Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 104


Ìpín 104

Ìfihàn tí a fún Wòlíì Joseph Smith, Kirtland, Ohio, 23 Oṣù Kẹrin 1834, nípa Ilé Iṣẹ́ Ìṣọ̀kan (wo àwọn àkọlé sí àwọn ìpín 78 ati 82). Àkókò náà ṣeéṣe kí ó jẹ́ ti ìpàdé ìgbìmọ̀ kan ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ilé Iṣẹ́ Ìṣọ̀kan èyítí ó jíròrò ní orí àwọn àìní nípa ti ara tí ó jẹ́ kíákíá fún Ìjọ. Ìpàdé ilé iṣẹ́ náà ṣaájú ní 10 Oṣù Kẹrin ti pinnu pé kí àgbékalẹ̀ náà jẹ́ títúká. Ìfihàn yìí dárí pé kí ilé iṣẹ́ náà jẹ́ títúntò dípò bẹ́ẹ̀; àwọn ohun ìní rẹ̀ yío jẹ́ pípín láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti ilé iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ ìríjú wọn. Ní abẹ́ ìdarí Joseph Smith, gbólóhun ọ̀rọ̀ “Ilé Iṣẹ́ Ìṣọkan” ni ó jẹ́ pípààrọ̀ ní ìgbẹ̀hìn pẹ̀lú “Ètò Ìṣọ̀kan” nínú ìfihàn náà.

1–10, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n bá rú òfin lòdì sí èto ìṣọ̀kan ni a ó fi bú; 11–16, Olúwa npèsè fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀ ní ọ̀nà ti ara Rẹ̀; 17–18, Òfin ìhìnrere nṣe àkóso ìtọ́jú àwọn tálákà; 19–46, Àwọn iṣẹ́ ìríjú àti àwọn ìbùkún ti onírúurú àwọn arákùnrin ni a là sílẹ̀; 47–53, Èto ìṣọ̀kan ní Kirtland àti ètò náà ní Síónì yíò máa ṣiṣẹ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; 54–66, Ìṣura mímọ́ Olúwa ni a gbé kalẹ̀ fún títẹ àwọn ìwé mímọ́; 67–77, Ìṣura gbogbogbòò ti èto ìṣọ̀kan yíò máa ṣiṣẹ́ ní orí ìfimọ̀ṣọ̀kan; 78–86, Àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ètò ìṣọ̀kan náà níláti san gbogbo gbèsè wọn, Olúwa yíò sì gbà wọ́n kúrò nínú ìdè gbèsè.

1 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, mo fi ìmọràn fún yín, àti òfin kan, nípa gbogbo àwọn ohun ìnì èyítí ó jẹ́ ti ètò náà èyítí mo pàṣẹ lati ṣe èto àti ìgbékalẹ̀ rẹ̀, láti jẹ́ èto ìṣọ̀kan, àti ètò ayérayé kan fún ànfàní ìjọ mi, àti fún ìgbàlà àwọn ènìyàn títí tí èmi yíò fi dé—

2 Pẹ̀lú ìlérí tí kò ṣe é yípadà àti tí kò le yẹ̀, pé níwọ̀nbí àwọn ti mo pàṣẹ fún bá jẹ́ olõtọ́ wọn yíò di alábùkún fún pẹ̀lú àwọn ìbùkún ní ìlọ́po àìníye;

3 Ṣùgbọ́n níwọ̀nbí wọn kò bá jẹ́ olõtọ́ wọ́n súnmọ́ ègún.

4 Nítorínáà, níwọ̀nbí díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ mi kò bá pa òfin náà mọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n sẹ́ májẹ̀mú náà nípasẹ̀ ojú kòkòrò, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, mo ti fi wọ́n bú pẹ̀lú ìfibú tí ó ṣòro ati tí ó bani nínújẹ́ jọjọ.

5 Nítorí èmi, Olúwa, ti pinnu nínú ọkàn mi, pé níwọ̀nbí a bá rí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti ètò náà bíi olùrékọjá, tàbí, ní ọ̀nà míràn, tí ó bá sẹ́ májẹ̀mú náà pẹ̀lú èyítí a fi dè yín, a ó fi í bú ní ìgbé ayé rẹ̀, òun yíò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹnití èmi bá fẹ́;

6 Nítorí èmi, Olúwa, èmi kò gbọdọ̀ di gígàn nínú àwọn ohun wọ̀nyìí—

7 Àti gbogbo èyí kí aláìṣẹ̀ láàrin yín má baà gba ìdálẹ́bi pẹ̀lú aláìṣòótọ́; àti kí ẹnití ó jẹ̀bi láàrin yín ó má baà ja àjàbọ́; nítorí èmi, Olúwa, ti ṣe ìlérí adé ogo kan fún yín ní ọwọ́ ọ̀tún mi.

8 Nítorínáà, níwọ̀nbí a bá ríi yín bíi olùrékọjá, ẹ̀yin kì yíò ja àjàbọ́ nínú ìbínú mi ní ayé yín.

9 Níwọ̀nbí a bá ké yín kúrò fún ìrékọjá, ẹ̀yin kì yíò lè ja àjàbọ́ nínú ìjẹníyà Sátánì títí di ọjọ́ ìràpadà.

10 Èmi sì fún yín nísisìyí ní agbára láti wákàtí yìí gan, pé bí a bá rí ẹnikẹ́ni láàrin yín, ti ètò náà, tí ó jẹ́ olùrékọjá tí kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú ibi náà, kí ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ìjẹníyà Sátánì; òun kì yíò sì ní agbára láti mú ibi wá sí orí yín.

11 Èyí jẹ́ ọgbọ́n nínú mi; nítorínáà, òfin kan ni mo fi fún yín, pé kí ẹyin ó ṣe èto ara yín kí ẹ sì yan iṣẹ́ ìríjú ti olúkúlùkù fún un;

12 Kí olúkúlùkù èniyàn ó lè ṣe ìṣirò fúnmi nípa ti iṣẹ́ ìríjú rẹ̀ èyítí a yàn fún un.

13 Nítorí ó tọ̀nà pé kí èmi, Olúwa, ó mú kí olúkúlùkù ènìyàn ó lè ṣe ìṣirò, bí ìríjú kan ní orí àwọn ìbùkún ayé, èyítí mo ti ṣe tí mo sì pèsè fún àwọn ẹ̀dá mi.

14 Èmi, Olúwa, tẹ́ pẹpẹ àwọn ọ̀run jade, mo sì kọ́ ilẹ̀ ayé, iṣẹ́ ọwọ́ mi gan; gbogbo àwọn ohun inú rẹ̀ sì jẹ́ tèmi.

15 Ó sì jẹ́ èrò mi láti pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́ mi, nítorí ohun gbogbo jẹ́ tèmi.

16 Ṣùgbọ́n ó gbọdọ̀ níláti jẹ́ ṣíṣe ní ọ̀nà tèmi; sì kíyèsíi èyí ni ọ̀nà náà tí èmi, Olúwa, ti pàṣẹ láti pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́ mi, pé kí á lè gbé àwọn tálákà ga, nínú èyí ni a rẹ àwọn ọlọ́rọ̀ sílẹ̀.

17 Nítorí ilẹ̀ ayé kún, ànító àti àniṣẹ́kù sì wà; bẹ́ẹ̀ni, mo pèsè ohun gbogbo, mo sì tí fi fún àwọn ọmọ ènìyàn láti jẹ́ aṣojú fún ara wọn.

18 Nítorínáà, bí ẹnikẹ́ni bá mú nínu ọ̀pọ̀ náà èyítí mo ti dá, tí òun kò sì fi nínú ìpín tirẹ̀, fún àwọn tálákà àti aláìní, gẹ́gẹ́bí òfin ìhìnrere mi, òun yíò pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú gbé ojú rẹ̀ sókè ní ọ̀run àpáàdì, ní wíwà nínú ìrora.

19 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, nípa àwọn ohun ìní ti èto náà—

20 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon ó ní ibití ó ngbé nísisìyí bí ibití a yàn fún un, àti ìpín ilẹ̀ tí a ti nṣe iṣẹ́ awọ fún iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, fún àtìlẹ́hìn rẹ̀ nígbàtí òun bá nṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi, àní bí èmi ṣe fẹ́, nígbàtí èmi yíò pàṣẹ fún un.

21 Ẹ sì jẹ́kí ohun gbogbo jẹ́ ṣíṣe gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ràn ti ètò náà, àti ìṣọ̀kan ìfọwọ́sí tàbí ohùn ti ètò náà, èyítí ó ngbé ní ilẹ̀ Kirtland.

22 Àti iṣẹ́ ìríjú àti ìbùkún yìí, èmi, Olúwa, fi lé orí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon fún ìbùkún kan ní orí rẹ̀, àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀;

23 Èmi yíò sì mú àwọn ìbùkún lọ́po ní orí rẹ̀, níwọ̀nbí òun yíò bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi.

24 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Martin Harris ó ní bíi èyítí a yàn fún un, fún iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, ìpín ilẹ̀ èyítí ìránṣẹ́ mi John Johnson gbà ní ìpààrọ̀ fún ogún rẹ̀ ti ìṣaájú, fún òun àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀;

25 Àti níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, èmi yíò mú àwọn ìbùkún lọ́po ní orí rẹ̀ àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀.

26 Ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Martin Harris ó fi àwọn owó rẹ̀ sílẹ̀ fún kíkéde àwọn ọ̀rọ̀ mi, gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, yíò ṣe darí.

27 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams ó ni orí ibi tí òun ngbé nísisìyí.

28 Ẹ sì jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery ó ni ìpín ilẹ̀ èyítí a yà sí apákan tí ó so mọ́ ile, èyítí yíó wà fún ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé, èyítí ó jẹ́ ìpín ilẹ̀ àkọ́kọ́, àti bákannáà ìpín ilẹ̀ ní orí èyítí bàbá rẹ̀ ngbé.

29 Ẹ sì jẹ́kí àwọn ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams àti Oliver Cowdery ó ni ìlé iṣẹ́ ìtẹ̀wé náà àti àwọn ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ọ.

30 Èyí ni yíò sì jẹ́ iṣẹ́ ìríjú wọn èyítí yíò jẹ́ yíyàn fún wọn.

31 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́, kíyèsíi èmi yíò bùkún wọn, èmi yíó sì mú kí àwọn ìbùkún lọ́po ní orí wọn.

32 Èyí sì ni ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìríjú náà èyítí mo ti yàn wọn sí, fún àwọn àti irú ọmọ wọn lẹ́hìn wọn.

33 Àti, níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́, èmi yíò mú kí àwọn ìbùkún lọ́po ní orí wọn àti irú ọmọ wọn lẹ́hìn wọn, àní àwọn ìbùkún ní ìlọ́po púpọ̀.

34 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ mi John Johnson ó ni ilé èyítí òun ngbé, àti ogún náà, gbogbo rẹ̀ yàtọ́ sí ilẹ̀ èyítí a ti fi pamọ́ fún kíkọ́ àwọn ilé tèmi, èyítí ó jẹ mọ́ ogún náà, àti àwọn ìpín wọnnì èyítí a ti dárúkọ fún ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery.

35 Àti pé níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, èmi yíò mú àwọn ìbùkún lọ́po ní orí rẹ̀.

36 Ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí òun ó ta àwọn ìpín ilẹ̀ tí a fi sí apákan fún kíkọ́ ìlú nlá ti àwọn ènìyàn mímọ́ mi, níwọ̀nbí a bá sọ ọ́ di mímọ̀ fún un nípa ohùn ti Ẹ̀mí, àti gẹ́gẹ́bí ìmọràn ti èto náà, àti nípa ohùn ti ètò náà.

37 Èyí sì ni ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìríjú náà èyítí èmi ti yàn fún un, fún ìbùkún kan fún òun àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀.

38 Àti níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, èmi yíò mú àwọn ìbùkún lọ́po ní ìlọ́po púpọ̀ ní orí rẹ̀.

39 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney ó ní ní yíyàn fún un àwọn ilé àti ìpín ilẹ̀ ibití ó ngbé nísisìyí, àti ìpín ilẹ̀ àti ilé èyítí ilé iṣẹ́ ọjà títà dúró lé ní orí, àti bákannáà ìpín ilẹ̀ náà èyítí ó wà ní igun apá gúsù ilé iṣẹ́ ọjà títà náà, àti bákannáà ìpín ilẹ̀ ní orí èyítí ibi eérú ṣíṣe wà.

40 Gbogbo èyí ni mo sì ti yàn fún ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney fún iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, fún ìbùkún kan ní orí rẹ̀ àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, fún ànfàní ilé iṣẹ́ ọjà títà náà ti ètò mi èyítí mo ti dá sílẹ̀ fún èèkàn mi ní ilẹ̀ Kirtland.

41 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, èyí ni iṣẹ́ ìríjú èyítí mo ti yàn fún ìránṣẹ́ mi N. K. Whitney, àní gbogbo ilé iṣẹ́ ìtajà yìí, òun àti aṣojú rẹ̀, àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀.

42 Àti níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa àwọn òfin mi mọ́, èyítí mo ti fi fún un, èmi yíò mú àwọn ìbùkún lọ́po ní orí òun àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn rẹ̀, àní àwọn ìbùkún ní ìlọ́po púpọ̀.

43 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, ó ni ìpín ilẹ̀ ní yíyàn fún un èyítí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan fún kíkọ́ ilé mi, èyítí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìwọn ogójì ọ̀pá àti méjìlá ní fífẹ̀, àti bákannáà ogún naà ní orí èyítí bàbá rẹ̀ ngbé nísisìyí;

44 Èyí sì ni ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìríjú èyítí mo ti yàn fún un, fún ìbùkún kan ní orí rẹ̀, àti ní orí bàbá rẹ̀.

45 Nítorí kíyèsíi, èmi ti fi ogún kan pamọ́ fún bàbá rẹ̀, fún àtilẹ́hìn rẹ̀; nítorínáà a ó kàá sí ínú ilé ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré.

46 Èmi yíò sì mú àwọn ìbùkún lọ́po ní orí ilé ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, àní àwọn ìbùkún ní ìlọ́po púpọ̀.

47 Àti nísisìyí, òfin kan ni mo fi fún yín nípa Síónì, pé ẹ̀yin kì yíò da ara yín pọ̀ mọ́ bíi ètò ìṣọ̀kan kan sí àwọn arákùnrin yín ti Síónì, bíkòṣe ní ọ̀nà yìí nìkan—

48 Lẹ́hìn tí a bá ṣètò yín, a ó pè yín ní Ètò Ìṣọkan ti Èèkàn Síónì, Ìlú nlá Kirtland. Àti àwọn arákùnrin yín, lẹ́hìn tí a bá ti ṣètò wọn, a ó pè wọ́n ní Ètò Ìṣọ̀kan ti Ìlú nlá Síónì.

49 A ó sì ṣe ètò wọ̀n ní àwọn orúkọ ti ara wọn, àti ní orúkọ tiwọn; wọn yíò sì ṣe iṣẹ́ okòwò wọn ní orúkọ tiwọn, àti ní àwọn orúkọ ti ara wọn;

50 Ẹ ó sì ṣe iṣẹ́ okòwò yín ní orúkọ tiyín, àti ní àwọn orúkọ ti ara yín.

51 Èyí ni mo sì pàṣẹ pé kí ó jẹ́ síṣe nítorí ìgbàlà yín, àti bákannáà fún igbàlà wọn, ní ìyọrísí lílé wọn jáde àti èyíinì tí yíò wá.

52 Àwọn májẹ̀mú náà tí ó di sísẹ́ nípasẹ̀ ìrékọjá, nípa ojúkòkòrò àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn—

53 Nítorínáà, a tú yín ká bíi ètò ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín, pé a kò so yín pọ̀ bíkòṣe títí di wákàtí yìí mọ́ wọn, bíkòṣe ní ọ̀nà yìí, bí èmi ṣe wí, nípa fífi yá bí a ó ṣe ṣe àdéhùn lati ọwọ́ ètò yìí nínú ìgbìmọ̀, bí àwọn ọ̀rọ̀ yín ṣe fi ààye gbà àti bí ohùn igbìmọ̀ bá ṣe darí.

54 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, òfin kan ni mo fi fún yín nípa iṣẹ́ ìríjú yín èyítí mo ti yàn fún yín.

55 Kíyèsíi, gbogbo àwọn ohun ìní wọ̀nyìí jẹ́ tèmi, tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ asán ni ìgbàgbọ́ yín, àgàbàgebè ni ẹ̀yin sì í ṣe, àwọn májẹ̀mú tí ẹ̀yin ti bá mi dá ti di sísẹ́;

56 Bí àwọn ohun ìní náà bá sì jẹ́ tèmi, nígbànáà ẹ̀yin jẹ́ ìríjú; bíkòṣe bẹ́ẹ̀ ẹ̀yin kìí ṣe ìríjú.

57 Ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi ti yàn fún yín láti jẹ́ ìríjú ní orí ilé mi, àní ìríjú nítòótọ́.

58 Àti fún ìdí èyí ni èmi ti pàṣẹ fún yín lati ṣètò ara yín, àní láti tẹ àwọn ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìwé mímọ́ mi, àwọn ìfihàn èyítí mo ti fi fún yín, àti èyítí èmi yíò fi fún yín, lẹ́hìnwá, láti ìgbà dé ìgbà—

59 Fún ìdí ti kíkọ́ ìjọ mi àti ìjọba ní orí ilẹ̀ ayé, àti láti múra àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ fún àkókò náà nígbàtí èmi yíò gbé pẹ̀lú wọn, èyítí ó súnmọ́ itòsí.

60 Ẹ̀yin yíò sì pèsè fún ara yín ibi kan fún ibi ìṣura, ẹ ó sì yàá sí mímọ́ sí orúkọ mi.

61 Ẹ̀yin yíò sì yan ẹnikan ní ààrin yín láti ṣe àmójútó ibi ìṣura náà, ẹ ó sì yàn án sí ìbùkún yìí.

62 Èdídí kan yíò sì wà ní orí ibi ìṣura náà, gbogbo àwọn ohun mímọ́ ni a ó sì gbé sí ibi ìṣúra náà; ẹnikẹ́ni ní ààrin yín kì yíò sì pèé ni tirẹ̀, tàbí èyíkéyìí apákan rẹ̀, nítorí yíò jẹ ti gbogbo yín pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.

63 Mo sì fi í fún yín láti wákàtí yìí gan; àti nísisìyí ẹ ríi pé, ẹ lọ kí ẹ sì ṣe àmúlò iṣẹ́ ìríjú èyítí mo ti yàn fún yín, yàtọ̀ sí ti àwọn ohun mímọ́, fún ìdí títẹ àwọn ohun mímọ́ wọ̀nyìí bí mo ti wí.

64 Àti pé àwọn èrè ti àwọn ohun mímọ́ náà ni a ó fi sí ibi ìṣura náà, èdídí kan yíó sì wà ní orí rẹ̀; a kì yíò sì lòó tàbí mú un jade kúrò nínú ibi ìṣura náà lati ọwọ́ ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ni èdídí náà kì yíó di títú èyítí a ó fi sí orí rẹ̀, bíkòṣe nípa ohùn ti ètò náà, tàbí nípa àṣẹ.

65 Báyìí ni ẹ ó sì pa àwọn èrè ti àwọn ohun mímọ́ náà mọ́ nínú ibi ìṣura náà, fún àwọn èrò tí ó ní ọ̀wọ̀ àti tí ó jẹ́ mímọ́.

66 Èyí ni a ó sì pè ní ibi ìṣura mímọ́ ti Olúwa; èdídí kan ni a ó sì pamọ́ ní orí rẹ̀ kí ó le jẹ́ mímọ́ àti yíyà sọ́tọ̀ sí Olúwa.

67 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ibi ìṣura míràn ni a ó pèsè sílẹ̀, a ó sì yan akápò kan láti pa ibi ìṣura náà mọ́, èdídí kan ni a ó sì fi sí orí rẹ̀;

68 Gbogbo àwọn owó tí ẹ bá sì gbà nínú iṣẹ́ ìríjú yín, nípa mímú àwọn ohun ìní tí mo ti yàn fún yín dára síi, nínú àwọn ilé, tàbí ní àwọn ilẹ̀, tàbí nínú ẹran ọ̀sìn, tàbí nínú ohun gbogbo bíkòṣe pé ó jẹ́ àwọn ohun kíkọ mímọ́ tí ó sì ní ọ̀wọ̀, èyítí mo ti pamọ́ fún ara mi fún àwọn èrò mímọ́ àti tí ó ní ọ̀wọ̀, ni a ó kó sínú ibi ìṣura ní kánkán tí ẹ bá ti gba àwọn owó náà, ní ọgọgọ́rũn, tàbí ní àdọ́ta-àdọ́ta, tàbí ní ogoogún, tàbí ní ẹẹ́wẹ̀ẹ̀wá, tàbí ní àrààrún.

69 Tàbí ní ọ̀nà míràn, bí ẹnikẹ́ni ní ààrin yín bá gba owó dọ́là márũn ẹ jẹ́ kí ó sọ ọ́ sínú ibi ìṣúra; tàbí bí òun bá gba mẹ́wàá, tàbí ogún, tàbí àádọ́ta, tàbí ọgọ́rũn kan, ẹ jẹ́kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́;

70 Ẹ má sì ṣe jẹ́kí ẹnikẹ́ni ni ààrin yín ó sọ pé ti òun ni; nítorí a kì yíò pèé ní tirẹ̀, tàbí èyíkéyìí apákan rẹ̀.

71 Kì yíò sì sí apákan rẹ̀ tí a ó lò, tàbí mú jade ní ibi ìṣura náà, bíkòṣe nípa ohùn àti ìfohùnṣọ̀kan ti ètò náà.

72 Èyí ní yíò sì jẹ́ ohùn àti ìfohùnṣọ̀kan ti ètò náà—pé ẹnikẹ́ni ní ààrin yín kí ó wí fún akápò: mo nílò èyí láti ràn mí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìríjú mi—

73 Bí ó bá jẹ́ dọ́là márũn, tàbí bí ó bá jẹ́ dọ́là mẹ́wàá, tàbí ogún, tàbí àádọ́ta, tàbí ọgọ́rũn kan, akápò yíò fún un ní iye owó tí òun béèrè láti ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìríjú rẹ̀—

74 Títí tí a ó fi rí òun bí arúfin, àti tí ó fi ara hàn kedere níwájú ìgbìmọ̀ ti ètò náà pé ó jẹ́ aláìṣõtọ́ àti aláìgbọ́n ìríjú.

75 Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbàtí òun bá wà nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbákẹ́gbẹ́, tí ó sì jẹ́ olõtọ́ àti ọlọ́gbọ́n nínú iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, èyí ni yíò jẹ́ àmì rẹ̀ sí akápò náà pé tí akápò kì yíó lè dá dúró.

76 Ṣùgbọ́n bí a bá rí ọ̀rọ̀ ìrékọjá, akápò yíò wà ní abẹ́ ìdarí ìgbìmọ̀ àti ohùn ti ètò náà.

77 Bí a bá sì rí pé akápò jẹ́ aláìṣõtọ́ àti aláìgbọ́n ìríjú, òun yíò wà ní abẹ́ ìdarí ìgbìmọ̀ àti ohùn ti ètò náà, a ó sì mú un kúrò ní àyè rẹ̀, a ó sì yan ẹlòmíràn dípò rẹ̀.

78 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, nípa àwọn gbèsè yín—kíyèsíi ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ san gbogbo àwọn gbèsè yín.

79 Ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú mi, kí ẹ sì gba ìbùkún yìí nípa aápọn àti ìrẹ̀lẹ̀ yín àti àdúrà ìgbàgbọ́.

80 Àti níwọ̀nbí ẹ̀yin bá nṣe aápọn tí ẹ sì ní ìrẹ̀lẹ̀, àti tí ẹ lo àdúrà ìgbàgbọ́, kíyèsíi, èmi yíò rọ ọkàn àwọn tí ẹ jẹ ní gbèsè, títí tí èmi yíò fi rán àwọn ọ̀nà síi yín fún ìtúsílẹ̀ yín.

81 Nítorínáà ẹ kọ̀wé kánkán sí New York kí ẹ sì kọ̀wé ní ìbámu sí èyítí a ó pè fún yín nípa Ẹ̀mí mi; èmi yíò sì mú ọkàn àwọn tí ẹ jẹ ní gbèsè rọ̀, pé kí á mú un jáde kúrò ní iyè wọn láti mú ìpọ́njú wá sí orí yín.

82 Àti níwọ̀nbí ẹ̀yin bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olõtọ́ tí ẹ sì ké pe orúkọ mi, kíyèsíi, èmi yíò fún yín ní ìṣẹ́gun náà.

83 Èmi fi ìlérí kan fún yín, pé a ó gbà yín kúrò lẹ́ẹ̀kan yìí jade ní oko ẹrú yín.

84 Níwọ̀nbí ẹ̀yin bá gba àyè láti yá owó ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀ọ̀rún, tàbí ní ẹgbẹgbẹ̀rún, àní títí tí ẹ ó fi yá èyí tí ó tó láti gba ara yín kúrò ní oko ẹrú, ó jẹ́ ànfàní yín.

85 Kí ẹ sì fi àwọn ohun ìní èyítí mo fi lé yín lọ́wọ́ ṣe ìdúró, lẹ́ẹ̀kan yìí, nípa fífúnni ní àwọn orúkọ yín nípa ìfohùnṣọkan tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́, bí ó bá ṣe dára ní ojú yín.

86 Èmi fún yín ní ànfàní yìí, lẹ́ẹ̀kan yìí; sì kíyèsíi, bí ẹ bá tẹ̀síwájú láti ṣe àwọn ohun èyítí mo ti fi sí iwájú yín, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyìí jẹ́ tèmi, ẹ̀yin sì jẹ́ ìríjú mi, olúwa náà kì yíò sì jọ̀wọ́ ilé rẹ̀ kí ó di títú ká. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.