́n nipa àwọn ìpéjọpọ̀ tàbí àwọn ìpàdé àpéjọpọ̀ ti Ìjọ tí ó ní àṣẹ. Àtúntẹ̀ ti 1876, tí a pèsè lati ọwọ́ Àlàgbà Orson Pratt ní abẹ́ ìdarí Brigham Young, ṣe ètò àwọn ìfihàn náà ní ìbámu sí àkójọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ ó sì mú àwọn àkọlé titun wá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú onítàn.

Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àtẹ̀jáde ti Ọdún 1835, àwọn ẹ̀kọ́ méje tẹ̀lé-n-tẹ̀lé nípa ìmọ̀ ẹ̀sìn wà nínú rẹ̀ bákannáà; ìwọ̀nyí ni a fún ní àkòrí Lectures on Faith (Ìdánilẹ́kọ̃ ní orí Ìgbàgbọ́). Ìwọ̀nyí ni a ti pèsè fún lílò ní Ilé Ẹ̀kọ́ àwọn Wòlíì ní Kirtland, Ohio, láti 1834 sí 1835. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ànfàní fún ẹ̀kọ́ àti ìtọ́sọ́nà, àwọn ìdánilẹ́kọ̃ wọ̀nyí ni a ti yọ kúrò nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú láti àtẹ̀jáde 1921 nítorí ti a kò fi wọ́n fúnni tàbí gbé wọn kalẹ̀ bíi àwọn ìfihàn sí gbogbo Ìjọ.

Nínú àtúntẹ̀ Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti 1981 ní Èdè Òyìnbó, àwọn àwẹ́ ìwé mẹ́ta jẹ́ fífikún fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìpín 137 àti 138, tí ó gbé àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ìgbàlà fún àwọn òkú kalẹ̀; àti Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 2, ní kíkéde pé gbogbo ọkùnrin ọmọ Ìjọ tí wọ́n bá yẹ le jẹ́ yíyàn sí oyè àlùfáà láì ka ẹ̀yà tàbí àwọ̀ ara sí.

Olukúlùkù àtúntẹ̀ titun ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ní àwọn àṣìṣe àtẹ̀hìnwá tí a ti túnṣe àti àfikún àwọn ọ̀rọ̀ ìwífúnni titun, pàápàá nínú àwọn abala onítàn ti àwọn àkọlé ìpín. Àtúntẹ̀ ti lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí tún àwọn ònkà ọjọ́ ṣe síi àti àwọn orúkọ ibìkan, ó sì ṣe àwọn àtúnṣe mìíràn. Àwọn àyípadà wọ̀nyí ni a ti ṣe láti mú ohun èlò náà wá sí ìbámu pẹ̀lú ìwífúnni onítàn tí ó péye jùlọ. Àwọn ìrí mìíràn tí àtúntẹ̀ titunjùlọ yìí ní nínú ni àwọn àwòrán tí a ti ṣe àgbéyẹ̀wò tí wọ́n nṣe àfihàn àwọn ibi aláwòrán pàtàkì nínú èyítí a ti gba àwọn ìfihàn, pẹ̀lú àwọn fọ́tò tí a ti mú dára síi ti àwọn ibi onítàn ti Ìjọ, àwọn atọ́ka sọ́tũn-sósì, àwọn àkọlé ìpín, ati àwọn àkékúrú àkòrí-ọ̀rọ̀, gbogbo èyítí ó jẹ́ pípèrò láti ran àwọn ònkàwé lọ́wọ́ láti ní òye àti láti yọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́ ti Olúwa bí a ṣe fi fúnni nínú Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú. Ìwífúnni fún àwọn àkọlé ìpín ni a ti mú láti inú Àfọwọ́kọ Ìwé Ìtàn Ìjọ àti History of the Church (Ìwé Ìtàn Ìjọ́) títẹ̀jáde (lápapọ̀ tí a ntọ́ka sí nínú àwọn àkọlé bíi ìtàn ti Joseph Smith) àti Joseph Smith Papers (Àwọn awẹ́ ìwé Joseph Smith).