Àwọn Ìwé Mímọ́
Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 1


Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 1

Bíbélì ati Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé ọkọ-kan-aya-kan ni ètò Ọlọ́run fún ìgbeyàwó bíkòṣe pé Ó bá ṣe ìkéde mĩràn (wo 2 Sámúẹlì 12:7–8 àti Jákọ́bù 2:27, 30). Ní títẹ̀lé ìfihàn kan sí Joseph Smith, ìṣe níní ìyàwó ju ẹyọ kan lọ di gbígbékalẹ̀ ní ààrin àwọn ọmọ Ìjọ ní ìbẹ̀rẹ̀ awọn ọdún 1840 (wo ìpín 132). Lati awọn ọdun 1860 sí àwọn ọdún 1880, ìjọba United States ṣe àwọn òfin lati sọ ìṣe ẹ̀sìn yìí di àìbófinmu. Àwọn òfin wọ̀nyí di mímúdúró ní ìgbẹ̀hìn lati ọwọ́ Ilẹ́ Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ti U.S. Lẹ́hìn gbígba ìfihàn, Ààrẹ Wilford Woodruff gbé Ìkéde Èrò Inú tí ó tẹ̀lé yìí jáde èyítí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ìjọ bíi jíjẹ́ àṣẹ àti gbígbéni-dè ní 6 Oṣù Kẹwã 1890. Èyí ní ó darí sí òpin níní ìyàwó ju ẹyọ kan lọ nínú Ìjọ.

Sí Ẹnití Ó Lè Kàn:

Àwọn Ìwé àtẹjáde bí a ti fi ránṣẹ́ fún àwọn èrò ọ̀rọ̀ òṣèlú, láti Salt Lake City, èyítí a ti tẹ̀ jade káàkiri, nipa pé Àjọ Utah, nínú ìròhìn wọn tí ó jade ní àìpẹ́ yìí sí Akọ̀wé Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé, fi ẹ̀sùn kàn pé ètò níní ìyàwó ju ẹyọ kan lọ sì njẹ́ fífi ọwọ́ sí àti pé ogójì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ irú àwọn ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ ni a ti ṣe ní Utah láti Oṣù Kẹfà tí ó kẹ́hìn tàbí ní ààrin ọdún tí ó kọjá, bákannáà, pé nínú àwọn ìjíròrò ìta gbangba àwọn asíwájú Ìjọ ti kọ́ni, gbani níyànjú àti rọni fún ìtẹ̀síwájú ti ṣíṣe ìkóbìnrinjọ—

Nítorínáà, èmi, bí Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, níhĩnyí, pẹ̀lú ìṣesí ọ̀wọ̀ jùlọ, kéde pé àwọn ìfisùn wọ̀nyí jẹ́ ìrọ́. Àwa kò kọ́ni ní ìkóbìnrinjọ tàbí níní ìyàwó jú ẹyọ kan, tàbí gba ẹnikẹ́ni láàyè láti wọ inú ìṣe yìí, mo sì kọ̀ jálẹ̀ pé bóyá ogójì tàbí èyíkéyìí iye mĩràn àwọn gbígbéyàwó ju ẹyọ kan lọ ti jẹ́ ṣíṣe ní ààrin igbà náà nínú àwọn Tẹ́mpìlì wa tàbí ní èyíkéyìí ibòmíràn ní Àgbègbè náà.

Ẹjọ́ kan ti jẹ́ fífisùn, nínú èyítí àwọn apákan fi ẹ̀sùn kàn pé ìgbéyàwó náà jẹ́ ṣíṣe nínú Ilé Ìbùkúnfúnni, ní ìlú nlá Salt Lake, ní Ìgbà ìrúwé ti 1889, ṣùgbọ́n èmi kò tíì mọ̀ ẹni tí ó ṣe ètò ayẹyẹ náà; ohunkóhun tí ó jẹ́ ṣíṣe nínú ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ láì sí ìmọ̀ mi. Ní ìyọrísí ìṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn yìí, Ilé Ìbùkúnfúnni náà, nípa àṣẹ mi, ni a wó lulẹ̀ lái sí ìdádúró.

Níwọ̀nbí àwọn òfin ṣe jẹ́ fifi lélẹ̀ nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ó ka fífẹ́ ìyàwó ju ẹyọkan lọ sí èèwọ, àwọn òfin èyítí a ti kéde pé wọ́n bá ìwé ìlànà òfin mu nípasẹ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ, mo kéde níhĩnyí ìpinnu mi láti tẹríba fún àwọn òfin wọnnì, àti láti lo agbára mi pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ ní orí èyítí mo nṣe àkóso láti mú kí wọn ó ṣe bákannáà.

Kò sí ohun kan nínú àwọn kíkọ́ni mi sí Ìjọ tàbí nínú ti àwọn akẹgbẹ́ mi, láàrin àkókò tí a sọ, èyítí ó le mú ọgbọ́n wá láti túmọ̀ sí rírọni tàbí gbani níyànjú ìkóbìnrinjọ; àti pé nígbàtí èyíkéyìí Alàgbà Ìjọ bá lo èdè, èyítí ó fi ara hàn pé ó gbé èyíkéyìí irú kíkọ́ni bẹ́ẹ̀, òun ti di bíbáwí ní kánkán. Àti nísisìyí èmi kéde ní gbangba pé ìmọ̀ràn mi sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni láti dá ara dúró nínú ṣíṣe èyíkéyìí ìgbéyàwó tí a ti kà léèwọ̀ nípa òfin ilẹ̀ náà.

Wilford Woodruff

Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì
ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn

Ààrẹ Lorenzo Snow dá ìmọ̀ràn tí ó tẹ̀lé yí:

“Mo dáa lábàá pé, ní mímọ Wilford Woodruff bíi Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àti ẹnikan ṣoṣo ní orí ilẹ̀ ayé ní àkókò yìí tí ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ìlanà èdídí, a ka òun sí pé a fi àṣẹ fún un ní kíkún nípasẹ̀ ipò rẹ̀ láti ṣe àgbéjáde Ìkéde Èro Inú náà èyítí a ti kà sí etí gbọ̀ wa, àti pé tí ó ní ònkà ọjọ́ 24 Oṣù Kẹsãn, Ọdún 1890, àti pé bí Ìjọ nínú ìpàdé Gbogbogbò tí a kó ara jọ, a gbà ìkéde rẹ̀ nípa ti àṣà igbéyawó nínú èyítí ọkùnrin kan yíò ti ní ju ìyàwó kan lọ bí jíjẹ́ àṣẹ àti gbígbéni-dè.”

Ìlú Nlá Salt Lake, Utah, 6 Oṣù Kẹwã 1890.

Àyọkà láti inú àwọn Ìbánisọ̀rọ̀ Mẹ́ta láti ọwọ́
Ààrẹ Wilford Woodruff
nípa Ìkéde Èrò Inú náà

Olúwa kì yíò gbà mí láàyè láé tàbí ẹlòmíràn tí ó bá dúró bí Ààrẹ Ìjọ yìí láti darí yín sí ìṣìnà. Kò sí nínú ètò náà. Kò sí nínú ọkàn Ọlọ́run. Bí mo bá gbìdánwò èyíinì, Olúwa yíò mú mi kúrò ní ààyè mi, àti bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́ ni òun yíò ṣe sí èyíkéyìí ẹlòmíràn ẹnití ó bá gbìdánwò láti mú àwọn ọmọ ènìyàn darí kúrò ní àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run àti kúrò ní ojúṣe wọn. (Ìpadé Gbogbogbò ti ìdajì Ọdún Ìkọkànlélọ́gọ́ta ti Ìjọ, Ọjọ́ Ajé, 6 Oṣù Kẹwã 1890, Ìlú nlá Salt Lake, Utah. Tí a ròhìn nínú Deseret Evening News, 11 Oṣù Kẹwã, 1890, p.2.)

Ẹnití ó yè tàbí ẹnití ó kú kò já mọ́ nkan, tàbí ẹnití a pè láti darí Ìjọ yìí, wọ́n níláti darí rẹ̀ nípasẹ̀ ìmísí ti Ọlọ́run Alágbara jùlọ. Bí wọn kò bá ṣeé ní ọ̀nà náà, wọn kì yíò lè ṣe é rárá. …

Mo ti ní àwọn ìfihàn díẹ̀ ní àìpẹ́ yìí, wọ́n sì jẹ́ pàtàkì gan an sí mi, èmi yíò sì sọ fún yín ohun tí Olúwa ti wí fún mi. Ẹ jẹ́ kí èmi mú ọkàn yín wá sí ohun tí a pè ní ìkéde èrò inú. …

Olúwa ti sọ fún mi láti béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn, Òun sì sọ fúnmi bákannáà pé bí wọn bá tẹ́tí sí ohun tí èmi wí fún wọn àti tí wọ́n dáhùn ìbéèrè tí a bi wọ́n, nípa Ẹ̀mí àti agbára Ọlọ́run, gbogbo wọn yíò dáhùn bákannáà, àti pé gbogbo wọn yíò gbàgbọ́ bákannáà nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Ìbéèrè náà ni èyí: Èwo ni ó jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n jùlọ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti tẹ̀lé—láti tẹ̀síwájú láti máa gbìdánwò ṣiṣe àṣa gbígbéyàwó ju ẹyọ kan lọ, pẹ̀lú àtakò àwọn òfin orílẹ̀-ède àti ìdojúkọ àwọn ènìyàn bí ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́ta, àti tí yíó ná wa ní gbígbẹ́sẹ̀lé àti pípàdánù gbogbo àwọn Tẹ́mpìlì, àti ìdádúró gbogbo àwọn ìlànà nínú wọn, fún àwọn alààyè àti àwọn òkú, àti jíjusẹ́wọ̀n Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti àwọn Méjìlá àti àwọn olórí àwọn ẹbí nínú Ìjọ, àti gbígbẹsẹ̀lé àwọn ohun ìní ti àwọn ènìyàn náà (gbogbo èyítí àwọn fúnra wọn yíò dáwọ́ àṣà náà dúró). tàbí, lẹhìn ṣíṣe àti jíjìyà ohun tí a ti là kọjá nípasẹ̀ fífaramọ́ ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí láti fi òpin sí àṣa náà àti títẹríba fún òfin náà, àti nípasẹ̀ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kí a fi àwọn Wòlíì, àwọn Àpóstélì àti àwọn bàbá sílẹ̀ ní ilé, kí wọ́n ó lè dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̃ kí wọn ó sì ṣe àwọn ojúṣe Ìjọ, àti bákannáà kí wọ́n ó fi àwọn Tẹ́mpìlì sílẹ̀ sí ọwọ́ Àwọn Ènìyàn Mímọ́, kí wọ́n ó lè ṣe àwọn ìlànà ti Ìhìnrere, fún àwọn alààyè àti àwọn òkú?

Olúwa fi hàn mí nípa ìran àti ìfihàn òhun gan an tí ìbá ṣẹlẹ̀ bí a kò bá dá àṣà yìí dúró. Bí kò bá ṣe pé a dá a dúró, ẹ̀yin kì yíò lè ní ìlò fún … ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn nínú Tẹ́mpìlì yìí ní Logan; nítorí gbogbo àwọn ìlànà ni ìbá di dídá dúró jákèjádò ilẹ̀ Síónì. Ìdàrúdàpọ̀ ìbá jọba jákèjádò Ísráẹ́lì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní a ó sì sọ di ará túbú. Ìpọ́njú yìí ìbá wá sí orí Ìjọ lápapọ̀, wọn ìbá sì ti fi agbára mú wa láti jáwọ́ nínú ìṣe náà. Nísisìyí, ìbéèrè náà ni, bọ́yá kí a dáa dúró ní ọ̀nà yìí, tàbí ní ọ̀nà tí Olúwa ti fi hàn fún wa, kí a sì fi àwọn Wòlíì, àti àwọn Àpóstélì àti àwọn bàbá sílẹ̀ ní òmìnira ènìyàn, àti àwọn Tẹ́mpìlì ní ọwọ́ àwọn ènìyàn náà, pé kí àwọn òkú ó le di ríràpadà. Púpọ̀ ni iye tí a ti gbà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀rí kúrò nínú ilé túbú ní ayé àwọn ẹ̀mí láti ọwọ́ àwọn ènìyàn yìí, àti pé ṣé kí iṣẹ́ náà kí ó tẹ̀síwájú ni tàbí kí ó dúró? Èyí ni ìbéèrè tí mo fi sí iwájú àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ẹ níláti dájọ́ fún ara yín. Èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó dáhùn rẹ̀ fún ara yín. Èmi kì yíò dáhùn rẹ̀; ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé èyíinì ni ipò gan an tí àwa bí ènìyàn kan ìbá wà bí a kò bá gba ọ̀nà tí a gbà náà.

…Mo rí ohun gan an tí ìbá wá sí ìmúṣẹ bí ohun kan kò bá jẹ́ ṣíṣe. Mo ti ní ẹ̀mí yìí pẹ̀lũ mi fún ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ sọ èyí: Èmi ìbá ti jẹ́ kí gbogbo àwọn Tẹ́mpìlì kí ó lọ kúrò ní ọwọ́ wa; èmi ìbá ti lọ sí túbú tìkárami, èmi ìbá sì jẹ́ kí gbogbo ènìyàn míràn lọ síbẹ̀, bí Ọlọ́run ọ̀run kò bá pàṣẹ fún mi láti ṣe ohun ti mo ṣe; àti pé nígbàtí wákàtí náà dé tí a pàṣẹ fún mi láti ṣe èyíinì, gbogbo rẹ̀ hàn kedere sí mi. Mo lọ síwájú Olúwa, mo sì kọ ohun ti Olúwa wí fún mi láti kọ. …

Èmi fi èyí sílẹ̀ pẹlú yín, fún yín láti ronú lé ní orí kí ẹ sì gbéyẹ̀wò. Olúwa wà níbi iṣẹ́ pẹ̀lú wa. (Ìpàdé Àpapọ̀ Èèkàn Cache, Logan, Utah, Ọjọ́ Àìkú, 1 Oṣù Kọkànlá, 1891. Tí a kọ ìrohìn rẹ̀ sínú Deseret Weekly (Dẹ́sárẹ́tì Ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀), 14 Oṣù Kọkànlá, 1891.)

Nísisìyí èmi yíò sọ fún yín ohun tí a fi hàn sí mi àti ohun tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe nínú nkan yìí. …Gbogbo ohun wọ̀nyí ìbá wá sí ìmúṣẹ, bí Ọlọ́run Alágbara ṣe wà láàyè, bí a kò bá fúnni ní Ìkéde Èrò Inú náà. Nítorínáà, ọmọ Ọlọ́run ní ìfẹ́ inú sí gbígbé ohun náà sí iwájú ìjọ àti sí àgbáyé fún àwọn èrò inú ọkàn tirẹ̀. Olúwa ti pàṣẹ ìgbékalẹ̀ Síónì. Òun ti pàṣẹ píparí tẹ́mpìlì yìí. Òun ti pàṣẹ pé ìgbàlà àwọn alààyè àti ti àwọn òkú níláti jẹ́ fífúnni nínú àwọn àfonífòjì wọ̀nyí ti àwọn òke. Ọlọ́run Alágbára Jùlọ sì pàṣẹ pé Èṣù kì yíò lè díi lọ́wọ́. Bí ẹ̀yin bá le ní òye pé, èyíinì ni kọ́kọ́rọ́ kan sí i. (Láti inú ọ̀rọ̀ sísọ kan ní abala ẹ̀ẹ̀kẹfà ti ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Ìlú Nlá Salt Lake, Oṣù Kẹrin 1893. Ẹ̀dà ìwé títẹ̀ ti àwọn Iṣẹ́ Ìsìn Ìyàsímímọ́, Àwọn ìwé Pípamọ́, Ẹ̀ka tí Nmójútó Ìwé ìtàn Ìjọ, Ìlú Nlá Salt Lake, Utah.)