Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 78


Ìpín 78

Ìfihàn tí a fifúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 1 Oṣù Kejì 1832. Ní ọjọ́ náà, Wòlíì àti àwọn olóri mĩràn ti péjọ lati sọ̀rọ̀ nípa okòwò Ìjọ. Ìfihàn yìí ti kọ́kọ́ fi àṣẹ fún Wòlíì, Sidney Rigdon, àti Newel K. Whitney lati rin ìrìnàjò lọ sí Míssouri kí wọn ó sì ṣe àgbékalẹ̀ àwọn aápọn okòwò àti ìtẹ̀wé ti Ìjọ nípa dídá “ilé iṣẹ́” kan tí yío máa mójútó àwọn aápọn wọ̀nyí, pa owó wọlé fún ìgbékalẹ̀ Síonì àti fún ànfààní àwọn aláìní. Ilé iṣẹ́ yìí, tí a mọ̀ sí Ilé Iṣẹ́ Ìṣọ̀kan, ni a gbékalẹ̀ ní Oṣù Kẹrin 1832 ó sì di títúká ní 1834 (wo ìpín 82). Ní ìgbà kan lẹ́hìn ìtúká rẹ̀, ní abẹ́ ìdarí ti Joseph Smith, gbólóhùn “àwọn ọ̀rọ̀ nípa ilé ìṣúra fún àwọn aláìní” rọ́pò “àwọn ìdásílẹ̀ fún okòwò àti ìtẹ̀wé” nínú ìfihàn náà, àti pé ọ̀rọ̀ “àjọ” rọ́pò “ilé iṣẹ́.”

1–4, Àwọn Ẹni Mímọ́ níláti kó ara wọn jọ kí wọ́n ó sì dá ilé ìṣúra kan sílẹ̀; 5–12, Lílo àwọn ohun ìní wọn pẹ̀lú ọgbọ́n yío tọ́ni sí ìgbàlà; 13–14, Ìjọ náà níláti jẹ́ olómìnira lọ́wọ́ àwọn agbára ayé; 15–16, Míkaẹlì (Ádámù) ṣiṣẹ́ ìsìn lábẹ́ ìdarí Ẹni Mímọ́ (Krístì); 17–22, Ìbùkún ni fún àwọn olõtọ́, nítorí wọn yíò jogún ohun gbogbo.

1 Olúwa bá Joseph Smith Kekere sọ̀rọ̀, wípé: Fetísílẹ̀ sími, ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí, ẹ̀yin tí a yàn sí ipò oyè àlùfáà gíga ti ìjọ mi, ẹ̀yin tí ẹ ti kó ara yín jọ papọ̀;

2 Ẹ sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn ẹni náà tí ó ti yàn yín láti ibi gíga, ẹnití yíò sọ àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n sí etí yín, kí ìgbàlà lè wà fún yín nínú ohun náà èyítí ẹ̀yin gbé kalẹ̀ níwájú mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

3 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, àkókò náà ti dé, ó sì ti wà nítosí; àti kíyèsíi, sì wòó, ó gbọdọ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ ti àwọn ènìyàn mi kan wà, ní dídarí àtí ṣíṣe ìdásílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ nípa ti ilé ìṣúra náà fún àwọn aláiní nínú àwọn ènìyàn mi, mẹ́jèèjì ní ìhín àti ní ilẹ̀ Síónì—

4 Fún pípẹ́ títí àti àìlópin ti ìdásílẹ̀ ati ètò sí ìjọ mi, láti mú ìlọsíwájú bá iṣẹ́ náà, èyí tí ẹ ti dáwọ́lé, fún ìgbàlà ènìyàn, àti fún ògo Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run;

5 Kí ẹ̀yin ó lè dọ́gba nínú àwọn àdéhùn àwọn ohun ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ni, àti àwọn ohun ti ayé bákannáà, fún gbígba àwọn ohun ti ọ̀run.

6 Nítorí bí ẹ̀yin kò bá dọ́gba nínú àwọn oun ti ayé ẹ̀yin kì yíò lè dọ́gba ní gbígba àwọn ohun ti ọ̀run;

7 Nítorí bí ẹ̀yin bá fẹ́ kí èmi fi ààyè kan fún yín ní ayé sẹ̀lẹ́stíà, ẹ gbọ́dọ̀ pèsè ara yín sílẹ̀ nípa ṣíṣe àwọn ohun tí èmi ti pàṣẹ fún yín àti tí mo béèrè lọ́wọ́ yín.

8 Àti nísisìyí, lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí, ó tọ̀nà pé kí á ṣe ohun gbogbo sí ògo mi, láti ọwọ́ yín ẹ̀yin tí a ti so pọ̀ nínú àjọ yìí.

9 Tàbí, ní ọ̀nà míràn, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney àti ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ó jókòó ní ìgbìmọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n wà ní Síónì;

10 Bíbẹ́ẹ̀kọ́ Satánì nwá ọ̀nà láti yí ọkàn wọn padà kúrò nínú òtítọ́, pé kí wọn lè di fífọ́jú kí wọ́n ó má sì lè ní òye àwọn ohun tí a ti pèsè fún wọn.

11 Nítorínáà, òfin kan ni mo fi fún yín, láti gbáradì kí ẹ sì ṣètò ara yín pẹ̀lu àdéhun kan tàbí májẹ́mú àìlópin èyí tí a kò lè rékọjá.

12 Àti pé ẹni tí ó bá ré e kọjá yíò pàdánù ipò iṣẹ́ àti ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ, a ó sì fàá kalẹ̀ fún àwọn ìjẹníyà ti Sátánì títí di ọjọ́ ìràpadà.

13 Kíyèsíi, èyí ni ìmúrasílẹ̀ nípa èyí tí mo ti múra fún yín, àti ìpìlẹ̀ náà, àti àpẹrẹ èyí tí mo fi fún yín, nípa èyí tí ẹ̀yin yíò lè ṣe àṣeparí àwọn òfin èyí tí a fi fún yín;

14 Pé nípasẹ̀ ìpèsè-sílẹ̀ mi, láìṣírò ìdààmú èyítí yíò sọ̀kalẹ̀ wá sí orí yín, pé kí ìjọ náà ó lè dá dúró lórii gbogbo àwọn ẹ̀dá míràn ní ìsàlẹ̀ ayé sẹ̀lẹ́stíà;

15 Pé kí ẹ̀yin ó lè gòkè wá fún adé náà tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín, kí á sì sọ yín di alákòóso ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọba, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ẹni Mímọ́ Síónì, ẹnití ó ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ Adam-ondi-Ahman;

16 Ẹnití ó ti yan Míkáẹlì ní ọmọ aláde yín, tí ó sì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó gbé e kalẹ̀ sí ibi gíga, àti tí ó ti fí àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbàlà fún un ní abẹ́ ìmọ̀ràn àti idarí ti Ẹni Mímọ́ náà, ẹni tí kò ní ìbẹrẹ̀ àwọn ọjọ́ tàbí òpin wíwà láàyè.

17 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, ẹ̀yin jẹ́ ọmọ wẹ́wẹ́, ẹ̀yin kò sì tíì ní òye nípa bí àwọn ìbùkún tí Baba ní lọ́wọ́ rẹ̀ àti tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín ṣe tóbi tó;

18 Àti pé ẹ̀yin kò lè gbà ohun gbogbo mọ́ra nísisìyí; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ tújú ka, nítorí èmi yíò ṣíwájú yín. Tiyín ni ìjọba náà àwọn ìbùkún inú rẹ̀ sì jẹ́ tiyín, àti àwọn ọrọ̀ ayérayé jẹ́ tiyín.

19 Àti pé ẹni náà tí ó bá gba ohun gbogbo pẹ̀lú ìdúpẹ́ ní a ó sọ di ológo; àti pé àwọn ohun ayé yìí ni a ó fi kún fún un, àní nígba ọ̀gọ́rũn, bẹ́ẹ̀ni, jù bẹ́ẹ̀ lọ.

20 Nítorínáà, ẹ ṣe àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún yín, ni Olùrapadà yín wí, àní Ọmọ Ahman, ẹni tí ó pèsè ohun gbogbo kí òun tó mú yín;

21 Nítorí ẹ̀yin ni ìjọ Àkọ́bí, òun yíò sì mú yín gòkè nínú àwọsánmọ̀, yíò sì yàn ìpín ti olúkúlùkù enìyàn fún un.

22 Àti ẹni náà tí ó bá jẹ́ olõtọ́ àti ọlọgbọ́n ìríjú yíò jogún ohun gbogbo. Àmín.