Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 36


Ìpín 36

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Edward Partridge, ní ẹ̀bá Fayette, New York, ọjọ́ kẹsãn Oṣù Kejìlá 1830. (wo àkọlé sí ìpín 35). Ìtàn ti Joseph Smith sọ pé Edward Partridge jẹ́ “àpẹrẹ kan nínú àwọn olùfọkànsìn, àti ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn nlá ti Olúwa.”

1–3, Olúwa gbé ọwọ́ Rẹ̀ lé Edward Partridge nípa ọwọ́ Sidney Rigdon; 4–8, Gbogbo ènìyàn tí ó bá ti gba ìhìnrere àti oyè àlùfáà ni a ó pè láti jade lọ wàásù.

1 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, Alágbára kan ti Israẹ́lì: Kíyèsíi, mo wí fún ọ́, ìránṣẹ́ mi Edward, pé ìbùkún ni fún ọ, a sì ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, àti pé a ti pè ọ́ láti wàásù ìhìnrere mi gẹ́gẹ́bií pẹ̀lú ohùn fèrè;

2 Àti pé èmi yíò gbé ọwọ́ mi lé ọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon, ìwọ yíò sì gba Ẹ̀mí mi, Ẹmí Mímọ́, àní Olùtùnú náà, èyítí yíò kọ́ ọ ní àwọn ohun àlãfíà ti ìjọba náà;

3 Àti pé ìwọ yíò kéde rẹ̀ pẹ̀lú ohùn ariwo, wipe: Hossana, ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run tí Ó ga jùlọ.

4 Àti nísisìyí ìpè àti òfin yìí ni èmi fi fún ọ nípa gbogbo ènìyàn—

5 Wípé iye àwọn tí wọ́n bá wá sí iwájú àwọn ìrànṣẹ́ mi Sidney Rigdon àti Joseph Smith Kékeré, tí wọ́n sì gba ìpè àti òfin yìí mọ́ra, ni a ó yàn tí a ó sì rán jade láti wàásù ìhìnrere ayérayé náà lààrin àwọn orílẹ̀-èdè—

6 Ní kíkígbe ironúpìwàdà, wipe: Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí, kí ẹ sì jade wá kúrò ní inú iná, ní kíkórìíra àní àwọn ẹ̀wù tí ẹran ara ti sọ di àbàwọ́n.

7 Àti pé òfin yìí ni a ó fi fún àwọn alàgbà ìjọ mi, pé kí olúkúlùkù ènìyàn tí yíò bá tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọkàn kan lè di yíyàn kí á sì lè rán wọn jade, àní bí èmi ṣe ti sọ̀rọ̀.

8 Emi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run; nítorínáà, ẹ di àmùrè yín èmi yíò sì dé ní àìròtìtẹ́lẹ̀ sínú tẹ́mpìlì mi. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.