Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 21


Ìpín 21

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith ní Fayette, New York, 6 Oṣù Kẹrin 1830. Ìfihàn yìí ni a fi fúnni ní àkókò tí à nṣe àkójọ ìjọ, ní ọjọ́ tí a dárúkọ yìí, nínú ilé Peter Whitmer Àgbà. Àwọn ọkùnrin mẹ́fà, tí a ti ṣe ìrìbọmi fún tẹ́lẹ̀, ni wọ́n kópa. Pẹ̀lú ìfohùnṣọ̀kan ìbò, àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi èrò ọkàn àti ìpinnu wọn hàn láti ṣe àkójọ, ní ìbámu sí àṣẹ Ọlọ́run (wo ìpín 20). Wọ́n tún di ìbò bákannáà láti gbà wọlé ati lati ṣe àtìlẹhìn Joseph Smith Kekeré àti Oliver Cowdery gẹ́gẹ́bí àwon olórí òṣìṣẹ́ ti ìjọ. Pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ léni ní orí, nígbànáà Joseph yan Oliver bíi alàgbà ìjọ, Oliver náà sì yan Joseph ní ọ̀nà kannáà. Lẹ́hìn ṣíṣe ìpínfúnni oúnjẹ alẹ́ Olúwa, Joseph àti Oliver gbé ọwọ́ lé àwọn olùkópa ní orí ní ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ìfifúnni Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún fifi ìdí ẹnìkọ̀ọ̀kan múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọmọ ìjọ.

1–3, A pe Joseph Smith lati jẹ́ aríran, olùtúmọ̀, wòlíì, àpóstélì, àti alàgbà; 4–8, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yíò ṣe ìtọ́ni sí ipa ọ̀nà Síónì; 9–12, Àwọn ènìyàn mímọ́ yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ bí òun ṣe nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmísí Olùtùnú.

1 Kíyèsíi, àkọsílẹ̀ kan ni a ó pamọ́ ní ààrin yín; àti nínú rẹ̀ a ó pè ọ́ ní aríran, olùtúmọ̀, wòlíì, àpóstélì ti Jésù Krístì, alàgbà ti ìjọ nipa ìfẹ́ inú ti Ọlọ́run Bàbá, àti oore ọ̀fẹ́ Olúwa rẹ Jésù Krístì,

2 Nítorí tí ó ní ìmísí ti Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ìpìlẹ̀ náà lélẹ̀, àti lati kọ́ọ sókè sí ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ.

3 Ìjọ èyítí a ṣe àkójọ rẹ̀ àti tí a gbé kalẹ̀ nínú ọdún Olúwa rẹ ọgọ́rũn méjìdínlógún ati ọgbọ̀n, ní oṣù kẹrin, àti ní ọjọ́ kẹfà ti oṣù èyítí à npè ní Oṣù Kẹrin.

4 Nítorínáà, tí ó túmọ̀ sí ìjọ, ẹ níláti ṣe àkíyèsíi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn àṣẹ èyítí òun yíò fi fún yín bí òun náà ṣe gbà wọ́n, rírìn ní gbogbo ìwà mímọ́ níwájú mi;

5 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ẹ̀yin yíó gbà, bí ẹnipé láti ẹnu tèmi, pẹ̀lú gbogbo sùúrù àti ìgbàgbọ́.

6 Nítorí nípa síṣe àwọn ohun wọ̀nyí àwọn ẹnu ọ̀na ọ̀run àpáàdì kì yíò lè borí yín; bẹ́ẹ̀ni, àti pé Olúwa Ọlọ́run yíò tú gbogbo agbára òkùnkùn ká ní iwájú yín, yíò sì mú kí ọ̀run ó mì tìtì fún ire yín, àti nítorí ogo orúkọ rẹ̀.

7 Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Òun ni èmi ti mísí láti mú kí ipa ọ̀nà Síónì kí ó tẹ̀ síwájú nínú agbára nlá fún ire, àti aápọn rẹ̀ ni èmi mọ̀, èmi sì ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ̀.

8 Bẹ́ẹ̀ni, ẹkún rẹ̀ fún Síónì ni èmi ti rí, èmi yíò sì mú kí òun máṣe ṣọ̀fọ̀ ní orí rẹ̀ mọ́; nítorí ìgbà inú dídùn rẹ̀ ti dé sí ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àti àwọn ìfarahàn àwọn ìbùkún mi ní orí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.

9 Nítorí, kíyèsíi, èmi yíò bùkún fún àwọn wọnnì tí wọ́n ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi pẹ̀lú ìbùkún nlá, wọn yíò sì gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyítí a fi fún òun nípasẹ̀ èmi lati ọwọ́ Olùtùnú, èyítí ó sọ ọ di mímọ̀ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ arayé, bẹ́ẹ̀ni, fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ sí ìròbìnújẹ́ ọkàn.

10 Nísisìyí, ó jẹ́ dandan fún mi pé kí á yàn án láti ọwọ́ rẹ, Oliver Cowdery àpóstélì mi;

11 Èyí jẹ́ ìlànà kan fún ọ, pé ìwọ jẹ́ alàgbà ní abẹ́ ìgbọ́wọ́lé ní orí rẹ̀, òun sì jẹ́ àkọ́kọ́ sí ìwọ, pé kí ìwọ baà lè jẹ́ alàgbà sí ìjọ ti Krístì, tí ó njẹ́ orúkọ mi—

12 Àti oníwàásù àkọ́kọ́ ti ìjọ yìí fún ìjọ, àti níwájú ayé, bẹ́ẹ̀ni, ní iwájú àwọn Kèfèrí; bẹ́ẹ̀ni, àti bayìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, wòó, wòó! sí àwọn Júù bákannáà. Àmín